ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 103
  • Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Ti Jí Jésù Dìde, Ibojì Rẹ̀ sì Ti Ṣófo!
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • “Mo Ti Rí Olúwa!”
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Jésù Jíǹde
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Rántí Ọmọ Rẹ̀
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 103
Jésù fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde

ÌTÀN 103

Jésù Wọnú Yàrá Kan Tí Wọ́n Tì Pa

LẸ́YÌN tí Pétérù àti Jòhánù kúrò ní ibojì tí wọ́n tẹ́ òkú Jésù sí, Màríà nìkan ló kù síbẹ̀. Ó ń sunkún. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ wo inú ibojì náà bá a ṣe rí i nínú àwòrán tó wà nínú ìtàn tá a kà kọjá. Ló bá rí àwọn áńgẹ́lì méjì nínú ibojì náà! Àwọn áńgẹ́lì náà sì bi í pé: ‘Kí ló dé tó ò ń sunkún?’

Màríà dá wọn lóhùn pé: ‘Wọ́n ti gbé Olúwa mi kúrò, mi ò sì mọ ibi tí wọ́n gbé e sí.’ Lẹ́yìn náà, Màríà yíjú padà ó sì rí ọkùnrin kan. Ọkùnrin náà bi í pé: ‘Ta ni ò ń wá?’

Màríà rò pé olùṣọ́gbà ni ọkùnrin náà, ó sì rò pé òun ló gbé òkú Jésù. Nítorí náà, ó sọ fún un pé: ‘Tó bá jẹ́ pé o ti gbé e kúrò níbí, sọ ibi tó o gbé e sí fún mi.’ Àmọ́ Jésù ni ọkùnrin tí Màríà ń bá sọ̀rọ̀ tí kò sì mọ̀. Ó ti gbé ara mìíràn tí Màríà ò mọ̀ wọ̀. Àmọ́, nígbà tó pè é lórúkọ rẹ̀ ló tó hàn sí Màríà pé Jésù ni. Ni Màríà bá sáré lọ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: ‘Mo ti rí Olúwa!’

Nígbà tó ṣe ní ọjọ́ yẹn kan náà, táwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì ń lọ sí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Ẹ́máọ́sì, ọkùnrin kan dara pọ̀ mọ́ wọn. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà bà jẹ́ nítorí pé wọ́n ti pa Jésù. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, ọkùnrin náà ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan fún wọn nínú Bíbélì, èyí sì tù wọ́n nínú. Ìgbà tí àkókò wá tó tí wọ́n fẹ́ jẹun ni wọ́n tó mọ̀ pé Jésù ni ọkùnrin náà. Kíá, ó tún ti rá mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì náà lójú. Àwọn náà ò sì jáfara, wọ́n yára padà sí Jerúsálẹ́mù láti sọ fáwọn àpọ́sítélì nípa Jésù.

Bí ìyẹn ṣe ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, Jésù tún lọ fara hàn Pétérù. Nígbà tí Pétérù sì sọ fáwọn tó kù, inú wọn dùn gan-an. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì náà lọ sí Jerúsálẹ́mù wọ́n sì wá àwọn àpọ́sítélì rí. Wọ́n sọ fún wọn nípa bí Jésù ṣe fara han àwọn náà lójú ọ̀nà. Bí wọ́n sì ṣe ń sọ fún wọn, ǹjẹ́ o mọ ohun ìyanu tó ṣẹlẹ̀?

Wo àwòrán yìí. Jésù wọnú yàrá náà ó sì fara hàn wọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ilẹ̀kùn yàrá náà pa. Inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dùn gan-an ni! O ò rí i pé ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ náà máa jẹ́ fún wọn? Ṣó o lè sọ iye ìgbà tí Jésù ti fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ báyìí? Ṣó o kà tó ìgbà márùn-ún?

Àpọ́sítélì Tọ́másì ò sí níbẹ̀ nígbà tí Jésù fara han àwọn tó kù. Nítorí náà àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún un pé: ‘A ti rí Olúwa!’ Àmọ́ Tọ́másì sọ pé òun ò ní gbà gbọ́ tóun ò bá fojú ara òun rí Jésù. Ní ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wà nínú yàrá kan tí wọ́n tì pa, tí Tọ́másì pẹ̀lú sì wà níbẹ̀, Jésù tún yọ sí wọn lójijì. Tọ́másì wá gbà gbọ́ nísinsìnyí.

Jòhánù 20:11-29; Lúùkù 24:13-43.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́