ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 6/1 ojú ìwé 8
  • ‘Ẹ Wá, Kí Ẹ sì Ràn Wá Lọ́wọ́’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Wá, Kí Ẹ sì Ràn Wá Lọ́wọ́’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Má Ṣe Gbàgbé Iṣẹ́ Ìwàásù Ilé-dé-Ilé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìdí Tí Sísọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn Fi Ń múnú Mi Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Mo Gba Okun Láti Kojú Àwọn Àdánwò Níwájú
    Jí!—1996
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 6/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

‘Ẹ Wá, Kí Ẹ sì Ràn Wá Lọ́wọ́’

NÍ OṢÙ July 2000, a ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó gbọ́ èdè Jámánì tí wọ́n sì ń gbé ní orílẹ̀-èdè Austria, Jámánì àti Switzerland pé kí wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè Bolivia. Àmọ́, kí nìdí tá a fi ní kí wọ́n lọ síbẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn Menno tó gbọ́ èdè Jámánì, tí wọ́n ń gbé láwọn àgbègbè àdádó tó wà ní ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà sí ìlú Santa Cruz ní Bolivia nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì.

Nǹkan bí ogóje Ẹlẹ́rìí ló jẹ́ ìpè náà. Àwọn kan lo ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan níbẹ̀, àwọn mìíràn sì lo ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣe bíi tàwọn míṣọ́nnárì ọ̀rúndún kìíní, ìyẹn àwọn tó jẹ́ ìpè tó sọ pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.”—Ìṣe 16:9, 10.

Báwo ni wíwàásù ní ìpínlẹ̀ náà ṣe rí? Ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ ìlú náà sọ pé: “Tá a bá gbé mọ́tò lọ sí ọ̀kan lára àgbègbè àdádó mẹ́tàlélógójì tí àwọn ọmọlẹ́yìn Menno ń gbé, ó máa ń gbà wá tó ìrìn-àjò wákàtí mẹ́jọ lójú ọ̀nà eléruku. A máa ń lò tó ọjọ́ mẹ́rin lójú ọ̀nà kí á tó lè dé àgbègbè àdádó tó jìnnà, a sì tún máa ń sùn sáwọn àgọ́ nígbà míì. Àmọ́ ìsapá yìí tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí pé bóyá la fi rẹ́ni tó tíì gbọ́ ìhìn rere rí lára àwọn èèyàn náà.”

Níbẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn Menno ò kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Àmọ́ lílọ táwọn Ẹlẹ́rìí náà ń lọ sọ́dọ̀ wọn lemọ́lemọ́ mú kí wọ́n mọyì ọ̀rọ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí wá ń sọ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó jẹ́ àgbẹ̀ sọ pé ó ti tó ọdún kan tóun ti ń ka ìwé ìròyìn Jí! Ó tún sọ pé: “Mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò fara mọ́ ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ, àmọ́ mo mọ̀ pé òtítọ́ ni.” Ní àgbègbè àdádó mìíràn, ọkùnrin kan sọ pé: “Lára àwọn tá a jọ ń gbé ládùúgbò kan náà sọ pé wòlíì èké ni yín, àwọn míì sọ pé ẹ̀yin gan-an lẹ̀ ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, màá fẹ́ ṣe ìwádìí fúnra mi.”

Ní báyìí, ìjọ tó ń sọ èdè Jámánì tí wà lórílẹ̀-èdè Bolivia, wọ́n ní akéde márùnlélọ́gbọ̀n tí oníwàásù alákòókò kíkún mẹ́rìnlá sì wà lára wọn. Títí di báyìí, mẹ́rìnlà lára àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Menno tẹ́lẹ̀ ló ti di akéde Ìjọba Ọlọ́run, àwọn mẹ́sàn-án mìíràn sì ń lọ sípàdé déédéé. Ọkùnrin àgbàlagbà kan tó ṣèrìbọmi lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé: “Ó hàn kedere pé Jèhófà ló ń darí wa. Ó ti rán àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó gbọ́ èdè Jámánì tí wọ́n sì ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà sí wa láti wá ràn wá lọ́wọ́. A dúpẹ́ á sì tún ọpẹ́ dá.” Ọmọbìnrin tí ọkùnrin náà bí tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún, tí òun náà ti ṣe ìrìbọmi sọ pé: “Ìtàra àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń ran àwọn ẹlòmíràn. Aṣáájú ọ̀nà ló pọ̀ jù lára wọn, wọ́n ń fi àkókò àti owó wọn ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Èyí ló mú kí n fẹ́ ṣe bíi tiwọn.”

Ká sòótọ́, àwọn tí wọ́n sapá láti “wá” kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ ń rí ayọ̀ púpọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́