Èrè Ìgbéraga—Báwo Ló Ṣe Tó?
NǸKAN ha ti da ìwọ àti ẹnì kan pọ̀ rí, tónítọ̀hún wá fẹ́ fi yé ẹ pé o ò já mọ́ nǹkan kan? Bóyá ọ̀gá iléeṣẹ́ lonítọ̀hún, tàbí alábòójútó, tàbí kó tilẹ̀ jẹ́ ẹbí ẹ, tó wá fojú kó ẹ mọ́lẹ̀, tó tẹ́ ẹ pátápátá? Irú èèyàn wo lo máa ka onítọ̀hún sí? Ǹjẹ́ ìwà rẹ̀ wù ẹ́? Kò lè wù ẹ́ láé! Èé ṣe? Nítorí pé ṣe ni ìgbéraga máa ń ya àwọn èèyàn nípa, ṣe ló máa ń bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀.
Ìgbéraga máa ń mú kí èèyàn rẹ àwọn ẹlòmíràn sílẹ̀, kí òun lè gbé ara rẹ̀ lékè. Èèyàn tó bá ní irú ìwà yẹn kì í sábà sọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíràn ní rere. Gbólóhùn àfi tó ní èrò òdì sábà máa ń wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, irú bíi, “bẹ́ẹ̀ ni, ó dáa láwọn ibì kan lóòótọ́, ṣùgbọ́n ó ní ìṣòro yìí tàbí àléébù tọ̀hún.”
Nínú ìwé náà, Thoughts of Gold in Words of Silver, a pe ìgbéraga ní “ìwà burúkú gbáà tí ń fa ìṣubú. Ó ń jẹni run, débi pé á fẹ́rẹ̀ẹ́ ba gbogbo dáadáa èèyàn jẹ́.” Ǹjẹ́ a ò rí ìdí rẹ̀ báyìí, táwọn èèyàn fi máa ń fẹ́ rìn jìnnà sí onígbèéraga? Àní, èrè tí ìgbéraga sábà máa ń mú wá ní ṣíṣàìní ojúlówó ọ̀rẹ́. Ìwé kan náà tún sọ pé: “Ní ìfiwéra, àwọn èèyàn fẹ́ràn onírẹ̀lẹ̀—kì í ṣe onírẹ̀lẹ̀ tó ń fi ìrẹ̀lẹ̀ yangàn, bí kò ṣe onírẹ̀lẹ̀ gidi.” Rẹ́gí lọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé: “Ìgbéraga èèyàn máa ń rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ yóò jèrè ọlá.”—Òwe 29:23, The Jerusalem Bible.
Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí ipa tó ní lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tàbí ọlá látọ̀dọ̀ ènìyàn, ipa wo ni ìgbéraga ń ní lórí ìbátan ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run? Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn agbéraga, àwọn onírera, àti ọ̀fẹgẹ̀? Ìgbéraga ni o, tàbí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni o—ǹjẹ́ Ọlọ́run ń wobẹ̀?
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Òǹkọ̀wé tí a mí sí, tó kọ ìwé Òwe sọ pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀. Ó sàn láti jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ ní ẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ọlọ́kàn tútù ju láti pín ohun ìfiṣèjẹ pẹ̀lú àwọn tí ń gbé ara wọn ga.” (Òwe 16:18, 19) Ọ̀ràn Náámánì, ọ̀gágun Síríà, tó gbé ayé nígbà Èlíṣà, wòlíì Ísírẹ́lì, kín ọ̀rọ̀ ọgbọ́n wọ̀nyẹn lẹ́yìn.
Adẹ́tẹ̀ ni Náámánì. Níbi tó ti ń wá ìwòsàn, ó rìnrìn àjò lọ sí ìlú Samáríà, ó rò pé òun pẹ̀lú Èlíṣà yóò jókòó sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wòlíì náà kàn rán ìránṣẹ́ rẹ̀ kó lọ sọ fún Náámánì pé kó lọ wẹ̀ lẹ́ẹ̀méje nínú Odò Jọ́dánì. Náámánì ka ìwà àti ìmọ̀ràn wòlíì náà sí ìwọ̀sí. Kí ló dé tí wòlíì náà kò lè jáde wá bá òun sọ̀rọ̀, tó jẹ́ pé ìránṣẹ́ ló rán? Odò Jọ́dánì ọ̀hún sì rèé, kò sóhun tó fi dáa ju odò èyíkéyìí ní Síríà! Ìgbéraga ló ń yọ ọ́ lẹ́nu. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Tóò, a bá a yọ̀, pé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n ló borí. “Látàrí ìyẹn, ó sọ̀ kalẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ri ara rẹ̀ bọ Jọ́dánì ní ìgbà méje ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́; lẹ́yìn èyí tí ẹran ara rẹ̀ padà wá gẹ́gẹ́ bí ẹran ara ọmọdékùnrin kékeré, ó sì mọ́.”—2 Àwọn Ọba 5:14.
Nígbà mí-ìn, ìwà ìrẹ̀lẹ̀ díẹ̀ lè yọrí sí èrè ńlá.
Èrè Ìrera
Ṣùgbọ́n o, ibi tí ìgbéraga lè sìn wá dé, lè kọjá kí a wulẹ̀ pàdánù àǹfààní tàbí èrè kan. Irú ìgbéraga mìíràn tún wà, tó ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, hybris. Gẹ́gẹ́ bí William Barclay, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè Gíríìkì, ti wí, hubris ní ìgbéraga àti ìwà òǹrorò nínú . . . , ìwà ìfojú tín-ín-rín ẹni tí ń mú kí [èèyàn] fojú èèyàn ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ gbolẹ̀.”
Àpẹẹrẹ tó hàn kedere nípa irú ìgbéraga tó pàpọ̀jù yìí ṣẹlẹ̀ nínú Bíbélì. Ó wáyé nínú ọ̀ràn Hánúnì, ọba Ámónì. Ìwé náà, Insight on the Scriptures ṣàlàyé pé: “Nítorí inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Náháṣì ṣe sí Dáfídì, Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ pé kí wọ́n lọ tu Hánúnì nínú nítorí pé baba rẹ̀ ṣaláìsí. Ṣùgbọ́n nítorí pé àwọn ọmọ aládé Hánúnì fi yé e pé ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí gbáà ni Dáfídì ń ta, pé kí ó lè ráyè ṣamí ìlú náà ni, Hánúnì fàbùkù kan àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì nípa fífá ààbọ̀ irùngbọ̀n wọn, ó gé ẹ̀wù wọn ní ààbọ̀ dé ekiti ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.”a Nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Barclay sọ pé: “Ìṣefọ́nńté ni irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ìwọ̀sí ni, ìfọ̀bọlọni gbáà ni, ìfàbùkùkanni ní gbangba ni, gbogbo rẹ̀ ló pé sínú ẹ̀.”—2 Sámúẹ́lì 10:1-5.
Bẹ́ẹ̀ ni, ìṣefọ́nńté pọ̀ lọ́wọ́ agbéraga, àfojúdi pọ̀ lọ́wọ́ ẹ̀, ó sì lè fàbùkù kan àwọn ẹlòmíràn. Ó kúndùn pípa àwọn ẹlòmíràn lára láìbìkítà rárá, ká má tilẹ̀ wá sọ pé kó gba tiwọn rò, lẹ́yìn tó bá ti ni ẹni náà lára, tó sì ti tẹ́ ẹ pẹlẹbẹ, yóò wá máa ṣe jàgínní-jàgínní. Ṣùgbọ́n o, idà olójú méjì lọ̀ràn títẹ́ ẹlòmíràn tàbí fífàbùkù kàn án jẹ́. Ó máa ń yọrí sí kí àwọn ọ̀rẹ́ máa sá fúnni, àfàìmọ̀ kó má sì sọni dọ̀tá.
Báwo ni Kristẹni tòótọ́ ṣe lè hu irú ìwà ìgbéraga burúkú bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí Ọ̀gá rẹ̀ ti pàṣẹ pé ‘kí ó nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀’? (Mátíù 7:12; 22:39) Ó lòdì pátápátá sí gbogbo ohun tí Ọlọ́run àti Kristi jẹ́. Lójú ìwòye èyí, Barclay sọ ọ̀rọ̀ tí ó ró kìì yìí: “Ìṣefọ́nńté ni ìgbéraga tí ń mú kí èèyàn ṣàyàgbàǹgbà pe Ọlọ́run níjà.” Èyí ni ìgbéraga tí ń sọ pé: “Jèhófà kò sí.” (Sáàmù 14:1) Tàbí, gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 10:4 ti sọ ọ́: “Ẹni burúkú, gẹ́gẹ́ bí ìruga rẹ̀, kò ṣe ìwádìí kankan; gbogbo èrò-ọkàn rẹ̀ ni pé: ‘Kò sí Ọlọ́run.’” Irú ìgbéraga, tàbí ìrera bẹ́ẹ̀, ń mú kí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rìn jìnnà síni, ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o, ó tún ń sọni dọ̀tá Ọlọ́run. Aburú náà mà pọ̀ o!
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìgbéraga Ba Tìẹ Jẹ́
Oríṣiríṣi ni ìgbéraga—ìgbéraga tí ń jẹ yọ láti inú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, láti inú ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, láti inú ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́, ìgbéraga nítorí ìmọ̀ ìwé, ọrọ̀, ipò iyì, àti agbára. Kóo tó mọ̀, ìgbéraga lè ti yọ́ wọlé sí ẹ lára, kó sì ba ìwà ẹ jẹ́.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ṣe bí onírẹ̀lẹ̀ bí ọ̀rọ̀ bá da àwọn pẹ̀lú ọ̀gá wọn, tàbí ojúgbà wọn pàápàá pọ̀. Ṣùgbọ́n kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ bí agbára bá bọ́ sí ẹni náà tí ń ṣe bí onírẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́? Á yí padà bírí di abàṣẹwàá, á fayé sú àwọn tó wà lábẹ́ ẹ̀! Èyí lè ṣẹlẹ̀ sáwọn kan, tí wọ́n bá gbé aṣọ iṣẹ́ wọ̀, tàbí tí wọ́n bá lẹ káàdì tó fi hàn pé agbára ń bẹ lọ́wọ́ wọn máyà. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba pàápàá lè bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ìgbéraga sáwọn aráàlú, wọ́n lè máa ronú pé ṣe ló yẹ kí ìlú máa sin àwọn, kì í ṣe káwọn máa sin ìlú. Ìgbéraga lè sọ ẹ́ di òǹrorò, aláìgbatẹnirò; ìrẹ̀lẹ̀ lè sọ ẹ́ di onínúure.
Bó bá ṣe pé Jésù fẹ́ gbéra ga tàbí kó rorò sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni, ì bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, ẹni pípé ni, Ọmọ Ọlọ́run ni, tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn aláìpé tí ń fi ìkùgìrì àti ìwàǹwára ṣe nǹkan. Síbẹ̀, ìpè wo ló pe àwọn tó fetí sí i? “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”—Mátíù 11:28-30.
A ha máa ń sapá nígbà gbogbo láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Tàbí kẹ̀, a ha rí i pé a jẹ́ òǹrorò, kìígbọ́-kìígbà, abàṣẹwàá, aláìlójú àánú, tàbí agbéraga? Gẹ́gẹ́ bí Jésù, gbìyànjú láti tuni lára, kì í ṣe láti nini lára. Dènà ìbàjẹ́ tí ìgbéraga ń fà.
Lójú gbogbo ohun táa ti ń sọ bọ̀, kí ni a lè sọ nípa ìgbéra-ẹni-níyì?
Ìgbéra-Ẹni-Níyì àti Ìjọra-Ẹni-Lójú
Ànímọ́ rere kan tó fẹ́ fara pẹ́ ọ̀rọ̀ yìí ni ìgbéra-ẹni-níyì. Ìgbéra-ẹni-níyì túmọ̀ sí fífi ọ̀wọ̀ wọ ara rẹ. Ó túmọ̀ sí pé o bìkítà nípa ohun táwọn èèyàn ń rò nípa rẹ. O bìkítà nípa ìrísí rẹ àti orúkọ rere rẹ. Òdodo ọ̀rọ̀ ni òwe Yorùbá kan tó sọ pé, “Ìwà jọ̀wà, ní í jẹ́ ọ̀rẹ́ jọ̀rẹ́.” Bóo bá yàn láti máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn wúruwùru, jákujàku, àwọn ọ̀lẹ, àti onísọkúsọ, nígbà náà, ìwọ yóò dà bí wọn. Ìṣarasíhùwà wọn yóò ràn ẹ́, ìwọ náà yóò sì pàdánù iyì rẹ.
Ṣùgbọ́n o, àṣejù tún máa ń wọ ọ̀ràn gbígbé ara ẹni níyì—ó lè di ìjọra-ẹni-lójú tàbí ìruga. Àwọn akọ̀wé òfin àti Farisí ọjọ́ Jésù máa ń yangàn nítorí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn àti ìmúra wọn lọ́nà ti ẹ̀sìn, tí wọ́n ti ki àṣejù bọ̀. Jésù ṣe kìlọ̀kìlọ̀ nípa wọn, pé: “Gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n ń ṣe kí àwọn ènìyàn lè rí wọn; nítorí wọ́n mú àwọn akóló ìkó-ìwé-mímọ́-sí fẹ̀, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ ara láti fi ṣe ìṣọ́rí, wọ́n sì sọ ìṣẹ́tí ẹ̀wù wọn di títóbi [kí wọ́n lè fara hàn bí olùfọkànsìn]. Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ níbi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù, àti ìkíni ní àwọn ibi ọjà àti kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní Rábì.”—Mátíù 23:5-7.
Fún ìdí yìí, ìgbéra-ẹni-níyì kì í ṣe ohun tí a ń ṣe láṣejù. Tún rántí pé ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wò, kì í kàn-án ṣe ìrísí òde ara. (1 Sámúẹ́lì 16:7; Jeremáyà 17:10) Ìṣòdodo lójú ara ẹni kì í ṣe òdodo Ọlọ́run. Àmọ́ o, ìbéèrè tó kàn báyìí ni, Báwo la ṣe lè mú ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ dàgbà, kí a sì yẹra fún aburú tí ìgbéraga ń fà?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ díẹ̀ mú èrè ńlá wá bá Náámánì