Mo Ti Rí Bí Òtítọ́ Bíbélì Ṣe Lágbára Tó
Gẹ́gẹ́ bí Vito Fraese ṣe sọ ọ́
ÌLÚ kékeré kan wà ní apá gúúsù ìlú Naples, lórílẹ̀-èdè Ítálì, orúkọ ìlú náà ni Trentinara. Ó ṣeé ṣe kó o máà gbọ́ orúkọ ìlú náà rí. Ìlú yìí ni wọ́n bí àwọn òbí mi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Angelo sí. Lẹ́yìn tí àwọn òbí mi bí Angelo, wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì ń gbé ní ìlú Rochester, ní ìpínlẹ̀ New York, ibẹ̀ sì ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1926. Ọdún 1922 ni bàbá mi kọ́kọ́ pàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́ nígbà yẹn. Kò sì pẹ́ tí bàbá mi àti màmá mi fi di Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Èèyàn jẹ́jẹ́ ni bàbá mi, ó sì máa ń ro àròjinlẹ̀, síbẹ̀ ìwà ìrẹ́jẹ máa ń bí i nínú. Kò nífẹ̀ẹ́ sí bí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń fi òtítọ́ pa mọ́ fún àwọn èèyàn, torí náà gbogbo ìgbà ló máa ń lo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn. Nígbà tó fẹ̀yìn tì, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe títí tí àìlera àti òtútù tó máa ń pọ̀ gan-an nígbà òtútù kò fi jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ náà mọ́ lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rin [74]. Síbẹ̀, ó ṣì ń lo ogójì sí ọgọ́ta wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣooṣù títí tó fi lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún. Àpẹẹrẹ bàbá mi ní ipa tó pọ̀ gan-an lórí mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń dápàárá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ ó mọ ohun tó ń ṣe. Ó sábà máa ń sọ pé, “Ọwọ́ pàtàkì ló yẹ kéèyàn fi mú òtítọ́.”
Bàbá mi àti màmá mi sapá láti kọ́ àwa ọmọ wọn márààrún lẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Mo ṣe ìrìbọmi ní August 23, 1943, mo sì di aṣáájú-ọ̀nà ní June 1944. Ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Carmela àti Fern tára rẹ̀ yọ̀ mọ́ọ̀yàn ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Geneva, ní ìpínlẹ̀ New York. Kò pẹ́ tí mo fi mọ̀ pé Fern ni ọmọbìnrin tí màá fi ṣe aya. Torí náà, a ṣègbéyàwó ní oṣù August, ọdún 1946.
Iṣẹ́ Ìsìn Míṣọ́nnárì
Lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ jọ ṣe, ní ìlú Geneva àti Norwich, ní ìpínlẹ̀ New York. Ní oṣù August, ọdún 1948, a láǹfààní láti lọ sí kíláàsì kejìlá ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn náà ni wọ́n rán wa lọ sí ìlú Naples, lórílẹ̀-èdè Ítálì, pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì míì tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, ìyẹn Carl àti Joanne Ridgeway. Nígbà yẹn, ràbọ̀ràbọ̀ ogun tó jà kò tíì kúrò ní ìlú Naples. Ó ṣòro láti rí ilé, torí náà, a gbé nínú yàrá kótópó méjì fún oṣù mélòó kan.
Èdè àdúgbò kan tí àwọn ará Ítálì tó ń gbé ìlú Naples ń sọ ni mo máa ń gbọ́ táwọn òbí mi ń sọ bí mo ti ń dàgbà, torí náà àwọn èèyàn gbọ́ èdè Italian tí mò ń sọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ahọ́n Amẹ́ríkà ni mo fi ń sọ ọ́. Fern kò tètè mọ èdè náà sọ. Àmọ́, nígbà tó yá, ó wá mọ èdè náà sọ ju èmi alára lọ.
Nígbà tá a dé ìlú Naples, ìdílé ẹlẹ́ni mẹ́rin tá a bá níbẹ̀ nìkan ló fìfẹ́ hàn sí òtítọ́. Sìgá tí ìjọba kò fọwọ́ sí ni wọ́n ń tà. Ojoojúmọ́ ni Teresa tó jẹ́ ọ̀kan lára ìdílé yẹn máa ń yí pa dà lọ́nà tó yani lẹ́nu. Lọ́wọ́ àárọ̀ tó bá ti kó sìgá kún inú àwọn àpò síkẹ́ẹ̀tì rẹ̀, ńṣe ló máa ń sanra, àmọ́ ńṣe ló máa ń rí pẹ́lẹ́ńgẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Ṣùgbọ́n òtítọ́ yí ìgbésí ayé ìdílé yìí pa dà pátápátá. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, èèyàn mẹ́rìndínlógún nínú ìdílé náà ló di Ẹlẹ́rìí. Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìlú Naples tó nǹkan bí ẹgbàajì ó dín ọ̀ọ́dúnrún [3,700].
Wọ́n Ṣàtakò sí Iṣẹ́ Wa
Lẹ́yìn tá a ti lo oṣù mẹ́sàn-án péré ní ìlú Naples, àwọn aláṣẹ fipá lé àwa mẹ́rẹ̀ẹ̀rin kúrò ní ìlú náà. A kọjá lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland fún nǹkan bí oṣù kan, a sì ń lo ìwé àṣẹ ìwọ̀lú gẹ́gẹ́ bí arìnrìn-àjò afẹ́ láti wọ orílẹ̀-èdè Ítálì. Wọ́n ní kí èmi àti Fern lọ máa sìn ní ìlú Turin. Nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀, a rẹ́ǹtì yàrá kan lọ́wọ́ ọ̀dọ́bìnrin kan, ilé ìwẹ̀ àti ilé ìdáná rẹ̀ la sì ń lò. Ṣùgbọ́n nígbà tí arákùnrin àti arábìnrin Ridgeway dé sí ìlú Turin, àwa pẹ̀lú wọn jọ rẹ́ǹtì ilé míì. Nígbà tó yá, àwa míṣọ́nnárì tá a jẹ́ tọkọtaya, tá a sì ń gbé nínú ilé kan náà jẹ́ márùn-ún.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1955 tí àwọn aláṣẹ lé wa kúrò ní ìlú Turin, a ti ń ṣètò bá a ṣe máa dá ìjọ tuntun mẹ́rin sílẹ̀. Àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tó dáńgájíá sì wà táá máa bójú tó àwọn ìjọ náà. Àwọn aláṣẹ sọ fún wa pé: “Ó dá wa lójú pé nígbà tí ẹ̀yin ará Amẹ́ríkà yìí bá lọ tán, gbogbo iṣẹ́ tẹ́ ẹ ti ṣe ló máa pa run.” Àmọ́, àwọn ìbísí tó wáyé lẹ́yìn náà fi hàn pé ọwọ́ Ọlọ́run ni àṣeyọrí iṣẹ́ náà wà. Ní báyìí, ìjọ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] ló wà ní ìlú Turin, àwọn Ẹlẹ́rìí tó sì wà níbẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó dín irínwó [4,600].
Florence, Ìlú Tó Fani Mọ́ra
Lẹ́yìn tá a kúrò ní ìlú Turin, wọ́n ní ká lọ sìn ní ìlú Florence. A ti máa ń gbọ́ nípa ìlú yìí, torí pé ibẹ̀ ni ẹ̀gbọ́n mi obìnrin Carmela àti ọkọ rẹ̀ Merlin Hartzler ti sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Ibẹ̀ mà tuni lára o, àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì bíi Piazza della Signoria, Ponte Vecchio, Piazzale Michelangelo àti Palazzo Pitti, mú kí ìlú náà fani mọ́ra! Ohun míì tó tún ń múni láyọ̀ nípa ìlú Florence ni bí àwọn èèyàn ibẹ̀ ṣe ń tẹ́tí sí ìhìn rere.
A bá ìdílé kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́, àwọn òbí wọn sì ṣe ìrìbọmi. Àmọ́, bàbá wọn máa ń mu sìgá. Lọ́dún 1973, Ile-Iṣọ Na ṣàlàyé pé sìgá mímu jẹ́ ìwà àìmọ́, ó sì rọ àwọn òǹkàwé láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Àwọn ọmọ rẹ̀ àgbà bẹ̀ ẹ́ pé kó jáwọ́ sìgá mímu. Ó ṣèlérí pé òun máa jáwọ́, àmọ́ kò jáwọ́. Lálẹ́ ọjọ́ kan, ìyàwó rẹ̀ ní kí àwọn ìbejì wọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lọ sùn, kó tó di pé ó gbàdúrà pẹ̀lú wọn bó ti máa ń ṣe. Lẹ́yìn náà, ó dùn ún pé kò tíì gbàdúrà pẹ̀lú wọn, ó wá lọ bá wọn ní yàrá. Kó tó débẹ̀ wọ́n ti gbàdúrà. Ó bi wọ́n pé: “Kí ni àdúrà yín dá lé lórí?” Wọ́n ní àwọn gbàdúrà pé: “Jèhófà jọ̀wọ́ ran Dádì lọ́wọ́ kí wọ́n má mu sìgá mọ́.” Ìyá wọn wá pe bàbá wọn ó sì sọ fún un pé: “Wá gbọ́ àdúrà táwọn ọmọ rẹ gbà.” Nígbà tó gbọ́, ńṣe ló bú sẹ́kún, ó sì sọ pé, “Mi ò tún jẹ́ mu sìgá mọ́ láé!” Ó mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ní báyìí ó lé ní èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ìdílé náà tó ti di Ẹlẹ́rìí.
Iṣẹ́ Ìsìn ní Áfíríkà
Lọ́dún 1959, wọ́n gbé àwa àti àwọn míṣọ́nnárì méjì míì, ìyẹn Arturo Leveris àti Angelo ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, lọ sí ìlú Mogadishu, lórílẹ̀-èdè Sòmálíà. Rògbòdìyàn òṣèlú wà lórílẹ̀-èdè náà nígbà tá a débẹ̀. Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ti pàṣẹ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Ítálì pé kí wọ́n ran orílẹ̀-èdè Sòmálíà lọ́wọ́ láti gba òmìnira, àmọ́ ó dà bíi pé ńṣe ni ipò nǹkan túbọ̀ ń burú sí i níbẹ̀. Àwọn ọmọ Ítálì kan tá à ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ kúrò ní orílẹ̀-èdè náà, kò sì rọrùn láti dá ìjọ sílẹ̀ níbẹ̀.
Láàárín àkókò yẹn, alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè dábàá pé kí n máa ran òun lọ́wọ́. Torí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilẹ̀ tó wà nítòsí orílẹ̀-èdè náà. Àwọn kan lára àwọn tá à ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀síwájú, àmọ́ wọ́n ní láti fi orílẹ̀-èdè wọn sílẹ̀ nítorí àtakò. Àwọn kan dúró, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti fara da ọ̀pọ̀ ìnira.a Bá a bá ronú nípa ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àtàwọn ohun tí wọ́n ní láti fara dà kí wọ́n lè dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́, ó ṣì máa ń mú kí omi dà lójú wa.
Ooru àti ọ̀rinrin tó wà ní orílẹ̀-èdè Sòmálíà àti Eritrea kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Ata máa ń pọ̀ gan-an nínú oúnjẹ wọn, èyí sì máa ń mú kí ara wa túbọ̀ gbóná. Ní ìgbà àkọ́kọ́ tá a jẹ oúnjẹ wọn lọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa kan, ìyàwó mi fi ṣàwàdà pé ńṣe letí òun ń hó yee!
Ó wá ku àwa nìkan nígbà tí wọ́n ní kí Angelo àti Arturo lọ máa sìn ní ibòmíì. Bí kò ṣe sí ẹni táá máa fún wa ní ìṣírí mú kí nǹkan le díẹ̀ fún wa. Àmọ́ ipò yìí mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì túbọ̀ fọkàn tán an. Àwọn ìbẹ̀wò tá a ṣe sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa tún fún wa ní ìṣírí gan-an.
A bá onírúurú ìṣòro pàdé lórílẹ̀-èdè Sòmálíà. A kò ní fìríìjì, torí náà ìwọ̀n oúnjẹ tá a máa jẹ lọ́jọ́ kan la máa ń rà, ì báà jẹ́ máńgòrò, ìbẹ́pẹ, èso àjàrà, àgbọn, ọ̀gẹ̀dẹ̀ tàbí ẹja ekurá. Àwọn kòkòrò tó ń fò kiri kì í jẹ́ ká gbádùn. Nígbà míì wọ́n máa ń bà lé wa lọ́rùn tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ṣá o, a kì í fi bẹ́ẹ̀ rìn fún ọ̀pọ̀ wákàtí nínú oòrùn tó mú ganrín-ganrín, torí pé a ní alùpùpù kan.
A Pa Dà sí Orílẹ̀-Èdè Ítálì
Ọpẹ́lọpẹ́ ìwà ọ̀làwọ́ àwọn ọ̀rẹ́ wa ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń kó ọ̀gẹ̀dẹ̀ wọ̀ pa dà lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì ká lè lọ sí àpéjọ àgbáyé tí wọ́n ṣe ní ìlú Turin lọ́dún 1961. Ibẹ̀ la ti gbọ́ pé wọ́n máa rán wa lọ sìn níbòmíì. Ní oṣù September, ọdún 1962, a pa dà sí orílẹ̀-èdè Ítálì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká níbẹ̀. A ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan, a sì lò ó fún ọdún márùn-ún láti máa fi ṣèbẹ̀wò sí àyíká méjì.
Lẹ́yìn tá a ti kúrò nínú ooru ilẹ̀ Áfíríkà, òtútù ló tún wá jẹ́ ìṣòro wa báyìí. Lásìkò òtútù nígbà tá à ń bẹ ìjọ kan tó wà ní ẹsẹ̀ òkè Alps wò, a sùn nínú yàrá kan tí kò ní ẹ̀rọ amúlémóoru, lórí koríko gbígbẹ. Òtútù náà mú débi pé ńṣe la wọṣọ tó wà lọ́rùn wa sùn. Lóru ọjọ́ yẹn, adìyẹ mẹ́rin àti ajá méjì ni òtútù náà pa nítòsí ibi tá a wà!
Nígbà tó yá, mo sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè. Láwọn ọdún yẹn, gbogbo orílẹ̀-èdè Ítálì la máa ń kárí. Ọ̀pọ̀ ìgbà la ṣèbẹ̀wò sí àwọn àgbègbè bíi Calabria àti Sicily. A fún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì wá àǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ, òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tàbí kí wọ́n lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì.
A ti kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ lára àwọn ọ̀rẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n sì ti sin Jèhófà tọkàntọkàn. A mọrírì àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní, irú bíi jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, ìwà ọ̀làwọ́, ìfẹ́ fún àwọn ará, fífara dà á lábẹ́ ipò èyíkéyìí tó bá yọjú àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ. A ti lọ síbi ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí òfin kà sí òjíṣẹ́ ìsìn tó láṣẹ láti so tọkọtaya pọ̀ ló sì darí àwọn ìgbéyàwó náà, bẹ́ẹ̀ a kò ronú pé irú èyí lè ṣeé ṣe lórílẹ̀-èdè yìí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àwọn ìjọ kò tún ṣèpàdé ní ilé ìdáná àwọn arákùnrin tàbí kí wọ́n jókòó sórí pákó mọ́, bí wọ́n ti máa ń ṣe ní ìlú Turin nígbà kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ìjọ ló ń gbádùn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rí rèǹtè-rente, èyí tó ń fògo fún Jèhófà. A kò tún ṣe àwọn àpéjọ wa mọ́ nínú àwọn gbọ̀ngàn eré ìtàgé tí kò dára tó, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó fẹ̀ dáadáa là ń lò báyìí. Ayọ̀ wa sì kún láti rí i pé iye àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ti lé ní ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún [243,000]. Nígbà tá a kọ́kọ́ dé orílẹ̀-èdè Ítálì, àádọ́rùn-ún lé nírínwó [490] làwọn akéde tá a bá níbẹ̀.
A Tí Yan Àwọn Ohun Tó Tọ́
A ti dojú kọ ọ̀pọ̀ ìnira, tó fi mọ́ ti àárò ilé tó máa ń sọ wá àti àìlera. Àárò ilé sábà máa ń sọ Fern nígbàkigbà tó bá rí òkun. Ó sì tún ti ṣe iṣẹ́ abẹ tó le gan-an nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà kan tó fẹ́ lọ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, alátakò kan fi amúga ńlá gún un. Ìyẹn sì gbé e dé ilé ìwòsàn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì nígbà míì, gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìdárò 3:24 ṣe sọ, a ti fi ‘ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Jèhófà.’ Òun ni Ọlọ́run ìtùnú. Nígbà kan tí a ní ìrẹ̀wẹ̀sì, Fern rí lẹ́tà ìṣírí kan gbà látọ̀dọ̀ Arákùnrin Nathan Knorr. Ó sọ pé ìtòsí ìlú Bethlehem, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, tí wọ́n bí òun sí ni Fern ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, torí náà òun mọ̀ dáadáa pé àwọn obìnrin bíi tiẹ̀ tó bá ti ibẹ̀ wá máa ń lágbára wọ́n sì máa ń dúró lórí ìpinnu wọn. Òótọ́ ló sọ. Bọ́dún ti ń gorí ọdún, a rí ìṣírí gbà lóríṣiríṣi ọ̀nà àti látọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn.
Láìka ti àwọn ìnira náà sí, a ti sapá láti má ṣe jẹ́ kí ìtara wa fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ jó rẹ̀yìn. Nígbà kan, ìyàwó mi fi ìtara wa wé Lambrusco, ìyẹn ọtí wáìnì pupa kan báyìí tó máa ń ta wíríwírí nínú ife èyí táwọn ará Ítálì máa ń mu. Ó wá ṣàwàdà pé, “Ìtara wa kò gbọ́dọ̀ dín kù, ńṣe ló yẹ kó máa ta wíríwírí.” Lẹ́yìn tá a ti lo ohun tó lé ní ogójì [40] ọdún lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti àgbègbè, a tún ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tuntun, ìyẹn ni ṣíṣe ìbẹ̀wò sí àwọn àwùjọ àti ìjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí èdè Italian àti ṣíṣètò irú àwọn àwùjọ bẹ́ẹ̀. Irú àwọn àwùjọ bẹ́ẹ̀ máa ń wàásù fún àwọn èèyàn tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè bíi Bangladesh, Ṣáínà, Eritrea, Etiópíà, Gánà, Íńdíà, Nàìjíríà, Philippines, Sri Lanka àtàwọn ilẹ̀ míì. A ti rí àwọn ọ̀nà àgbàyanu tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbà mú ìyípadà bá ìgbésí ayé àwọn èèyàn tó ti tọ́ àánú Jèhófà wò, tá a bá ṣe odindi ìwé kan, kò lè tó láti fi ṣèròyìn rẹ̀.—Míkà 7:18, 19.
Ojoojúmọ́ là ń gbàdúrà pé kí Jèhófà máa fún wa ní okun àti agbára tá a nílò láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nìṣó. Ìdùnnú Olúwa ni okun wa. Ó ń mú kí ojú wa máa tàn yanran ó sì ń mú ká gbà gbọ́ dájú pé a ti yan àwọn ohun tó tọ́ nígbèésí ayé wa, bá a ṣe ń tan òtítọ́ Bíbélì kálẹ̀.—Éfé. 3:7; Kól. 1:29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé ọdọọdún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ìyẹn 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 95 sí 184.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27-29]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn òbí mi rèé ní ìlú Rochester, ní ìpínlẹ̀ New York
1948
Nígbà tí mo wà nílùú South Lansing fún kíláàsì kejìlá ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì
1949
Èmi àti Fern rèé ká tó gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì
Capri, Ítálì
1952
Àwa àtàwọn míṣọ́nnárì míì ní ìlú Turin àti Naples
1963
Fern àti díẹ̀ lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
“Ìtara wa kò gbọ́dọ̀ dín kù, ńṣe ló yẹ kó máa ta wíríwírí”