Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?
ǸJẸ́ inú rẹ kì í dùn tó o bá ń rìn láàárín ibi tí wọ́n gbin òdòdó olóòórùn dídùn sí? Ǹjẹ́ ara kì í tù ọ́ tó o bá rí odò tó rọra ń ṣàn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́? Ǹjẹ́ orí rẹ kì í wú tó o bá ń wo agbami tó lọ salalu tàbí tó o rí àwọn òkè tó ga fíofío? Kí nìdí tó fi máa ń wù wá láti fetí sí àwọn ẹyẹ tí wọ́n ń kọrin aládùn látorí igi tí wọ́n lé téńté sí? Kí nìdí tó sì fi máa ń wù wá láti wo bí àwọn ọ̀bọ ṣe ń fara pitú tàbí láti rí àwọn ẹranko bí egbin tó jẹ́ pé wọ́n lẹ́wà gan-an?
Ìdáhùn kan ṣoṣo ló wà fún gbogbo ìbéèrè wọ̀nyí. Òun ni pé inú Párádísè ni Ọlọ́run dá ọmọ èèyàn láti máa gbé! Ibẹ̀ làwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wọn dá ìfẹ́ láti máa gbé nínú Párádísè mọ́ wọn, àwa náà sì jogún ìfẹ́ yìí lọ́dọ̀ wọn. Ẹlẹ́dàá mọ̀ pé àwa èèyàn á láyọ̀ tá a bá wà nínú Párádísè torí pé ó ti dá àwọn ohun tó máa jẹ́ ká gbádùn Párádísè tó jẹ́ ilé wa mọ́ wa.
Kí nìdí tí Jèhófà fi dá ilẹ̀ ayé? Ńṣe ló “ṣẹ̀dá rẹ̀ kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) “Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé” fún Ádámù àti Éfà ní ibi ẹlẹ́wà tí wọ́n á máa gbé, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì. (Jeremáyà10:12; Jẹ́nẹ́sísì 2:7-9, 15, 21, 22) Ó dájú pé àwọn odò, igi àti òdòdó ibẹ̀ á máa múnú wọn dùn gan-an! Wọ́n á máa wo àwọn ẹyẹ tó lẹ́wà bí wọ́n ṣe ń fò lókè, àti bí oríṣiríṣi ẹranko ṣe ń jẹ̀ kiri níbẹ̀ láìsí pé èyíkéyìí lára wọn ń yọ wọ́n lẹ́nu. Wọ́n á máa wo bí ẹja àtàwọn ẹ̀dá omi mìíràn ṣe ń lúwẹ̀ẹ́ nínú omi tó tòrò minimini tó sì mọ́ gaara. Èyí tó tiẹ̀ wá ju gbogbo rẹ̀ lọ ni pé, ńṣe ni Ádámù àti Éfà jọ wà pa pọ̀. Wọ́n lè bímọ káwọn àti àtọmọdọ́mọ wọn sì máa fi ayọ̀ gbé nínú Párádísè ilé wọn tí wọ́n á mú kó máa fẹ̀ sí i báwọn èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ ayé kì í ṣe Párádísè nísinsìnyí, a lè fi wé ilé dáradára kan níbi tí ìdílé aláyọ̀ kan ń gbé. Gbogbo ohun tá a nílò ló pé sínú ilé tí Ọlọ́run fún wa yìí, iná ni o, omi ni o, oúnjẹ ni o, kò sóhun tí kò sí níbẹ̀. Àní, àwọn ohun tó lè mú kí ilẹ̀ ayé móoru tí kò fi ní tutù nini tún wà pẹ̀lú. A mà dúpẹ́ o fún ooru àti ìmọ́lẹ̀ tí oòrùn ń fún wa àti ìmọ́lẹ̀ òṣùpá lálẹ́! (Jẹ́nẹ́sísì 1:14-18) Àwọn nǹkan bí èédú àti epo rọ̀bì tá a lè lò láti fi mú kí nǹkan móoru tún wà lábẹ́ ilẹ̀ pẹ̀lú. Ètò tí Ọlọ́run ṣe nípa bí oòrùn ṣe ń fa omi lọ sójú ọ̀run tó sì tún ń padà rọ òjò sórí ilẹ̀ ayé, àtàwọn odò, adágún omi àti òkun tó fún wa la fi ń rí omi lò. Ìyẹn nìkan kọ́ o, koríko tó tutù yọ̀yọ̀ tó dà bíi kápẹ́ẹ̀tì tún bo gbogbo ilẹ̀.
Bí ìgbà téèyàn tọ́jú oúnjẹ sílé ni Ẹlẹ́dàá wa ṣe pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ sórí ilẹ̀ ayé. Jèhófà ń lo onírúurú irúgbìn tó wà ní pápá àtàwọn igi eléso tó kúnnú igbó láti ‘fún wa ní àwọn àsìkò eléso àti láti fi ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà wa.’ (Ìṣe 14:16, 17) Níwọ̀n bí ayé ti jẹ́ irú ibùgbé tó dára bẹ́ẹ̀, fojú inú wo bó ṣe máa rí ná tí Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀” bá wá sọ ọ́ di Párádísè!—1 Tímótì 1:11.
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ilẹ̀ ayé: NASA photo; Ìràwọ̀: NASA, ESA and AURA/Caltech