Ṣé Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Fífi Èdè Fọ̀ Ti Wá?
Ọ KÙNRIN kan tó ń jẹ́ Devon sọ pé: “Kò yé mi o. Ó jọ pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gba ẹ̀mí mímọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì mi, tí wọ́n sì máa ń fi iṣẹ́ ìyanu sọ onírúurú èdè. Àwọn kan lára wọn jẹ́ oníṣekúṣe. Àmọ́, èmi ń gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Síbẹ̀, kò sí bí mo ṣe gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ tó, mi ò tíì rí ẹ̀bùn ẹ̀mí yìí gbà. Kí ló dé tí mi ò rí i gbà?”
Bákan náà, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Gabriel ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan tí àwọn èèyàn sọ pé àwọ́n ti ń rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, tí wọ́n sì ń fi èdè fọ̀. Ó ṣàlàyé pé, “Ohun tó ń dùn mí ni pé nígbà tí mo bá ń gbàdúrà lọ́wọ́, ńṣe lohùn àwọn míì máa ń lọ sókè, tí wọ́n á máa sọ̀rọ̀ tí kò yé mi, ọ̀rọ̀ náà kò sì yé àwọn fúnra wọn. Kò sí ẹni tó ń jàǹfààní látinú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ náà. Àmọ́ ṣé kò yẹ kí ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn láwọn ọ̀nà kan?”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Devon àti Gabriel mú kéèyàn béèrè kan tó fani lọ́kàn mọ́ra. Ìbéèrè náà ni pé, Ṣé àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni fífi èdè fọ̀ ti ń wá lóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan lónìí ti ń fèdè fọ̀? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀bùn sísọ̀ èdè lọ́nà iṣẹ́ ìyanu láàárín àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.
Wọ́n “Bẹ̀rẹ̀ Sí Fi Onírúurú Ahọ́n Àjèjì Sọ̀rọ̀”
Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, a kà nípa àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí wọ́n gba agbára láti máa sọ èdè tí wọn kò kọ́ rí. Èyí kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìyẹn lọ́sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù Kristi kú. Lọ́jọ́ yẹn ní Jerúsálẹ́mù, nǹkan bí ọgọ́fà [120] ọmọ ẹ̀yin Jésù “kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.” Àwọn àlejò láti ilẹ̀ òkèèrè ni ‘ìdàrúdàpọ̀-ọkàn sì bá, nítorí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ ní èdè tirẹ̀.’—Ìṣe 1:15; 2:1-6.
Bíbélì mẹ́nu kan àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù míì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n ní agbára tó kàmàmà yìí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀mí mímọ́ fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lágbára láti lè fi iṣẹ́ ìyanu sọ onírúurú èdè. (Ìṣe 19:6; 1 Kọ́ríńtì 12:10, 28; 14:18) Àmọ́, ó bọ́gbọ́n mu pé irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ní láti ṣàǹfààní fún àwọn èèyàn láwọn ọ̀nà kan. Nítorí náà, àǹfààní wo ló wà nínú fífi èdè fọ̀ ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
Ó Jẹ́ Àmì Ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì, ìyẹn àwọn tí àwọn kan lára wọn lè fi èdè fọ̀, ó ṣàlàyé pé “àwọn ahọ́n àjèjì wà fún iṣẹ́ àmì, . . . fún àwọn aláìgbàgbọ́.” (1 Kọ́ríńtì 14:22) Nítorí náà, agbára láti fi èdè fọ̀ àtàwọn agbára iṣẹ́ ìyanu míì jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn tó ń wò wọ́n, pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ìjọ Kristẹni tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, tó sì ń tì í lẹ́yìn. Àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu dà bí ohun tó ń tọ́ka sí ibi tí àwọn tó ń wá òtítọ́ ní láti lọ kí wọ́n lè rí àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ti yàn.
Ohun pàtàkì kan ni pé kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé Jésù tàbí àwọn wòlíì tó wà ṣáájú ìgbà àwọn Kristẹni fi iṣẹ́ ìyanu sọ onírúurú èdè tí wọn kò kọ́ rí. Ó hàn kedere nígbà náà pé, ó ní àwọn ìdí kan táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi rí ẹ̀bùn sísọ onírúurú èdè gbà.
Wọ́n Lò Ó Láti fi Tan Ìhìn Rere Kálẹ̀
Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn Júù nìkan. (Mátíù 10:6; 15:24) Nítorí èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ wàásù ní ibi táwọn Júù kì í gbé. Àmọ́, ìyípadà máa tó dé.
Kété lẹ́yìn ikú Jésù ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù tó ti jíǹde pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Ó tún sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé wọn yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 28:19; Ìṣe 1:8) Títan ìhìn rere dé ibi jíjìnnà yẹn gba pé kí wọ́n sọ onírúurú èdè tó yàtọ̀ sí èdè Hébérù.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn nígbà yẹn ni wọ́n jẹ́ “àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” (Ìṣe 4:13) Báwo wá ni wọ́n ṣe máa wàásù láwọn ilẹ̀ òkèèrè níbi tí àwọn èèyàn ti ń sọ èdè táwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí, tí wọn kò sì lè sọ? Ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn kan lára àwọn onítara tí ń wàásù náà lágbára lọ́nà iṣẹ́ ìyanu láti fi àwọn èdè tí wọn kò kọ́ rí sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn.
Nítorí náà, ẹ̀bùn sísọ onírúurú èdè wà fún ìdí pàtàkì méjì. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, ó fúnni ní ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́yìn. Èkejì ni pé, ó jẹ́ ohun èlò tó ran àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn láṣeyanjú, ìyẹn ni láti wàásù fún àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè. Ǹjẹ́ fífi èdè fọ̀ ní ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì lónìí jẹ́ nítorí àwọn ìdí méjì yìí?
Ṣé Àmì Ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run Ni Fífi Èdè Fọ̀ Jẹ́ Lónìí?
Tí wọ́n bá ní kó o gbé àmì kan tó máa ṣe àwọn èèyàn àdúgbò rẹ láǹfààní sí ibì kan, ibo ló máa gbé e sí? Ṣé inú ilé kékeré kan ni? Rárá o! Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì sọ fún wa pé “ògìdìgbó” àwọn tó ń kọjá lọ ló rí ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ṣe, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń fi iṣẹ́ ìyanu sọ onírúurú èdè. Àbájáde rẹ̀ ni pé “nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn ni a sì fi kún” ìjọ Kristẹni ní ọjọ́ yẹn! (Ìṣe 2:5, 6, 41) Bí àwọn èèyàn lónìí bá sọ pé àwọn ń fi èdè fọ̀, tó sì jẹ́ pé inú ṣọ́ọ̀ṣì nìkan ni wọ́n ti ń ṣe é, ṣé ìyẹn lè jẹ́ àmì tó hàn kedere fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé àgbèrè àti àwọn “iṣẹ́ ti ara” yòókù kì í jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ṣiṣẹ́, ó sì fi kún un pé “àwọn tí ń fi irúfẹ́ nǹkan báwọ̀nyí ṣe ìwà hù kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:17-21) Tó o bá rí i tí àwọn tí ìwà wọn kò dára bá ń fi èdè fọ̀, ǹjẹ́ o kò ní máa ṣe kàyéfì pé ṣé Ọlọ́run náà ló ń fún àwọn tó ń ṣe ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lẹ́bi ní ẹ̀mí mímọ́? Ńṣe nìyẹn máa dà bí ìgbà téèyàn gbé àmì kan sójú ọ̀nà tó ń darí àwọn èèyàn gba ibi tí kò dára.
Ṣé Fífi Èdè Fọ̀ Lónìí Wà fún Títan Ìhìn Rere Kálẹ̀?
Kí la lè sọ nípa ìdí míì tí ẹ̀bùn fifi èdè fọ̀ fi wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? Ǹjẹ́ fífi èdè fọ̀ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì lóde òní wà fún sísọ ìhìn rere fún àwọn èèyàn tí ń sọ onírúurú èdè? Má gbàgbé pé àwọn tó ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n sì lóye àwọn èdè táwọn ọmọ ẹ̀yìn ń sọ lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ti àwọn tó ń fi èdè fọ̀ lóde òní yàtọ̀ gan-an nítorí pé ọ̀rọ̀ tí kò yé ẹnikẹ́ni ni wọ́n sábà máa ń sọ.
Ó hàn gbangba pé fífi èdè fọ̀ lónìí yàtọ̀ gan-an sí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún kìíní rí gbà. Kódà, kò sí àkọsílẹ̀ kankan tó ṣeé gbára lé pé ẹnì kan gba irú ẹ̀bùn agbára iṣẹ́ ìyanu kan náà látìgbà tí àwọn àpọ́sítélì ti kú. Èyí kò ya àwọn tó lóye Bíbélì lẹ́nu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu, títí kan fífi èdè fọ̀, ó ní: “A óò mú wọn wá sí òpin.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Wàyí o, báwo la ṣe lè mọ àwọn tó ní ẹ̀mí mímọ́ lóde òní?
Àwọn Wo Ló Ń Fi Hàn Pé Àwọn Ní Ẹ̀mí Mímọ́?
Jésù mọ̀ pé ẹ̀bùn sísọ onírúurú èdè yóò dópin kété lẹ́yìn tí ìjọ Kristẹni bá ti fìdí múlẹ̀. Ní àkókò díẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó kú, ó sọ àmì kan tó máa wà pẹ́ títí, tí a ó fi máa dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ mọ̀. Ó sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Kódà, ẹsẹ Bíbélì tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu máa dópin, tún sọ pé: “Ìfẹ́ kì í kùnà láé.”—1 Kọ́ríńtì 13:8.
Ìfẹ́ ni àkọ́kọ́ lára apá mẹ́sàn-án tí “èso” ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run pín sí. (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, àwọn tí wọ́n ní ẹ̀mí Ọlọ́run lóòótọ́ tí Ọlọ́run sì ń tì lẹ́yìn, á máa fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sí ara wọn. Ní àfikún sí ìyẹn, àlàáfíà ni apá kẹta lára èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Fún ìdí yẹn, àwọn tó ní ẹ̀mí mímọ́ lónìí ní láti jẹ́ ẹni àlàáfíà, tó ń sapá láti yẹra fún ìwà àìgba èrò ẹlòmíì, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ìwà ipá.
Tún rántí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó wà ní Ìṣe 1:8. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á gba agbára láti máa ṣe ẹlẹ́rìí òun “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” Jésù tún fi hàn pé iṣẹ́ yìí á máa bá a nìṣó títí “de opin aiye.” (Mátíù 28:20, Bibeli Mimọ) Nítorí náà, iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé yìí yóò máa jẹ́ àmì tá a fi ń dá àwọn tí ẹ̀mí mímọ́ fún lágbára mọ̀.
Kí ni èrò rẹ? Àwùjọ àwọn èèyàn wo ni ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ní ẹ̀mí mímọ́? Àwọn wo ló ń fi èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ní pàtàkì ìfẹ́ àti àlàáfíà hàn, tí ìyẹn sì mú kí àwọn ìjọba máa fìyà jẹ wọ́n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ogun jíjà níbikíbi lágbàáyé? (Aísáyà 2:4) Àwọn wo ló ń sapá láti yàgò fún àwọn iṣẹ́ ti ara, bí àgbèrè, àní tí wọ́n sì tún ń mú àwọn tó ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ tí wọ́n kò ronú pìwà dà kúrò láàárín wọn? (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Àwọn wo ló ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún aráyé ní gbogbo ilẹ̀ ayé?—Mátíù 24:14.
Àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí kò lọ́ra láti sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá àpèjúwe tí Bíbélì ṣe mu nípa àwọn tó ní ẹ̀mí mímọ́. O ò ṣe dojúlùmọ̀ wọn kó o sì rí i fúnra rẹ bóyá lóòótọ́ ni Ọlọ́run ń tì wọ́n lẹ́yìn.