Ogun Àjàpàdánù Tí A Ń Bá Ìwà Ọ̀daràn Jà
ÌWÉ agbéròyìnjáde Liverpool Daily Post ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fa ọ̀rọ̀ tí ọ̀gá Ọlọ́pàá Ìlú Ńlá kan tẹ́lẹ́ rí sọ yọ pé: “A lè ṣàkóso ìwà ọ̀daràn ní ọ̀sán-kan-òru-kan bí olúkúlùkù ènìyàn bá múra tán láti sapá.” Ní gidi, bí olúkúlùkù ènìyàn bá ṣègbọràn sí òfin, ìwà ọ̀daràn yóò wábi gbà.
Síbẹ̀, ní ibi púpọ̀ jù lọ, ńṣe ni ìwà ọ̀daràn ń pọ̀ sí i. Ìgbà tiwa ni a ń rí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti sọ ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn pé: “Ilẹ̀ ayé sì wá bàjẹ́ ní ojú Ọlọ́run tòótọ́, ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:11)—Wo àpótí tó wà lójú ewé tó kọjú sí èyí.
Ibi Kékeré Ni Ìwà Ọ̀daràn Ti Bẹ̀rẹ̀
Nípa rírú òfin nínú àwọn ohun kéékèèké, ẹnì kan lè di ẹni tí yóò rú u nínú àwọn ohun tí ó túbọ̀ tóbi. Kí olùkọ́ kan lè tẹ òtítọ́ yìí mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́kàn, ó ṣàlàyé pé: “Ibi jíjí pẹ́ńsùlù ní ilé ẹ̀kọ́ ni àwọn tí wọ́n ń fọ́ ilé ìfowópamọ́ ti ń bẹ̀rẹ̀.”
Lẹ́yìn náà, kí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ní ibi iṣẹ́? Àwọn ènìyàn kì í lọ síbi iṣẹ́ nítorí àìsàn tí wọ́n sọ pé ó ń ṣe àwọn, wọn óò sì wá gba àwọn ìpèsè ìrànwọ́ tí wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Ìwà àìṣòtítọ́ yìí wọ́pọ̀ gan-an ju bí ẹnì kan ti lè rò lọ. Fún àpẹẹrẹ, ní Germany, ìpín 6 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọjọ́ tí àwọn ènìyàn ń gbà nítorí àìsàn máa ń bọ́ sí ọjọ́ Wednesday, ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún ń bọ́ sí ọjọ́ Tuesday, ìpín 16 nínú ọgọ́rùn-ún sì ń bọ́ sí ọjọ́ Thursday, síbẹ̀, ìwọ̀n jaburata ìpín 31 nínú ọgọ́rùn-ún ń bọ́ sí àwọn ọjọ́ Monday, tí ti ìpín 37 nínú ọgọ́rùn-ún tí ń bọ́ sí àwọn ọjọ́ Friday sì pọ̀ jù lọ! Ní ti gidi, ṣé àwọn ènìyàn sábà máa ń ṣàìsàn gan-an ní àwọn ọjọ́ Monday àti Friday ni, àbí èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí wọ́n ń gbà jalè?
Àwọn Wo Ní Ọ̀daràn Náà?
Dájúdájú, ìwà ọ̀daràn tí àwọn ènìyàn gbáàtúù ń hù kì í sábà ní ìyọrísí kan náà bí èyí tí àwọn tí wọ́n wà ní ipò agbára ń hù. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ìwà ọ̀daràn olóṣèlú kan, tí ó le gan-an, gbo United States jìgìjìgì débi pé orúkọ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú rẹ̀ tilẹ̀ wá di apá kan èdè Gẹ̀ẹ́sì.
Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Barnhart Dictionary of New English, tú ọ̀rọ̀ náà, “Watergate,” sí “ìwàkiwà, ní pàtàkì èyí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìsapá láti bo ìsọfúnni tí ó lè ba nǹkan jẹ́ tàbí àwọn ìlépa aláìbófinmu mọ́lẹ̀.”a Ó wá fi kún un pé: “Ọ̀ràn Watergate náà fi ipa mánìígbàgbé kan sílẹ̀ lórí èdè tí a ń sọ ní àwọn ọdún 1970. Ọ̀rọ̀ náà mú onírúurú àgbélẹ̀rọ ọ̀rọ̀ àti irú àkànpọ̀ ọ̀rọ̀ tó ní -gate nínú, tí a lò láti tọ́ka sí ìwàkiwà tàbí ìwà ìbàjẹ́, wá sójútáyé.”
Láti ìgbà yẹn, iye Watergate yòó wù kí ó ti ṣẹlẹ̀ ti fi hàn pé ìwà ọ̀daràn ti gbalẹ̀ kan, kódà láàárín àwọn tí ó yẹ kí wọ́n jẹ́ àwòṣàpẹẹrẹ nínú gbígbé òfin ró. Ní Japan, ìwà ìbàjẹ́ olóṣèlú gbalẹ̀ kan gan-an débi tí wọ́n fi ní láti gbé àwọn òfin tuntun jáde láti ṣẹ́pá rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990. Ní 1992, wọ́n gba ipò lọ́wọ́ ààrẹ ilẹ̀ Brazil látàrí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́.
Kò ha ṣe kedere pé ìwà àìtọ́ tí àwọn tí wọ́n wà ní ipò aláṣẹ, títí kan àwọn òbí, àwọn olùkọ́, àti àwọn òṣìṣẹ́ amófinṣẹ ń hù, ń dá kún ìwà ọ̀daràn tí àwọn ènìyàn gbáàtúù ń hù bí?
Ìgbèrò Rere Kò Tó
Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn yóò fohùn ṣọ̀kan pé àwọn ìjọba fẹ́ mú ìwà ọ̀daràn kúrò. Síbẹ̀, òṣìṣẹ́ kan tí ó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ sọ nípa orílẹ̀-èdè rẹ̀ pé: “Ohun tí ìjọba ṣe láti mú kí ìyọrísí ìṣiṣẹ́ ìdájọ́ òdodo yára kánkán, kí ó sì gbéṣẹ́ kò tó nǹkan. Àwọn adájọ́ tí a ní kò tó, nítorí náà, iṣẹ́ ti pá àwọn díẹ̀ tí a ní lórí. Àwọn ọlọ́pàá tí a ní kò tó, wọn kò sì ní èlò iṣẹ́ tí ó tó. Nígbà mìíràn, a kì í fún àwọn ọlọ́pàá lówó oṣù wọn lásìkò, tí èyí sì ń mú kí wọ́n kó sínú ìdẹwò gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.”
Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Ítálì náà, La Civiltà Cattolica, kédàárò nípa “ipò àìrọ́wọ́mú Ìjọba nínú ìfojúkojú pẹ̀lú ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò,” ó tún wá sọ pé: “A mọrírì fífi tí àwọn ẹ̀ka agbófinró àti ẹ̀ka ìdájọ́ ń fara jin gbígbógunti ìwà ọ̀daràn, àmọ́ ó hàn gbangba pé kò tu irun kankan lára ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni okun àti agbára rẹ̀ ń peléke sí i.”
Ó ṣe kedere pé èrò rere tí ìjọba ní láti ṣẹ́pá ìwà ọ̀daràn kò tó. Anita Gradin, kọmíṣọ́nnà ètò ìṣíwọ̀lú àti ìdájọ́ ní ilẹ̀ Yúróòpù, sọ lọ́nà tó bá a mu pé: “A nílò àwọn ìlànà tí ó sàn jù, tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́, fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nínú ogun tí a ń bá òwò fàyàwọ́ àti òwò oògùn líle, kíkó àwọn àjèjì wọ̀lú láìbófinmu àti ìṣíwọ̀lú láìbófinmu, ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò, jìbìtì àti ìwà ìbàjẹ́ jà.”
Báwo Ni Àwọn Òṣìṣẹ́ Agbófinró Ṣe Fara Jin Iṣẹ́ Tó?
Àwọn kan pe bí àwọn aláṣẹ ṣe fara jin bíbá ìwà ọ̀daràn jagun tó níjà. Ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀-èdè kan sọ pé, ó kéré tán, olúkúlùkù ènìyàn “máa ń bẹnu àtẹ́ lu ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ọ̀daràn ní ti ètò ọrọ̀ ajé” ní gbangba. Ó sọ pé, síbẹ̀, gbogbo ènìyàn kọ́ ló ní ìfẹ́ ọkàn gidi láti mú ìwà ọ̀daràn àti ìwà ìbàjẹ́ kúrò. Iye àwọn ènìyàn tí ń pọ̀ sí i—títí kan àwọn òṣìṣẹ́ agbófinró—ni ó hàn kedere pé wọ́n ń wo àbẹ̀tẹ́lẹ̀, jìbìtì, àti olè jíjà bí ọ̀nà àtimókè tí ó ṣètẹ́wọ́gbà.
Gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè kan ṣe sọ ọ́, òtítọ́ náà pé ọ̀pọ̀ àwọn tí “ń hùwà ọ̀daràn ń mú un jẹ” jẹ́ ìdí kan tí kò ṣeé jiyàn lé lórí tí ń fa kí ìwà ọ̀daràn máa pọ̀ sí i. Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ̀jáde kan ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà sọ nípa “bí àwọn ọ̀daràn ṣe ń fìrọ̀rùn lọ láìjìyà.” Ìtẹ̀jáde náà fi kún un pé, èyí “dà bí ohun tí ń sún àwọn ènìyàn gbáàtúù láti lọ hu àwọn ìwà ọ̀daràn tí ó burú jáì.” Èyí rí bí òǹkọ̀wé Bíbélì náà ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Nítorí pé a kò fi ìyára kánkán mú ìdájọ́ ṣẹ lòdì sí iṣẹ́ búburú, ìdí nìyẹn tí ọkàn-àyà àwọn ọmọ ènìyàn fi di líle gbagidi nínú wọn láti ṣe búburú.”—Oníwàásù 8:11.
Kì í ṣe àsọdùn láti wí pé àwọn ìjọba ń bá ìwà ọ̀daràn ja ogun àjàpàdánù. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà, Rheinischer Merkur, sọ pé: “Ẹ̀rù tí ń ba àwọn aráàlú nípa ìwà ọ̀daràn tí ń pọ̀ sí i jinlẹ̀ gan-an, ariwo ẹgbẹ́ òṣèlú tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ tàbí àkọsílẹ̀ oníṣirò tí ń fi hàn pé ipò náà kò burú tó bí ó ti jọ pé ó rí kò sì lè dín in kù.”
Kàkà kí ìwà ọ̀daràn má burú tó bí ó ti jọ pé o rí, òdì kejì rẹ̀ ni ó ṣeé ṣe jù lọ pé kí ọ̀ràn náà jẹ́. Síbẹ̀, àyè wà fún ríretí pé nǹkan yóò dára. Ayé kan tí kò ti ní sí ìwà ọ̀daràn túbọ̀ ń sún mọ́lé sí i, ìwọ́ sì lè wà láàyè láti fojú rẹ rí i. Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò fi ìdí tí a fi sọ bẹ́ẹ̀ hàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A sọ ọ̀ràn Watergate lórúkọ náà nítorí ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ilé kan tí a sọ lórúkọ yẹn ló kó ọ̀ràn náà síta. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìwàkiwà náà mú kí Ààrẹ Richard Nixon ti United States kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀, ó sì mú kí wọ́n fi àwọn mélòó kan lára àwọn olórí olùgbaninímọ̀ràn rẹ̀ sẹ́wọ̀n.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń wo ìwà ọ̀daràn bí ọ̀nà àtimókè tí ó ṣètẹ́wọ́gbà
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ayé Kan Tí Ó Kún fún Ìwà Ipá
BRAZIL: “Ní ìhùwàpadà sí ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá tí ń pọ̀ sí i, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn rọ́ kún àwọn òpópó àgbègbè ìṣòwò ìlú [Rio de Janeiro], wọ́n ń fi ẹ̀rù àti ìbínú hàn látàrí ìwà ọ̀daràn tí ó ti gbé ìlú ńlá wọn dè.”—International Herald Tribune.
CHINA: “Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ ìpàǹpá tún ti ń pa dà wá ní China, ó sì jọ pé apá kò ká àwọn ìwà ọ̀daràn pàtàkì-pàtàkì mọ́. . . . Àwọn ògbóǹkangí ọmọ ilẹ̀ China sọ pé, iye àjọ ìpàǹpá àti ‘ẹgbẹ́ òkùnkùn’ ń pọ̀ sí i ju bí àwọn ọlọ́pàá ti lè kà wọ́n lọ.”—The New York Times.
GERMANY: “Àlàfo tó wà láàárín ìmúratán láti hu ìwà ipá àti ohun tó fa sábàbí kí ẹnì kan ṣe bẹ́ẹ̀ ń kéré sí i láìdábọ̀. Nítorí náà, kò fi bẹ́ẹ̀ yani lẹ́nu pé ìwà ipá ti di ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́.”—Rheinischer Merkur.
GREAT BRITAIN: “Ohun tí ń ṣokùnfà ìwà ipá kì í tó nǹkan mọ́, ó sì túbọ̀ ń ṣeé ṣe sí i pé kí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ kọ́kọ́ hu ìwà ipá.”—The Independent.
GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ: “Ìwà ipá tí a kò lè kó níjàánu, tí a sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè ṣàkóso ń wu olúkúlùkù wa léwu, àti gbogbo ohun tí a ń ṣe—a sì gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.”—The Star.
IRELAND: “Ẹ̀ka àjọ ìpàǹpá bíi ti ẹgbẹ́ oníwà ọ̀daràn ti ta gbòǹgbò ní ìlú ńlá Dublin kíkúnfọ́fọ́ àti ní àwọn àgbègbè ìhà ìwọ̀ oòrùn rẹ̀ tí kò jọjú. Àwọn àjọ ìpàǹpá ń gbára dì dáradára lọ́nà púpọ̀ sí i pẹ̀lú ohun ìjà.”—The Economist.
MEXICO: “Ìwà ọ̀daràn ti yára lọ sókè gan-an láàárín ìwọ̀nba àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ó ń dáni níjì.”—The Wall Street Journal.
NÀÌJÍRÍÀ: “Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ ọlọ́pàá náà, Ọ̀gbẹ́ni Frank Odita ti sọ, agbo ìdílé, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, mọ́ṣáláṣí, ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn ẹgbẹ́ ti kùnà láti ṣe ojúṣe wọn láti máà jẹ́ kí àwọn èwe lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn.”—Daily Champion.
PHILIPPINES: “Mẹ́fà lára ìdílé mẹ́wàá ní Philippines sọ pé àwọn kò nímọ̀lára àìséwu ní ilé àwọn tàbí ní ojú pópó.”—Asiaweek.
RỌ́ṢÍÀ: “Àwọn àjọ ìpàǹpá bí ẹgbẹ́ ọ̀daràn ti sọ ìlú ńlá kan, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tó láàbò jù lọ lágbàáyé nígbà tí ó wà lábẹ́ ìjọba Soviet, di ibi tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìlú ńlá àkànṣe oníwà ọ̀daràn. . . . Ọlọ́pàá lẹ́fútẹ́náǹtì náà, Gennadi Groshikov, sọ pé: ‘Fún ọdún 17 tí mo ti ń ṣe ìwọ́de kiri, n kò tí ì rí i kí ìwà ọ̀daràn pọ̀ tó báyìí ní Moscow, bẹ́ẹ̀ ni n kò tí ì rí ohun tí ó burú tó èyí rí.’”—Time.
TAIWAN: “Ní Taiwan . . . ìwọ̀n olè jíjà, ìfipákọluni àti ìpànìyàn ti yọ́ wọnú àwùjọ níkọ̀ọ̀kan . . . Ní gidi, ìwọ̀n ìwà ọ̀daràn ti ń pọ̀ sí i díẹ̀díẹ̀, àti nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó pọ̀ ju àwọn tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè ìhà Ìwọ̀ Oòrùn lọ.”—The New York Times.
UNITED STATES: “United States ni orílẹ̀-èdè tí ìwà ọ̀daràn ti pọ̀ jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè onílé-iṣẹ́-ẹ̀rọ. . . . Kò sí orílẹ̀-èdè onílé-iṣẹ́-ẹ̀rọ mìíràn tí ó ti ń ṣẹlẹ̀ tó o.”—Time.