“Àwọn Ọmọ Jẹ́ Ẹlẹgẹ́”
‘Àwọn ọmọ jẹ́ ẹlẹgẹ́; èmi yóò máa bá ìrìn àjò náà bọ̀ lọ́nà tí ó rọrùn, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣísẹ̀ àwọn ọmọ.’—Jékọ́bù, bàbá ọlọ́mọ yọyọ, ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa.
HÍHÙWÀ àìda sí àwọn ọmọdé kì í ṣe nǹkan tuntun. Ọ̀làjú ayé àtijọ́—bíi ti àwọn Aztec, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Quechuan tí ń gbé Peru, àti àwọn ará Fòníṣíà—ní orúkọ burúkú ní ti àṣa fífi ọmọdé rúbọ. Àwọn ohun tí a wà jáde nínú ilẹ̀ ní ìlú Carthage ní Fòníṣíà (tó jẹ́ orúkọ àgbègbè kan ní Tunis, Àríwá Áfíríkà) fi hàn pé láàárín ọ̀rúndún karùn-ún sí ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀kẹ́ kan [20,000] ọmọdé ni a fi rúbọ sí òrìṣà tí ń jẹ́ Báálì àti abo-ọlọ́run Tanit! Iye yìí túbọ̀ máa ń bani lẹ́rù tí a bá rántí pé nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ [250,000] péré ni wọ́n sọ pé ó ń gbé Carthage ní àkókò tí nǹkan ń rọ̀ ṣọ̀mù níbẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwùjọ kan tó yàtọ̀ wà látijọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ń pa ọmọdé lára yí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ká lọ́tùn-ún lósì, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà bá àwọn ọmọdé lò yàtọ̀ pátápátá. Jékọ́bù tó jẹ́ bàbá orílẹ̀-èdè yẹn ló fi àpẹẹrẹ yẹn lélẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì, nígbà tí Jékọ́bù ń padà sí ilẹ̀ ìbí rẹ̀, ó ní kí gbogbo àwọn tó ń bá òun lọ rọra rìn kí ìrìn àjò náà má bàa ni àwọn ọmọdé lára. Ó sọ pé: “Àwọn ọmọdé jẹ́ ẹlẹgẹ́.” Nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún sí mẹ́rìnlá ni àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ nígbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 33:13, 14) Àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, Ísírẹ́lì, gba ti àìní àwọn ọmọdé rò, wọ́n sì bọlá fún wọn.
Dájúdájú, àwọn ọmọdé tí a bí nígbà tí a ń kọ Bíbélì ní ohun púpọ̀ láti ṣe. Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, lójú méjèèjì ni àwọn bàbá ń kọ́ àwọn ọmọkùnrin ní iṣẹ́ àgbẹ̀, tàbí iṣẹ́ ọwọ́ bíi káfíńtà. (Jẹ́nẹ́sísì 37:2; 1 Sámúẹ́lì 16:11) Nílé, àwọn ìyá ń kọ́ àwọn ọmọbìnrin ní iṣẹ́ ilé tí yóò ṣàǹfààní fún wọn nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Olùṣọ́ àgùntàn ni Rákélì, ìyàwó Jékọ́bù, nígbà tó wà lọ́mọge. (Jẹ́nẹ́sísì 29:6-9) Àwọn ọmọdébìnrin máa ń ṣiṣẹ́ nínú oko lákòókò ìkórè ọkà àti nínú ọgbà àjàrà. (Rúùtù 2:5-9; Orin Sólómọ́nì 1:6)a Abẹ́ ìdarí onífẹ̀ẹ́ àwọn òbí ni wọ́n ti máa ń ṣe irú àwọn iṣẹ́ yẹn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ ìwé kì í gbẹ́yìn.
Bákan náà, àwọn ọmọ kéékèèké ní Ísírẹ́lì mọ irú ìdùnnú tó wà nínú fàájì àti eré ṣíṣe. Wòlíì Sekaráyà sọ nípa ‘àwọn ojúde ìlú ńlá tó kún fún àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin tí ń ṣeré.’ (Sekaráyà 8:5) Jésù Kristi sì mẹ́nu kan àwọn ọmọdé tí wọ́n jókòó ní àwọn ibi ọjà tí wọ́n ń fọn fèrè tí wọ́n sì ń jó. (Mátíù 11:16, 17) Kí ló fa yíyẹ́ àwọn ọmọdé sí lọ́nà tó lọ́lá bẹ́ẹ̀?
Àwọn Ìlànà Gíga
Níwọ̀n bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń ṣàyẹ̀wò àwọn òfin Ọlọ́run, wọn kò hùwà àìda sí àwọn ọmọ wọn tàbí kí wọ́n yàn wọ́n jẹ. (Fi Diutarónómì 18:10 wé Jeremáyà 7:31.) Wọ́n ka àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn sí “ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” “èrè.” (Sáàmù 127:3-5) Òbí kan ka àwọn ọmọ rẹ̀ sí ‘àwọn àgélọ́ igi ólífì tó yí tábìlì rẹ̀ ká’—àwọn igi ólífì sì ṣeyebíye gan-an ní àwùjọ àwọn àgbẹ̀ yẹn! (Sáàmù 128:3-6) Òpìtàn Alfred Edersheim sọ pé yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, àwọn ará Hébérù ìgbàanì ní ọ̀rọ̀ mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń lò fún ọmọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì jẹ́ fún ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn. Ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Dájúdájú, ó ní láti jẹ́ pé àwọn tí ń fìṣọ́ra kíyèsí ìgbésí ayé àwọn ọmọdé débi tí wọ́n fi lè ṣàpèjúwe ìpele kọ̀ọ̀kan nínú rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì sún mọ́ wọn gan-an.”
Ní sànmánì Kristẹni, a gba àwọn òbí nímọ̀ràn láti ṣàyẹ́sí àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì fún wọn lọ́wọ̀. Jésù fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ lọ́nà tó ń gbà bá ọmọ àwọn ẹlòmíràn lò. Ní ìgbà kan, nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ń parí lọ, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ọmọ wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó hàn gbangba pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rò pé ọwọ́ rẹ̀ dí gan-an tí kò fi ní fẹ́ kí a wá yọ òun lẹ́nu, wọ́n bá gbìyànjú láti lé àwọn ènìyàn náà padà. Ṣùgbọ́n Jésù bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Jésù tilẹ̀ “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀.” Kò sí àníàní pé ó ka àwọn ọmọdé sí ẹni tó ṣeyebíye, tó sì yẹ ká ṣe jẹ́jẹ́.—Máàkù 10:14, 16; Lúùkù 18:15-17.
Ní àkókò mìíràn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí fún àwọn bàbá pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.” (Kólósè 3:21) Ní ìbámu pẹ̀lú òfin yìí, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni nígbà náà àti lónìí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn di ẹni tí a ń fi iṣẹ́ pá lórí. Wọ́n mọ̀ pé kí ọwọ́ ìtọ́jú lè yọ lára àwọn ọmọ wọn, kí ìmọ̀lára wọ́n lè jí pépé, kí wọ́n sì lè ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí, wọ́n nílò àyíká onífẹ̀ẹ́, tí a ti bìkítà fún wọn, tí ó sì láàbò. Ó yẹ kí ìfẹ́ gidi tí àwọn òbí ní fún àwọn ọmọ wọ́n hàn gbangba. Èyí yóò kan ṣíṣàìjẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n ṣiṣẹ́ lábẹ́ àwọn ipò tí yóò sọ wọ́n di ahẹrẹpẹ.
Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Òní
Lóòótọ́, “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” ni a ń gbé. (2 Tímótì 3:1-5) Nítorí ètò ọrọ̀ ajé tí kò dára, ó lè pọndandan fún ọ̀pọ̀ ìdílé, pàápàá ìdílé àwọn Kristẹni, láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n máa ṣiṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, kò sí ohun tó burú nínú iṣẹ́ tó gbámúṣé tó sì ń kọ́ àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lè mú kí ìdàgbàsókè ọmọ ní ti ìrísí, èrò orí, nípa tẹ̀mí, ìwà rere, tàbí ìṣesí láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà sunwọ̀n sí i láìṣèdíwọ́ fún ẹ̀kọ́ ìwé tó pọndandan, eré ìtura níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti ìsinmi tó pọndandan.
Láìsí àníàní, àwọn Kristẹni òbí ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ wọn, kì í ṣe bí ẹrú lọ́nà kan ṣáá lábẹ́ àwọn agbanisíṣẹ́ oníwàkíwà, tí kì í gba tẹni rò, tó ya òkú òǹrorò. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ rí i dájú pé irú iṣẹ́ èyíkéyìí tí àwọn ọmọ wọ́n bá ń ṣe kò ní fi wọ́n sínú ipò tí a ó ti máa fìyà jẹ wọ́n, tí a ó ti máa bá wọn ṣèṣekúṣe, tàbí tí a ò ní gba ti ìmọ̀lára wọn rò. Bákan náà, wọn ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn wà nítòsí wọn. Lọ́nà yìí, wọ́n lè mú ipò wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni nípa tẹ̀mí ṣẹ, èyí tí a gbé karí Bíbélì tó sọ pé: “Kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n [ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:6, 7.
Síwájú sí i, a ní kí Kristẹni máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ó sì ní ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. (1 Pétérù 3:8) A fún un níṣìírí láti máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.” (Gálátíà 6:10) Bí a bá ní láti fi irú àwọn ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ hàn sí gbogbo ènìyàn, mélòómélòó ni a ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọmọdé! Ní ṣíṣègbọràn sí Òfin Oníwúrà—“gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn”—àwọn Kristẹni kò jẹ́ hùwà àìda sí ọmọ àwọn ẹlòmíràn, yálà wọ́n jẹ́ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí wọn kì í ṣe Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn. (Mátíù 7:12) Ní àfikún sí i, níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ti jẹ́ olùpa-òfin-mọ́, wọ́n ń fẹ́ láti ṣọ́ra kí wọ́n má bàa rú òfin ìjọba ní ti gbèǹdéke tí a dá lé ọjọ́ orí àwọn tí ń ṣiṣẹ́ fún wọn.—Róòmù 13:1.
Ojútùú Gidi Náà
Ọjọ́ iwájú ńkọ́? Nǹkan yóò ṣẹnuure fún àwọn ọmọdé àti àgbàlagbà lọ́jọ́ iwájú. Ó dá àwọn Kristẹni tòótọ́ lójú pé ìjọba kan tí yóò kárí ayé tí Bíbélì pè ní “ìjọba ọ̀run” ni ojútùú tí yóò mú ìṣòro àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ kúrò pátápátá. (Mátíù 3:2) Àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run ti ń gbàdúrà fún èyí láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, Ìjọba yìí yóò mú àwọn ipò tí ń fà á tí àwọn ọmọdé fi ń ṣiṣẹ́ kúrò. Yóò mú ipò àìní kúrò. “Dájúdájú, ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.” (Sáàmù 67:6) Ìjọba Ọlọ́run yóò rí i dájú pé olúkúlùkù ènìyàn kọ́ ẹ̀kọ́ tó gbámúṣé tí a gbé karí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run. “Nígbà tí àwọn ìdájọ́ bá ti ọ̀dọ̀ [Ọlọ́run] wá fún ilẹ̀ ayé, òdodo ni àwọn olùgbé ilẹ̀ eléso yóò kọ́ dájúdájú.”—Aísáyà 26:9.
Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ètò ọrọ̀ ajé tí ń mú kí ẹnì kan lọ́lá ju ẹnì kan lọ kúrò. Ìyàsọ́tọ̀ ìran, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ọjọ́ orí, tàbí ẹ̀yà kò ní sí nígbà náà nítorí pé òfin tí yóò borí nínú ìjọba yẹn yóò jẹ́ òfin ìfẹ́, títí kan òfin tó wí pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Lábẹ́ irú ìjọba òdodo yẹn tí ó kárí ayé, ìṣòro àṣà kíkó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Èyí kò sọ àwọn obìnrin di ẹni tí a rẹ̀ nípò wálẹ̀ sí mẹ́ńbà ìdílé onípò rírẹlẹ̀ tó wúlò fún kìkì iṣẹ́ ilé tàbí iṣẹ́ oko. Àpèjúwe “aya tí ó dáńgájíá” nínú ìwé Òwe fi hàn pé kì í ṣe àbójútó ilé nìkan ni obìnrin tó wà nílé ọkọ lè ṣe ṣùgbọ́n ó tún lè bójútó ọ̀ràn dúkìá ilé àti ilẹ̀, kí ó dá oko tí ń mú irè wá, kí ó sì ṣe òwò kan tó mọ níwọ̀n.—Òwe 31:10, 16, 18, 24.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìyálóde Àwọn Aṣẹ́wó Dá Àwọn Ọmọbìnrin Tó Ń Kó Ṣiṣẹ́ Aṣẹ́wó Sílẹ̀
ỌDÚN mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni Ceciliab fi ní ilé aṣẹ́wó tí àwọn ènìyàn sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Caribbean. Ó ra ọmọdébìnrin bíi méjìlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́ẹ̀kan náà, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún méjìdínlógún. Kì í ṣe pé àwọn ọmọdébìnrin náà fẹ́ wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n wà níbẹ̀ nítorí gbèsè tí àwọn ẹbí wọn jẹ. Cecilia bá wọn san àwọn gbèsè wọn, ó sì kó àwọn ọmọdébìnrin náà láti lọ máa ṣiṣẹ́ fún un. Owó tí wọ́n ń pa ló fi ń ra oúnjẹ fún wọn tó sì fi ń tọ́jú wọn, ó sì tún ń yọ díẹ̀ lára rẹ̀ tó fi ń dí owó tó fi rà wọ́n. Ó máa ń pẹ́ gan-an kí wọ́n tó lè di òmìnira. Kì í jẹ́ kí àwọn ọmọdébìnrin náà jáde nílé àyàfi tí ẹ̀ṣọ́ kan bá tẹ̀ lé wọn.
Cecilia ṣì rántí ọ̀rọ̀ ọmọdébìnrin kan dáadáa. Ìyá ọmọdébìnrin aṣẹ́wó kan máa ń wá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti gba àwọn àpótí oúnjẹ—oúnjẹ tí “iṣẹ́” tí ọmọbìnrin rẹ̀ ń ṣe ń mú wá. Ọmọdébìnrin náà ń tọ́ ọmọkùnrin kan. Kò lè ṣiṣẹ́ láti san gbèsè rẹ̀ mọ́, kò sì nírètí pé òun lè ní òmìnira mọ́ láyé òun. Ó pa ara rẹ̀ lọ́jọ́ kan, ó sì kọ̀wé sílẹ̀ tó fi fa ọmọ rẹ̀ lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́. Cecilia tọ́ ọmọkùnrin náà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ mẹ́rin tí òun náà bí.
Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin tí Cecilia bí bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n rọ Cecilia láti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ṣùgbọ́n ó kọ́kọ́ kọ̀ nítorí pé kò mọ ìwé kọ bẹ́ẹ̀ sì ni kò mọ̀ ọ́n kà. Àmọ́, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bó ṣe ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń jíròrò nínú Bíbélì, irú ìfẹ́ àti sùúrù tí Ọlọ́run ní wá ń yé e, ó sì wá mọyì ọ̀nà tó ń gbà dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini. (Aísáyà 43:25) Nítorí pé òun fúnra rẹ̀ nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí a ṣe ń kọ̀wé tí a sì ń kàwé. Bí ìmọ̀ Bíbélì tó ń ní ṣe ń pọ̀ sí i, ó wá rí ìdí tí ó fi ní láti mú ara rẹ̀ bá ìlànà ìwà rere gíga ti Ọlọ́run mu.
Ó ya àwọn ọmọdébìnrin náà lẹ́nu lọ́jọ́ kan tó wí fún wọn pé kí wọ́n máa lọ! Ó ṣàlàyé pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dùn mọ́ Jèhófà nínú rárá. Kò sí èyí tó san owó tí wọ́n jẹ ẹ́ padà nínú wọn. Ṣùgbọ́n méjì lára wọn dúró tì í, wọ́n sì ń gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀kan nínú wọn wá di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi níkẹyìn. Ó ti pé ọdún mọ́kànlá báyìí tí Cecilia ti ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tó ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò wu Ọlọ́run.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
b Kì í ṣe orúkọ rẹ̀ gangan ni.