A Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọ́run Nígbà Ìpọ́njú
GẸ́GẸ́ BÍ ROSIE MAJOR ṢE SỌ Ọ́
Àkọ́ní oyún mi ti pé oṣù márùn-ún nígbà tí ìyá ọkọ mi ṣàkíyèsí pé ẹsẹ̀ mi wú yàtọ̀. Lọ́jọ́ tí mo ń wí yìí, ní oṣù March 1992, èmi àti Joey, ọkọ mi, ò mọ̀ rárá pé ibi tí ohun tó ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ lórí wa yẹn yóò já sí á dán ìgbọ́kànlé wa nínú Jèhófà wò.
Ọ̀SẸ̀ kan lẹ́yìn náà ni Dókítà olùtọ́jú aboyún tó ń tọ́jú mi wá rí i pé ẹ̀jẹ̀ mi ti ru kọjá bó ṣe yẹ. Nígbà tó sọ pé kí wọ́n dá mi dúró sílé ìwòsàn kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò mi, kí wọ́n sì wo bó ṣe ń ṣe mí, ńṣe lẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà mí. Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe fi hàn pé preeclampsia, àìlera ìpele àkọ́kọ́ àìsàn àìperí àti ẹ̀jẹ̀ ríru tí ń ṣẹlẹ̀ sí aboyún tó bá kù díẹ̀ kó bímọ ló ń ṣe mí.a
Dókítà tó wà ní ilé ìwòsàn náà ní ó di dandan kí wọ́n fún mi lóògùn tí yóò jẹ́ kí n bímọ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí ewu lè fo èmi àti ọmọ náà dá. Ẹ̀rù ba èmi àti ọkọ mi gan-an. Ohùn mi ń gbọ̀n bí mo ti ń sọ pé: “Oyún yìí ò tíì pé oṣù mẹ́fà! Báwo ni ọmọ náà ṣe máa rù ú là tí ò bá sí nínú?” Dókítà náà sọ̀rọ̀ tàánútàánú pé: “Ó dáa, màá wò ẹ́ fún ìgbà díẹ̀ sí i. Ṣùgbọ́n bí ìṣòro náà bá le sí i, màá gbẹ̀bí fún ẹ ni o.” Ọjọ́ mẹ́tàlá kọjá, ṣùgbọ́n ńṣe làìsàn náà ń le sí i. Dókítà náà pe ọkọ mi wọlé, a sì ṣèpinnu ńlá náà pé kó gbẹ̀bí fún mi.
Gbígbẹ̀bí fún Mi
Alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n gbẹ̀bí fún mi náà, Dókítà McNeil, tó jẹ́ oníṣègùn àwọn ọmọdé, bá wa sọ̀rọ̀, ó sì ṣàlàyé ìṣòro tí a lè ní nínú ọ̀ràn ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé—ọpọlọ rẹ̀ lè lábùkù, ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ lè máà gbó tí kò sì ní lè ṣiṣẹ́ dáadáa, ọ̀pọ̀ àìlera mìíràn sì lè ṣẹlẹ̀ sí i. Mo gbàdúrà kí n lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” àti okun tí màá fi lè fara mọ́ ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ àti láti lè fara dà á. (Fílípì 4:7) Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì wọ́n gbẹ̀bí fún mi nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ. Kò tóbi ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin gíráàmù péré lọ. JoAnn Shelley lorúkọ táa sọ ọmọbìnrin náà.
Ọjọ́ márùn-ún lẹ́yìn náà ni mo padà sílé lọ́wọ́ òfo. Ọmọ mi jòjòló wà nílé ìwòsàn, ní wọ́ọ̀dù ìtọ́jú ọmọ ọwọ́ tó níṣòro, ó wà níbẹ̀ bí ẹní máa kú, bí ẹní máa yè. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, òtútù àyà kọ lu JoAnn. Inú wa dùn pé ó bọ́ nínú ìyẹn, ṣùgbọ́n ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn ni àrùn kan tún wọ inú ìfun rẹ̀, wọ́n sì ní láti gbé e lọ sí ẹ̀ka ìtọ́jú àkànṣe ní wọ́ọ̀dù náà. Láàárín ọjọ́ mẹ́fà mìíràn, ara JoAnn ti yá díẹ̀, ó sì ń sanra díẹ̀díẹ̀. Inú wa dùn gan-an! Ṣùgbọ́n ayọ̀ wa kò tọ́jọ́. Dókítà McNeil sọ fún wa pé ẹ̀jẹ̀ kò tó lára JoAnn. Ó dámọ̀ràn gbígbìyànjú láti fún un ní àgbélẹ̀rọ èròjà inú kíndìnrín tí ń mú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa pọ̀ sí i (EPO) tí yóò mú kí sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ JoAnn pọ̀ sí i. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bahamas níhìn-ín kàn sí àwọn aṣojú Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Nípa Ilé Ìwòsàn ní Brooklyn, New York. Kíákíá ni wọ́n pèsè ìsọfúnni lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa èròjà EPO fún Dókítà McNeil àti bí wọ́n ṣe ń lò ó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lò ó fún un.
Ìṣòro Ń Bẹ Níwájú
Òkè lọkàn wa wà láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan tó tẹ̀ lé e. Ohun tó ń bá JoAnn fínra báyìí ni àrùn kan tó wọnú ìfun rẹ̀, gìrì tó ń fa àìlèmí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àìtó èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀, àti òtútù ẹ̀dọ̀fóró. Ẹ̀rù ń bà wá pé ó lè jẹ́ èyíkéyìí lára àwọn àìsàn yìí ló máa dá ìṣòro ńlá táá fa ikú ọmọ náà sílẹ̀. Ṣùgbọ́n JoAnn ń là á já díẹ̀díẹ̀. Nígbà tó pé ọmọ oṣù mẹ́ta, ó ṣì wà nílé ìwòsàn kò sì tóbi ju nǹkan bí kìlógíráàmù kan àtààbọ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ìgbà yìí ló kọ́kọ́ dá mí láìsí àfikún afẹ́fẹ́ láti inú ẹ̀rọ. Èròjà pupa inú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ dáadáa lára rẹ̀. Dókítà sọ pé tó bá sanra ní ìwọ̀n ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta gíráàmù sí i, a lè máa gbé e lọ sílé.
Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìṣòro àìlèmí ki JoAnn mọ́lẹ̀ gan-an. Àwọn àyẹ̀wò tí a ṣe kò fi ohun tó fà á hàn. Ìkìmọ́lẹ̀ àìlèmí náà wá ń ṣe lemọ́lemọ́, ìgbà tó bá sì ń jẹun ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Ìgbẹ̀yìngbẹ́yín la wá rí i pé ńṣe ni oúnjẹ máa ń padà lọ́nà ọ̀fun JoAnn. Ọ̀nà ọ̀fun rẹ̀ kì í pa dé tó bá gbé oúnjẹ mì, oúnjẹ náà á wá padà sí ọ̀fun rẹ̀. Tó bá sì ti ṣẹlẹ̀, ńṣe ló máa ń há a lọ́fun, kò wá ní lè mí mọ́.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October, JoAnn kó àrùn onífáírọ́ọ̀sì ní wọ́ọ̀dù àwọn ọmọ ọwọ́. Àrùn náà ń pa ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ tí oṣù wọn kò pé tó wà níbẹ̀. Bí JoAnn ṣe rọ jọwọlọ síbẹ̀ ni ìṣòro àìlèmí tó jọ pé òun ló tíì ṣe é fúngbà pípẹ́ jù lọ tún ń bá a fínra. Gbogbo ìsapá láti mú kó bẹ̀rẹ̀ sí mí padà kò ṣiṣẹ́. Díẹ̀ ló kù kí Dókítà tó ń tọ́jú àwọn ọmọdé náà sọ pé ó ti kú, ló bá tún bẹ̀rẹ̀ sí mí, kò sí ẹni tó lè ṣàlàyé bó ṣe ṣẹlẹ̀—ẹsẹ̀kẹsẹ̀ náà ni gìrì tún bẹ̀rẹ̀ sí gbé e. Wọ́n tún gbé e sínú ẹ̀rọ àfimí, a sì ti sọ lọ́kàn wa pé ibi tí ayé JoAnn máa parí sí nìyẹn. Ṣùgbọ́n ó mà tún rù ú là o, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.
Kíkọ́ Láti Túbọ̀ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Gan-an
A lè fi àwọn ìṣòro tí a ní ká tó bí JoAnn wé jíjábọ́ látinú ọkọ̀ ojú omi sítòsí èbúté, níbi tí a ti lè fìrọ̀rùn lúwẹ̀ẹ́ dé orí ilẹ̀ létídò. Ní báyìí, ńṣe ló jọ pé a ti jábọ́ sáàárín agbami láti inú ọkọ̀ ojú omi, tí kò síbi tí a lè gúnlẹ̀ sí nítòsí. Nígbà tí a ronú sẹ́yìn, a rí i pé ká tó bí ọmọ náà, a ti máa ń gbọ́kàn lé ara wa jù lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n lójú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ọ̀ràn ti JoAnn yìí, a ti kọ́ láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú àwọn ọ̀ràn tí èèyàn ò bá lè rí ojútùú sí. A kọ́ láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe gbà wá níyànjú—láti má ṣe fi wàháhà tọ̀la kún tòní. (Mátíù 6:34) A kọ́ láti gbára lé Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a kì í mọ ohun tí a máa gbàdúrà fún. Nísinsìnyí, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ọgbọ́n táa rí kọ́ látinú Bíbélì àti “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti fara da irú ìṣòro bíburú jáì bẹ́ẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
Ó sábà máa ń ṣòro fún mi láti ṣọkàn gírí nígbà ìṣòro. Ọ̀ràn JoAnn nìkan ni mo ń fi ojoojúmọ́ ayé rò. Joey, ọkọ mi kò láfiwé nínú ká ranni lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin nípa tẹ̀mí. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ rẹ̀ fún èyí.
JoAnn Wá Sílé
JoAnn bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn díẹ̀díẹ̀. Lọ́jọ́ kan, òun fúnra rẹ̀ yọ rọ́bà ẹ̀rọ àfimí náà kúrò lẹ́nu rẹ̀. Dókítà McNeil wá ronú pé JoAnn lè máa lọ sílé. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wa! Ní ìmúrasílẹ̀ fún wíwá sílé rẹ̀, a kọ́ bí a óò ṣe máa fún un lóúnjẹ gba inú ọ̀pá onírọ́bà. A tún gbé ẹ̀rọ àfimí kan sílé, a háyà ẹ̀rọ tí ń wo ìṣiṣẹ́ ọkàn-àyà àti mímí, a sì kọ́ nípa bí a ṣe lè mú un bọ̀ sípò tó bá séèémí. Níkẹyìn, ní October 30, 1992, wọ́n ní kí JoAnn máa lọ sílé. Ó ti lo ọjọ́ méjìlá-lé-nígba ní wọ́ọ̀dù ìtọ́jú ọmọ ọwọ́ tó níṣòro, iye ọjọ́ tí àwa náà sì ti lò níbẹ̀ nìyẹn.
Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa àti àwọn ará ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò ti fẹ̀rí hàn pé ńṣe ni Jèhófà fi àwọn kẹ́ wa. Wọ́n máa ń wá bá wa tún inú ilé àti àyíká ilé wa ṣe, wọ́n máa ń bá wa gbọ́únjẹ, wọ́n máa ń wá gbé wa lọ sílé ìwòsàn, wọ́n sì máa ń dúró ti JoAnn kí èmi náà bàa lè sùn díẹ̀. Bí èyí ti ń ṣẹlẹ̀, a wá ń rí àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí wọ́n ní tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ àwọn ohun tẹ̀mí tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti forí ti àwọn ìṣòro tí àwọn náà ti ní.
Bí Nǹkan Ṣe Rí fún Wa Nísinsìnyí
A ti ṣiṣẹ́ kára láti pèsè ìtọ́jú ìṣègùn tó dára jù tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti yanjú ọ̀pọ̀ àìsàn tó ń yọ JoAnn lẹ́nu. Nígbà tí JoAnn pé ọmọ oṣù mọ́kàndínlógún, wọ́n sọ fún wa pé ó ní àrùn ọpọlọ. Lẹ́yìn náà, ní oṣù September 1994, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un nítorí ìṣòro pípadà tí oúnjẹ ń padà lọ́nà ọ̀fun rẹ̀. Ní ọdún 1997, gìrì tó lè gbẹ̀mí èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí bá JoAnn fínra. Inú wa dùn pé nígbà tí a pawọ́ irú àwọn oúnjẹ tó ń jẹ dà, gìrì náà kò ṣe é mọ́. Àìlera JoAnn kò jẹ́ kó lè dàgbà bó ṣe yẹ. Ṣùgbọ́n ó ti ń lọ sí àkànṣe ilé ìwé kan, ó sì ń ṣe dáadáa. Kò lè rìn, kò sì lè sọ̀rọ̀ púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ìpàdé Kristẹni ló ń bá wa lọ, ó sì ń bá wa jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Ó jọ pé ó láyọ̀.
Jèhófà ti pèsè ìtùnú púpọ̀ gan-an fún wa lákòókò àdánwò yìí. A ti pinnu láti máa gbára lé e nìṣó àti láti “máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ń yọjú lọ́tùn-ún lósì. (Hábákúkù 3:17, 18; Oníwàásù 9:11) A ń fojú sọ́nà gan-an fún Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí, níbi tí JoAnn ọmọ wa ọ̀wọ́n yóò ti gbádùn ìlera pípé.—Aísáyà 33:24.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àìlera ìpele àkọ́kọ́ àìsàn àìperí àti ẹ̀jẹ̀ ríru tí ń ṣẹlẹ̀ sí aboyún tó bá kù díẹ̀ kó bímọ jẹ́ ìṣòro àìṣiṣẹ́ dáadáa iṣan ẹ̀jẹ̀ aboyún, tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ dé inú ẹ̀yà ara rẹ̀ àti inú ibi ọmọ àti ọmọ inú rẹ̀ dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ ohun tó ń fà á, ẹ̀rí fi hàn pé àjogúnbá ni àìsàn náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ọmọbìnrin wa, JoAnn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara JoAnn kò le, ọmọ tó láyọ̀ ni