Ilé Rẹ Ha Wà Láìséwu Bí?—Nǹkan Ogún Tó Yẹ Kóo Gbé Yẹ̀ Wò
“ILÉ làbọ̀ sinmi oko!” Bóyá ńṣe lo mí kanlẹ̀ nígbà tóo padà délé láti ibi iṣẹ́, inú rẹ dùn pé o délé láyọ̀, láìséwu. Ṣùgbọ́n ṣé kò séwu lóòótọ́? Ó lè yani lẹ́nu láti gbọ́ pé àwọn èèyàn kan ń ko ewu ńlá nílé, wọ́n sì lè má mọ̀. Ní pàtàkì àwọn tí wọ́n ní àwọn ọmọ kéékèèké gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti dín ewu tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé kù. Oò ṣe fi àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí a kọ sísàlẹ̀ yìí ṣàyẹ̀wò ilé rẹ kí o sì ṣàkíyèsí àtúnṣe èyíkéyìí tó yẹ ní ṣíṣe?
✔ Irúgbìn. Bí o bá ní àwọn ọmọ kéékèèké, rí i dájú pé èyíkéyìí lára àwọn irúgbìn rẹ kì í ṣe onímájèlé. Rántí pé kò sí ohun tí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n lójúmìító kò lè kì bẹnu.
✔ Kọ́tìnnì. Má ṣe jẹ́ kí okùn kọ́tìnnì wà níbi tọ́wọ́ ti lè tètè tó o. Wọ́n lè lọ́ mọ́ ọmọdé lára tàbí kí wọ́n tilẹ̀ fún wọn lọ́rùn pa.
✔ Àpótí ìkó-ǹkan-sí àti kọ́bọ́ọ̀dù. Gbìyànjú láti ṣe àwọn irin tí ń sé ilẹ̀kùn sí i. Èyí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọdé dédìí ohun èlò tẹ́nu rẹ̀ mú àti àwọn èròjà tó léwu tí a fi ń nu nǹkan.
✔ Àkàsọ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì. Ǹjẹ́ iná ibẹ̀ mọ́lẹ̀ rekete, tí kò sì sí ẹrù jágajàga níbẹ̀? Ǹjẹ́ o ti ṣe ilẹ̀kùn tí kò ní jẹ́ kí ọmọ ọwọ́ ṣubú láti ibẹ̀?
✔ Sítóòfù. Yí iga àwọn ìsebẹ̀ àti ìdínran sápá ẹ̀yìn sítóòfù, pàápàá nígbà tí o bá ń gbọ́únjẹ lọ́wọ́.
✔ Ẹ̀rọ tí a fi ń yan ẹran. Máa nù ún déédéé. Ilé ìdáná lè gbiná tí gírísì bá pọ̀ jù nínú abọ́ ìyan-ǹkan tó wà nínú ẹ̀rọ náà.
✔ Ohun èlò ìpaná. Má ṣàìni nílé, bó ṣe ẹyọ kan péré, sì rí i dájú pé gbogbo ẹni tó bá ti dàgbà tó ló mọ bí a ṣe ń lò ó.
✔ Ibùsùn ọmọdé. Rí i pé àwọn igi rẹ̀ sún mọ́ra dáadáa. Àyè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ tìmùtìmù kò gbọ́dọ̀ tóbi débi tí orí ọmọ ọwọ́ a fi lè há síbẹ̀.
✔ Àwọn fèrèsé. Àwọn irin ojú fèrèsé kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọdé lè já bọ́, yóò sì rọrùn fún àgbàlagbà láti tètè yọ ọ́ bí iná bá ń jólé.
✔ Àwọn fítámì àti oògùn mìíràn. Kó wọn pa mọ́ sínú àpótí tí o tì pa tàbí sí ibi tí ọwọ́ àwọn ọmọdé ò lè tó.
✔ Ọpọ́n ìwẹ̀. Má ṣe dá fi ọmọdé sínú ọpọ́n ìwẹ̀ láìsí ọ níbẹ̀. Kì í pẹ́ rárá—kì í sì í gba omi tó pọ̀—kí ọmọdé tó mumi kú.
✔ Ẹ̀rọ ìyan-ǹkan. Rántí pé ẹ̀rọ ìyan-ǹkan tètè máa ń móúnjẹ gbóná. Fún àpẹẹrẹ, oúnjẹ tóo pò fọ́mọ lè ti gbóná gan-an ṣùgbọ́n kí ìgò oúnjẹ náà ṣì lọ́ wọ́ọ́rọ́.
✔ Ààrò oníná. Máa yẹ ààrò rẹ wò látìgbàdégbà bóyá èéfín rẹ̀ ń jò.
✔ Ayanran. Rí i dájú pé àwọn ọmọdé jìnnà dáadáa sí ayanran nígbà tó ṣì gbóná.
✔ Ilẹ̀kùn ibi ìgbọ́kọ̀sí. Kìlọ̀ fún àwọn ọmọdé láti má ṣe sáré kọjá lábẹ́ ilẹ̀kùn ibi ìgbọ́kọ̀sí nígbà tó bá ń tì lọ́wọ́, pàápàá tó bá jẹ́ iná ló ń bá ṣiṣẹ́.
✔ Ẹ̀rọ tí ń ró tí èéfín bá wà. Jẹ́ kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, kí o sì máa yẹ̀ wọ́n wò déédéé. Máa pààrọ̀ bátìrì wọn lọ́dọọdún.
✔ Àwọn wáyà iná àti ihò iná. Kó àwọn wáyà iná tó ti bó dà nù. Ó dára gan-an kí àwọn ihò iná tí a kò lò ní ìbòrí.
✔ Àwọn ẹ̀rọ tí ń loná. Má ṣe gbé àwọn ẹ̀rọ tí ń loná sítòsí àgbá ìwẹ̀ tàbí ibi tí a ti ń fọwọ́. Àwọn ìhùmọ̀ tí kì í jẹ́ kí iná mànàmánà gbéni tí a rì mọ́lẹ̀ wúlò nílé.
✔ Ibi tí a ń kó ohun ìṣeré ọmọdé sí. Dáhò kan tàbí bí mélòó kan sára ibi tí ẹ ń kó ohun ìṣeré ọmọdé sí, sì fi ìwàkùn tí kò ní jẹ́ kí ìdérí rẹ̀ pa dé lójijì sí i.
✔ Áyọ́ọ̀nù ìlọṣọ. Gbé áyọ́ọ̀nù ìlọṣọ rẹ—àti okùn rẹ̀ tó wà ní títú—síbi tọ́wọ́ àwọn ọmọdé ò ti ní tó o.