Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mo Rí i Pé ó Yẹ Kéèyàn Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pátápátá
Gẹ́gẹ́ Bí Aubrey Baxter Ti Sọ Ọ́
Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé kan lọ́dún 1940, àwọn ọkùnrin méjì kan dojú ìjà kọ mí, wọ́n gbá mi débi pé mo ṣubú lulẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá méjì wà nítòsí ibẹ̀, àmọ́ dípò kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́, ńṣe ni wọ́n ń bú mi tí wọ́n sì ń sọ pé ohun táwọn ìkà èèyàn wọ̀nyẹn ṣe dára. Àwọn ohun kan ṣẹlẹ̀ sí mi ní nǹkan bí ọdún márùn-ún ṣáájú àkókò yẹn, nígbà tí mò ń ṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà kan, tó mú kí wọ́n hu ìwà ìkà yìí sí mi. Jẹ́ kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀.
ÈMI ni ẹ̀kẹta nínú ọmọkùnrin mẹ́rin táwọn òbí mi bí. Ọdún 1913 ni wọ́n bí mi nílùú kan tó wà létí òkun ní ìpínlẹ̀ New South Wales, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, àrùn gágá táwọn èèyàn bẹ̀rù rẹ̀ gan-an nígbà yẹn kọ lu gbogbo wa nínú ìdílé wa. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni àrùn yìí pa ní gbogbo ayé. Inú wa dùn pé kò sẹ́nì kankan tó kú nínú wa. Àmọ́ lọ́dún 1933, nǹkan ìbànújẹ́ kan ṣẹlẹ̀ sí wa. Màmá mi kú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta. Ó jẹ́ ẹnì kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run. Kó tó di pé ó kú, ó ti gba ìdìpọ̀ méjì ìwé Light, ìyẹn ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pín fáwọn èèyàn láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Lákòókò yẹn, ibi ìwakùsà kan ni mo ti ń ṣiṣẹ́. Mo máa ń kó àwọn ìwé yẹn dání lọ síbi iṣẹ́ nítorí pé àyè máa ń ṣí sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn tá a bá ti ṣiṣẹ́ kára fún àkókò díẹ̀, mo sì máa ń fi iná tó wà lára akoto tá a máa ń dé ka àwọn ìwé náà. Kò pẹ́ rárá tí mo fi mọ̀ pé mo ti rí òtítọ́. Bákan náà, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sáwọn àsọyé Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gbé jáde lórí rédíò. Ohun tó túbọ̀ wá múnú mi dùn ni pé, bàbá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Lọ́dún 1935, nǹkan ìbànújẹ́ mìíràn tún ṣẹlẹ̀ sí wa. Àìsàn òtútù àyà kọ lu àbúrò mi tó ń jẹ́ Billy, ó sì pà á. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni nígbà yẹn. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ìrètí àjíǹde tù wá nínú. (Ìṣe 24:15) Nígbà tó yá, bàbá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, ìyẹn Verner àti Harold, àtàwọn ìyàwó wọn, ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Nínú gbogbo àwọn ọmọ ìyá mi, èmi nìkan ló ṣẹ́ kù. Àmọ́ ìyàwó Verner kejì, ìyẹn Marjorie, àti Elizabeth tó jẹ́ ìyàwó Harold, ṣì ń sin Jèhófà títí dòní.
Bí Mo Ṣe Kọ́ Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Àárín ọdún 1935 lèmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀, nígbà tí obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ukraine gun kẹ̀kẹ́ wá sílé wa láti wá bá wa sọ̀rọ̀. Lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e, mo lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́, ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà ni mo sì bá wọn lọ sóde ìwàásù. Ẹlẹ́rìí tó darí ìpàdé tó ń wáyé kí wọ́n tó jáde lọ wàásù kó àwọn ìwé kékeré kan fún mi, ó sì yà mí lẹ́nu nígbà tó sọ pé kí èmi nìkan lọ máa wàásù! Nílé àkọ́kọ́ tí mo lọ, ẹ̀rù bà mí gan-an, ńṣe ló dà bíi pé kí ilẹ̀ lanu kó sì gbé mi mì! Àmọ́ ẹni tí mo bá sọ̀rọ̀ jẹ́ èèyàn dáadáa, kódà ó gbàwé lọ́wọ́ mi.
Àwọn ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ bíi Oníwàásù 12:1 àti Mátíù 28:19, 20 wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin, ó sì wù mí láti di aṣáájú-ọ̀nà, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Bàbá mi fọwọ́ sí ohun tí mo sọ pé mo fẹ́ ṣe yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tíì ṣèrìbọmi nígbà yẹn, mo mú ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù July ọdún 1936 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí màá bẹ̀rẹ̀. Lọ́jọ́ yẹn, mo lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Sydney. Nígbà tí mo débẹ̀, wọ́n ní kí n lọ máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà méjìlá kan ṣiṣẹ́ níbì kan tó ń jẹ́ Dulwich Hill, tó jẹ́ ìgbèríko ìlú Sydney. Wọ́n kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń lo ọlọ aláfọwọ́yí tí wọ́n fi ń lọ àlìkámà, èyí táwọn aṣáájú-ọ̀nà fi ń ṣe ìyẹ̀fun lákòókò yẹn tó sì ń dín owó tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń ná lórí oúnjẹ kù.
Mò Ń Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Ní Ìgbèríko
Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi lọ́dún yẹn, wọ́n ní kémi àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì kan, ìyẹn Aubrey Wills àti Clive Shade lọ máa wàásù ní àárín gbùngbùn ìpínlẹ̀ Queensland. Àwọn ohun tá a kó lọ ni: bọ́ọ̀sì kan tó jẹ́ ti Aubrey, kẹ̀kẹ́ bíi mélòó kan, ẹ̀rọ giramafóònù tí kò tóbi púpọ̀ tá a fi ń gbé àwọn àsọyé Bíbélì jáde sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn, àgọ́ kan tá a gbénú rẹ̀ fún odindi ọdún mẹ́ta, bẹ́ẹ̀dì mẹ́ta, tábìlì kan, àti ìkòkò onírin tá a fi ń se oúnjẹ. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tó kàn mí láti dáná, mo pinnu pé àkànṣe oúnjẹ ni màá sè, ẹ̀fọ́ àti ìyẹ̀fun àlìkámà ni màá sì lò. Àmọ́ kò sẹ́nì kankan nínú wa tó lè jẹ oúnjẹ ọ̀hún. Ẹṣin kan wà nítòsí wa, mo wá gbé oúnjẹ náà fún un. Bó ṣe fimú gbóòórùn rẹ̀ báyìí, ńṣe ló gbọnrí tó sì kúrò nídìí rẹ̀! Ibi tí mo parí àkànṣe oúnjẹ tí mo gbìyànjú láti sè sí nìyẹn.
Nígbà tó yá, a pinnu pé a fẹ́ tètè parí ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù. La bá pín in sọ́nà mẹ́ta, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì mú apá kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ibi tí mo máa ń wà lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ máa ń jìnnà gan-an síbi tí àgọ́ wa wà, kì í sì í rọrùn fún mi láti gun kẹ̀kẹ́ padà sílé. Ọ̀dọ̀ àwọn ará abúlé tó nífẹ̀ẹ́ àlejò ni mo máa ń sùn mọ́jú nígbà míì. Nígbà kan, mo sùn sórí bẹ́ẹ̀dì olówó iyebíye nínú yàrá ìgbàlejò tó wà ní ọgbà ẹran ọ̀sìn kan. Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, ilẹ̀ẹ́lẹ̀ tó dọ̀tí ni mo sùn sí, nínú ahéré ọdẹ kan tó máa ń pa ẹranko kangaroo, awọ ẹran tó kó jọ tó ń rùn kùù sì yí mi ká. Lọ́pọ̀ ìgbà, inú igbó ni mo máa ń sùn mọ́jú. Ìgbà kan tiẹ̀ wà táwọn ajá igbó yí mi ká, àmọ́ wọn ò sún mọ́ mi, igbe wọn sì gba inú òkùnkùn kan. Mi ò sùn mọ́jú ọjọ́ náà, àmọ́ nígbà tí ilẹ̀ mọ́, mo wá rí i pé èmi kọ́ ni wọ́n wá bá bí kò ṣe àwọn ìfun ẹran táwọn kan wá dà sí tòsí ibi tí mo sùn sí.
À Ń Fi Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́ Tá A So Ẹ̀rọ Agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Mọ́ Wàásù
A máa ń lo ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tá a so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ láti wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nílùú Townsville tó wà ní àríwá ìpínlẹ̀ Queensland, àwọn ọlọ́pàá gbà wá láyè láti dúró ní ọ̀gangan àárín ìlú náà ká sì máa gbé ìwàásù wa jáde sórí afẹ́fẹ́ látibẹ̀. Àmọ́ àsọyé tá a ń gbé jáde yìí múnú bí àwọn kan tó jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ìgbàlà, wọ́n sì ní ká kúrò níbẹ̀. Nígbà tá a kọ̀, àwọn márùn-ún lára wọn mi bọ́ọ̀sì wa jìgìjìgì. Inú bọ́ọ̀sì náà ni mo wà lákòókò yẹn, tí mò ń mójú tó ẹ̀rọ náà! A rí i pé kò ní bọ́gbọ́n mu ká sọ pé a fẹ́ dúró lórí ẹ̀tọ́ wa, la bá kúrò lágbègbè náà nígbà táwọn ọkùnrin náà fi ọkọ̀ wa sílẹ̀.
Nílùú Bundaberg, ọkùnrin kan tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yá wa ní ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ ká lè máa gbé àsọyé Bíbélì jáde láti orí Odò Burnett tó la àárín ìlú náà já. Aubrey àti Clive bá ọkọ̀ ojú omi náà lọ pẹ̀lú ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ yẹn èmi sì dúró dè wọ́n ní gbọ̀ngàn tá a háyà. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ńṣe ni ohùn Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó rinlẹ̀ tí wọ́n gbà sílẹ̀ láti orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba gbogbo ìlú Bundaberg kan, bó ti ń polongo ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó lágbára gan-an. Ká sòótọ́, àwọn àkókò yẹn dùn mọ́ni gan-an àmọ́ ó gba pé káwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìgboyà àti ìgbàgbọ́.
Ogun Dá Kún Ìṣòro Wa
Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ lóṣù September ọdún 1939 tí Ilé Ìṣọ́ November 1 fi jíròrò ìdí táwa Kristẹni kò fi ń lọ́wọ́ sí ogun àti ìṣèlú. Nígbà tó yá, inú mi wá dùn gan-an pé mo ti kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ tó bọ́ sásìkò yìí. Lẹ́yìn témi àti Aubrey àti Clive ti jọ wà pa pọ̀ fọ́dún mẹ́ta, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gba iṣẹ́ ìsìn tó mú ká gbọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n ní kémi lọ máa ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ní ìpínlẹ̀ Queensland tó wà lápá àríwá, iṣẹ́ ìsìn yìí sì dán bí ìgbẹ́kẹ̀lé mi nínú Jèhófà ṣe tó wò.
Lóṣù August ọdún 1940, mo lọ bẹ ìjọ tó wà nílùú Townsville wò. Aṣáájú-ọ̀nà mẹ́rin ló wà nínú ìjọ náà, orúkọ wọn sì ni Percy àti Ilma Iszlauba pẹ̀lú Norman àti Beatrice Bellotti tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá kan náà. Beatrice wá di aya mi ní ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà. Lẹ́yìn tí gbogbo wa parí ìjẹ́rìí ojú pópó nírọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé kan ni wàhálà tí mo sọ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣẹlẹ̀. Àmọ́ ńṣe nìwà ìkà tí wọ́n hù sí mi yẹn mú kí n túbọ̀ jára mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Àwọn arábìnrin méjì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Una àti Merle Kilpatrick wà lápá àríwá, aṣáájú-ọ̀nà ni wọ́n, wọn ò sì fiṣẹ́ ìwàásù ṣeré rárá. Lọ́jọ́ kan tí mo bá wọn jáde lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, èyí tí mo gbádùn gan-an, wọ́n sọ pé kí n fọkọ̀ ojú omi gbé àwọn sọdá sí òdìkejì odò káwọn lè lọ sọ́dọ̀ ìdílé kan tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn túmọ̀ sí pé màá lúwẹ̀ẹ́ lọ síbi tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi kan gúnlẹ̀ sí lódìkejì odò, màá gbé ọkọ̀ náà wá bá wọn, lẹ́yìn náà màá wá fi gbé wọn sọdá odò náà. Àmọ́ nígbà tí mo débi tọ́kọ̀ ojú omi náà wà, kò sáwọn àjẹ̀ tí wọ́n fi ń wà á níbẹ̀! Ìgbà tó yá la wá mọ̀ pé ẹnì kan tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa ló lọ kó wọn pa mọ́. Àmọ́ ète tó pa yẹn kò dá wa dúró. Láti bí ọdún mélòó kan lèmi ti ń ṣiṣẹ́ àwọn tó máa ń yọ àwọn tó bá fẹ́ rì sínú omi mo sì lè lúwẹ̀ẹ́ dáadáa. Ni mo bá so okùn tó máa ń wà lára ìdákọ̀ró ọkọ̀ mọ́ ìbàdí mi, mo sì fọwọ́ fa ọkọ̀ ojú omi náà lọ bá wọn, ni mo bá fi gbé wọn padà. Jèhófà bù kún ìsapá wa nítorí pé ìdílé náà di Ẹlẹ́rìí nígbà tó yá.
Jèhófà Dáàbò Bò Mí
Nítorí ọ̀ràn ààbò, àwọn ológun ṣe ibì kan táwọn ẹ̀ṣọ́ ojú ọ̀nà máa ń dúró sí ní apá ìsàlẹ̀ ìlú Innisfail. Nítorí pé mo láṣẹ láti gbé lágbègbè yẹn, ó ṣeé ṣe fún mi láti gba àṣẹ láti wọ ìlú náà, èyí sì ṣèrànwọ́ gan-an nígbà táwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wá sílùú yẹn. Kí n lè gbé wọn kọjá níbi táwọn ẹ̀ṣọ́ náà ń dúró sí, mo máa ń sọ fún arákùnrin tí mo bá gbé pé kó sá pa mọ́ sábẹ́ ìjókòó ẹ̀yìn ọkọ̀ mi, níbi tí wọn ò ti lè rí i.
Epo mọ́tò ṣọ̀wọ́n gan-an lákòókò yẹn, wọ́n sì ṣe ẹ̀rọ tó ń mú gáàsì jáde sínú ọ̀pọ̀ mọ́tò. Kí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ lè ṣiṣẹ́, ẹ̀rọ yìí máa ń fa gáàsì látinú èédú gbígbóná. Òru ni mo máa ń rìnrìn àjò, tí màá kó àpò èédú tìrìgàngàn lé orí ibi táwọn arákùnrin yẹn sá pa mọ́ sí. Nígbà tí mo bá ń dúró níbi táwọn ẹ̀ṣọ́ ojú ọ̀nà wà, mo máa ń jẹ́ kí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ máa ṣiṣẹ́ gan-an, ibi tí èédú wà yẹn á sì máa gbóná girigiri, èyí kì í jẹ́ káwọn ẹ̀ṣọ́ náà fura sí mi. Lálẹ́ ọjọ́ kan bẹ́ẹ̀ tí mò ń lọ, mo kígbe sáwọn ẹ̀ṣọ́ náà pé: “Tí mo bá paná ọkọ̀ yìí gáàsì kò ní lè jáde dáadáa á sì ṣòro kí ọkọ̀ yìí tó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.” Nítorí pé ooru iná, ariwo, àti èéfín èédú kò jẹ́ káwọn ẹ̀ṣọ́ náà gbádùn, páápààpá ni wọ́n yẹ ọkọ̀ mi wò, wọ́n sì ní kí n máa lọ.
Lákòókò yẹn, wọ́n ní kí n lọ ṣètò ìpàdé àgbègbè kan fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Townsville. Ìjọba ló máa ń pín oúnjẹ, ká sì tó lè rí oúnjẹ tá a nílò, ó di dandan kẹ́ni tó jẹ́ aṣojú ìjọba lágbègbè náà fọwọ́ sí i. Ìjọba ń ju àwọn arákùnrin wa sẹ́wọ̀n lásìkò yìí nítorí pé wọn ò lọ́wọ́ sógun. Èyí mú kí n máa bí ara mi léèrè nígbà tí mo fẹ́ lọ rí ọkùnrin náà pé ‘Ǹjẹ́ ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí bọ́gbọ́n mu àbí ńṣe ni mo fẹ́ lọ fa wàhálà lẹ́sẹ̀?’ Síbẹ̀, mo lọ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ní kí n ṣe.
Ìdí tábìlì ńlá kan ni aṣojú ìjọba náà jókòó sí, ó sì sọ pé kémi náà jókòó. Nígbà tí mo sọ ìdí tí mo fi wá, ó jókòó dáadáa, ojú tó sì fi wò mí kò dára. Lẹ́yìn náà ló túra ká tó sì sọ pé: “Báwo loúnjẹ tó o fẹ́ ṣe pọ̀ tó?” Mo fún un ní bébà tá a kọ àwọn ohun tá a nílò sí, ní ìwọ̀n tó kéré gan-an. Ó yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì sọ pé: “Ó jọ pé èyí kò lè tó. Á dára ká ṣeé ní ìlọ́po méjì.” Bí mo ti ń jáde nínú ọ́fíìsì rẹ̀, ńṣe ni mò ń dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó tún gba ọ̀nà mìíràn kọ́ mí lẹ́kọ̀ọ́ láti máa gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá.
Lóṣù January ọdún 1941, ìjọba fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Ọsirélíà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí wa kódà wọ́n sọ pé à ń ṣamí fún ilẹ̀ Japan! Nígbà kan, àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n kúnnú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì ya wọ Oko Society, ìyẹn ilẹ̀ kékeré kan lágbègbè Atherton tó jẹ́ Ilẹ̀ Títẹ́jú, èyí tá a rà láti máa fi ṣọ̀gbìn oúnjẹ. Iná amọ́lẹ̀yòò kan tí wọ́n gbà pé a fi ń ṣamí fáwọn ọ̀tá ni wọ́n wá wá. Wọ́n tún fẹ̀sùn kàn wá pé ńṣe la gbin àgbàdo wa lọ́nà tá a fi ń sọ nǹkan kan fáwọn ọ̀tá látojú òfuurufú! Àmọ́ wọ́n rí i pé irọ́ pátá ni gbogbo àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí.
Nítorí ìfòfindè yìí, a ní láti ṣọ́ra nígbà tá a bá ń kówèé lọ sáwọn ìjọ ká sì mọ oríṣiríṣi ọ̀nà tó yàtọ̀ síra láti máa fi ṣiṣẹ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwé kan jáde tó ń jẹ́ Children, mo gba páálí kan rẹ̀, mo wá wọ ọkọ̀ ojú irin gba ọ̀nà àríwá, mo sì ń yọ àwọn ìwé náà sílẹ̀ láwọn ibi tí ìjọ wà tá a máa ń jáwèé sí. Káwọn ọlọ́pàá àtàwọn ológun tó jẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ máa bàa sọ pé kí n máa ṣí páálí náà, mo mú ayùn kan tó rí roboto dání, mo sì máa ń dè é mọ́ páálí náà kí n tó sọ̀ kalẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n yìí kò fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú, síbẹ̀ òun ni kò jẹ́ kí wọ́n rí mi mú. Nígbà tí wọ́n mú ìfòfindè yìí kúrò lóṣù June ọdún 1943, inú àwọn èèyàn Jèhófà dùn gan-an. Adájọ́ kan sọ pé ìfòfindè yìí jẹ́ ohun tí wọ́n fi “ìwàǹwára àti ìkùgìrì ṣe, ó sì jẹ́ ìninilára.”
Wọ́n Ní Kí N Wá Wọṣẹ́ Ológun
Ṣáájú ọdún 1943 ni wọ́n pe èmi àti Aubrey Wills àti Norman Bellotti, pé ká wá wọṣẹ́ ológun. Ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú kí wọ́n tó ní kí n wá fara hàn nílé ẹjọ́ ni wọ́n ti pe Aubrey àti Norman tí wọ́n sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà. Lákòókò yẹn, ńṣe nilé ìfìwéránṣẹ́ máa ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tórúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n mọ̀ bá ti wà lára rẹ̀, àmọ́ wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ sí tàwọn mìíràn tí wọ́n ṣèdáwó fáwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí. Iṣẹ́ wa ni pé ká wá ọ̀kan lára àwọn èèyàn wọ̀nyí rí, ká ṣe ọ̀pọ̀ ẹ̀dà àwọn ìwé ìròyìn yẹn, ká sì pín in fáwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwa. Èyí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé.
Nígbà tí wọ́n dá ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà tí mo ti ń retí fún mi, kíá ni mo pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ọ́fíìsì nílùú Sydney ti ní kí n ṣe. Ìdí tá a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká lè dá lilọ́ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n mi dúró títí dìgbà tí wọ́n á fi yan ẹlòmíràn tí yóò máa bójú tó iṣẹ́ ìwàásù. Mo lo àǹfààní òmìnira tí mo ní yẹn láti lọ sọ́dọ̀ díẹ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́kànlélógún tí wọ́n wà ní àtìmọ́lé ní ìpínlẹ̀ Queensland tó wà lápá àríwá. Inú ọgbà ẹ̀wọ̀n kan náà ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n wà, wọ́dà tó wà níbẹ̀ sì kórìíra wa. Nígbà tí mo sọ fún un pé ṣebí wọ́n ń fún àwọn àlùfáà àwọn ẹ̀sìn yòókù láyè láti wá wo àwọn èèyàn wọn, inú bí i. Ló bá pariwo mọ́ mi pé: “Ká ní pé ó ṣeé ṣe fún mi ni, ńṣe ni màá sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tò sórí ìlà, tí màá sì yìnbọn pa wọ́n!” Làwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà níbẹ̀ bá mú mi jáde kíákíá.
Nígbà tákòókò tó láti gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí mo pè, wọ́n fún mi ní lọ́yà gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe sọ. Àmọ́ ká sòótọ́, èmi fúnra mi ni mo ro ẹjọ́ mi, èyí tó gba pé kí n gbára lé Jèhófà gan-an. Jèhófà kò sì já mi kulẹ̀. (Lúùkù 12:11, 12; Fílípì 4:6, 7) Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí mo pè yẹn yọrí sí rere, torí pé wọ́n rí àwọn àṣìṣe kan nínú àwọn ìwé ìpẹ̀jọ́ náà!
Lọ́dún 1944, wọ́n yàn mí sí àyíká kan tó fẹ̀ gan-an, tó kárí gbogbo ìpínlẹ̀ South Australia lọ dé àríwá Victoria, títí kan ìlú Sydney ní New South Wales. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àsọyé kan wáyé ní gbogbo ayé, olùbánisọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ló sì ní láti múra ohun tó máa sọ, èyí tí yóò gbé ka ìlapa èrò kan tí ètò Jèhófà pèsè, ojú ewé kan sì ni ìlapa èrò náà. Sísọ àsọyé tó gba wákàtí kan jẹ́ ohun tí a kò ṣe rí, àmọ́ a bẹ̀rẹ̀ sí í múra rẹ̀, a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì bù kún ìsapá wa.
Mo Ṣègbéyàwó, Mo Tún Gba Àfikún Iṣẹ́
Lóṣù July ọdún 1946, èmi àti Beatrice Bellotti ṣègbéyàwó, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ilé alágbèérìn tí wọ́n fi pákó fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kọ́ là ń gbé. Lóṣù December ọdún 1950, a bí ọmọ wa obìnrin tá a sọ orúkọ rẹ̀ ní Jannyce, òun sì ni ọmọ kan ṣoṣo tá a bí. A ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ọ̀pọ̀ àgbègbè, títí kan ìlú Kempsey, tó wà ní New South Wales, níbi tó ti jẹ́ pé àwa nìkan ṣoṣo ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Lọ́jọọjọ́ Sunday, a máa ń lọ sí gbọ̀ngàn kan tó wà nínú ìlú náà, màá sì sọ àsọyé kan tá a ti fi ìwé ìléwọ́ polongo rẹ̀. Fún oṣù bíi mélòó kan ló fi jẹ́ pé ìyàwó mi nìkan àti ọmọ wa kóńkóló, ìyẹn Jann, làwọn tó ń gbọ́ àsọyé mi. Àmọ́ kò pẹ́ kò jìnnà táwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá díẹ̀díẹ̀. Ìjọ méjì tó ń ṣe dáadáa ló wà nílùú Kempsey báyìí.
Nígbà tí Jann pé ọmọ ọdún méjì, a lọ ń gbé nílùú Brisbane. Nígbà tó sì ṣe tán níléèwé, gbogbo wa jọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọdún mẹ́rin nílùú Cessnock, èyí tó wà ní ìpínlẹ̀ New South Wales, ká tó tún wá padà sílùú Brisbane láti lọ tọ́jú màmá ìyàwó mi tó ń ṣàìsàn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, mò ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Chermside.
Èmi àti Beatrice, ìyàwó mi, dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìbùkún rẹ̀ tí kò lóǹkà, títí kan àǹfààní tá a ní láti ran àwọn èèyàn méjìlélọ́gbọ̀n lọ́wọ́ láti wá mọ̀ ọ́n. Ní tèmi, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìyàwó mi ọ̀wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni, kò bẹ̀rù rárá láti máa ti ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì lẹ́yìn. Ìfẹ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run, ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú rẹ̀, àti jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni ‘tójú rẹ̀ mú ọ̀nà kan’ ti mú kó jẹ́ aya rere, ó sì tún jẹ́ ìyá àtàtà. (Mátíù 6:22, 23; Òwe 12:4) Pẹ̀lú ìyàwó mi, mo lè fi gbogbo ọkàn sọ pé: “Ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”—Jeremáyà 17:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Percy Iszlaub wà nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí, ti November 15, 1981.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yìí la so ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ mọ́ tá a sì lò ó ní ìpínlẹ̀ Queensland tó wà lápá àríwá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Mo ran àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò tórúkọ bàbá wọn ń jẹ́ Kilpatrick lọ́wọ́ láti ti ọkọ̀ wọn lákòókò òjò ní ìpínlẹ̀ Queensland
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ọjọ́ ìgbéyàwó wa