ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 2/1 ojú ìwé 3
  • Kí Nìdí Tí Ọ̀pọ̀ Ìgbéyàwó Fi Ń Tú Ká?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Ọ̀pọ̀ Ìgbéyàwó Fi Ń Tú Ká?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Híhá Sínú Ìgbéyàwó Aláìnífẹ̀ẹ́
    Jí!—2001
  • Ṣé Ìjì Tó Ń Jà Yìí Ò Ní Í Gbé Ìgbéyàwó Lọ?
    Jí!—2006
  • Ojú Wo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ìkọ̀sílẹ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú “Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 2/1 ojú ìwé 3

Kí Nìdí Tí Ọ̀pọ̀ Ìgbéyàwó Fi Ń Tú Ká?

“Àwọn Farisí sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n dójú lé dídẹ ẹ́ wò, wọ́n sì wí pé: ‘Ó ha bófin mu fún ọkùnrin láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí gbogbo?’”—Mátíù 19:3.

ÀWỌN kan nígbà ayé Jésù rò pé kò yẹ kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”a (Mátíù 19:4-6) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run fẹ́ kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí.

Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí, tí wọ́n bá ṣe ìgbéyàwó mẹ́wàá, mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú wọn ló máa ń tú ká, tí wọ́n á kọ ara wọn sílẹ̀. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fúnni nípa ìgbéyàwó kò wúlò mọ́? Àbí ó lè jẹ́ pé ètò ìgbéyàwó ní àbùkù kan ni kò fi yọrí sí rere?

Wo àpèjúwe yìí ná: Àwọn tọkọtaya méjì ra oríṣi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan náà, tọkọtaya kan ń tọ́jú ọkọ̀ tiwọn, wọ́n sì ń wà á jẹ́jẹ́. Nítorí náà, ọkọ̀ wọn kò bà jẹ́. Àmọ́ tọkọtaya kejì, kìí tọ́jú ọkọ̀ wọn, wọn kì í sì í wakọ̀ náà jẹ́jẹ́. Nítorí náà, ọkọ̀ náà bà jẹ́, wọ́n sì pa á tì. Ẹ̀bi ta ni? Ṣé ẹ̀bi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ni àbí ti àwọn tó ni ọkọ̀ náà? Kò sí iyè méjì pé àwọn tó ni ọkọ̀ náà ló jẹ̀bi.

Bákan náà, pé àwọn ìgbéyàwó kan ń tú ká kò túmọ̀ sí pé ètò ìgbéyàwó ní àbùkù. Ọ̀kẹ́ àìmọye ìgbéyàwó tó ti yọrí sí rere fi hàn pé ètò ìgbéyàwó kò ní àbùkù. Àwọn ìgbéyàwó yẹn ń mú ayọ̀ bá ẹnì kọ̀ọ̀kan, ìdílé àti àwùjọ èèyàn, ó sì ń mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Àmọ́, ìgbéyàwó nílò àbójútó àti ìtọ́jú tó yẹ bíi ti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yẹn, kó bàa lè wà pẹ́ títí.

Bóyá o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tàbí ó ti ṣe é tipẹ́, àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì lórí bó o ṣe lè bójú tó ìgbéyàwó rẹ àti bó o ṣe lè fún un lókun wúlò gan-an. Kíyè sí àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ohun kan tí Bíbélì sọ pé ó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀ ni, bí ẹnì kan nínú wọn bá lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì.—Mátíù 19:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́