Ó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àgbàdo
Ọ̀PỌ̀ ọdún ni Harlin ti fi ṣọ̀gbìn àgbàdo, lágbègbè olómi adágún tí wọ́n ń pè ní Finger Lakes nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Inú ẹ̀ máa ń dùn láti máa ṣàlàyé àwọn ohun tó jẹ́ àgbàyanu nípa àgbàdo fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ àtàwọn àlejò tó bá wá kí i. Àwọn akọ̀ròyìn Jí! sọ fún un pé kó sọ díẹ̀ fáwọn òǹkàwé wa. A sì tún máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan míì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ohun ọ̀gbìn yìí. Bí àpẹẹrẹ, ibo ni àgbàdo ti wá? Báwo ló ṣe di ohun tí wọ́n ń gbìn kárí ayé? Kí sì làwọn nǹkan tá a lè fi ṣe? Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá fetí ara wa gbọ́ díẹ̀ lára àwọn ohun tí Harlin sọ nípa àrà tá a lè fi àgbàdo dá.
Àgbàdo Máa Ń “Sọ̀rọ̀”
“Mo ti kíyè sí i pé iṣẹ́ ọnà àti ìṣirò tó kọjá sísọ ló wá lára àgbàdo. Gbogbo ẹ̀yà ara ẹ̀ ló máa ń tò sẹ́músẹ́mú lọ́nà tó jojú ní gbèsè, látorí ewé ẹ̀ títí dórí àwọn ọmọ tó wà lára kùkù àgbàdo. Ìyẹn nìkan kọ́ o, bí àgbàdo bá ṣe ń dàgbà ló máa ń “sọ̀rọ̀.” Ó máa sọ fún ẹ bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́ tàbí tí kò bá rí oúnjẹ gidi jẹ. Ọmọ ìkókó máa ń ké nígbà tó bá nílò nǹkan kan. Bí àgbàdo pàápàá ṣe máa ń ṣe nìyẹn. Bíi tàwọn ohun ọ̀gbìn míì, bó bá nílò nǹkan kan, àwọ̀ ewé ẹ̀ lè yí pa dà tàbí kó bẹ̀rẹ̀ sí í rọ. Ti àgbẹ̀ ṣáà ni pé kó ti gbọ́ igbe tí àgbàdo ń ké yìí kó sì fún un lóhun tó ń fẹ́.
“Bí kò bá sí èròjà phosphate nínú ilẹ̀ ibi tó o bá gbin àgbàdo sí, ewé ẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í pọ́n rẹ́súrẹ́sú. Bá a bá sì kíyè sí àwọn nǹkan míì tó dà bí àrùn lára àgbàdo, ó lè jẹ́ pé àwọn èròjà bíi magnesium, nitrogen tàbí potash ni kò sí nínú ilẹ̀ yẹn. Bí àgbẹ̀ bá sì wo àgbàdo lásán, ó lè mọ̀ bí kòkòrò àrùn bá ti kọ lù ú tàbí tí kẹ́míkà bá ti ṣèpalára fún un.
“Bíi tàwọn àgbẹ̀ míì tó máa ń gbin àgbàdo, ìgbà tójò bá bẹ̀rẹ̀ lèmi náà máa ń gbìn ín, torí pé lásìkò yẹn, ooru inú ilẹ̀ máa ń mú kí àgbàdo hù. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin sí mẹ́fà tí àgbàdo náà bá ti dàgbà, ó máa ga tó nǹkan bíi mítà méjì, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà.
“Díẹ̀díẹ̀ ni àgbàdo máa ń dàgbà, èèyàn sì lè fi iye ewé tó bá ti yọ lára ẹ̀ mọ ibi tó dàgbà dé. Tó bá ti yọ ewé tó tó márùn-ún, ìgbà yẹn ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í lo agbára tó ní láti fa èròjà látinú ilẹ̀ kó lè hù dáadáa. Ohun tó máa ń kọ́kọ́ ṣe ni pé, ó máa ń lo àwọn ìtàkùn ẹ̀ láti fi mọ bí ilẹ̀ bá ṣe rí. Ìyẹn ló máa pinnu bó ṣe máa tóbi tó àti bí èso tó fẹ́ mú jáde ṣe máa rí, iye ọmọ àgbàdo tó bá sì tò sára kùkù ẹ̀ la máa fi mọ̀. Bí ewé orí ẹ̀ bá sì máa fi tó méjìlá [12] sí mẹ́tàdínlógún [17], ó máa túbọ̀ fi ìtàkùn ẹ̀ yẹ ilẹ̀ wò láti mọ bí iye ọmọ àgbàdo tó máa wà lára kùkù ṣe máa pọ̀ tó. Ká kúkú sọ pé ó ní bí àgbàdo kọ̀ọ̀kan ṣe máa ń fi èròjà tó wà nínú ilẹ̀ ṣe ara ẹ̀ lóore. Bá a bá tún wá mọ bí ìrùkẹ̀rẹ̀ àgbàdo àti yẹtuyẹtu tó máa ń wà lórí háhá ẹ̀ ṣe ń dọmọ, á túbọ̀ yé wa pé ohun àgbàyanu ni àgbàdo.”
Ìrùkẹ̀rẹ̀ Àgbàdo àti Yẹtuyẹtu Orí Ẹ̀
“Ẹ̀yà akọ àti abo máa ń wà lára gbogbo igi àgbàdo. Ìrùkẹ̀rẹ̀ tó wà lórí igi àgbàdo ló máa ń mú ẹ̀yà akọ jáde. Àwọn èso wẹ́wẹ́ tó dà bí ìrẹsì tó tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ló sì máa ń wà nínú ìrùkẹ̀rẹ̀ orí àgbàdo kọ̀ọ̀kan. Látinú àwọn èso wẹ́wẹ́ tó dà bí ìrẹsì wọ̀nyí ni ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ohun tín-tìn-tín tí atẹ́gùn lè gbé kiri ti máa ń jáde. Àwọn ohun tín-tìn-tín wọ̀nyí ni atẹ́gùn máa ń gbé láti lọ sọ àwọn ẹyin tó wà lára kùkù àgbàdo dọmọ. Inú háhá, ìyẹn èèpo tó máa ń wà lára kùkù àgbàdo làwọn ẹyin wọ̀nyí máa ń wà kí atẹ́gùn tó gbé àwọn ohun tín-tìn-tín tó jẹ́ ẹ̀yà akọ lọ bá wọn.
“Àmọ́ báwo làwọn ohun tín-tìn-tín wọ̀nyí ṣe ń kọjá lára háhá àgbàdo láti lọ sọ àwọn ẹyin tó wà nínú ẹ̀ dọmọ? Inú yẹtuyẹtu àgbàdo ni wọ́n ń gbà kọjá. Yẹtuyẹtu yìí làwọn fọ́nrán aláwọ̀ funfun tó máa ń dì ṣìkìtì sórí àgbàdo tí háhá ṣì wà lára ẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún fọ́nrán yìí ló sì máa ń wà lórí irú àgbàdo bẹ́ẹ̀. Tá a bá tọ fọ́nrán kọ̀ọ̀kan lọ sára kùkù àgbàdo tó wà nínú háhá, a máa rí awọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí ẹyin wà nínú ẹ̀. Fọ́nrán kọ̀ọ̀kan ló lọ sídìí ẹyin kọ̀ọ̀kan. Ẹyin kọ̀ọ̀kan ló sì máa wá di ọmọ àgbàdo kọ̀ọ̀kan.
“Atẹ́gùn máa ń fẹ́ àwọn ohun tín-tìn-tín tó wá látinú ìrùkẹ̀rẹ̀ lọ sórí yẹtuyẹtu tó wà lórí háhá àgbàdo. Bí èyíkéyìí lára àwọn ohun tín-tìn-tín náà bá ti bọ́ sórí fọ́nrán yẹtuyẹtu, ó máa bẹ̀rẹ̀ sí í hù, á wá tọ ipasẹ̀ fọ́nrán yẹn lọ sínú lọ́hùn-ún láti lọ sọ ẹyin tó wà lára kùkù dọmọ.
“Bọ́rọ̀ ò bá rí bá a ṣe ṣàpèjúwe ẹ̀ lókè yìí, bóyá nítorí pé fọ́nrán kan ò tètè hù, ọmọ àgbàdo ò ní pé nínú kùkù, ìyẹn ló sì máa ń yọrí sí àgbàdo ọlọ́mọṣíkàtà. Àìtó omi látinú ilẹ̀ sì lè fà á pẹ̀lú. Bí àgbẹ̀ bá sì ti mọ ohun tó fà á, ó lè wá nǹkan ṣe sí i, kí gbogbo àgbàdo tó máa so lóko ẹ̀ má lọ jẹ́ ọlọ́mọṣíkàtà. Ohun tí mo máa ń ṣe ni pé bí mo bá gbin àgbàdo sórí ilẹ̀ kan lọ́dún yìí, ẹ̀wà sóyà, ni màá gbìn sórí ẹ̀ lọ́dún tó ń bọ̀, lẹ́yìn ìyẹn ni màá tún wá gbin àgbàdo sórí ẹ̀. Ẹ̀wà sóyà yìí máa ń jẹ́ kí èròjà nitrogen pọ̀ dáadáa nínú ilẹ̀, àwọn kòkòrò mùkúlú kì í sì í lè jẹ ẹ́.
“Inú mi máa ń dùn láti rí i tí ilẹ̀ gbalasa bá ń di oko ọ̀gbìn tó sì ń mú oúnjẹ jáde lọ́nà tí kò la ariwo lọ, tó mọ tónítóní, tó sì fa ojú mọ́ra. Lóòótọ́ ni mo gbà pé, bíi tàwọn ohun ọ̀gbìn yòókù, ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run dá ni àgbàdo. Ohun tí mo sì mọ̀ yìí ò tíì tó nǹkan kan.”
Ṣé àwọn nǹkan tí Harlin sọ wọ̀nyí ti jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àgbàdo? Gbọ́ ìtàn nípa ibi tó ti wá àti oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n ń fi àgbàdo ṣe.
Láti Mẹ́síkò Ló Ti Tàn Dé Gbogbo Ayé!
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìlú Mẹ́síkò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbin àgbàdo. Àwọn ará Peru máa ń jọ́sìn abo ọlọ́run àgbàdo, wọ́n máa ń ṣe adé tí wọ́n tó àgbàdo sí lórí ṣaraṣara láti fi dé abo òrìṣà náà lórí. Joseph Kastner tó máa ń kọ̀wé nípa ìṣẹ̀dá sọ pé àwọn ará Íńdíà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà “jọ́sìn [àgbàdo], wọ́n gbà pé àwọn ọlọ́run wọn ló dá àgbàdo àti pé àgbàdo ni ọlọ́run wọn fi dá èèyàn . . . Ó rọrùn láti gbìn, igi àgbàdo kan sì lè bọ́ èèyàn kan fún odindi ọjọ́ kan.” Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Latin-America máa ń fi ẹ̀wà sí àgbàdo tí wọ́n ń jẹ, bí wọ́n sì ṣe ń jẹ ẹ́ títí dòní olónìí nìyẹn.
Lẹ́yìn tí ọ̀gbẹ́ni Christopher Columbus tó máa ń ṣèwádìí kiri dé ságbègbè Caribbean lọ́dún 1492 làwọn ará Yúróòpù tó mọ ohun tí wọ́n ń pè ní àgbàdo. Ọmọ Columbus, ìyẹn Ferdinand, sọ nínú ìwé tó kọ pé bàbá òun rí ohun oníhóró kan “táwọn pè ní àgbàdo. Ó máa ń dùn gan-an bí wọ́n bá sè é, bí wọ́n bá sùn ún, tàbí tí wọ́n bá lọ̀ ọ́.” Columbus mú àwọn èso àgbàdo yẹn lọ sílé, nígbà tó sì máa fi di “nǹkan bí ọdún 1550,” Kastner kọ̀wé pé, “kì í ṣe ìlú Sípéènì nìkan ni wọ́n ti ń gbin [àgbàdo] báyìí ò, àmọ́ wọ́n ti ń gbìn ín ní orílẹ̀-èdè Bulgaria àti orílẹ̀-èdè Tọ́kì pàápàá. Àwọn tó ń ṣòwò ẹrú ló mú àgbàdo dé ilẹ̀ Áfíríkà . . . Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú [Ferdinand] Magellan, [ọmọ ilẹ̀ Sípéènì tó máa ń ṣèwádìí, àmọ́ tí wọ́n bí sórílẹ̀-èdè Potogí] ló mú àwọn èso àgbàdo wọ̀nyí láti ilẹ̀ Mẹ́síkò dé orílẹ̀-èdè Philippines àti Éṣíà.” Bí ọ̀gbìn àgbàdo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí búrẹ́kẹ́ nìyẹn.
Lóde òní, yàtọ̀ sí àlìkámà, àgbàdo ni oúnjẹ oníhóró kejì tó pọ̀ jù lọ ní gbogbo ayé. Ìrẹsì ló wà nípò kẹta. Àwọn oúnjẹ pàtàkì mẹ́ta wọ̀nyí lọ̀pọ̀ èèyàn ń jẹ lóde òní tó fi mọ́ àwọn ẹran ọ̀sìn.
Bíi tàwọn ohun ọ̀gbìn tó kù, oríṣiríṣi àgbàdo ló wà. Kódà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìkan, oríṣi àgbàdo tó wà, títí kan àwọn àgbàdo àtọwọ́dá, lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000]. Àwọn igi àgbàdo wọ̀nyí kì í ga ju ọgọ́ta sẹ̀ǹtímítà, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà méjì lọ, nígbà táwọn míì sì máa ń ga tó pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà kan! Báwọn àgbàdo fúnra wọn ṣe máa ń rí ò dọ́gba. Àwọn míì kì í gùn ju àtàǹpàkò lọ; àwọn míì sì máa ń gùn tó ọgọ́ta sẹ̀ǹtímítà, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà méjì. Ìwé kan tó dá lórí oúnjẹ sísè, Latin American Cooking, sọ pé: “Oríṣi àgbàdo kan wà tí wọ́n máa ń gbìn ní Amẹ́ríkà Gúúsù, tí kùkù ẹ̀ máa ń rí róbóróbó bíi bọ́ọ̀lù, táwọn ọmọ àgbàdo tó máa ń tò sí i lára sì máa ń pẹlẹbẹ, tí gígùn àti fífẹ̀ wọn sì máa ń tó ìdajì àtàǹpàkò.”
Oríṣiríṣi àwọ̀ ni àgbàdo máa ń ní. Yàtọ̀ sí àwọ̀ ìyeyè, àgbàdo míì lè pupa, ìmí lè ní àwọ̀ aró, ìmí máa ń ní àwọ̀ osùn, nígbà táwọn míì máa ń dúdú. Ìgbà míì lè wà táwọn ọmọ àgbàdo tó wà lára kùkù kan lè mú kó dà bíi pé èso àgbàdo yẹn ní ọ̀já, àmì tó-tò-tó tàbí ìlà lára. Abájọ táwọn èèyàn kan kì í fi í fẹ́ se irú àwọn èso àgbàdo bẹ́ẹ̀ jẹ, wọ́n á wá fi ṣe ilé wọn lọ́ṣọ̀ọ́.
Oríṣiríṣi Nǹkan Ni Wọ́n Máa Ń Fi Ṣe
A lè pín onírúurú àgbàdo tó wà sí ọ̀nà mẹ́fà, ìyẹn àgbàdo títẹ̀, àgbàdo oníhóró líle, àgbàdo ìyẹ̀fun, àgbàdo olóyin, àgbàdo dídán, àti àgbàdo gbúgbúrú. Àgbàdo olóyin yẹn kì í sábà pọ̀. Ìdí tá a fi ń pé ní olóyin ni pé àwọn èròjà kan tí kò pọ̀ tó nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà nínú kóró àgbàdo yìí máa ń fa àpọ̀jù ṣúgà. Ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá àwọn àgbàdo tí wọ́n ń gbìn yíká ayé ni wọ́n fi ń bọ́ àwọn ẹran ọ̀sìn nígbà tí èyí táwa èèyàn ń jẹ ò ju ìdá méjì nínú mẹ́wàá lọ. Ìdá méjì tó kù ni wọ́n ń lò láwọn ilé iṣẹ́, lára ẹ̀ náà làwọn àgbẹ̀ sì máa ń gbìn. Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan tí wọ́n ń lo àgbàdo fún yàtọ̀ síra láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn.
Oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n máa ń fi àgbàdo ṣe. Wọ́n máa ń lo àgbàdo tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n mú jáde látara àgbàdo láti fi ṣe gọ́ọ̀mù àtàwọn nǹkan tó dà bíi bọ́tà tí wọ́n fi ń jẹ búrẹ́dì, wọ́n máa ń lò ó láti fi ṣe ọtí bíà tó fi mọ́ ìtẹ́dìí ọmọdé. Kódà, ó ní irú oríṣi epo kan tí wọ́n ń fi àgbàdo ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnu ò tíì kò lórí bóyá kí wọ́n máa fi ṣe ọtí ògógóró. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tá a lè fi ohun ọ̀gbìn tó wúlò lónírúurú ọ̀nà yìí ṣe.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Àgbàdo Àtọwọ́dá
Lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn àgbẹ̀ tó ń ṣọ̀gbìn àgbàdo sábà máa ń gbin àwọn àgbàdo àtọwọ́dá torí pé wọ́n máa ń so dáadáa. Àwọn àgbẹ̀ kan sábà máa ń lo àgbàdo títẹ̀ tó bá ní àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ lára láti mú oríṣi àgbàdo míì, tá a lè pè ní àgbàdo àtọwọ́dá, jáde. Ibi tọ́rọ̀ náà wá já sí ni pé, àfi káwọn àgbẹ̀ tó bá fẹ́ gbin àwọn àgbàdo àtọwọ́dá wọ̀nyí máa ra oríṣi àgbàdo tí wọ́n máa gbìn lọ́dọọdún. Ìdí ni pé tí wọ́n bá gbìn lára àwọn àgbàdo àtọwọ́dá tó ti wà lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀, èso wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ dáa tó, ó sì lè má pọ̀ tó.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Oríṣiríṣi àgbàdo ló wà yíká ayé
[Àwọn Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Sam Fentress
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Jenny Mealing/flickr.com