Jèhófà Ti Jẹ́ Ààbò Mi
GẸ́GẸ́ BÍ PENELOPE MAKRIS ṢE SỌ
Màmá mi fi taratara bẹ̀ mí pé: “Fi ọkọ rẹ sílẹ̀; àwọn arákùnrin rẹ yóò bá ọ wá ẹni tí ó sàn jù.” Èé ṣe tí màmá mi onífẹ̀ẹ́ fi fẹ́ kí n tú ìgbéyàwó mi ká? Kí ni ó mú inú bí i tó bẹ́ẹ̀?
ABÍ mi ní 1897, ní abúlé kékeré Ambelos, ní erékùṣù ilẹ̀ Gíríìsì ti Samos. Ìdílé wá jẹ́ mẹ́ḿbà olùfọkànsìn ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì. Bàbá kú gẹ́rẹ́ ṣáájú kí a tó bí mi, èmí, Màmá, àti àwọn arákùnrin mi mẹ́ta sì ní láti ṣiṣẹ́ kára kí a ṣáà lè wà láàyè nínú ipò òṣì paraku tí ń bẹ ní àkókò wọ̀nyẹn.
Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1914, kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà, a pàṣẹ fún àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin méjèèjì láti kó wọnú iṣẹ́ ológun. Ṣùgbọ́n láti lè yẹra fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣí lọ sí America, ní fífi èmi àti arákùnrin mi kan yóò kù sílẹ̀ nílé pẹ̀lú Màmá. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, ní 1920, mo fẹ́ Dimitris, olùkọ́ kan tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ ní abúlé wa.
Ìbẹ̀wò Pàtàkì Kan
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣègbéyàwó, ẹ̀gbọ́n màmá mi ọkùnrin wá láti America láti bẹ̀ wá wò. Ó mú ọ̀kan nínú àwọn ìdìpọ̀ ìwé Studies in the Scriptures, tí Charles Taze Russell kọ dání. Ìtẹ̀jáde àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí a mọ̀ nísinsìnyí sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.
Nígbà tí Dimitris ṣí ìwé náà, ó kíyè sí kókó ẹ̀kọ́ kan tí ó ti ń ṣiyè méjì nípa rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọdé pé, “Kí ni ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn nígbà tí ó bá kú?” Ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó ti béèrè nípa kókó ẹ̀kọ́ yìí gan-an lọ́wọ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì kan, ṣùgbọ́n kò rí ìdáhùn tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn gbà. Àlàyé ṣíṣe kedere, tí ó sì bọ́gbọ́n mu tí a pèsè nínú ìtẹ̀jáde náà mú inú Dimitris dùn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi lọ tààràtà sí ilé tí wọ́n ti ń ta kọfí ní abúlé náà, níbi tí àwọn ọkùnrin ní ilẹ̀ Gíríìsì tí máa ń kójọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà. Ibẹ̀ ni ó ti ròyìn àwọn ohun tí ó rí kọ́ nínú Bíbélì.
Ìdúró Wa fún Òtítọ́ Bíbélì
Ní àkókò yìí—ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920—ilẹ̀ Gíríìsì ti tún wà nínú ogun mìíràn. A fi agbára mú Dimitris, a sì rán an lọ sí ẹ̀bákè ilẹ̀ Turkey, ní Éṣíà Kékeré. Ó fara gbọgbẹ́, a sì rán an padà sílé. Lẹ́yìn tí ó kọ́fẹ padà, mo bá a lọ sí Símínà, ní Éṣíà Kékeré (tí ó ń jẹ́ Izmir, ní Turkey nísinsìnyí). Nígbà tí ogun náà parí lójijì ní 1922, a ní láti sá lọ. Ní tòótọ́, agbára káká ni a fi sá àsálà kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi kan, tí ó bàjẹ́ kọjá àlà, lọ sí Samos. Nígbà tí a délé, a kúnlẹ̀ a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run—Ọlọ́run tí ó jẹ́ pé ìmọ̀ tí kò tó nǹkan ni a ṣì ní nípa rẹ̀.
Láìpẹ́, a yanṣẹ́ fún Dimitris láti kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ tí ó wà ní Vathy, olú ìlú erékùṣù náà. Ó ń bá a nìṣó láti máa ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn méjì lára wọn láti erékùṣù Chios sì bẹ̀ wá wò ní alẹ́ ọjọ́ kan tí òjò ń rọ̀. Wọ́n padà wá láti America láti ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùpín ìwé ìsìn kiri, bí a ṣe ń pe àwọn ajínhìnrere alákòókò kíkún nígbà náà lọ́hùn-ún. A gbà wọ́n sílé lóru yẹn, wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa àwọn ète Ọlọ́run.
Lẹ́yìn náà, Dimitris sọ fún mi pé: “Penelope, mo rí i pé òtítọ́ nìyí, mo sì gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé e. Èyí túmọ̀ sí pé mo gbọ́dọ̀ ṣíwọ́ kíkọrin nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì, àti pé n kò ní lè máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀lú àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ wa nípa Jèhófà kéré, ìfẹ́ ọkàn wa láti ṣiṣẹ́ sìn ín lágbára. Nítorí náà, mo fèsì pé: “N kò ní jẹ́ ohun ìdíwọ́ fún ọ. Ṣáà tẹ̀ síwájú.”
Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n bí ipa ọ̀nà wá bá hàn sí gbangba, n óò pàdánù iṣẹ́ mi.”
Mo sọ pé: “Má fòyà, ṣe iṣẹ́ olùkọ́ ni gbogbo ènìyàn ń ṣe jẹun ni? Ọ̀dọ́ ni wá, a sì lágbára, Ọlọ́run sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ mìíràn.”
Ní àkókò yìí, a gbọ́ pé Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míràn—tí ó tún jẹ́ olùpín ìwé ìsìn kiri—ti wá sí Samos. Nígbà tí a gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá kò fún un láyè láti sọ ọ̀rọ̀ àsọyé Bíbélì, a bẹ̀rẹ̀ sí í wá a kiri. A rí i nínú ilé ìtàjà kan tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ilẹ̀ Gíríìsì méjì sọ̀rọ̀. Bí ojú ti ti àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà nítorí pé wọn kò lè fi Bíbélì gbèjà ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n lọ láìpẹ́. Bí ìmọ̀ tí olùpín ìwé ìsìn kiri náà ní ti wú ọkọ mi lórí, ó béèrè pé: “Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé o lè lo Bíbélì tìrọ̀rùntìrọ̀rùn bẹ́ẹ̀?”
Ó fèsì pé: “A ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé ni.” Ní ṣíṣí àpò rẹ̀, ó mú ìwé náà, Duru Ọlọrun, jáde, ó sì fi bí a ṣe ń lo ìwé yìí nínú irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ hàn wá. A hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pé lọ́gán, èmi, ọkọ mi, olùpín ìwé ìsìn kiri náà, àti àwọn ọkùnrin méjì míràn bá onílé ìtàjà náà lọ sí ilé rẹ̀. Olùpín ìwé ìsìn kiri náà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ẹ̀dà ìwé Duru Ọlọrun, a sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ lójú ẹsẹ̀. A ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nìṣó títí tí àjìn òru fi kọjá dáadáa, bí ilẹ̀ sì ti ń mọ́ lọ, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn orin tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń kọ.
Láti ìgbà yẹn lọ, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wákàtí mélòó kan lójúmọ́. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ilẹ̀ òkèèrè ń pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wa. Ní January 1926, mo ṣe ìyàsímímọ́ mi sí Ọlọ́run nínú àdúrà, ní jíjẹ́jẹ̀ẹ́ pátápátá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, èmi àti ọkọ mi fi àmì ìyàsímímọ́ wa hàn nípasẹ̀ batisí nínú omi. A ní ìfẹ́ ọkàn lílágbára láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a ti kọ́, nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé ní lílo ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Message of Hope.
Fífarada Àtakò Gbígbóná Janjan
Ní ọjọ́ kan, ọ̀dọ́bìnrin kan ké sí mi láti wá sí ààtò ìsìn kan ní ilé ìjọsìn kékeré kan, tí ó jẹ́ ti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìsì. Mo ṣàlàyé pé: “Mo ti ṣíwọ́ jíjọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà yẹn. Nísinsìnyí, mo ń jọ́sìn rẹ̀ ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti fi kọ́ni.” (Jòhánù 4:23, 24) Ó yà á lẹ́nu, ó sì ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ káàkiri, ó kó bá ọkọ mi pẹ̀lú.
Ní ti gidi, olúkúlùkù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàtakò. A ò rí imú mí mọ́—ì báà jẹ́ nílé wa tàbí ní àwọn ìpàdé tí a máa ń bá àwọn olùfìfẹ́hàn mélòó kan tí ń bẹ ní erékùṣù náà ṣe. Bí àwọn àlùfáà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ru àwọn èrò sókè, wọ́n pé jọ sí ìta ibi ìpàdé wa, wọ́n ń ju òkúta, wọ́n sì ń kígbe bí wọ́n ti ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ èébú.
Nígbà tí a pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Message of Hope, àwọn ọmọdé péjọ yíká wa, wọ́n sì ń ké igbe “Ẹ̀yin Onígbàgbọ́ Ẹgbẹ̀rúndún” àti àwọn gbólóhùn tí ń buni kù míràn. Àwọn ẹlẹgbẹ́ ọkọ mi ní ibi iṣẹ́ tún bẹ̀rẹ̀ sí í kógun tì í. Ní ìparí 1926, a pè é lẹ́jọ́, a fẹ̀sùn kàn án pé kò tóótun láti jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ìjọba, a sì jù ú sẹ́wọ̀n ọjọ́ 15.
Nígbà tí Màmá gbọ́ nípa èyí, ó gbà mí nímọ̀ràn láti fi ọkọ mi sílẹ̀. Mo fèsì pé: “Màmá mi ọ̀wọ́n, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin náà mọ̀ bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín gan-an tó, tí mo sì bọ̀wọ̀ fún un yín tó. Ṣùgbọ́n, n kò wulẹ̀ lè jẹ́ kí ẹ dí wa lọ́wọ́ jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà.” Ó padà sí abúlé rẹ̀ pẹ̀lú ìjákulẹ̀ gidigidi.
Ní ọdún 1927, a ṣe àpéjọ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Áténì, Jèhófà sì mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti lọ. Inú wá dùn, a sì fún wa lókun nípa tẹ̀mí nípa pípéjọ pọ̀ pẹ̀lú ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni. Ní pípadà sí Samos, a pín 5,000 ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, A Testimony to the Rulers of the World, kiri ní ìlú àti abúlé tí ó wà ní erékùṣù wa.
Ní àkókò yẹn, a lé Dimitris kúrò lẹ́nu iṣẹ́ olùkọ́ rẹ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé ṣe láti rí iṣẹ́, nítorí ẹ̀tanú tí a ní sí wa. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí mo ti mọ aṣọ rán, tí Dimitris sì jẹ́ kunlékunlé tí ó kọ́ṣẹ́mọṣẹ́, ó ṣeé ṣe fún wa láti rí owó gbọ́ bùkátà. Ní ọdún 1928, a fi ọkọ mi, títí kan àwọn Kristẹni arákùnrin mẹ́rin yòó kù ní Samos, sí ẹ̀wọ̀n oṣù méjì nítorí wíwàásù ìhìn rere. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣoṣo tí ó wà lómìnira, ó ṣeé ṣe fún mi láti pèsè oúnjẹ fún wọn nínú ẹ̀wọ̀n.
Bíbá Àìlera Lílekoko Jagun
Nígbà kan, àrùn tubercular spondylitis kọlù mí, àrùn búburú jáì kan, tí a kò tí ì mọ̀ nígbà náà. Oúnjẹ kò wù mí jẹ mọ́, mo sì ní akọ ibà tí kò dáwọ́ dúró. Ìtọ́jú ní mímọ nǹkan yí ara mi ká láti ọrùn mi títí dé itan mi, nínú. Láti lè kájú ìnáwó náà, ọkọ mi ta ilẹ̀ kan kí n baà lè máa gba ìtọ́jú nìṣó. Bí wàhálà ti bá mi, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run lójoojúmọ́ fún okun.
Nígbà tí àwọn ìbátan bá ṣe ìbẹ̀wò sí ọ̀dọ̀ mi, wọ́n ń bá a nìṣó láti mú àtakò gbóná janjan. Màmá sọ pé gbogbo wàhálà wọ̀nyí ń bá wa nítorí pé a ti yí ìsìn wa padà. Níwọ̀n bí n kò ti lè yíra padà, mo fi omijé rẹ ìrọ̀rí mi gbìngbìn bí mo ti ń fi taratara bẹ Bàbá wa ọ̀run láti fún mi ní sùúrù àti ìgboyà láti fara dà.
Lórí tábìlì ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi, mo kó Bíbélì mi àti ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé àṣàrò kúkúrú díẹ̀ síbẹ̀ fún àwọn àlejò. Ìbùkún ni ó jẹ́ pé ilé wa ni ìjọ wa kékeré ti ń ṣe ìpàdé; ó ṣeé ṣe fún mi láti gba ìṣírí tẹ̀mí déédéé. A ní láti ta ilẹ̀ míràn sí i láti lè san owó ìtọ́jú ìṣègùn tí dókítà kan láti Áténì ṣe.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, alábòójútó arìnrìn àjò bẹ̀ wá wò. Ó káàánú láti rí mi ní ipò yìí, àti láti rí Dimitris láìníṣẹ́ lọ́wọ́. Lọ́nà onínúure, ó ràn wá lọ́wọ́ láti ṣètò láti gbé ní Mytilene ní erékùṣù Lesbos. A ṣí lọ síbẹ̀ ní 1934, ó sì ṣeé ṣe fún Dimitris láti rí iṣẹ́. Níbẹ̀, a tún rí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin àtàtà, tí wọ́n bójú tó mi nínú àìlera mi. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lẹ́yìn ìtọ́jú ọdún márùn-ún, mo kọ́fẹ padà pátápátá.
Ṣùgbọ́n, ní 1946, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, mo tún ṣàìsàn gidigidi, lọ́tẹ̀ yìí, ó jẹ́ àìsàn tubercular peritonitis. Mo wà lórí ibùsùn fún oṣù márùn-ún, tí mo ní ibà líle koko àti ìrora gidigidi. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bíi ti ìṣáájú, n kò ṣíwọ́ bíbá àwọn àlejò mi sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. Láìpẹ́, ara mí le.
Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Láìka Àtakò Sí
Àtakò tí kò dáwọ́ dúró ṣẹlẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Gíríìsì ní àwọn ọdún ẹ̀yìn ogun. A fàṣẹ ọba mú wa lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí a ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Ọkọ mi lo èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan lẹ́wọ̀n ní àpapọ̀. Nígbà tí a bá ń jáde lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, a sábà máa ń wéwèé láti lo òru náà lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá lábẹ́ ìfàṣẹ ọba múni. Síbẹ̀, Jèhófà kò pa wá tì láé. Ìgbà gbogbo ni ó máa ń pèsè ìgboyà àti okun tí a nílò láti fara dà.
Ní àwọn ọdún 1940, mo ka nínú Informant (tí a ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nísinsìnyí) nípa ìpèsè tí ó wà fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà alákòókò ìsinmi. Mo pinnu láti gbìyànjú nínípìn-ín nínú apá iṣẹ́ ìsìn yìí tí ó ń béèrè yíya wákàtí 75 sọ́tọ̀ lóṣù fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi pọ̀ sí i—ní àkókò kan, mo ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ 17 lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mo tún bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn ní agbègbè ìṣòwò ti Mytilene, níbi tí mo ti máa ń kó nǹkan bíi 300 ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ sí àwọn ilé ìtàjà, ọ́fíìsì, àti báǹkì déédéé.
Nígbà tí alábòójútó arìnrìn àjò bẹ ìjọ wa wò ní ọdún 1964, ó sọ pé: “Arábìnrin Penelope, mo rí àṣeyọrí àgbàyanu tí o ń ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ láti inú àkọsílẹ̀ Publisher’s Record Card rẹ. Èé ṣe tí o kò fi kọ̀wé béèrè fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé?” Gbogbo ìgbà ni n óò máa dúpẹ́ fún ìṣírí rẹ̀; iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti jẹ́ ìdùnnú mi fún ohun tí ó ju ẹ̀wádún mẹ́ta lọ.
Ìrírí Tí Ó Lérè
Ní Mytilene, àdúgbò kíkún fọ́fọ́ kan wà tí a ń pè ní Langada, níbi tí àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí wọ́n jẹ́ Gíríìkì ń gbé. A yẹra fún lílọ láti ẹnu-ọ̀nà-dé-ẹnu-ọ̀nà níbẹ̀ nítorí àtakò ẹhànnà tí a ti bá pàdé. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ọkọ mi fi wà lẹ́wọ̀n, mo ní láti gba agbègbè yìí kọjá láti bẹ̀ ẹ́ wò. Ní ọjọ́ kan tí òjò ń rọ̀, obìnrin kan ké sí mi sínú ilé rẹ̀ láti béèrè ìdí tí ọkọ mi fi wà lẹ́wọ̀n. Mo ṣàlàyé pé ó jẹ́ nítorí wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àti pé ó ń jìyà gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi ṣe jìyà.
Láìpẹ́, obìnrin mìíràn ṣètò fún mi láti dúró ní ilé rẹ̀. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí i pé ó ti ké sí obìnrin 12 lápapọ̀. Mo fojú sọ́nà pé àtakò lè ṣẹlẹ̀, nítorí náà, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run láti fún mi ní ọgbọ́n àti ìgboyà láti kojú ohun yòó wù kí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn obìnrin náà ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè, àwọn kan sì ṣàtakò, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe fún mi láti pèsè àwọn ìdáhùn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. Nígbà tí mo dìde láti máa lọ, obìnrin onílé náà sọ pé kí n tún padà wá lọ́jọ́ kejì. Mo fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà. Nígbà tí èmi àti ẹnì kejì mi débẹ̀ ní ọjọ́ kejì, a bá àwọn obìnrin náà tí wọ́n ti ń dúró dè wá.
Lẹ́yìn ìgbà náà, ìjíròrò wa láti inú Ìwé Mímọ́ ń bá a nìṣó déédéé, a sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn kan lára àwọn obìnrin náà tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ pípéye, àwọn ìdílé wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwùjọ yìí ni ó wá di ìpìlẹ̀ ìjọ tuntun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mytilene.
Jèhófà Ti Ṣe Mí Lóore
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, Jèhófà ti san ẹ̀san fún ìsapá ọkọ mi àti tèmi láti ṣiṣẹ́ sìn Ín. Ìwọ̀nba kéréje àwọn Ẹlẹ́rìí ní Samos ní àwọn ọdún 1920 ti dàgbà sókè di ìjọ méjì àti àwùjọ kan tí ó ní nǹkan bí 130 akéde. Àti ní erékùṣù Lesbos, ìjọ mẹ́rin àti àwùjọ márùn-ún tí ó ní nǹkan bí 430 àwọn olùpòkìkí Ìjọba ni ó ń bẹ níbẹ̀. Ọkọ mi pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run tìtaratìtara títí tí ó fi kú ní ọdún 1977. Ẹ wo àǹfààní tí ó jẹ́ láti rí àwọn tí a ràn lọ́wọ́ tí wọ́n ṣì jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ síbẹ̀! Họ́wù, pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, pẹ̀lú àwọn ọmọ-ọmọ wọn, àti pẹ̀lú àwọn ọmọ tí àwọn ọmọ-ọmọ wọ́n bí, wọ́n jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń jọ́sìn Jèhófà ní ìṣọ̀kan!
Ipa ọ̀nà iṣẹ́ ìsìn Kristẹni mi, tí ó ti gba ohun tí ó ju 70 ọdún nísinsìnyí, kì í ṣe èyí tí ó rọrùn. Síbẹ̀, Jèhófà ti jẹ́ odi agbára tí kò láfiwé. Nítorí ọjọ́ ogbó àti ìlera tí ń jagọ̀, orí ibùsùn ni mo wà, díẹ̀ kíún sì ni ìwàásù tí mo lè ṣe. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bíi ti onísáàmù náà, mo lè sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ààbò àti odi mi; Ọlọ́run mi, ẹni tí èmí gbẹ́kẹ̀ lé.”—Orin Dáfídì 91:2.
(Arábìnrin Makris kú nígbà tí a ń ṣètò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí lọ́wọ́. Ó ní ìrètí ti ọ̀run.)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ní 1955
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Arábìnrin Makris ì bá di ẹni 100 ọdún ní January 1997