ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 3/1 ojú ìwé 22
  • Jehofa San Ẹsan Rere Fun Ọdọ Oluṣotitọ kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa San Ẹsan Rere Fun Ọdọ Oluṣotitọ kan
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíjẹ́rìí Ń So Èso ní Ilé àti ní Ilé Ẹ̀kọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Iwọ Ha Ń Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Lati Yan Jehofa Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Fara Wé Jèhófà Nígbà Tóo Bá Ń tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ̀yin Èwe Ẹ Lè Múnú Àwọn Òbí Yín Dùn Tàbí Kẹ́ Ẹ Bà Wọ́n Nínú Jẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 3/1 ojú ìwé 22

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Jehofa San Ẹsan Rere Fun Ọdọ Oluṣotitọ kan

AWỌN ọdọ oluṣotitọ ṣeyebiye gan-an loju Jehofa. Iriri ti o tẹle e yii ti ọdọkunrin oluṣotitọ kan gbọdọ fun awọn ọdọ miiran niṣiiri lati pa iwatitọ wọn mọ bi wọn ti ń ṣiṣẹsin Jehofa.

Ni Argentina ọdọmọkunrin ẹni ọdun 11 ati aburo rẹ̀ ọkunrin kẹkọọ iwe naa Otitọ ti Nṣinni Lọ si Iye Aiyeraiye lọdọ iya wọn àgbà. Lọ́gán, obi awọn ọmọdekunrin naa fi àtakò han, wọn sì kà á léèwọ̀ fun wọn lati lọ si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba. Fun akoko kan, ki wọn baa lè lọ si awọn ipade, awọn ọmọdekunrin naa gba oju ferese balùwẹ̀ jade, wọn bẹ́ sori ìgbásẹ̀ ogiri, ati lati ibẹ̀ bọ́ sí odikeji ogiri lọ si ìgbásẹ̀ ogiri aladuugbo ati lati ibẹ̀ lọ si Gbọngan Ijọba. Lẹhin naa ẹnikan sọ fun iya wọn pe wọn ń lọ si ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ìyá naa halẹ̀ nínà mọ́ wọn, eyi sì dáyàfo ọmọdekunrin ti o jẹ́ aburo, ẹni ti o pa kikẹkọọ tì. Ṣugbọn eyi ẹgbọn tẹpẹlẹmọ́ ọn. Fun ọdun marun-un o dọgbọn lati lọ si awọn ipade laijẹ ki awọn obi rẹ̀ mọ̀.

Nigba ti o pe ọmọ ọdun 16, ó fẹ lati kọ ẹkọ kan ti wọn kii kọ́ni ni ilu rẹ̀ ni ile-iwe giga. Kikuro ni ile yoo fun un ni ominira pupọ sii lati lepa otitọ. Awọn obi rẹ̀ gbà lati jẹ ki o lọ, ohun gbogbo sì lọ deedee fun oṣu mẹta. Lẹhin naa ọ̀gá ile-ẹkọ giga naa fi tó awọn obi rẹ̀ leti pe ọmọkunrin wọn kìí kí àsíá tabi kọ orin orilẹ-ede. Ni iwaju awujọ awọn ọ̀gá ile-ẹkọ giga, awọn obi rẹ̀, akọwe kan, lọ́yà kan, ati ọjọgbọn mẹwaa, ọdọmọkunrin naa ni o ṣeeṣe fun lati funni ni ẹ̀rí daradara gan-an nipa idi ti oun kò fi ṣe awọn nǹkan wọnyi pẹlu ẹ̀rí-ọkàn. (Ẹkisodu 20:4, 5) Awọn obi rẹ̀ gbanájẹ. Ìyá naa ra ìbọn revolver, ó ní i lọkan lati yìnbọn lu ìyá àgbà, ti ó kà sí ẹni ti ó dá eyi silẹ. Ṣugbọn kò lè rí i ki o danikan wà.

Nigba ti o yá, ní titẹle idamọran ọ̀rẹ́ idile naa kan ati pẹlu ifọwọsi ọ̀gá ile-ẹkọ giga naa, awọn obi naa pinnu lati mu ọ̀dọ́ naa lọ si ile iṣegun fun aisan ọpọlọ, ni rírò pe iwosan àrùn ọpọlọ yoo mú ki o pa igbagbọ rẹ̀ tì. Awọn oṣiṣẹ ile iṣegun naa fi ọkọ ayọkẹlẹ gbé ọmọdekunrin naa lọ jinna si 60 ibusọ wọn sì gún un ni abẹrẹ insulin ati awọn oogun miiran ti iwọn rẹ̀ pọ titi ti yoo fi padanu níní imọlara. Nigba ti o bá jí, kò ni mọ ohun ti ó ń ṣe mọ́, kò mọ ẹnikankan, o sì niriiri ìgbàgbé lápákan. Lẹhin ọpọlọpọ àyẹ̀wò awọn dokita kò lè ri ìdàrúdàpọ̀ ọpọlọ kan lara rẹ̀. Ṣugbọn ile iṣegun naa ṣì ń bá itọju iṣegun naa lọ. Nigba ti iyè rẹ̀ sọji, ọmọdekunrin naa gbadura leralera si Jehofa lati maṣe fi oun silẹ ó sì bẹ̀ ẹ́ fun okun lati farada. Jehofa daabobò ó, ati ni aṣẹhinwa-aṣẹhinbọ a dá a silẹ kuro ni ile iṣegun naa.

Ni akoko kan ni ọ̀gá ile-ẹkọ giga naa beere lọwọ ọdọkunrin naa bi o bá ti ṣetan lati yí ero rẹ̀ pada. Nigba ti ó sọ pe rárá, ọ̀gá ile-ẹkọ giga naa sọ fun awọn obi rẹ̀ lati mú un pada lọ si ile iṣegun nitori pe ori rẹ̀ ti daru ju ti tẹlẹ lọ. Awọn obi rẹ̀ mu un lọ si ile ti a ti ń founjẹ bọ́ ọ wọn sì sọ fun ìyá onile naa lati rí i daju pe kò lọ si ipade Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Lẹhin ti awọn obi rẹ̀ ti lọ tán, iru iyalẹnu wo ni ọmọdekunrin naa rigba! Awọn ti wọn ni ile ti a ti ń fi ounjẹ bọ́ ọ naa jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa! Nikẹhin awọn obi mu un kuro lẹnu itọju iwosan àrùn ọpọlọ, ó dá wọn loju pe awọn dokita naa ti purọ fun wọn. Ni àfo akoko yii ná Ile-ẹjọ Gigaju ti Argentina paṣe pe ọmọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a kò lè lé kuro ni ile-ẹkọ nitori ṣiṣai ki àsíá.

Awọn adanwo wọnyi ha ṣanfaani fun ọ̀dọ́ oluṣotitọ yii bi? Bẹẹni. Ó sọ pe: “Ó ṣeeṣe fun mi lati fi ijẹrii gbigbooro fun awọn dokita, ọjọgbọn, ọmọ ile-iwe ẹlẹgbẹ mi, awọn obi, ati ibatan, ati, gbogbo ilu naa niti gidi. Awọn obi mi ti rọ̀ lọna kan ṣáá wọn sì ni èrò didara ju nipa Awọn Ẹlẹ́rìí. Nisinsinyi, nigba ti mo ba wẹhin pada si igba ọmọde mi, mo ri bi Ọlọrun wa ti jẹ́ agbayanu ati onijẹlẹnkẹ tó ni bibojuto ẹnikan ti ó duroṣinṣin tì í. Ó jẹ́ bi onisaamu naa ti sọ gẹlẹ ni Saamu 27:10 pe: ‘Nigba ti baba ati ìyá mi kọ̀ mi silẹ, nigba naa ni Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo tẹwọgba mi.’”

Ọdọmọkunrin yii jẹ́ ẹni ọdun 23 nisinsinyi, ó ti gbeyawo, ó sì jẹ́ alaapọn ninu iṣẹ-isin Jehofa. Nitootọ, agbara agbeniro Jehofa kò ni ààlà.—Saamu 55:22.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́