Ó Dájú Pé Ewu Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Kò Tíì Kásẹ̀ Nílẹ̀
“Pípọ̀ tí àwọn ohun ìjà alágbára ń pọ̀ sí i ti wá di ohun tó ń jáni láyà jù lọ tí pílánẹ́ẹ̀tì yìí ń kojú rẹ̀.”—CRITICAL MASS, TÍ WILLIAM E. BURROWS ÀTI ROBERT WINDREM KỌ
NÍGBÀ tí ọ̀yẹ̀ là ní January 25, 1995, àwòrán ìdágìrì ewu kan dédé yọ lójú àwọn awò ẹ̀rọ tí ń kìlọ̀ ewu káàkiri ìhà àríwá Rọ́ṣíà. Rọ́kẹ́ẹ̀tì kan ti gbéra láti etíkun orílẹ̀-èdè Norway! Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ tí ń kìlọ̀ ewu ta Moscow lólobó pé ó ṣeé ṣe kí bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan já lu ilẹ̀ wọn. Láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan, wọ́n ti gbé àpò kan lé ààrẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà lọ́wọ́, àwọn ìhùmọ̀ abánáṣiṣẹ́ tó máa fi pàṣẹ pé kí àwọn náà rọ̀jò ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé padà ló wà nínú rẹ̀. Ó jọ pé ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé àjàkú-akátá yóò bẹ́ sílẹ̀ láìpẹ́.
Ọpẹ́lọpẹ́ pé wọ́n lo ìkóra-ẹni-níjàánu, wọ́n wá rí i pé bí rọ́kẹ́ẹ̀tì náà ṣe ń bọ̀ kò lè ṣèjàǹbá fún Rọ́ṣíà. Ẹ̀yìn náà ni wọ́n wá gbọ́ pé àwọn ohun èlò ìwádìí nípa wíwojú ọjọ́ sàsọtẹ́lẹ̀ ló wà nínú rọ́kẹ́ẹ̀tì náà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Washington Post sọ pé: “Ìwọ̀nyí lè jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àkókò tó léwu jù lọ nínú sànmánì olóhun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé yìí. Wọ́n rọra fi hàn wá bí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà rọ̀jò ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé agbékánkán-ṣiṣẹ́ tí wọ́n lò nígbà Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ṣì ṣe gbéṣẹ́ tó, àti bó ṣe lè ṣèèṣì yọrí sí àgbákò ńlá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbáradíje tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá ti dópin.”
Wíwà Lójúfò Láti Rọ̀jò Ọta Tí A Ti Kẹ́ Sílẹ̀
Fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, ìdúró tí Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà mú lórí ọ̀ràn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé dá lórí èròǹgbà ìhalẹ̀mọ́ra tí a mọ̀ sí àmúdájú ìparun tọ̀túntòsì. Ọ̀kan pàtàkì lára èròǹgbà àmúdájú ìparun tọ̀túntòsì ni ìwéwèé tí wọ́n pè ní ìrọ̀jò-ọta tí a bá rí àmì ìkìlọ̀. Èyí ń mú un dá ìhà méjèèjì lójú lọ́nà líle pé bí àwọn bá kọ́kọ́ rọ̀jò ọta, ọ̀tá wọn á rọ̀jò ọta padà tìrìgàngàn kí ọta àwọn tiẹ̀ tó dé ibi tí wọ́n rán an lọ. Ohun kejì tó ṣe pàtàkì lára èròǹgbà àmúdájú ìparun tọ̀túntòsì ni ìwéwèé tí ń jẹ́ ìrọ̀jò-ọta tí ọ̀tá bá rọ̀jò ọta luni. Èyí ń tọ́ka sí agbára láti gbẹ̀san kódà lẹ́yìn tí ọta àwọn ọ̀tá bá ti ṣèjàǹbá tán.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ náà ti kásẹ̀ nílẹ̀, ìjì èròǹgbà àmúdájú ìparun tọ̀túntòsì ṣì ń jà lórí aráyé. Òótọ́ ni pé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti Rọ́ṣíà ti dín àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí wọ́n ń tò jọ pelemọ kù gan-an—àwọn kan sọ pé ó ti dín kù tó ìdajì—ṣùgbọ́n ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ṣì wà. Nítorí náà, àwọn kan ṣì lè ṣèèṣì rọ̀jò ọta tàbí kí wọ́n rọ̀jò ọta láìgbàṣẹ. Àti pé nítorí pé orílẹ̀-èdè méjèèjì ṣì ń bẹ̀rù pé èrò náà pé ọwọ́ ẹnì kan lè yá ju ti èkejì lọ, tí wọ́n rò pé kò lè ṣẹlẹ̀, lè wá ṣẹlẹ̀, ni wọ́n ṣì ṣe ní ohun ìjà rẹpẹtẹ tí wọ́n ti kẹ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì wà lójúfò láti rọ̀jò wọn níṣẹ̀ẹ́jú akàn.
Lóòótọ́, ní ọdún 1994, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà àti Rọ́ṣíà ṣàdéhùn láti má kọjú àwọn ohun ìjà atamátàsé síra wọn mọ́. Ìwé ìròyìn Scientific American sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyípadà yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ tó ṣètẹ́wọ́gbà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà já mọ́ nǹkan kan tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ogun. Àwọn tí ń darí ohun ìjà lè tún tẹ àwọn nọ́ńbà ibi ìfojúsùn sínú kọ̀ǹpútà tí ń tọ́ ẹ̀rọ arọ̀jò bọ́ǹbù wọn sọ́nà ní ìṣẹ́jú akàn.”
Ṣé Kì Í Ṣe Pé Àwọn Ohun Ìjà Tuntun Ń Bọ̀ Lọ́nà?
Ká má gbàgbé ṣá o pé ìwádìí ṣì ń bá a lọ ní pẹrẹu nípa àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, wọ́n sì ń rọ àwọn tuntun. Fún àpẹẹrẹ, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, iye owó tí a ń wéwèé lọ́dọọdún láti ná lórí irú àwọn ohun ìjà bẹ́ẹ̀ jẹ́ nǹkan bí bílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ dọ́là! Ní ọdún 1997, ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé: “Kò ṣeé gbà gbọ́ pé Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ń ná ju iye tó ná nígbà ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀ lọ sórí pípa àwọn ẹ̀rọ ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé rẹ̀ mọ́. Eélòó kan lára owó náà ni a sì ti yà sọ́tọ̀ fún àwọn ètò tó rúni lójú, tí àwọn tó ta kò ó sọ pé ó fẹ́ jọ àkọ̀tun ìdíje ohun ìjà ogun.”
Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn ti wà nípa iṣẹ́ ẹlẹ́gbàágbèje dọ́là tí ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà dáwọ́ lé tí wọ́n pè ní Ètò Àkóso àti Àbójútó Ìtòpelemọ Nǹkan Ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ète tó hàn síta tí wọ́n ṣe ń ṣe ètò náà jẹ́ láti máa bójú tó àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tó ti wà ná, àwọn tó ta kò ó sọ pé ó tún ń ṣiṣẹ́ fún ète burúkú kan. Ìwé ìròyìn The Bulletin of the Atomic Scientists sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìwéwèé wà fún ṣíṣàyípadà, ṣíṣàtúnṣe, ìmúbágbàmu, àti pípààrọ̀ ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé—kì í ṣe láti wulẹ̀ mú kí ó pẹ́ sí i níbi tí a tò ó pelemọ sí . . . ṣùgbọ́n láti mú kí ó ‘sunwọ̀n sí i’ pẹ̀lú.”
Ní ọdún 1997, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí bínú nítorí ṣíṣe bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan tí wọ́n pè ní B-61, tó lágbára láti kọ́kọ́ wọ inú ilẹ̀ kó tó bú gbàù. Lọ́nà yìí, ó lè ba ibùdó ìṣàkóso ti àwọn ológun, àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, àti ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tó wà lábẹ́ ilẹ̀ jẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ ń sọ pé ó wulẹ̀ jẹ́ àtúntò bọ́ǹbù tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ ni, àwọn tó ta kò ó sọ pé bọ́ǹbù tuntun ni—èyí já sí pé ìjọba Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà tàpá pátápátá sí ìlérí tó ṣe pé òun ò ní ṣe àwọn ohun ìjà tuntun mọ́.
Ká má fọ̀rọ̀ gùn, Ted Taylor, tó jẹ́ ògbógi nípa èròjà ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ní Yunifásítì Princeton, sọ pé: “Mo gbà pé irú ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ (ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà) ń lọ lọ́wọ́ ní Rọ́ṣíà, ilẹ̀ Faransé, Jámánì àti ní àwọn ibòmíràn, mo sì gbà pé àwọn kan lára àwọn iṣẹ́ tí a ń dáwọ́lé ń sin ayé lọ sínú àkọ̀tun ìdíje ohun ìjà ogun.” Àwọn alátakò tún sọ pé àwọn tó ń ṣe àwọn ohun ìjà náà fúnra wọn ló ń ṣonígbọ̀wọ́ ìwádìí, ìdàgbàsókè, àti àpilẹ̀ṣe àwọn ohun ìjà tuntun náà lójú méjèèjì. Ó lè jẹ́ ìgbéraga tí a ṣẹ́pá rẹ̀, ipò iyì tí ń dín kù, àti ìṣòro owó ni ohun bàbàrà tó ń sún àwọn ọ̀jáfáfá onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wọ̀nyí láti máa pàrọwà pé kí a tún bẹ̀rẹ̀ ìwádìí nípa ohun ìjà.
Àwọn Orílẹ̀-Èdè Mìíràn Ń Ní Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé
Láfikún sí i, àwọn ìyípadà tún wà nínú ọ̀ràn ìṣèlú lágbàáyé. Bó ti máa ń rí tẹ́lẹ̀, orílẹ̀-èdè márùn-ún ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ olóhun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, àwọn ni: China, ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àti Rọ́ṣíà. Àmọ́, àwọn èèyàn ti wá mọ̀ níbi gbogbo pé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ti ń ṣe àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Fún àpẹẹrẹ, Íńdíà àti Pakistan dán ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé wọn wò láìpẹ́ yìí, èyí sì dẹ́rù ba àwọn èèyàn pé ìdíje ohun ìjà ogun tó lágbára yóò ṣẹlẹ̀ ní Ìlà Oòrùn gúúsù Éṣíà. Algeria, Iran, Iraq, àti North Korea wà lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí a fura sí pé àwọn náà ní ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lọ́wọ́. Ó lé ní ọgọ́sàn-án orílẹ̀-èdè tó fọwọ́ sí Àdéhùn Fífòpinsí Ìtànkálẹ̀ Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé lọ́dún 1970. Àmọ́ títí di báyìí, àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan tí gbogbo ayé ń fura sí pé wọn ò fẹ́ sọ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe fún ẹnikẹ́ni ní ti ọ̀ràn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò tíì fọwọ́ sí àdéhùn náà.
Ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Àwọn ògbógi tí ń rí sí ọ̀ràn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí ń pọ̀ rẹpẹtẹ ṣì gbà gbọ́ pé ibi tí ewu wà jù ni ọ̀ràn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tí àwọn aṣáájú wọn ń fẹ́ ní nǹkan ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tiwọn.” Àwọn alákìíyèsí kan ronú pé Àdéhùn Fífòpinsí Ìtànkálẹ̀ Ohun Ìjà Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí wọ́n ṣe náà kò wulẹ̀ lè dá àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti pinnu láti ní ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti àwọn ohun èlò tí wọ́n á fi ṣe ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tiwọn ní bòókẹ́lẹ́ dúró, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfìyàjẹni wà fún un. James Clapper, tó jẹ́ ọ̀gá ní Ẹ̀ka Ìgbèjà Ìlú Tó Ń Bójú Tó Ìsọfúnni Nípa Ọ̀tá ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Tó bá fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti lágbára láti to ohun ìjà [oníkẹ́míkà, oníkòkòrò àrùn, tàbí ọ̀gbálẹ̀gbáràwé] pọ̀ mọ́ ohun ìjà tí wọ́n ṣe ládùúgbò wọn.”
Bákan náà ni kò jọ pé gbogbo orílẹ̀-èdè yóò juwọ́ sílẹ̀ fún yíyọ tí a ń yọ wọ́n lẹ́nu láti fòfin de dídán ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé wò. Nígbà tí a rọ àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan láti fọwọ́ síwèé Àdéhùn Ìfòfinde Dídán Gbogbo Ohun Ìjà Wò ní ọdún 1996, ọ̀rọ̀ olóòtú kan nínú ìwé ìròyìn Asiaweek sọ pé: “Ọ̀rọ̀ dùn lẹ́nu àwọn ará Amẹ́ríkà tàbí àwọn ará Yúróòpù láti máa wàásù ìfòfinde dídán ohun ìjà wò, nítorí pé àwọn ti dán gbogbo èyí tí wọ́n fẹ́ wò tán lára àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, ohun tó kù ni pé kí wọ́n máa wá lo àwọn ìsọfúnni tí wọ́n ti kó jọ.”
Bí Fàyàwọ́ Èròjà Bọ́ǹbù Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé àti Ìpániláyà Ṣe Kanra
Àwọn kan ronú pé ewu tó burú jù ni pé ẹgbẹ́ àwọn apániláyà kan lè lọ ní ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan kí wọ́n sì yìn ín—tàbí ó kéré tán, kí wọ́n halẹ̀ láti yìn ín—kí wọ́n baà lè fi tipátipá béèrè ohun tí wọ́n fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba. Àwọn èèyàn tún ń bẹ̀rù pé ẹgbẹ́ ọ̀daràn kan tún lè lo àwọn èròjà onítànṣán olóró láti fipá gba owó ńlá lọ́wọ́ ìjọba tàbí ilé iṣẹ́ ńlá kan. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Scientific American ṣàlàyé pé: “Yóò rọrùn gidigidi fún afipágbowó tó ń lo èròjà bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé láti jẹ́ kí àwọn èèyàn gba òun gbọ́ nípa fífi díẹ̀ lára èròjà náà sílẹ̀ fún àyẹ̀wò. Híhalẹ̀ lẹ́yìn náà pé òun yóò dà á sáfẹ́fẹ́ tàbí orísun omi, tàbí pé òun yóò tilẹ̀ yin díẹ̀ lára èròjà bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé náà, lè fún un lágbára dé àyè kan.” Àwọn agbèfọ́ba ti táṣìírí àwọn kan tó ń gbìyànjú láti ṣe fàyàwọ́ èròjà bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Èyí tún ń mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ máa bẹ̀rù pé ó lè jẹ́ òótọ́ pé ẹgbẹ́ àwọn afàjọ̀gbọ̀n ẹ̀dá ń gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé.
Lóòótọ́, àwọn alálàyé kan sọ pé ṣíṣe fàyàwọ́ èròjà bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kì í ṣe ewu bàbàrà kan. Wọ́n sọ pé, àwọn èròjà tó ti tọwọ́ ẹnì kan dé ọwọ́ ẹlòmíràn kò tó nǹkan rárá, àti pé bó yẹ̀ ní ìwọ̀nba díẹ̀, ọ̀pọ̀ lára irú èròjà bẹ́ẹ̀ kò tóó fi ṣe ohun ìjà. Bó ti wù kó rí, ìwé ìròyìn Scientific American rán àwọn òǹkàwé létí pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo ọjà òkùnkùn tó wà, kékeré bín-ń-tín ni wọ́n máa ń gbé síta, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdí tí ọ̀ràn ti ọjà òkùnkùn tí wọ́n ti ń ta àwọn èròjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé fi máa yàtọ̀. . . . Yóò jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti gbà gbọ́ pé àwọn aláṣẹ kì í jẹ́ kí wọ́n kó ohun tó lé ní ìpín ọgọ́rin nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn èròjà náà wọ̀lú. Ní àfikún sí i, jíjẹ́ kí wọ́n kó ìwọ̀nba kéréje wọlé pàápàá lè yọrí sí nǹkan ńlá.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àṣírí tí a pa mọ́ dáadáa ni wọ́n fi ọ̀ràn iye tó jẹ́ gan-an ṣe, a fojú díwọ̀n pé a nílò nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́ta sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n èròjà uranium tí a ṣiṣẹ́ lé lórí tàbí bíi kìlógíráàmù kan sí mẹ́jọ èròjà plutonium tó jẹ́ ìsọ̀rí èyí tí wọ́n fi ń ṣe ohun ìjà láti ṣe bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan. Ó ń dùn mọ́ àwọn tí ń ṣe fàyàwọ́ nínú pé kìlógíráàmù méje èròjà plutonium fẹ́rẹ̀ẹ́ kún agolo ọtí ẹlẹ́rìndòdò kan. Àwọn kan tiẹ̀ rò pé èròjà plutonium tó jẹ́ ìsọ̀rí èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìhùmọ̀ tí ń darí ìgbéjáde agbára átọ́míìkì—tí ó rọrùn láti tètè rí rà ju ti ìsọ̀rí èyí tí wọ́n fi ń ṣe ohun ìjà—ni a lè fi ṣe àgbélẹ̀rọ bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan, ṣùgbọ́n tó lè ṣèparun. Bí ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi ṣe sọ, bí a kò bá dáàbò bo àwọn èròjà onítànṣán olóró tí a kó jọ dáadáa, ó lè rọrùn láti tètè jí wọn kó ju bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rò lọ. Mikhail Kulik tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ní Rọ́ṣíà, ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Ó jọ pé àwọn èèyàn ń dáàbò bo ọ̀dùnkún dáadáa lónìí ju àwọn èròjà onítànṣán olóró lọ.”
Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ẹ̀rù ti ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ń dá bani, bí ewu tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, ṣì ń fì dirodiro lórí aráyé. Ìrètí kankan ha wà pé ó ṣeé mú kúrò bí?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
“Àwọn ògbógi tí ń rí sí ọ̀ràn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí ń pọ̀ rẹpẹtẹ ṣì gbà gbọ́ pé ibi tí ewu wà jù ni ọ̀ràn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè tí àwọn aṣáájú wọn ń fẹ́ ní ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tiwọn.”—Asiaweek
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ewu Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn àti Oníkẹ́míkà
Àwọn orílẹ̀-èdè oníjàgídíjàgan tí wọ́n tòṣì gan-an débi pé wọn kò lè ṣe ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lè wá ṣe àwọn ohun ìjà atamátàsé tí kì í fi bẹ́ẹ̀ rìn jìnnà tí wọ́n fi gáàsì olóró tàbí àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn ṣe. Irú àwọn wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tí owó àwọn òtòṣì ká. Ní gidi, ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé ń bẹ̀rù pé irú ìhùmọ̀ ogun bẹ́ẹ̀ mà tún lè lọ di ohun ìjà tí àwọn apániláyà yàn láàyò.
Bó ti wù kó rí, àwọn ohun ìjà oníkòkòrò àrùn àti oníkẹ́míkà lè ṣèpalára tí wọ́n fẹ́ ṣe, kódà bí kò bá sí àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń rọ̀jò wọn tí a fi ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga ṣe. William Cohen tó jẹ́ Olùdarí Ètò Ààbò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ ní November 1997 pé: “Níwọ̀n bí ìlọsíwájú ti wà nínú ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, tí ayé sì ti lu jára, agbára ìrọ̀jò àrùn, ikú, àti ìparun sórí ẹ̀dá ti wá pọ̀ gan-an lónìí. Ayírí èèyàn kan tàbí àwùjọ àwọn agbawèrèmẹ́sìn tí ìgò kẹ́míkà, àkàṣù bakitéríà tí ń fa àrùn, tàbí tí àgbélẹ̀rọ bọ́ǹbù ọ̀gbálẹ̀gbáràwé wà lọ́wọ́ wọn lè halẹ̀ tàbí kí wọ́n pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n bá dá rúkèrúdò sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Ọ̀rọ̀ tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ ló kùkù ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn apániláyà ẹlẹ́gbẹ́ awo tú kẹ́míkà sarin, èròjà tí ń ba iṣan ara jẹ́, sílẹ̀ láàárín àwọn èrò ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ ní Tokyo ní March 1995. Èèyàn méjìlá ló kú síbẹ̀, tí ẹgbẹ̀rún márùn-ún lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [5,500] sì fara pa.
Leonard Cole tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ìṣèlú sọ pé: “Bí fífi ohun ìjà oníkẹ́míkà kọluni bá ń dẹ́rù bani, ohun ìjà oníkòkòrò àrùn á páni láyà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà kì í ṣe abẹ̀mí, ṣùgbọ́n àwọn oníbakitéríà, onífáírọ́ọ̀sì, àti àwọn èròjà abẹ̀mí mìíràn lè ràn káàkiri, kí wọ́n sì bí sí i. Bí wọ́n bá gbilẹ̀ ní àgbègbè kan, wọ́n lè gbèrú. Láìdà bí ohun ìjà mìíràn, wọ́n lè túbọ̀ léwu sí i bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.”
Nínú ìsapá láti máà jẹ́ kí àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà àti oníkòkòrò àrùn gbèrú, wọ́n ti ṣàmúlò Àdéhùn Lórí Àwọn Ohun Ìjà Oníkòkòrò Àrùn àti Onímájèlé ti 1972 àti Àdéhùn Lórí Àwọn Ohun Ìjà Oníkẹ́míkà ti 1993. Àmọ́, ìwé ìròyìn The Economist sọ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ dára, “kò sí ìjọba kan tó lè ṣàkóso ohun ìjà lọ́nà pípé. . . . Wọn ò lè rí gbogbo àṣìṣe tó wà.” Ìwé ìròyìn yìí kan náà sọ pé: “Bákan náà, ó dájú pé àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́tàn gan-an lè má fọwọ́ síwèé àdéhùn kankan.”
[Àwọn àwòrán]
Àwọn agbófinró ń fòyà pé àwọn apániláyà lè fìrọ̀rùn lo àwọn ohun ìjà oníkẹ́míkà àti oníkòkòrò àrùn
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 7]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lágbára àtirọ ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé
ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ
CHINA
ILẸ̀ FARANSÉ
RỌ́ṢÍÀ
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ
Àwọn orílẹ̀-èdè tí a mọ̀ pé wọ́n ti dán ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé wò
ÍŃDÍÀ
ÍSÍRẸ́LÌ
PAKISTAN
Àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà pé wọ́n ń rọ ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé
ALGERIA
IRAN
IRAQ
NORTH KOREA
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Nígbà tí wọ́n ń ju bọ́ǹbù B-61 ọ̀gbálẹ̀gbáràwé, tí wọ́n ṣe fún bíba àwọn nǹkan tó wà lábẹ́ ilẹ̀ jẹ́
[Credit Line]
Fọ́tò U.S. Air Force
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Fọ́tò U.S. Air Force