Ẹ̀sìn Wo Ló Yẹ Kó O Yàn?
‘ONÍRÚURÚ ẹ̀sìn wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó ń sinni lọ́ sí ibì kan náà ni. Ó ṣe tán Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, àbí kì í ṣe Ọlọ́run kan ni?’ Èrò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní nìyẹn, wọ́n sọ pé òótọ́ ni pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn ní ẹ̀sìn tó ń ṣe, síbẹ̀ ẹ̀sìn tó bá wu kálukú ló lè ṣe.
Tá a bá kọ́kọ́ yiiri ọ̀rọ̀ náà wò, á jọ pé èrò yẹn mọ́gbọ́n dání níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run Olódùmarè kan ṣoṣo ló wà. (Aísáyà 44:6; Jòhánù 17:3; 1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Àmọ́, ìyàtọ̀ àti ìtakora tó wà láàárín ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn tí wọ́n pera wọn ní olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà kò ṣeé gbójú fò dá. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jọ́sìn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́, títí kan ẹ̀kọ́ àti ìlànà wọn yàtọ̀ síra pátápátá. Ìyàtọ̀ ọ̀hún sì pọ̀ débi pé ó máa ń ṣòro fún àwọn tó ń ṣe irú ẹ̀sìn kan láti lóye tàbí tẹ́wọ́ gba ohun táwọn ẹlẹ́sìn mìíràn fi ń kọ́ni tàbí èyí tí wọ́n gbà gbọ́.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jésù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí, àwọn tí ń jọ́sìn rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ǹjẹ́ jíjọ́sìn Ọlọ́run ní òtítọ́ fàyè gba onírúurú èrò tó ta kora nípa Ọlọ́run, nípa ohun tí ète rẹ̀ jẹ́ àti bó ṣe fẹ́ ká máa jọ́sìn òun? Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run Olódùmarè kò bìkítà nípa bó ṣe yẹ ká máa jọ́sìn òun?
Àwọn Kristẹni ní Ọ̀rúndún Kìíní àti Nísinsìnyí
Nígbà mìíràn, èrò tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní nípa nǹkan máa ń yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà ní Kọ́ríńtì, ó ní: “Àwọn tí wọ́n jẹ́ ará ilé Kílóè sọ ọ́ di mímọ̀ fún mi nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé ìyapa wà láàárín yín. Ohun tí mo ní lọ́kàn nìyí, pé olúkúlùkù yín ń wí pé: ‘Èmi jẹ́ ti Pọ́ọ̀lù,’ ‘Ṣùgbọ́n èmi ti Àpólò,’ ‘Ṣùgbọ́n èmi ti Kéfà,’ ‘Ṣùgbọ́n èmi ti Kristi.’”—1 Kọ́ríńtì 1:11, 12.
Ǹjẹ́ Pọ́ọ̀lù fojú kékeré wo ọ̀ràn yìí? Ṣé ọ̀nà tó bá sáà ti wu kálukú ló ń gbà láti rí ìgbàlà? Rárá o! Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ìṣítí fún wọn pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, àti pé kí ìpínyà má ṣe sí láàárín yín, ṣùgbọ́n kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.”—1 Kọ́ríńtì 1:10.
Lóòótọ́, a ò lè fagídí mú àwọn èèyàn ṣọ̀kan nínú ìgbàgbọ́. Ọ̀nà kan ṣoṣo tó lè gbà ṣeé ṣe ni pé kí kálukú fara balẹ̀ ṣe ìwádìí àwọn ọ̀ràn, ká jọ dé ìparí èrò kan, ká sì gbà á gbọ́. Nípa bẹ́ẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe kókó, ó sì tún ṣe pàtàkì pé ká máa fi àwọn nǹkan tá à ń kọ́ ṣèwà hù kí á lè ní irú ìṣọ̀kan tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ a lè rí irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ó ti pẹ́ gan-an tí Ọlọ́run ti ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Ǹjẹ́ a lè mọ àwùjọ yẹn lónìí?
Àǹfààní Tí Ń Bẹ Nínú Bíbá Àwùjọ tí Ọlọ́run Fọwọ́ sí Kẹ́gbẹ́
Nígbà kan rí, onísáàmù náà Dáfídì béèrè pé: “Jèhófà, ta ni yóò jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè ńlá mímọ́ rẹ?” Ìbéèrè tó gba ìrònújinlẹ̀ nìyẹn. Dáfídì dáhùn ìbéèrè náà, ó ní: “Ẹni tí ń rìn láìlálèébù, tí ó sì ń fi òdodo ṣe ìwà hù tí ó sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Sáàmù 15:1, 2) Ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì yóò jẹ́ ká lè mọ ìsìn tó dójú ìlà àwọn ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́. Nígbà náà, tá a bá wá dara pọ̀ mọ́ ìsìn náà, a óò ní àjọṣe tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan àti “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwùjọ kan gba ohun kan náà gbọ́, kí wọ́n sì máa ṣe nǹkan pa pọ̀ níṣọ̀kan àní nínú ayé oníyapa yìí. Onírúurú èèyàn tí wọ́n ti fìgbà kan wà nínú onírúurú ẹ̀sìn, tí wọ́n sì wá láti ìbílẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wà lára wọn. Àwọn tí wọ́n fìgbà kan rí gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kò-ṣeé-mọ̀ àtàwọn tí wọn ò gbà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run wà ń bẹ lára àwọn Ẹlẹ́rìí yìí. Síbẹ̀, nígbà kan rí àwọn mìíràn lára wọn ò fọwọ́ pàtàkì mú ìsìn. Látinú onírúurú ẹ̀sìn, àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí wọ̀nyí ni àwọn tó wá ń gbádùn ìṣọ̀kan nínú ìjọsìn nísinsìnyí ti wá, irú ìṣọ̀kan yìí ni kò sì sí nínú ayé lónìí.
Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìpìlẹ̀ tí wọ́n gbé ìṣọ̀kan yìí kà. Lóòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé àwọn ò lè máa fipá mú àwọn èèyàn ṣe nǹkan. Àmọ́, wọ́n mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti fún àwọn èèyàn níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì káwọn èèyàn náà lè gbé ìpinnu wọn tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìsìn ka ìpìlẹ̀ tó le korán yìí. Lọ́nà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn yóò lè jàǹfààní nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”
Lónìí, ewu kékeré kọ́ ni ipa búburú àti àwọn nǹkan míì tó ń fani mọ́ra lè kóni sí. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tí ó tọ́. Bíbélì sọ pé “ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n” àti pé “ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ààbò ló jẹ́ tá a bá ń bá àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́. Nítorí náà, Bíbélì rán wa létí pé: “Ẹ . . . jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Ẹ ò rí i pé ìbùkún ló jẹ́ pé kí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìyẹn àwọn arákùnrin àti arábìnrin máa fi ìfẹ́ ran ara wọn lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wọn níwájú Ọlọ́run!
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ottmar fara mọ́ èrò yẹn. Ìdílé Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ ọkùnrin náà dàgbà ní orílẹ̀-èdè Jámánì, kò sì ṣe ẹ̀sìn ọ̀hún mọ́. Ó sọ pé: “Nígbàkigbà tí mo bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, bí ọkàn mi ṣe pòkúdu kí n tó lọ náà ni ọkàn mi máa ń rí tí mo bá padà dé.” Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Ọlọ́run kò yìnrìn. Nígbà tó ṣe, ó bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé, ó sì gbà pé àwọn ni ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run. Ó rí i pé ó yẹ kí òun dara pọ̀ mọ́ wọn. Ó wá sọ pé: “Nítorí pé ọwọ́ mi di nínú ètò àjọ àgbáyé yìí, ó fi ọkàn mi balẹ̀. Wọn ò yéé ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nínú Bíbélì. Nǹkan pàtàkì lèyí jẹ́ fún mi.”
A Ké sí Àwọn Tó Fẹ́ Mọ Òtítọ́
Tí àwọn tí èrò wọn jọra bá ṣe iṣẹ́ kan pa pọ̀, àṣeyọrí wọn máa ń ga ju ìgbà tí kálukú wọn bá ń dá ṣe nǹkan ọ̀hún lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ìtọ́ni tí Jésù fi dágbére fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Báwo ni iṣẹ́ yẹn ṣe lè kẹ́sẹ járí tí kò bá sí ìdarí tàbí ètò kankan? Báwo lẹnì kan ṣe lè tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ yìí bí onítọ̀hún bá ń gbìyànjú láti sin Ọlọ́run lóun nìkan?
Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé pín àwọn ìwé ńlá tá a gbé karí Bíbélì àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí iye rẹ̀ jẹ́ 91,933,280, iye ìwé ìròyìn tí wọ́n sì pín jẹ́ 697,603,247. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó wà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] orílẹ̀-èdè mọ̀ nípa ìhìn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ẹ̀rí títayọ pé àṣeyọrí àwùjọ tó wà níṣọ̀kan, tí wọ́n sì wà létòlétò máa ń pọ̀ ju tàwọn tó dá wà láìsí ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni!
Yàtọ̀ sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pín, wọ́n tún máa ń bá àwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní òye kíkún nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe. Lọ́dún tó kọjá, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n bá àwọn èèyàn ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan tàbí gẹ́gẹ́ bí àwùjọ jẹ́ 5,726,509 ní ìpíndọ́gba. Ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti rí ìpìlẹ̀ tó le korán tí wọ́n yóò gbé ìpinnu wọn ní ti ọ̀ràn ẹ̀sìn kà. A ké sí ọ pé kí o wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ó lè wá yan ìsìn tí wàá máa ṣe.—Éfésù 4:13; Fílípì 1:9; 1 Tímótì 6:20; 2 Pétérù 3:18.
Tó o bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, ó ṣe pàtàkì pé kí o dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan, àmọ́, kì í kàn-án ṣe ẹ̀sìn tàbí ìjọ èyíkéyìí o. Ìmọ̀ pípéye tó wà nínú Bíbélì ló yẹ kí o gbé ìpinnu rẹ kà, kì í ṣe lórí ẹ̀kọ́ tàbí àhesọ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Òwe 16:25) Kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun tí ìsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ dójú ìlà rẹ̀. Fi àwọn ohun tó o kọ́ wé àwọn ohun tó o gbà gbọ́. Lẹ́yìn náà kó o wá yan ìsìn tí wàá máa ṣe.—Diutarónómì 30:19.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní ìṣọ̀kan nínú ayé oníyapa yìí