‘Gbigba Imọ Nipa Ọlọrun Ati Jesu Sinu’
“ÌYÈ ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ ran.” (Johanu 17:3) Bẹẹ ni Jesu ṣe sọ ninu adura si Baba rẹ̀ ọrun, ati ni ọna yii ó fi ohun àkọ́kọ́ beere ṣiṣekoko fun ìyè ayeraye han. Bi o ti wu ki o ri, eeṣe ti New World Translation fi tumọ ẹsẹ yii si “ń gba ìmọ̀ . . . Ọlọrun” dipo “mọ . . . Ọlọrun,” gẹgẹ bi ọpọjulọ awọn ẹ̀dà itumọ Bibeli miiran ṣe ṣalaye rẹ̀?—Tun wo àlàyé ẹsẹ iwe si Johanu 17:3, NW.
Ọrọ Giriiki ti a tumọ nihin-in sí ‘gba ìmọ̀ sinu’ tabi “mọ” jẹ́ ẹ̀dà ọrọ iṣe naa gi·noʹsko. Iṣetumọ ninu New World Translation ni a sì pete lati mu itumọ ọrọ yẹn jade ni kikun bi o ti lè ṣeeṣe tó. Itumọ gi·noʹsko ni ipilẹ ni lati “mọ,” ṣugbọn ọrọ Giriiki naa ni oniruuru itumọ abẹ́nú. Ṣakiyesi awọn itumọ ti ó tẹle e yii:
“GINŌSKŌ (γινώσκω) duro fun lati maa gba ìmọ̀ sinu, lati wá lati mọ̀, mọdaju, loye, tabi lati loye patapata.” (Expository Dictionary of New Testament Words, W. E. Vine) Fun idi yii, titumọ gi·noʹsko si ‘gba ìmọ̀ sinu’ kii ṣe ‘yiyi Bibeli pada,’ gẹgẹ bi awọn oluṣelameyiitọ New World Translation ti sọ. Ninu ijiroro oniruuru itumọ abẹ́nú tí ọrọ naa lè kópọ̀, ìjìmì onṣewe atumọ èdè James Hope Moulton sọ pe: “Ọrọ kanṣoṣo pọ́ńbélé ti ń tọka iṣẹlẹ lọwọlọwọ naa, γινώσκειν, jẹ́ eyi ti ń fi ohun tí ń baalọ hàn, ‘lati maa gba ìmọ̀ sinu.’”—A Grammar of New Testament Greek.
Iwe A Grammatical Analysis of the Greek New Testament ṣalaye gi·noʹsko gẹgẹ bi o ti farahan ni Johanu 17:3 gẹgẹ bi eyi ti o “damọran ọ̀nà ìgbà ṣiṣẹ ti ń baa lọ.” Àlàyé siwaju sii lori ọrọ Giriiki yii farahan ninu Word Studies in the New Testament, lati ọwọ Marvin R. Vincent. Eyi sọ pe: “Ìmọ̀ jẹ́ apa pataki kan ninu ìyè ayeraye, tabi dipo bẹẹ ilepa ìmọ̀, niwọn bi ọrọ atọka akoko iṣẹlẹ lọwọlọwọ naa ti sami si ìlóye kan ti ń baa lọ, ti ń tẹsiwaju.” (Ikọwe wínníwínní jẹ́ tirẹ̀.) Word Pictures in the New Testament ti A. T. Robertson damọran titumọ ọrọ naa “nilati maa baa lọ ni mímọ̀.”
Nitori naa, ninu ojulowo Giriiki, awọn ọrọ Jesu ní Johanu 17:3 dọgbọn tumọsi isapa ti ń baa lọ lati mọ Ọlọrun tootọ naa ati Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, eyi ni a sì mu jade daradara ninu iṣetumọ New World Translation. A ń gba ìmọ̀ yii nipa ikẹkọọ alaapọn ninu Ọrọ Ọlọrun ati nipa fifi igbọran mu igbesi-aye wa ba awọn ọpa idiwọn rẹ̀ mu. (Fiwe Hosea 4:1, 2; 8:2; 2 Timoti 3:16, 17.) Ẹsan rere wo ni o duro de awọn wọnni ti wọn sọ araawọn dojulumọ Ọlọrun gẹgẹ bi ẹnikan ati ti Ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn sì làkàkà lẹhin naa lati ṣafarawe wọn? Ìyè ainipẹkun!