ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/1 ojú ìwé 24
  • Awọn Olùwá Otitọ Kiri Dahunpada Sí Ijẹrii Aláìjẹ́ Bí Àṣà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Olùwá Otitọ Kiri Dahunpada Sí Ijẹrii Aláìjẹ́ Bí Àṣà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Dé Tí Ẹ Kì Í Ṣe Kérésìmesì?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Keresimesi—Eeṣe Ti Ó Fi Gbajúmọ̀ Tobẹẹ ni Japan?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kí Ni Keresimesi Túmọ̀ Sí fún Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/1 ojú ìwé 24

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Awọn Olùwá Otitọ Kiri Dahunpada Sí Ijẹrii Aláìjẹ́ Bí Àṣà

BIBELI fi tó wa leti pe awọn ẹni bi agutan yoo dahunpada sí ohùn Oluṣọ agutan Rere naa. (Johanu 10:27) Eyi ti jẹ́ bẹẹ ni ọpọlọpọ ilẹ, ti o ní Britain ninu.

◻ Fun apẹẹrẹ, ni 1988, kété ṣaaju Keresimesi, Pamela, ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dahun ìkésíni tẹlifoonu ninu ọfiisi ibi ti ó ti nṣiṣẹ ó sì ba ọkunrin ontaja kan ti nṣiṣẹ fun ile-iṣẹ kan naa ni apa ibomiran ni England sọrọ. Ni opin ikesini naa, ọkunrin naa beere pe: “Iwọ ha ti murasilẹ fun Keresimesi bi? Pamela sọ pe: “Bẹẹkọ!” “Ko ha ti pẹ́ ọ jù bi?” ni olùkésíni naa beere. “Emi kii ṣe ayẹyẹ Keresimesi,” ni Pamela fesi pada. Ọkunrin naa wi pe iyẹn ṣajeji o sì beere idi rẹ̀. Pamela sọ fun un pe oun jẹ́ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa o sì nbaa lọ lati salaye pe ko sí aṣẹ kankan ninu Bibeli lati ṣayẹyẹ ọjọ ìbí Jesu, ati yatọ si iyẹn, a kò bí Jesu ni December 25. Siwaju sii, Keresimesi jẹ́ ayẹyẹ abọriṣa ni ipilẹṣẹ. Olùkésíni naa sọ pe gbogbo ọrọ rẹ̀ jọ pe ó runilọkan soke.

Oṣu mẹta lẹhin naa Pamela dahun ìkésíni lori foonu, olùkésíni naa sì wi pe: “Iwọ ha ranti pe o bá mi sọrọ ṣaaju Keresimesi ti o sì sọ fun mi pe iwọ kii ṣayẹyẹ Keresimesi bi? O dara, mo ti rí otitọ!” Ó jẹ ọkunrin kan naa, o sì ṣalaye pe ọsẹ meji lẹhin Keresimesi, awọn Ẹlẹ́rìí meji wá si ile rẹ̀. Ó ké sí wọn wọle, ikẹkọọ Bibeli sì bẹrẹ. Ó rohin pe oun ti ṣe itẹsiwaju ti ó yara kánkán ninu ikẹkọọ oun. Ó sọ fun ọrẹbinrin rẹ̀ ti nba a gbe pe ọna igbesi-aye awọn kò wu Jehofa, nitori naa wọn pinya ati nisinsinyi awọn mejeeji nlọ si ipade ni Gbọngan Ijọba.

Ni opin ọdun naa, a tẹwọgba wọn gẹgẹ bi akede alaiṣeribọmi, ati ni ibẹrẹ 1990 wọ́n ṣegbeyawo. Lẹhin naa wọn ṣeribọmi nigba kan naa. Iyọrisi agbayanu kan lati inu ijẹrii ṣoki, alaijẹ bi aṣa lori tẹlifoonu!

◻ Jehofa bukun arabinrin miiran ti ó jẹrii lọna aijẹ bi aṣa ni England. Nigba ti ọkunrin oṣiṣẹ abanigbofo kan wá sí ẹnu ọna rẹ̀, arabinrin naa beere lọwọ rẹ̀ bi oun yoo ba fẹ lati gba idaloju ilera didara, ayọ, ati iye ainipẹkun. O sọ pe bẹẹni o sì beere ilana eto abánigbófò ti ó nsọrọ nipa rẹ̀. Nigba ti a fi ileri Ọlọrun ti iye ainipẹkun ninu Paradise ilẹ-aye han an ninu Bibeli, o gba ẹda kan iwe naa Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye ó sì ka gbogbo itẹjade naa tan ni irọlẹ kan. Nigba ti o bẹ arabinrin naa wò lẹẹkan si, ó sọ fun un pe isọfunni naa jẹ́ agbayanu—kiki bi oun bá ni igbagbọ lati gba a gbọ. Arabinrin naa ṣalaye pe ó nilati kẹkọọ Bibeli ki ó sì maa lọ sí awọn ipade ni Gbọngan Ijọba. Ikẹkọọ Bibeli ni a ṣeto, ó sì bẹrẹ sii lọ si awọn ipade. A bamtisi rẹ̀ ni igba ẹ̀rùn ni ọdun yẹn kan naa. Kìkì ọdun kan lẹhin naa ó fẹ́ ọmọbinrin arabinrin naa ti ó ti jẹrii fun un. Arabinrin naa wi pe, “Nitori naa mo jere arakunrin ati àna nipasẹ ijẹrii alaijẹ bi aṣa mi!”

Ó jẹ́ otitọ pe awọn olùwá otitọ kiri ndahunpada nigba ti a bá tàtaré otitọ Bibeli nipasẹ ijẹrii alaijẹ bi aṣa. Gẹgẹ bi Jesu ti wí, awọn agutan rẹ̀ nfetisilẹ si ohùn rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́