Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
February 8, 2002
Ìgbéyàwó—Bó O Ṣe Lè Fayọ̀ Bẹ̀rẹ̀ Rẹ̀
Ìmúra ńláǹlà làwọn èèyàn sábà máa ń ṣe nítorí ọjọ́ ìgbéyàwó wọn. Àmọ́ báwo ni ìgbéyàwó fúnra rẹ̀ ṣe lè jẹ́ èyí tó mìrìngìndìn, tó sì wà pẹ́ títí?
3 “Ọjọ́ Tó Dùn Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Wa”
4 Ọjọ́ Ìgbéyàwó—Ọjọ́ Olóyinmọmọ Ni Àmọ́ ó Tún Ní Wàhálà Tiẹ̀
9 Ìdè Tó Yẹ Kó Wà Pẹ́ Títí Ni Ìgbéyàwó
14 Ǹjẹ́ O Mọ̀?
15 Àwọn Èèyàn Tó Ń Wá Ibi Ààbò Kiri
18 Wíwá Ibi Tí Wọ́n Lè Fi Ṣe Ilé
23 Ayé Kan Tó Máa Dẹrùn fún Gbogbo Èèyàn
32 “Gbogbo Ìgbà Làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Máa Ń Ṣèwádìí Nínú Rẹ̀”
Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì Náà? 12
Nínú Bíbélì, áńgẹ́lì méjì péré la dárúkọ wọn. Kọ́ nípa ẹni tí áńgẹ́lì tá a pè ní Máíkẹ́lì jẹ́ ní ti gidi.
Kí Ló Ń Mú Kí Ìbínú Máa Ru Bo Àwọn Èèyàn Lójú Tó Bẹ́ẹ̀? 26
Kí ló dé tí bíbínú táwọn awakọ̀ ń bínú lójú títì, táwọn èèyàn ń bínú nínú ọkọ̀ òfuurufú, nínú ilé àti láwọn ibòmíràn fi ń ròkè sí i?