ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 10/1 ojú ìwé 19
  • Dídé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Kò Rọrùn Láti Rí Bá Sọ̀rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Dídé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Kò Rọrùn Láti Rí Bá Sọ̀rọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Dídarí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Náà Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Irin Iṣẹ́ Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Tó Ń Súnni Ṣiṣẹ́, Tó sì Tún Ń Fúnni Lókun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • A Bù Kún Ìdánúṣe Tó Lò
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 10/1 ojú ìwé 19

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Dídé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí Kò Rọrùn Láti Rí Bá Sọ̀rọ̀

ÀWỌN Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sa gbogbo ipá wọn láti mú ìhìn Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tí wọ́n bá lè mú un dé. Nígbà mìíràn, ó máa ń gba ìsapá àrà ọ̀tọ̀ láti bá àwọn tí kì í sábàá sí nílé sọ̀rọ̀. (Máàkù 13:10) Nítorí ìdí èyí, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó wà lórílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Amẹ́ríkà sọ ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí.

“Ní ọjọ́ kan, mo gbọ́ pé gómìnà yóò ṣèbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ tí wọ́n yan èmi àti aya mi sí. Níwọ̀n bó ti dájú pé ọ̀kan lára àwọn tí kì í sábà wà nílé ni, mo wá kọ lẹ́tà kan sí i, mo sì fi àwọn ìtẹ̀jáde bíi mélòó kan ránṣẹ́ sí i, títí kan ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? àti ìwé Mankind’s Search for God àti ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Mo ṣàlàyé ète ọ̀kọ̀ọ̀kan ìtẹ̀jáde wọ̀nyí sínú lẹ́tà mi.

“Nítorí pé mo fẹ́ mọ èrò rẹ̀ nípa àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo tọrọ àyè láti bá a sọ̀rọ̀. Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n fún mi láyè láti wá bá a sọ̀rọ̀. Bí mo ṣe ń lọ, mo mú ẹ̀dà fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name dání. Ìjíròrò náà gba nǹkan bíi wákàtí méjì. Lẹ́yìn tí èmi àti gómìnà náà wo fídíò ọ̀hún tán, mo béèrè èrò rẹ̀ nípa fídíò náà. Ó fèsì pé: ‘Kò sí ètò àjọ èyíkéyìí tó dà bíi tiyín láyé. Ǹ bá yọ̀ ká ní mo rí irú àwọn èèyàn bíi tiyín tó lè ràn mí lọ́wọ́ láti parí àwọn iṣẹ́ tí ìjọba mi ti dáwọ́ lé!’ Lẹ́yìn náà, ó wá bi mí bí mo bá ti dé orílé iṣẹ́ ètò àjọ wa rí. Mo sọ fún un pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó ti ń wù mí látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá nìyẹn, síbẹ̀ mi ò tíì láǹfààní àtilọ sí orílé iṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun téèyàn ò lè kù gìrì ṣe. Bó ṣe tẹjú mọ́ mi tó ń wò mí fúngbà díẹ̀ nìyẹn. Ó wá sọ pé òun fẹ́ kí n ní àǹfààní yẹn. Ó bá wa ṣètò àwọn ìwé àṣẹ ìwọ̀lú, ó sì fún wa ní tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfuurufú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn!

“Gómìnà náà ti ń gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! déédéé báyìí. A lérò pé láìpẹ́, yóò ṣeé ṣe fún wa láti bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́