ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 1/1 ojú ìwé 9-11
  • Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Nípa Ọgbà Édẹ́nì Fi Kàn Ẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Nípa Ọgbà Édẹ́nì Fi Kàn Ẹ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • A Sọ Párádísè Nù
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Torí Kí Ni Ọlọ́run Ṣe Dá Ilẹ̀ Ayé?
    Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
  • Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 1/1 ojú ìwé 9-11

Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Nípa Ọgbà Édẹ́nì Fi Kàn Ẹ́

Ọ̀KAN lára àtakò tó yani lẹ́nu jù lọ táwọn ọ̀mọ̀wé kan gbé dìde nípa àkọsílẹ̀ ìtàn ọgbà Édẹ́nì ni pé, àwọn apá yòókù nínú Bíbélì kò tì í lẹ́yìn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Paul Morris tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìsìn kọ̀wé pé: “Kò sí apá ibòmíì nínú Bíbélì tó sọ̀rọ̀ ní tààràtà nípa ìtàn Édẹ́nì.” Àwọn kan tó pe ara wọn ní ògbóǹkangí lè gba ọ̀rọ̀ tó sọ yìí gbọ́, àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe òótọ́ rárá.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì sọ nípa ọgbà Édẹ́nì, Ádámù, Éfà àti ejò náà.a Nítorí náà, àṣìṣe àwọn ọ̀mọ̀wé kan kò tó nǹkan kan rárá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti àwọn alátakò Bíbélì àti ti àwọn aṣáájú ìsìn. Ńṣe ni àwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn alátakò Bíbélì ń bẹnu àtẹ́ lu Bíbélì nípa sísọ pé ọgbà Édẹ́nì, èyí tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì kìí ṣe òótọ́. Lọ́nà wo?

Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì kéèyàn tó lè lóye apá yòókù Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí àwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ tí ẹ̀dá èèyàn ní. Léraléra ni àwọn ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn máa ń jẹ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì. Jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

● Kí nìdí tá a fi ń darúgbó tí a sì ń kú? Ádámù àti Éfà yóò máa wà láàyè títí láé tí wọ́n bá fira wọn sábẹ́ ìdarí Jèhófà. Tí wọ́n bá ṣàìgbọràn nìkan ni wọ́n máa kú. Láti ọjọ́ tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kú díẹ̀díẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:19) Wọ́n pàdánù ìjẹ́pípé, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àwọn ọmọ wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

● Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìwà ibi? Nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì sọ pé òpùrọ́ ni Ọlọ́run, ó ní Ọlọ́run ń fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀dá èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:3-5) Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ pé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣàkóso kò tọ́. Ádámù àti Éfà yàn láti tẹ̀ lé Sátánì, nítorí náà, wọ́n kọ ìṣàkóso Jèhófà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé èèyàn lè fúnra rẹ̀ pinnu pé ohun kan dára tàbí pé kò dára. Nítorí pé ìdájọ́ àti ọgbọ́n Jèhófà jẹ́ pípé, ó mọ̀ pé ọ̀nà kan ṣoṣo tó dára jù lọ láti dáhùn àtakò yìí ni pé, kí òun yọ̀ǹda àkókò fún àwọn ẹ̀dá èèyàn, kí òun sì fún wọn láǹfààní láti ṣàkóso ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fẹ́. Àwọn kan lára àbájáde búburú tó ti wáyé jẹ́ nítorí ipa tí Sátánì ń kó nínú ọ̀ràn yìí, èyí sì ti wá fi òtítọ́ pàtàkì kan hàn pé: Ẹ̀dá èèyàn kò lè ṣàkóso ara rẹ̀ láìsí ọwọ́ Ọlọ́run níbẹ̀.—Jeremáyà 10:23.

● Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé? Jèhófà fi ọgbà Édẹ́nì ṣàpẹẹrẹ bí ilẹ̀ ayé ṣe máa lẹ́wà tó. Ó sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n bímọ, kí wọ́n kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì “ṣèkáwọ́ rẹ̀,” kí wọ́n mú ẹwà àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ọgbà náà gbòòrò yíká ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé ni pé kó di Párádísè, níbi tí àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé á ti máa gbé ní ìṣọ̀kan. Ibi púpọ̀ nínú Bíbélì ló sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe máa mú ohun tó ní lọ́kàn yìí ṣẹ.

● Kí nìdí tí Jésù Kristi fi wá sí ayé? Ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì yọrí sí ikú fún Ádámù àti Éfà àti gbogbo ọmọ wọn, àmọ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ fún wa ní ìrètí. Ó rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé láti wá pèsè ohun tí Bíbélì pè ní ìràpadà. (Mátíù 20:28) Kí ló ń jẹ́ ìràpadà? Jésù ni “Ádámù ìkẹyìn” nítorí pé ó ṣàṣeyọrí níbi tí Ádámù ti kùnà. Jésù ń jẹ́ ẹni pípé nìṣó, nítorí pé ó jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà. Ó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ìwàláàyè rẹ̀ láti ṣe ìrúbọ tàbí ìràpadà, ó mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo olóòótọ́ èèyàn láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà, tí wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ ní irú ìwàláàyè tí Ádámù àti Éfà ní kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:22, 45; Jòhánù 3:16) Nítorí náà, Jésù fi dáni lójú pé, Jèhófà máa mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ láti sọ ayé yìí di Párádísè tó rí bí ọgbà Édẹ́nì.b

Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé kì í ṣe ohun tí èèyàn kò lè lóye, kì í sì í ṣe àdììtú ẹ̀kọ́ ìsìn. Ohun gidi ni. Bí ọgbà Édẹ́nì ti jẹ́ ibi gidi kan ni orí ilẹ̀ ayé yìí, tí àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn gidi sì wà níbẹ̀, bákan náà ni ìlérí Ọlọ́run nípa ọjọ́ iwájú ṣe dájú, ohun gidi tí kò ní pẹ́ dé ni. Ṣé ìwọ náà fẹ́ wà níbẹ̀? Ọwọ́ rẹ ní èyí tó pọ̀ wà o. Ọlọ́run fẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní ọjọ́ ọ̀la yìí, títí kan àwọn tí kò tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run ní ìgbésí ayé wọn pàápàá.—1 Tímótì 2:3, 4.

Nígbà tí Jésù ń kú lọ, ó bá ọkùnrin kan tí ìgbésí ayé rẹ̀ ti dìdàkudà sọ̀rọ̀. Ọ̀daràn ni ọkùnrin náà, ó sì mọ̀ pé ikú tọ́ sí òun. Àmọ́, ó yíjú sí Jésù kó lè rí ìtùnú àti ìrètí gbà. Kí wá ni Jésù fi dá a lóhùn? “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Tí Jésù bá fẹ́ kí ọ̀daràn yìí jíǹde, kó sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè tó rí bí ọgbà Édẹ́nì, ǹjẹ́ kò ní fẹ́ kí ìwọ náà nírú àǹfààní yìí? Ó dájú pé ó fẹ́ bẹ́ẹ̀! Bàbá rẹ̀ náà fẹ́ bẹ́ẹ̀! Tó o bá fẹ́ gbé inú Párádísè, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tó gbin ọgbà Édẹ́nì.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí àpẹẹrẹ, wo ìwé Jẹ́nẹ́sísì 13:10; Diutarónómì 32:8; 2 Sámúẹ́lì 7:14; 1 Kíróníkà 1:1; Aísáyà 51:3; Ìsíkíẹ́lì 28:13; 31:8, 9; Lúùkù 3:38; Róòmù 5:12-14; 1 Kọ́ríńtì 15:22, 45; 2 Kọ́ríńtì 11:3; 1 Tímótì 2:13, 14; Júdà 14; àti Ìṣípayá 12:9.

b Láti mọ púpọ̀ sí i nípa ẹbọ ìràpadà Kristi, ka orí 5 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

ASỌTẸ́LẸ̀ TÓ MÚ KÍ BÍBÉLÌ ṢỌ̀KAN

“Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ [ejò] àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.

Èyí ni àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tí Ọlọ́run sọ ní Édẹ́nì. Tá ni obìnrin náà àti irú-ọmọ rẹ̀ àti ejò náà àti irú-ọmọ rẹ̀? Báwo ni “ìṣọ̀tá” tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ náà ṣe wáyé?

EJÒ NÁÀ

Sátánì Èṣù.—Ìṣípayá 12:9.

OBÌNRIN NÁÀ

Apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà. (Gálátíà 4:26, 27) Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “obìnrin náà,” pé ó máa bí orílẹ̀ èdè tẹ̀mí kan lọ́jọ́ iwájú.—Aísáyà 54:1; 66:8.

IRÚ-ỌMỌ EJÒ NÁÀ

Àwọn tó yàn láti máa ṣe ìfẹ́ Sátánì.—Jòhánù 8:44.

IRÚ-ỌMỌ OBÌNRIN NÁÀ

Jésù Kristi tó wá látinú apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà ni ẹni àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ obìnrin náà. Àwọn tó tún jẹ́ “irú ọmọ” náà ni, àwọn arákùnrin Kristi nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ń ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí ló para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 3:16, 29; 6:16; Jẹ́nẹ́sísì 22:18.

ỌGBẸ́ GÌGÍSẸ̀

Mèsáyà gba ọgbẹ́ tó dùn ún wọra, àmọ́ ọgbẹ́ náà kò wà títí lọ. Sátánì rí sí i pé wọ́n pa Jésù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Àmọ́ Jésù jíǹde.

ỌGBẸ́ ORÍ

Sátánì gba ọgbẹ́ ikú. Jésù máa pa Sátánì run títí láé. Ṣáájú ìgbà yẹn pàápàá, Jésù máa mú ìwà ibi tí Sátánì dá sílẹ̀ ní Édẹ́nì kúrò.—1 Jòhánù 3:8; Ìṣípayá 20:10.

Fún àlàyé ṣókí nípa ohun tí Bíbélì dá lé, ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ádámù àti Éfà jìyà àbájáde tó burú jáì tí ẹ̀ṣẹ̀ mú wá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́