Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Jẹ́wọ́
“Póòpù Gbé Ṣọ́ọ̀ṣì Sáyé.” “Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀ àti Ìkórìíra Àwùjọ Àwọn Júù—Ṣọ́ọ̀ṣì Ń Múra Láti Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Rẹ̀.” “Jíjẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ fún Ìpakúpa Rẹpẹtẹ.” “Àwọn Onísìn Mẹ́tọ́díìsì Tọrọ Àforíjì Lọ́wọ́ Àwọn Àmẹ́ríńdíà ti Ìwọ̀ Oòrùn.”
ÌWỌ ha ti ka àwọn àkọlé ìròyìn bí ìwọ̀nyí bí? Ó dà bíi pé lọ́nà tí ó ṣe lemọ́lemọ́ sí i, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi wọn, wọ́n sì ń tọrọ àforíjì fún ohun tí wọ́n ti ṣe ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá. Léraléra ni ilé iṣẹ́ ìròyìn ń tẹnu mọ́ ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí póòpù ń ṣe lákọ̀tun.
Ìgbà Tí Póòpù Tọrọ Àforíjì
Láàárín 1980 sí 1996, akọ̀ròyìn Vatican náà, Luigi Accattoli, sọ nínú ìwé rẹ̀ Quando il papa chiede perdono (Ìgbà Tí Póòpù Tọrọ Àforíjì) pé, John Paul Kejì ‘tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi pípàfiyèsí tí Ṣọ́ọ̀ṣì jẹ tàbí ó tọrọ àforíjì’ nígbà 94, ó kéré tán. Gẹ́gẹ́ bí Accattoli ti sọ, “nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, póòpù nìkan ni ó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.” Ó sì ti ṣe èyí, ní títọ́kasí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó fa họ́wùhọ́wù jù lọ nínú ìtàn Kátólíìkì—Ogun Ìsìn, ogun, títi ìjọba aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ lẹ́yìn, ìyapa nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, ìkórìíra Àwùjọ Àwọn Júù, Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀, Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn, àti ẹ̀mí ẹ̀yà tèmi lọ̀gá. Nínú àkọsílẹ̀ ìránnilétí tí a fi ránṣẹ́ ní 1994 sí àwọn kádínà (tí àwọn kan kà sí ìwé àkọsílẹ̀ ṣíṣe pàtàkì jù lọ láti ọ̀dọ̀ póòpù), John Paul Kejì dábàá “jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbogbòò tí a dá ní ẹgbẹ̀rúndún.”
Àwọn bíṣọ́ọ̀bù mélòó kan ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ póòpù. Ní December 1994, ìwé ìròyìn Ítálì náà, Il Giornale, ròyìn pé: “Ọ̀pọ̀ bíṣọ́ọ̀bù Amẹ́ríkà ń fara hàn lórí tẹlifíṣọ̀n, tí wọ́n ń tọrọ àforíjì ní gbangba.” Fún kí ni? Fún fífojú kéré ìṣòro àwọn àlùfáà abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe, sí ìpalára ọ̀pọ̀ ọmọdé tí a ti bá ṣèṣekúṣe. Ní January ọdún 1995, ìwé ìròyìn La Repubblica ròyìn nípa “ìṣe àyẹ́sí tí kò ní àfiwé nínú ìtàn Ìsìn Kátólíìkì òde òní”—a sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro pípa tí Póòpù Pius Kejìlá pẹnu mọ́ ní ti Ìpakúpa Rẹpẹtẹ. Ní January ọdún 1995, ìwé ìròyìn kan náà ròyìn pé àwọn bíṣọ́ọ̀bù Germany tọrọ àforíjì fún “ọ̀pọ̀ ẹ̀bi” àwọn ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì tí ó ti ìwà ọ̀daràn ìjọba Nazi lẹ́yìn. Onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì pẹ̀lú ti ṣe lámèyítọ́ ara wọn.
Èé Ṣe?
Bíbélì rọ̀ wá láti tọrọ àforíjì nígbà tí a bá jẹ̀bi, ọ̀pọ̀ sì gbóṣùbà fún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tí wọ́n ṣe lámèyítọ́ ara wọn. (Jákọ́bù 5:16) Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fi ń ṣe èyí? Báwo ni ó ṣe yẹ kí ó nípa lórí ojú ti a fi ń wò wọ́n?