Ìwọ Ha Rántí Bí?
Àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ha ti wúlò fún ọ ní ti gidi bí? Nígbà náà, èé ṣe tí o kò fi fi àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí dán agbára ìrántí rẹ wò:
◻ Àwọn ìbéèrè méjì wo ló ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n dojú kọ ṣíṣe àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ iṣẹ́ láti dá ṣèpinnu?
Ìbéèrè pàtàkì àkọ́kọ́ nìyí: A ha ka iṣẹ́ yìí ni pàtó léèwọ̀ nínú Bíbélì bí? Ìbéèrè kejì rèé: Ṣíṣe irú iṣẹ́ yìí ní pàtó yóò ha sọ ẹni bẹ́ẹ̀ di agbódegbà fún àwọn ìwà tí kò dára bí?—4/15, ojú ìwé 28.
◻ Ọ̀nà wo la gbà ‘tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo’? (Róòmù 8:20)
A ‘tẹ̀ wá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo,’ nítorí ìgbésẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà. Kì í ṣe “nípasẹ̀ ìfẹ́ [wa]” tàbí nítorí pé ó wù wá bẹ́ẹ̀ lèyí ṣe ṣẹlẹ̀. A jogún rẹ̀ ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìpé, ẹ̀ṣẹ̀, àti ikú nìkan làwọn òbí wa lè tàtaré rẹ̀, Jèhófà ṣàánú wọn nípa yíyọ̀ǹda pé kí wọ́n bímọ. Nítorí náà, ikú tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn, lọ́nà yẹn, Ọlọ́run “tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.”—5/1, ojú ìwé 5.
◻ Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ó ṣì di ọjọ́ iwájú kí “ohun ìríra” náà tó “dúró ní ibi mímọ́”? (Mátíù 24:15)
Nínú ìmúṣẹ ti ìgbàanì, a pe ‘ohun ìríra tó dúró ní ibi mímọ́’ náà ní ìkọlù àwọn ará Róòmù lábẹ́ Ọ̀gágun Gallus lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa. Ìkọlù tòde òní tó jẹ́ aláfijọ tọjọ́sí—ìyẹn ni ìbẹ́sílẹ̀ “ìpọ́njú ńlá”—ṣì wà níwájú. (Mátíù 24:21) Nítorí náà, “ohun ìríra tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro,” kò tí ì dúró ní ibi mímọ́.—5/1, ojú ìwé 16, 17.
◻ Báwo ni baba àti ìyá táwọn méjèèjì ń ṣiṣẹ́ ṣe lè rí àkókò fún àwọn ọmọ wọn?
Ìyá tó máa ń rẹ̀ lẹ́yìn tó bá ṣíwọ́ iṣẹ́ lè sọ pé kí òun àtàwọn ọmọ jọ gbọ́únjẹ. Bàbá tí iṣẹ́ pọ̀ lọ jàra fún láti ṣe níparí ọ̀sẹ̀ lè jẹ́ kí òun àtàwọn ọmọ jọ ṣe díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ náà.—5/15, ojú ìwé 6.
◻ Kí ni àwọn tí ń “rìn ní ọ̀nà Jèhófà” lè ṣe? (Jeremáyà 7:23)
Rírìn ní ọ̀nà Jèhófà ń béèrè ìdúróṣinṣin—ìpinnu láti máa sin òun nìkan ṣoṣo. Ó ń béèrè ìgbẹ́kẹ̀lé—ìgbàgbọ́ àtọkànwá pé àwọn ìlérí Jèhófà ṣeé gbára lé àti pé wọn yóò ní ìmúṣẹ. Rírìn ní ọ̀nà Jèhófà ń béèrè ìgbọràn—pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ láìyà bàrá àti títẹ̀lé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga rẹ̀. (Sáàmù 11:7)—5/15, ojú ìwé 14.
◻ Kí ni ojúṣe mẹ́rin pàtàkì tí “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” gbọ́dọ̀ ṣe? (Éfésù 4:8)
Wọ́n lè fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tọ́ wa sọ́nà, kí wọ́n fi ìfẹ́ gbé wa ró, wọ́n lè ṣàlékún ìṣọ̀kan wa pẹ̀lú ìjọ, wọ́n sì lè fi ìgboyà dáàbò bò wá. (Éfésù 4:12-14)—6/1, ojú ìwé 14.
◻ Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìbákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn bí ọgọ́rùn-ún ènìyàn tí a mẹ́nu kàn nínú ìwé Ìṣe àti nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀?
Ó yẹ ká máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run, pẹ̀lú ìjọ àdúgbò wa, àti pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. A nílò ìrànlọ́wọ́ wọn, ìtìlẹ́yìn wọn, àti ìtùnú wọn ní àkókò tí nǹkan lọ geere àti ní àkókò ìdààmú.—6/1, ojú ìwé 31.
◻ Àwọn kókó mẹ́ta wo lo lè fi ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti ronú nípa Ẹlẹ́dàá?
Ìṣètò fínnífínní táa rí nínú àgbáálá ayé tó lọ salalu, bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro pé, ọpọlọ ènìyàn jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ pátápátá, táa bá ronú nípa onírúurú ohun táa lè fi ṣe.—6/15, ojú ìwé 18.
◻ Èé ṣe ti lílóye orúkọ Ẹlẹ́dàá náà fúnra rẹ̀ fi ṣe pàtàkì?
Orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di,” ó fi hàn pé ó ń pète, ó sì ń gbégbèésẹ̀. Nípa mímọ orúkọ rẹ̀ àti lílò ó a lè túbọ̀ wá mọ̀ pé bó ti ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, bẹ́ẹ̀ ló ń mú ète rẹ̀ ṣẹ.—6/15, ojú ìwé 21.
◻ Báwo ni àwọn ọmọ ṣe lè kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé?
Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ṣètò pé kí ọmọ kọ̀ọ̀kan ní Bíbélì àti ìwé ìròyìn tirẹ̀ tí ẹ óò fi ṣèkẹ́kọ̀ọ́. A lè sọ pé kí ọ̀dọ́mọdé kan ṣàlàyé àwòrán tó wà lójú ìwé tí à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, a sì tún lè sọ fún ọmọ kan pé òun ni yóò ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. A lè sọ fún èyí tó dàgbà díẹ̀ láti mẹ́nu kan àwọn àǹfààní tó wà nínú fífi àwọn ohun táa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sílò.—7/1, ojú ìwé 15.
◻ Àwọn góńgó wo ni ìdílé lè fi kún mímúra ìpàdé ìjọ sílẹ̀?
(1) Kí olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé múra láti dáhùn nínú ìpàdé ìjọ; (2) kí olúkúlùkù rí i pé òun dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara òun; (3) kí olúkúlùkù lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìdáhùn rẹ̀; àti (4) kí olúkúlùkù lè fọ́ ọ̀rọ̀ sí wẹ́wẹ́ láti jẹ́ ká mọ bí a óò ṣe fi sílò.—7/1, ojú ìwé 20.
◻ Kí ni àṣírí ìgbéyàwó aláṣeyọrí?
Ohun kan tó pọndandan tí ọwọ́ ẹni fi lè tẹ ayọ̀ oníyebíye tó wà nínú ìgbéyàwó aláṣeyọrí, kí a sì ní ìrírí rẹ̀ ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán. Èyí ní ṣíṣàjọpín ìmọ̀ àti èrò nínú. Àti pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dídán mọ́rán ní í ṣe pẹ̀lú àwọn nǹkan tí ń gbéni ró, tí ń tuni lára, àwọn ohun tó dára, tó yẹ fún ìyìn, tó sì ń tuni nínú. (Éfésù 4:29-32; Fílípì 4:8)—7/15, ojú ìwé 21.
◻ Kí ni ‘ọ̀nà Jèhófà’? (Sáàmù 25:8, 9, 12)
Ọ̀nà yẹn jẹ́ ọ̀nà ìfẹ́. A gbé e karí ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọ́run. Bíbélì pe lílo irú ìfẹ́ yìí tí a gbé karí ìlànà ní “ọ̀nà títayọ ré kọjá.” (1 Kọ́ríńtì 12:31)—8/1, ojú ìwé 12.