ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 1/1 ojú ìwé 12
  • Kí Nìdí Tí Sátánì Fi Lo Ejò Láti Bá Éfà Sọ̀rọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Sátánì Fi Lo Ejò Láti Bá Éfà Sọ̀rọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Ohun Tí O Bá Ṣe Lè Dun Ọlọ́run—Bí O Ṣe Lè Mú Inú Rẹ̀ Dùn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 1/1 ojú ìwé 12

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Tí Sátánì Fi Lo Ejò Láti Bá Éfà Sọ̀rọ̀?

▪ Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ lójú ìwé 8, wàá gbà pé Sátánì ló lo ejò láti bá Éfà sọ̀rọ̀. Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn. Àmọ́, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Kí nìdí tí áńgẹ́lì alágbára kan fi ní láti lo ejò bí ìgbà táwọn èèyàn bá ta ọgbọ́n láti mú kó dà bíi pé ọmọlangidi ń sọ̀rọ̀?’

Bíbélì pe ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń lò ní “ètekéte,” ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sì jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà. (Éfésù 6:11) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Édẹ́nì pé ẹranko sọ̀rọ̀ kì í ṣe ìtàn àròsọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àpẹẹrẹ bí ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì ń lò láti fẹ̀tàn mú àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ti léwu tó. Lọ́nà wo?

Sátánì fara balẹ̀ yan ẹni tó fẹ́ tàn jẹ. Éfà lọjọ́ orí rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ẹ̀dá olóye tó wà láyé àtọ̀run nígbà yẹn. Nítorí pé kò tíì ní ìrírí, Sátánì tàn án jẹ, ó sì mú un dẹ́ṣẹ̀. Sátánì lo ejò tó jẹ́ ẹ̀dá oníṣọ̀ọ́ra, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìwà ògbójú àti ẹ̀mí ìlépa ipò tí ó ní má ṣe hàn sójútáyé. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1) Tún wo ohun tó ṣe láṣeyọrí nígbà tó mú kó dà bíi pé ejò ló ń sọ̀rọ̀.

Lákọ̀ọ́kọ́, Sátánì gba gbogbo àfiyèsí Éfà. Éfà mọ̀ pé ejò kò lè sọ̀rọ̀, ọkọ rẹ̀ ló sọ gbogbo ẹranko lórúkọ, títí kan ejò, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tó ti fara balẹ̀ wo ẹranko kọ̀ọ̀kàn ló fún wọn lórúkọ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:19) Kò sí àní-àní pé, Éfà náà ti kíyè sí ẹranko tó jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra yìí. Nítorí náà, ọgbọ́n tí Sátánì lò yìí mú kí Éfà fẹ́ mọ fìn-ín ìdí kókò, ó mú kí Éfà máa ronú nípa ohun kan ṣoṣo tí Ọlọ́run kàléèwọ̀ nínú gbogbo ohun tó wà nínú ọgbà náà. Ohun kejì ni pé, tó bá jẹ́ orí àwọn ẹ̀ka igi tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà ni ejò náà wà, èrò wo ló ṣeé ṣe kó wá sí ọkàn Éfà? Ṣé kò ní ronú pé ẹranko tí kò lè sọ̀rọ̀ yìí ti jẹ nínú èso igi náà tí ìyẹn sì mú kó máa sọ̀rọ̀? Nígbà náà, bí èso náà bá lè ṣe ohun tó tó èyí fún ejò náà, ṣé kò ní ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ fún òun? A kò mọ ohun tí Éfà ń rò gan-an, a ò sì mọ̀ bóyá ejò náà jẹ èso náà, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé nígbà tí ejò sọ fún Éfà pé èso náà máa mú kó “dà bí Ọlọ́run,” ó gba irọ́ yẹn gbọ́.

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Sátánì lò tún jẹ́ ká mọ ohun tó pọ̀ nípa ọgbọ́nkọ́gbọ́n rẹ̀. Ó dá iyè méjì sílẹ̀ lọ́kàn Éfà, ó sọ pé Ọlọ́run ń fawọ́ ohun rere kúrò lọ́dọ̀ Éfà, kò sì jẹ́ kó ní òmìnira tó yẹ. Bí Éfà bá jẹ́ kí ìmọtara ẹni nìkan rẹ̀ borí ìfẹ́ tó ní fún Ọlọ́run tó fún un ní gbogbo nǹkan ni ètekéte Sátánì yìí tó lè kẹ́sẹ járí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4, 5) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí Sátánì lò ṣiṣẹ́, Éfà àti Ádámù kò tíì ní ìfẹ́ àti ìmọrírì àtọkànwá fún Jèhófà. Ohun kan náà ni Sátánì ṣì ń lò lónìí, ó ń mú káwọn èèyàn jẹ́ onímọtara ẹni nìkan, ó sì ń mú kí wọ́n máa rò pé ohun tó burú dára.

Àmọ́, kí ló wà lọ́kàn Sátánì? Kí ló ń lépa? Nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì gbìyànjú láti fi irú ẹni tó jẹ́ àtohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ pa mọ́. Àmọ́ nígbà tó yá, ó fi irú ẹni tó jẹ́ gan-an hàn. Nígbà tó dán Jésù wò, kò lè fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ pa mọ́ mọ́. Ó sọ fún Jésù ní tààràtà pé: “Wólẹ̀,” kí o sì “jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Mátíù 4:9) Ó dájú pé, ó ti pẹ́ gan-an tí Sátánì ti ń fẹ́ ìjọsìn tó tọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run nìkan. Ó máa ṣe gbogbo ohun tó wà lágbára rẹ̀ láti rí i pé ọwọ́ òun tẹ ìjọsìn náà, tàbí kó sọ ìjọsìn àwọn èèyàn dìdàkudà. Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni láti ba ìwà títọ́ àwọn èèyàn sí Ọlọ́run jẹ́.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé elétekéte ni Sátánì, ó sì ṣe tán láti ṣekú pa àwọn tó ń sin Ọlọ́run. Àmọ́, kò yẹ kí Sátánì rí wa tàn jẹ bíi ti Éfà, “nítorí àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 2:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́