ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ol apá 8 ojú ìwé 25-28
  • Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́
  • Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Já Ara Rẹ Gbà Lọ́wọ́ Ìsìn Èké
  • Kó Àwọn Nǹkan Tí Wọ́n Ń Lò fún Ìjọsìn Èké Dà Nù
  • Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Èèyàn Jèhófà
  • Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ṣiṣẹsin Jehofa, Kii Ṣe Satani
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kọ Ẹ̀sìn Èké Sílẹ̀!
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
Àwọn Míì
Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
ol apá 8 ojú ìwé 25-28

APÁ 8

Jáwọ́ Nínú Ìsìn Èké; Máa Ṣe Ìsìn Tòótọ́

1. Ní ti ọ̀ràn ìjọsìn, kí làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ yàn láti ṣe lónìí?

JÉSÙ sọ pé: “Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi.” (Mátíù 12:30) A gbọ́dọ̀ wà lọ́dọ̀ ẹnì kan, bí a ò bá ti sí lọ́dọ̀ Jèhófà a jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Sátánì la wà yẹn. Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ló ń ronú pé àwọn ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé Sátánì “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló gbà pé àwọn ń sin Ọlọ́run nígbà tó sì jẹ́ pé Sátánì Èṣù ni wọ́n ń sìn ní ti gidi! Àwọn èèyàn lónìí gbọ́dọ̀ yan ohun kan nítorí a kì í jẹ méjì lábà Àlàdé: Wọ́n gbọ́dọ̀ sin yálà Jèhófà, “Ọlọ́run òtítọ́,” tàbí Sátánì, “baba irọ́.”—Sáàmù 31:5; Jòhánù 8:44.

Já Ara Rẹ Gbà Lọ́wọ́ Ìsìn Èké

2. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tí Sátánì máa ń fẹ́ lò láti mú kí àwọn èèyàn má lè jọ́sìn Jèhófà?

2 Kí á pinnu láti sin Jèhófà lohun tó bọ́gbọ́n mu, ìyẹn ló ń múni rí ojú rere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n inú Sátánì kì í dùn sí ẹnikẹ́ni tó bá ń sin Ọlọ́run; wàhálà ló máa ń kó bá àwọn tó bá ń sin Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ọ̀nà tó máa ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni nípa mímú kí àwọn ẹlòmíràn títí kan àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ará ilé ẹni máa fini ṣẹ̀sín tàbí kí wọ́n máa ta koni. Jésù kìlọ̀ pé: “Ní tòótọ́, àwọn ọ̀tá ènìyàn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn agbo ilé òun fúnra rẹ̀.”—Mátíù 10:36.

3. Bí ìdílé rẹ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ta ko jíjọ́sìn tí ò ń jọ́sìn Ọlọ́run, kí ni wàá ṣe?

3 Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, kí lo máa ṣe? Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé ọ̀nà táwọn ń gbà jọ́sìn kò tọ́, síbẹ̀ wọ́n ń lọ́ tìkọ̀ láti fi í sílẹ̀. Wọ́n ronú pé báwọn bá fi í sílẹ̀, àwọn ti ṣẹ ìdílé àwọn. Ǹjẹ́ ìyẹn bọ́gbọ́n mu? Bí o bá mọ̀ pé àwọn èèyàn rẹ tímọ́tímọ́ kan ń lo oògùn olóró, ǹjẹ́ o ò ní kìlọ̀ fún wọn pé oògùn náà yóò ṣe wọ́n léṣe? O kò ní bá wọn máa lo oògùn náà, àbí wàá ṣe bẹ́ẹ̀?

4. Kí ni Jóṣúà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìjọsìn ìgbà ayé rẹ̀?

4 Jóṣúà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìṣe àti àṣà ìsìn èké tó jẹ́ ti àwọn baba ńlá wọn. Ó sọ pé: “Wàyí o, ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́, kí ẹ sì mú àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìhà kejì Odò àti ní Íjíbítì kúrò, kí ẹ sì máa sin Jèhófà.” (Jóṣúà 24:14) Jóṣúà dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run, Jèhófà sì bù kún un. Bí a bá dúró ṣinṣin ti Jèhófà, yóò bù kún àwa náà.—2 Sámúẹ́lì 22:26.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìsìn—Èyí Tó Jẹ́ Òótọ́ àti Èyí Tó Jẹ́ Èké

  • Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń kọ́ obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ Bíbélì

    Mẹ́talọ́kan: Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Wọ́n sọ pé “Baba jẹ́ Ọlọ́run, Ọmọ [Jésù] jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ kò sí Ọlọ́run mẹ́ta, Ọlọ́run kan ló wà.”

    Bíbélì ò tiẹ̀ mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà, “Mẹ́talọ́kan,” bẹ́ẹ̀ ni kò sì kọ́ni pé Jèhófà jẹ́ ẹni mẹ́ta nínú ọ̀kan. Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run. Kọ́ríńtì Kìíní 8:6 sọ pé: “Ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba.” Jèhófà ni Ẹni Gíga Jù Lọ. Jésù kì í ṣe Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó jẹ́ “Ọmọ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:15) Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe Ọlọ́run. Àní ẹ̀mí mímọ́ kì í tiẹ̀ ṣe ẹnì kan ní ti gidi. Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ló jẹ́.—Ìṣe 1:8; Éfésù 5:18.

  • Ọkàn: Ọ̀pọ̀ ìsìn ló ń kọ́ni pé ọkàn jẹ́ nǹkan kan tó wà nínú èèyàn tí kì í sì í kú. Bíbélì kọ́ni pé èèyàn gan-an ni ọkàn, ó sì dájú pé èèyàn lè kú.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkíẹ́lì 18:4.

  • Iná Ọ̀run Àpáàdì: Àwọn ẹ̀sìn èké fi ń kọ́ni pé ńṣe la máa dá ọkàn àwọn ẹni burúkú lóró títí láé ní ọ̀run àpáàdì. Bíbélì sọ pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Bíbélì tún kọ́ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́, kò jẹ́ finá dá àwọn èèyàn lóró láé.

Àpótí: Kí ni Bíbélì fi kọ́ni nípa Mẹ́talọ́kan, ọkàn, àti iná ọ̀run àpáàdì?

Kó Àwọn Nǹkan Tí Wọ́n Ń Lò fún Ìjọsìn Èké Dà Nù

Obìnrin kan ń dáná sun gbogbo àwọn ohun tó fi ń pidán

5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ pa àwọn ohun èlò iṣẹ́ òkùnkùn run?

5 Láti já ara wa gbà kúrò nínú ìsìn èké tún túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ dáná sun ohun èlò iṣẹ́ òkùnkùn èyíkéyìí tá a bá ní, àwọn bí, oògùn ìṣọ́ra, ońdè, òrùka ẹ̀rẹ, ìgbàdí àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Èyí ṣe pàtàkì nítorí yóò fi hàn pé Jèhófà la gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá.

6. Kí làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe sáwọn ìwé idán tí wọ́n ní?

6 Wo ohun táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kan ṣe nígbà tí wọ́n pinnu láti ṣe ìsìn tòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.”—Ìṣe 19:19.

7. Kí la lè ṣe bí àwọn ẹ̀mí èṣù bá ń dààmú wa?

7 Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀mí èṣù dààmú àwọn kan tó bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ rí wọ́n ti lọ́wọ́ ní tààràtà nínú iṣẹ́ àjẹ́, iṣẹ́ adáhunṣe tàbí àwọn iṣẹ́ òkùnkùn mìíràn. Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, gbàdúrà sókè ketekete sí Jèhófà, kí o ké pe orúkọ rẹ̀. Òun yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.—Òwe 18:10; Jákọ́bù 4:7.

8. Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo òrìṣà, ère àti àwòrán táwọn èèyàn máa ń lò nínú ìjọsìn èké?

8 Àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà kò gbọ́dọ̀ ní òrìṣà, ère tàbí àwòrán ìsìn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn èké, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọ́dọ̀ júbà wọn. ‘Nípa ìgbàgbọ́ ni [àwọn Kristẹni tòótọ́ máa] ń rìn, kì í ṣe nípa ohun tí wọ́n rí.’ (2 Kọ́ríńtì 5:7) Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run tó ka lílo ère èyíkéyìí nínú ìjọsìn léèwọ̀.—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Dara Pọ̀ Mọ́ Àwọn Èèyàn Jèhófà

Ìyá kan àti ọmọbìnrin rẹ̀ jọ ń dáná

9. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì gbani lórí dídi ọlọgbọ́n?

9 Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Bí a bá fẹ́ gbọ́n, a óò ní láti máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rìn tàbí kí a máa dara pọ̀ mọ́ wọn. Àwọn ló ń rin ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Mátíù 7:14.

10. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run?

10 Ire àwọn èèyàn jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí lógún púpọ̀. Iṣẹ́ wọn ni pé kí wọ́n ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Bíbélì tó ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun. Wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nípa bíbá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Wọ́n á dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ, wọ́n á sì fi bí o ṣe lè fi ìmọ̀ Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé rẹ hàn ọ́.—Jòhánù 17:3.

11. Báwo ni àwọn ìpàdé Kristẹni yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́?

11 Wàá túbọ̀ kọ́ nípa ọ̀nà Jèhófà láwọn ìpàdé wọn, tí wọ́n sábà máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. A óò fún ọ lókun láti túbọ̀ fẹ́ láti máa ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Wàá sì tún gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì.—Hébérù 10:24, 25.

Wọ́n ń ṣèpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba

12. Báwo ni àdúrà yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sin Ọlọ́run?

12 Bí o ṣe túbọ̀ ń kọ́ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àti nípa ète rẹ̀, òye rẹ nípa àwọn ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti ìmọrírì rẹ fún un yóò túbọ̀ pọ̀ sí i. Ó yẹ kí o túbọ̀ máa fẹ́ láti ṣe ohun tí ó fẹ́, kí o sì yẹra fún ohun tí kò fẹ́. Rántí pé o lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́ kí o sì yẹra fún ohun tí kò tọ́.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Fílípì 4:6.

Ìdílé kan jọ ń ka Bíbélì

Báwo lo ṣe lè dẹni tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́?

13. Báwo ni o ṣe lè mú ọkàn Jèhófà yọ̀?

13 Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ tí o sì ń tẹ̀ síwájú sí i nípa tẹ̀mí, ó dájú pé wàá rí i pé ó yẹ kí o ya ara rẹ sí mímọ́ kí o sì ṣèrìbọmi láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí o bá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn èèyàn Jèhófà, wàá mú ọkàn Jèhófà yọ̀. (Òwe 27:11) Wàá wà lára àwọn èèyàn aláyọ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa wọn pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn, èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”—2 Kọ́ríńtì 6:16.

Mo Já Ara Mi Gbà Lọ́wọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù

Josephine Ikezu àti díẹ̀ lára àwọn ọmọ rẹ̀

Lóru ọjọ́ kan nígbà tí èmi àti ọkọ mi wà lórí ibùsùn, mo gbọ́ ohùn kan tó pe orúkọ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta. Ni mo bá rí i tí àjà ilé là sí méjì, tí kinní kan tó pọ́n bí iná, tó sì dà bíi bọ́ọ̀lù já bọ́ sórí ikùn mi. Àmọ́, ọkọ mi kò rí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí o. Síbẹ̀, nǹkan bí oṣù mélòó kan lara mi fi ń gbóná fòò.

Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, ohùn yẹn tún pè mí. Lọ́gán, ńṣe ló dà bíi pé gbogbo ilé náà wà nínú ibú omi. Ejò ńlá kan jáde wá látinú omi náà, ó sì wé mọ́ ọwọ́ mi. Mo gbìyànjú láti yán an sọ nù ṣùgbọ́n kò ṣeé ṣe. Ẹ̀rù bà mí gidigidi. Ìgbà tó yá ni mi ò tún rí omi àti ejò yìí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni nǹkan kan sì fà mí lulẹ̀ gbìì. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mi ò fi mọ nǹkan kan. Ni ohùn yẹn bá wá sọ fún mi pé kí n lọ sí ilé òrìṣà tí wọ́n ti ń fi ẹ̀mí èṣù ṣe ìwòsàn ní abúlé náà. Nígbà tí mo béèrè orúkọ ẹ̀mí ọ̀hún, ó sọ orúkọ kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ jẹ́, “alọ́rọ̀-máà-lọ́mọ.” Ó ṣèlérí pé òun á fi agbára ìwòsàn sọ mí di ọlọ́rọ̀.

Àwọn aláìsàn tó wà nítòsí àtàwọn tó wà lọ́nà jíjìn ló máa ń wá sọ́dọ̀ mi. Kí wọ́n tó dé ilé mi, wọ́n á ti hàn nínú dígí àrà tí mo ní. Bí onítọ̀hún bá wá dé, màá fi àtẹ́lẹwọ́ mi gbá tiẹ̀, pàà, ẹ̀mí yẹn yóò wá fi irú àìsàn tó ń ṣe ẹni náà tàbí irú ìṣòro tẹ́ni náà ní àti ojútùú rẹ̀ hàn mí lọ́gán. Ẹ̀mí yẹn tún máa ń sọ iye owó tí ẹni náà yóò san.

Nítorí irú agbára kì-í-bà-á-tì tí mo fi ń ṣe ìwòsàn ọ̀hún, ńṣe ni owó àti ẹ̀bùn ń ya wọlé mi. Mo di ẹni tó ‘lọ́rọ̀’ ní tòótọ́, ṣùgbọ́n mi ò ṣaláìmọ ìtumọ̀ apá tó kẹ́yìn náà, “máà-lọ́mọ.” Bí mo bá ṣe ń bímọ kan ni èyí tí mo bí ṣáájú rẹ̀ yóò kú. Èyí bà mí nínú jẹ́ gidigidi. Ní gbogbo ọdún méjìlá tí mo fi sin ẹ̀mí náà, ọmọ mi mẹ́fà ló kú.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó ràn mí lọ́wọ́. Mo gbàdúrà tọkàntọkàn. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kanlẹ̀kùn mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo sábà máa ń lé wọn ni, mo pinnu lọ́jọ́ yẹn láti gbọ́ ohun tí wọ́n ní láti sọ. Ohun tí wọ́n bá mi sọ jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹ̀mí èṣù ni mò ń sìn! Ni mo bá pinnu láti jáwọ́ nínú ìbẹ́mìílò.

Ìgbà tí mo sọ ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ẹ̀mí náà, ó kìlọ̀ fún mi pé kí n má dán an wò. Ṣùgbọ́n, mo sọ pé: “Mi ò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ẹ mọ́.”

Mo sun gbogbo ohun tí mo fi ń ṣe iṣẹ́ wíwò níná. Mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí, mo di ìránṣẹ́ Jèhófà, mo sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1973. Nísinsìnyí, mo ní ọmọ márùn-ún tí ara wọn dá ṣáṣá. Ọkọ mi pẹ̀lú di Ẹlẹ́rìí tó ṣèrìbọmi.—Gẹ́gẹ́ bí Josephine Ikezu ṣe sọ ọ́.

Àpótí: Báwo ni obìnrin kan ṣe já ara rẹ̀ gbà lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́