ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/08 ojú ìwé 31
  • Ìwé Ìròyìn Jí! Ràn Mí Lọ́wọ́ Láìròtẹ́lẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Ìròyìn Jí! Ràn Mí Lọ́wọ́ Láìròtẹ́lẹ̀
  • Jí!—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Ti Fún Mi Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 10/08 ojú ìwé 31

Ìwé Ìròyìn Jí! Ràn Mí Lọ́wọ́ Láìròtẹ́lẹ̀

LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ BENIN

◼ Nígbà tí ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] kan tó ń jẹ́ Noël pinnu pé òun ò fẹ́ lọ síléèwé mọ́ kóun bàa lè di ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá lọwọ́ rẹ̀ máa lè tẹ́nu. Kò sì rọrùn fún un lóòótọ́, torí pé kò tètè ríṣẹ́ tá á jẹ́ kó máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí wàásù. Torí náà, nígbà tí ìwé ìròyìn Jí! gbé àpilẹ̀kọ náà “Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́” jáde, Noël fara balẹ̀ kà á lákàtúnkà.a Ṣé ohun tó kà ràn án lọ́wọ́? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ kì í ṣe lọ́nà tó rò pé ó máa gbà ran òun lọ́wọ́.

Ọ̀gá iléèwé àdáni kan rí Noël nígbà tó ń wàásù láti ilé dé ilé ó sì bi í bóyá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Ọ̀gá náà ń wá tíṣà tó fẹ́ gbà síṣẹ́, níwọ̀n bó sì ti kíyè sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó dáńgájíá, ó béèrè lọ́wọ́ Noël bóyá ó mọ ẹnikẹ́ni tá á fẹ́ láti ṣiṣẹ́ tíṣà. Nígbà tí Noël sọ pé, òun ò mọ ẹnì kankan, ọ̀gá náà sọ pé, “Ìwọ ńkọ́?”

Noël ò tíì ṣiṣẹ́ tíṣà rí, ó sì máa ń kólòlò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìṣòro sì lèyí jẹ́ lórílẹ̀-èdè Benin torí pé àjọ tó ń rí sí ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ti ní kí gbogbo tíṣà máa ṣe ìdánwò tó máa fi hàn pé wọn kì í kólòlò. Ọ̀gá yìí fọwọ́ sọ̀yà fún Noël, ó sì sọ fún un pé: “Ìwọ ṣáà ti gbàwé ẹ̀rí, màá sì fún ẹ níṣẹ́.”

Noël ti tẹ̀ síwájú gan-an nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, tó jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n dá sílẹ̀ láti mú kéèyàn mọ̀rọ̀ sọ dáadáa, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe é nínú ìjọ wọn. Ó tiẹ̀ máa ń sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn nínú ìjọ tó ń lọ. Síbẹ̀, ojora mú un nígbà tó lọ ṣe ìdánwò náà.

Ẹni tó darí ìdánwò náà mú ìwé ìròyìn kan lé e lọ́wọ́ ó sì ní kó ka ìpínrọ̀ kan tí wọ́n fa ìlà pupa sí. Ẹnu ya Noël nígbà tó rí i pé àpilẹ̀kọ “Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́” ni wọ́n gbé lé òun lọ́wọ́. Ó ka ìpínrọ̀ náà lọ́nà tó já gaara, wọ́n sì fún un níwèé ẹ̀rí.

Lẹ́yìn ìyẹn ni ẹni tó darí ìdánwò náà sọ pé òun máa ń ka ìwé ìròyìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn ìwé ìròyìn yìí kún fún ẹ̀kọ́, wọ́n sì kọ wọ́n dáadáa débi pé mo máa ń lò wọ́n fún ìdánwò.”

Noël bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́, ọ̀gá iléèwé náà sì fẹ́ kó tún máa bá iṣẹ́ náà nìṣó lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àmọ́ Noël ní nǹkan míì tó fẹ́ ṣe. Wọ́n ti ní kó wá máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ibẹ̀ ló sì wà báyìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí! July 8, 2005, ojú ìwé 4 sí 9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́