ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/12 ojú ìwé 7-8
  • Bí O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
  • Jí!—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Gbogbo Ìdílé
  • Ohun Tó Lè Mú Kí Èèyàn Túbọ̀ Láyọ̀
  • Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Bọ́ Lọ́wọ́ Gbèsè
    Jí!—1996
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná?
    Jí!—2006
  • Máa Fọgbọ́n Náwó
    Jí!—2009
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2012
g 1/12 ojú ìwé 7-8

Bí O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná

Ọ̀NÀ mẹ́ta pàtàkì tí èèyàn lè gbà máa ṣọ́wó ná nìwọ̀nyí: (1) Ná owó, (2) tọ́jú owó pa mọ́ tàbí (3) fúnni lówó. Jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè máa fi ọgbọ́n ná owó.

Ẹ̀kọ́ pàtàkì tá a lè rí kọ́ nínú ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ni pé, ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa fara balẹ̀ ṣètò àwọn ìnáwó rẹ̀. Kí ni ètò ìnáwó? Ó jẹ́ gbígbé ìṣirò lé bí èèyàn á ṣe máa ná owó tó ń wọlé fúnni, ì báà jẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìdílé, ilé iṣẹ́ tàbí ìjọba.

Iṣẹ́ Gbogbo Ìdílé

Báwo lo ṣe lè ṣe ètò ìnáwó? Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ètò ìnáwó tí wọ́n orúkọ rẹ̀ ní Budgeting, tí ọ̀gbẹ́ni Denise Chambers kọ, sọ pé: “Gbogbo ìdílé gbọ́dọ̀ kópa nínú ṣíṣe àkọsílẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa náwó, kó bàa lè jẹ́ pé gbogbo wọn ló máa fọwọ́ pàtàkì mú ètò tí wọ́n ṣe.” Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí gbogbo ìdílé jókòó pa pọ̀ láti wo bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ètò náà sí. Àǹfààní púpọ̀ ló wà níbẹ̀ tí gbogbo ìdílé bá lè pawọ́ pọ̀ láti ṣètò ìnáwó wọn, tí gbogbo wọn sì ń sapá láti má ṣe máa ná kọjá owó tó ń wọlé.

Àwọn kan máa ń lo kọ̀ǹpútà láti ṣètò ìnáwó wọn. Àwọn míì máa ń fi pẹ́ńsù fa ìlà sí abala ìwé láti pín in sí apá méjì. Wọ́n á kọ iye tó ń wọlé fún wọn sí apá kan, wọ́n á sì kọ iye tí wọ́n máa ná sí apá kejì. Ohun míì tó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ìdílé fi kún àkọsílẹ̀ ìnáwó wọn ni, iye tí wọ́n á máa tọ́jú lóṣooṣù láti fi san owó tí wọ́n máa ń ná lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, irú bí owó orí tàbí owó tí wọ́n máa ná nígbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ fún ìsinmi.

Ọ̀nà míì tún wà táwọn kan máa ń gbà ṣètò ìnáwó wọn, tí ẹ̀rí sì fi hàn pé ó dáa gan-an, ìyẹn ni kíkọ àwọn nǹkan téèyàn fẹ́ lo owó fún sára àwọn àpò ìwé, irú bí “Oúnjẹ,” “Owó Ilé,” “Owó Ọkọ̀,” “Owó Iná,” “Ìtọ́jú Ìṣègùn,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Láwọn ìgbà kan, ńṣe làwọn èèyàn máa ń fi owó tí wọ́n bá fẹ́ ná sórí àwọn nǹkan yìí sínú àpò ìwé kọ̀ọ̀kan lóṣooṣù. Àmọ́ ní báyìí, nítorí ààbò àti ìrọ̀rùn, ọ̀pọ̀ èèyàn ronú pé, ó sàn kéèyàn máa kó owó lọ sí báńkì, tí èèyàn á sì lọ gbà á nígbà tó bá nílò rẹ̀.

Tọkọtaya kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Jonathan àti Anne ń gbé ní orílẹ̀-èdè South Africa, wọ́n sì ní ọmọbìnrin méjì, wọ́n sábà máa ń kọ àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ náwó lé sára àwọn àpò ìwé. Jonathan sọ pé: “Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé báńkì lo máa ń tọ́jú owó oṣù rẹ sí, ó ṣì ṣe pàtàkì pé kó o má ṣe gba gbẹ̀rẹ́ rárá pẹ̀lú bó o ṣe ń pín owó rẹ. Bí àpẹẹrẹ, bí owó tó o yà sọ́tọ̀ lóṣooṣù fún ẹran bá ti tán, o kò gbọ́dọ̀ fi owó tó ò ń tọ́jú pa mọ́ ra ẹran sí i.”

Nígbà kan, Jonathan ní okòwò kan, àmọ́ ní báyìí, òun àti ìdílé rẹ̀ ti yọ̀ǹda ara wọn láti máa kọ́ àwọn ilé ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí pé wọ́n ń gbádùn iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n ń ṣe yìí, ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa ṣètò ìnáwó wọn dáadáa. Ìdílé yìí máa ń jókòó pa pọ̀ déédéé kí wọ́n lè jíròrò bí ètò tí wọ́n ṣe ṣe ń lọ dáadáa sí, kí wọ́n sì lè ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ.

Ohun Tó Lè Mú Kí Èèyàn Túbọ̀ Láyọ̀

Ìwádìí fi hàn pé téèyàn bá ń fún àwọn èèyàn lára ohun téèyàn ní, tó fi mọ́ àkókò, okun àti owó pàápàá, ó máa ń fún èèyàn láyọ̀ púpọ̀ gan-an. Nínú ohun mẹ́ta tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ohun tó dára jù lọ ní pé kó o máa fún àwọn èèyàn lára ohun tó o ní, débi tí agbára rẹ bá gbé e dé.

Nínú ìwé kan tí ọ̀gbẹ́ni Chris Farrell kọ tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè máa ṣọ́wó ná, ìyẹn The New Frugality, ó sọ pé títọ́jú owó pa mọ́ jẹ́ “ọ̀nà téèyàn lè máa gbà rí owó ná.” Ó tún sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣàǹfààní tó sì bọ́gbọ́n mu jù lọ tó o lè fi owó rẹ ṣe ni pé kó o máa fún àwọn èèyàn lówó.”a Ọ̀gbẹ́ni Farrell tún fi kún un pé: “Nígbà téèyàn bá ń ronú nípa ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, kì í ṣe kíkó owó àtàwọn ohun ìní jọ bí kò ṣe àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn, àwọn ìrírí wa àti ṣíṣe ohun tó máa mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn dára sí i.”

Ó jọ pé ọ̀gbẹ́ni Michael Wagner, tó jẹ́ onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé gbà pẹ̀lú èrò yìí. Nínú ìwé rẹ̀, Your Money, Day One, èyí tó ṣe láti fi fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí pé kí wọ́n máa tọ́jú owó pa mọ́, ó sọ pé: “Tó o bá mú un lọ́ràn-an-yàn fún ara rẹ pé ó fẹ́ máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà tó dára lo máa gbà jèrè inúure àti ìwà ọ̀làwọ́ yẹn, àǹfààní tó ga jù lọ tó o máa jèrè ni pé inú rẹ máa dùn gan-an pé o ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn.”

Bíbélì fi hàn pé téèyàn bá jẹ́ ọ̀làwọ́, ó máa ń fúnni láyọ̀. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n wà nínú Bíbélì tó lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa fi ọgbọ́n náwó. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n méje mìíràn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ara ọ̀nà téèyàn lè gbà náwó fún àwọn èèyàn ni pé, kéèyàn ra ẹ̀bùn fúnni tàbí kéèyàn ṣe àwọn èèyàn lálejò, irú bíi gbígbọ́únjẹ fún tẹbí tọ̀rẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́