ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 3/1 ojú ìwé 4-7
  • Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Tọrọ Àforíjì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Tọrọ Àforíjì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwá Ìṣọ̀kan Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé àti Ìdúró Rere
  • Kì Í Ṣe Gbogbo Wọn Ló Gbà
  • Ìdájọ́ Àtọ̀runwá
  • Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Jẹ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣé ‘Ìsìn Tòótọ́’ Kan Ṣoṣo Ló Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Èé Ṣe Tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kò Fi Nípa Lórí Àwọn Ènìyàn Mọ́?
    Jí!—1996
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 3/1 ojú ìwé 4-7

Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Ń Tọrọ Àforíjì?

ÈRÒ pé kí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe ara wọn kì í ṣe tuntun. Religioni e miti (Àwọn Ìsìn àti Ìtàn Àròsọ), ìwé atúmọ̀ èdè tí ó jẹ́ ti ìsìn, sọ pé ìwà títọ́ tí a rò pé ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí ní fa ọkàn àwọn ènìyàn mọ́ra nígbà Sànmánì Agbede Méjì, ó sì sún ọ̀pọ̀ láti béèrè fún àtúnṣe.

Ní ọdún 1523, lẹ́yìn tí Martin Luther ya kúrò nínú ẹ̀sìn Róòmù, Póòpù Adrian Kẹfà gbìdánwò láti mú ìṣọ̀kan wá nípa fífi iṣẹ́ yìí ránṣẹ́ sí Ìpàdé Àwọn Ọ̀tọ̀kùlú ní Nuremberg, ó wí pé: “A mọ̀ dáradára pé, fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ohun tí ó yẹ láti kórìíra ti gbára jọ sórí Ibùjókòó Póòpù . . . A óò sa gbogbo ipá láti ṣàtúnṣe Ọ́fíìsì Róòmù lákọ̀ọ́kọ́ ná, bóyá, inú rẹ̀ ni gbogbo ibi wọ̀nyí ti pilẹ̀ wá.” Ṣùgbọ́n, ìjẹ́wọ́ yẹn kò mú kí ìṣọ̀kan wá, kò sì ṣẹ́pá ìwà ìbàjẹ́ nínú Ọ́fíìsì póòpù.

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí a ti ṣe lámèyítọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì fún àìfọhùn nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ. A tún ti fẹ̀sùn kàn wọ́n fún ṣíṣàìdá àwọn mẹ́ńbà wọn lẹ́kun lílọ́wọ́ nínú ogun. Ní ọdún 1941, bí Ogun Àgbáyé Kejì ti ń jà, àlùfáà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Primo Mazzolari béèrè pé: “Èé ṣe tí Róòmù kò fi tíì fagbára sọ̀rọ̀ lòdì sí ìwólulẹ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe nígbà yẹn, tí ó sì ń ṣe dòní olónìí, nínú àwọn ọ̀ràn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu?” Àwọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu tó èwo? Àlùfáà náà ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tí ń fa ogun, tí ó ba ọ̀làjú jẹ́ pátápátá nígbà náà.

Ṣùgbọ́n, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, bí kì í bá ṣe ni ẹnu àìpẹ́ yìí, ìsìn kì í sábà gbà pé àwọn jẹ̀bi. Ní ọdún 1832, ní dídáhùnpadà sí àwọn kan tí ń rọ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti ‘ṣàtúnṣe ara rẹ̀,’ Gregory Kẹrìndínlógún sọ pé: “Kò bọ́gbọ́n mu rárá, ó sì léwu gidigidi láti dábàá ‘ìmúpadàbọ̀sípò àti àtúnṣe’ kan báyìí fún ààbò àti ìdàgbàsókè [ṣọ́ọ̀ṣì], bí pé àbùkù lè kàn án.” Àwọn àbùkù tí ó ṣe kedere, tí kò ṣeé sẹ́ ńkọ́? A ti hùmọ̀ onírúurú ọ̀nà láti wí àwíjàre nípa wọn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ti tẹnu mọ́ ọn pé ṣọ́ọ̀ṣì náà jẹ́ mímọ́, ó sì tún jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Wọ́n sọ pé àjọ náà fúnra rẹ̀ jẹ́ mímọ́—tí Ọlọ́run kì í jẹ́ kí ó ṣàṣìṣe. Síbẹ̀, àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Nípa báyìí, nígbà tí a bá hùwà ìkà bíburú jáì lórúkọ ṣọ́ọ̀ṣì, kò yẹ kí a di ẹ̀bi náà ru ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì ni ó ni ẹ̀bi náà. Ìyẹn ha bọ́gbọ́n mu bí? Kò bọ́gbọ́n mu rárá lójú ìwòye ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn Roman Kátólíìkì náà, Hans Küng, tí ó kọ̀wé pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì pípé tí ìwà aráyé kì í nípa lé lórí kò sí.” Ó ṣàlàyé pé: “Kò sí Ṣọ́ọ̀ṣì tí kò lẹ́ṣẹ̀ tí yóò jẹ́wọ́.”

Wíwá Ìṣọ̀kan Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé àti Ìdúró Rere

O lè máa ṣe kàyéfì nípa àwọn ìdàgbàsókè tí ó sún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sínú títọrọ àforíjì nísinsìnyí. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àti Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì gbà pé àwọn jẹ̀bi “àwọn ìpínyà àtẹ̀yìnwá” tí ó wáyé láàárín onírúurú ìjọ. Wọ́n ṣe èyí níbi àpérò wíwá ìṣọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé ti “Ìgbàgbọ́ àti Ètò,” tí ó wáyé ní Lausanne, Switzerland, ní ọdún 1927. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Ní pàtàkì láti ìgbà àpérò Vatican Kejì,a àwọn bíṣọ́ọ̀bù àgbà, títí kan àwọn póòpù, ti tọrọ àforíjì léraléra, lọ́nà tí ó túbọ̀ ń ga sí i, fún fífa ìpínyà nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Fún ète wo? Ó ṣe kedere pé, wọ́n ń fẹ́ ìṣọ̀kan púpọ̀ sí i nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Òpìtàn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì náà, Nicolino Sarale, sọ pé, nínú “ìdáwọ́lé ‘jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀’” ti John Paul Kejì, “ìwéwèé àfìṣọ́raṣe kan ń bẹ níbẹ̀, ìyẹn sì ni wíwá ìṣọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé.”

Ṣùgbọ́n, ohun tí ó wé mọ́ ọn ju wíwá ìṣọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé. Lónìí, ìtàn burúkú tí ó ti wà nípa Kirisẹ́ńdọ̀mù ti di ohun tí ayé mọ̀. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Hans Urs von Balthasar, sọ pé: “Kò ṣeé ṣe fún ẹ̀sìn Kátólíìkì láti dágunlá sí gbogbo ìtàn yìí.” Ó fi kún un pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì gan-an tí póòpù dara pọ̀ mọ́ ti ṣe tàbí ti yọ̀ǹda kí a ṣe àwọn ohun tí ó dájú pé a kò lè fọwọ́ sí lóde òní.” Nítorí náà, póòpù ti yan ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan láti “ṣàlàyé iṣẹ́ láabi tí ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣe, kí wọ́n baà lè . . . tọrọ àforíjì.” Nígbà náà, ó jọ bí pé ìdí mìíràn tí ṣọ́ọ̀ṣì fi múra tán láti ṣe lámèyítọ́ ara rẹ̀ jẹ́ nítorí ìfẹ́ láti jèrè ìdúró rere rẹ̀ padà.

Lọ́nà kan náà, òpìtàn Alberto Melloni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí títọrọ tí ṣọ́ọ̀ṣì ń tọrọ àforíjì, kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, ohun tí wọ́n ń béèrè fún nígbà mìíràn jẹ́ bíbọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi fún ìgbà díẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó jọ bí pé Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń gbìyànjú láti dágunlá sí ẹrù ìnira ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtẹ̀yìnwá, kí àwọn ènìyàn lè padà gbára lé e. Ṣùgbọ́n, láìṣàbòsí, a gbọ́dọ̀ sọ pé, ó jọ bí pé wíwá àlàáfíà pẹ̀lú ayé jẹ ẹ́ lọ́kàn ju wíwá àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run lọ.

Irú ìwà bẹ́ẹ̀ rán wa létí Sọ́ọ̀lù, ọba àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 15:1-12) Ó dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo kan, nígbà tí a sì tú èyí fó, ó kọ́kọ́ gbìyànjú láti dá ara rẹ̀ láre—láti wí àwíjàre—níwájú Sámúẹ́lì, olùṣòtítọ́ wòlíì Ọlọ́run. (1 Sámúẹ́lì 15:13-21) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ọba náà ní láti jẹ́wọ́ fún Sámúẹ́lì pé: “Mo ti ṣẹ̀; nítorí mo ti tẹ àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà . . . lójú.” (1 Sámúẹ́lì 15:24, 25) Bẹ́ẹ̀ ni, ó gbà pé òun jẹ̀bi. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ̀ lé e sí Sámúẹ́lì ṣí ohun tí ó jẹ ẹ́ lọ́kàn jù lọ payá: “Mo ti ṣẹ̀. Jọ̀wọ́, bọlá fún mi wàyí, ní iwájú àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn mi àti ní iwájú Ísírẹ́lì.” (1 Sámúẹ́lì 15:30) Ní kedere, ipò Sọ́ọ̀lù ní Ísírẹ́lì jẹ ẹ́ lógún ju pípadà bá Ọlọ́run rẹ́ lọ. Ìṣarasíhùwà yìí kò mú kí Ọlọ́run dárí ji Sọ́ọ̀lù. Ìwọ ha rò pé irú ìṣarasíhùwà kan náà yóò mú kí Ọlọ́run dárí ji àwọn ṣọ́ọ̀ṣì bí?

Kì Í Ṣe Gbogbo Wọn Ló Gbà

Kì í ṣe gbogbo wọn ló gbà pé kí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tọrọ àforíjì ní gbangba. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì ni ìdààmú bá nígbà tí póòpù wọn tọrọ àforíjì fún ìṣòwò ẹrú tàbí nígbà tí ó kéde ìgbàpadà “àwọn aládàámọ̀” bí Hus àti Calvin. Gẹ́gẹ́ bí ìsọfúnni tí ó wá láti Vatican ti sọ, àwọn kádínà, tí ó pé jọ sí ìpàdé aláàtò ìsìn tí a ṣe ní June ọdún 1994, ṣe lámèyítọ́ ìwé tí a fi ránṣẹ́ sí wọn, tí ó ń dábàá “ṣíṣèwádìí ẹ̀rí ọkàn” lórí ìtàn ẹgbẹ̀rúndún tí ó kọjá ti ẹ̀sìn Kátólíìkì. Síbẹ̀, nígbà tí póòpù fẹ́ láti fi kókó inú àbá náà kún inú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn bíṣọ́ọ̀bù, kádínà ará Ítálì náà, Giacomo Biffi, mú ìwé kan jáde nípa ìṣolùṣọ́-àgùntàn, ó sọ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì kò lẹ́ṣẹ̀.” Síbẹ̀, ó gbà pé: “Títọrọ àforíjì fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ṣọ́ọ̀ṣì ti dá ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ti kọjá . . . lè mú kí àwọn ènìyàn fojú tí ó dára wò wá.”

Òǹkọ̀wé Vatican náà, Luigi Accattoli, sọ pé: “Ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn kókó tí ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ jù lọ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Bí póòpù bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn míṣọ́nnárì, àwọn míṣọ́nnárì kan wà tí yóò ta kò ó pátápátá.” Síwájú sí i, akọ̀ròyìn ẹ̀sìn Roman Kátólíìkì kan kọ̀wé pé: “Bí póòpù bá ní èrò tí ó dẹ́rù bà á tó bẹ́ẹ̀ ni ti gidi nípa ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì, ó ṣòro láti lóye bí ó ṣe lè gbé Ṣọ́ọ̀ṣì kan náà yìí kalẹ̀ nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ajàjàgbara fún ‘ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn,’ ‘ìyá àti olùkọ́’ kan ṣoṣo tí ó lè ṣamọ̀nà ẹ̀dá ènìyàn sínú ẹgbẹ̀rúndún kẹta amọ́kànyọ̀.”

Bíbélì kìlọ̀ nípa ìrònúpìwàdà tí a ṣe nítorí ìtìjú kíkánimọ́ ìdí ìwà àìtọ́. Irú ìrònúpìwàdà bẹ́ẹ̀ kì í sábà sún ẹni tí ń ronú pìwà dá náà ṣe ìyípadà pípẹ́ títí. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 7:8-11.) “Àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà”—ìyẹn ni, ẹ̀rí ojúlówó ìrònúpìwàdà náà—máa ń bá ìrònúpìwàdà tí ó níye lórí lójú Ọlọ́run rìn.—Lúùkù 3:8.

Bíbélì sọ pé, ẹni tí ń ronú pìwà dà tí ó sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, gbọ́dọ̀ fi àwọn ìwà àìtọ́ náà sílẹ̀, kí ó jáwọ́ nínú wọn. (Òwe 28:13) Èyí ha ti ṣẹlẹ̀ bí? Tóò, lẹ́yìn gbogbo ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì àti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yòókù, kí ní ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ogun abẹ́lé tí ó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní àárín gbùngbùn Áfíríkà àti Ìlà Oòrùn Yúróòpù, tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ “Kristẹni” lọ́wọ́ sí? Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ha ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ipá fún àlàáfíà bí? Gbogbo àwọn olórí wọn ha panu pọ̀ sọ̀rọ̀ jáde lòdì sí ìwà ìkà bíburú jáì tí àwọn mẹ́ńbà wọn ń hù bí? Wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Họ́wù, àní àwọn òjíṣẹ́ ẹ̀sìn kan tilẹ̀ kópa nínú ìpakúpa náà!

Ìdájọ́ Àtọ̀runwá

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí póòpù ń ṣe lemọ́lemọ́, Kádínà Biffi béèrè lọ́nà ẹ̀dà ọ̀rọ̀ pé: “Fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtẹ̀yìnwá, kò ha ní dára fún wa láti dúró de ìdájọ́ àgbáyé bí?” Tóò, ìdájọ́ gbogbo aráyé ti sún mọ́lé. Jèhófà Ọlọ́run mọ gbogbo láabi tí ìsìn ti ṣe nínú ìtàn dáradára. Láìpẹ́, láìjìnnà, òun yóò ṣèdájọ́ àwọn tí ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. (Ìṣípayá 18:4-8) Ní báyìí ná, ó ha ṣeé ṣe láti rí ọ̀nà ìjọsìn kan tí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, àìráragba-nǹkan-sí aṣekúpani, àti àwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù ń tọrọ àforíjì fún kò kábààwọ́n bá bí? Bẹ́ẹ̀ ni.

Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? Nípa lílo ìlànà tí Jésù Kristi sọ, nígbà tí ó wí pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.” Kì í ṣe kìkì àwọn tí Jésù pè ní “wòlíì èké” ni àkọsílẹ̀ ìtàn, tí àwọn ìsìn kan yóò fẹ́ kí a gbàgbé, ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀, ó tún ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn tí ó ti mú “èso àtàtà” jáde. (Mátíù 7:15-20) Àwọn wo ni ìwọ̀nyí? A ké sí ọ láti ṣàwárí wọn fúnra rẹ, nípa ṣíṣàyẹ̀wò Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Fojú ara rẹ rí àwọn tí ń gbìyànjú ní tòótọ́ lónìí láti tẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dípò wíwá láti pa ipò alágbára mọ́ nínú ayé.—Ìṣe 17:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpérò kọkànlélógún ti wíwá ìṣọ̀kan àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àgbáyé tí ó wáyé nígbà mẹ́rin ní Róòmù láti ọdún 1962 sí 1965.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń tọrọ àforíjì fún ìwà ìkà bíburú jáì bí èyí

[Credit Line]

The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́