Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Òtòṣì Paraku?
IPÒ òṣì paraku máa ń mú kí ìgbésí ayé nira. Èèyàn kò ní ní oúnjẹ, omi àti ohun ìdáná tí ó tó, kò sì ní sí ilé tó dára láti gbé, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ní sí ìtọ́jú ara àti ẹ̀kọ́ ìwé tó dára. Irú nǹkan yìí ló ń ṣẹlẹ̀ sí bílíọ̀nù kan èèyàn, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù àti Amẹ́ríkà Àríwá ni kò mọ ohun tó túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan tó jẹ́ òtòṣì paraku. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ òtòṣì paraku sọ.
Mbarushimana ń gbé lórílẹ̀-èdè Rwanda, nílẹ̀ Áfíríkà pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, ó sì ní ọmọ mẹ́fà. Àmọ́ àrùn ibà ló pa ọmọ kẹfà. Ọ̀gbẹ́ni yìí sọ pé: “Bàbá mi pín ilẹ̀ rẹ̀ fún àwa ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà. Èyí tó kàn mí nínú ilẹ̀ náà kéré gan-an, nítorí náà mo kó ọmọ àti ìyàwó mi lọ sí ìlú míì. Iṣẹ́ àwọn tó ń ru àpò òkúta àti yanrìn lèmi àti ìyàwó mi ń ṣe. Ilé wa kò ní fèrèsé. Kànga kan tó wà ní àgọ́ ọlọ́pàá la ti máa ń pọn omi. Ẹ̀ẹ̀kan lójúmọ́ la sábà máa ń jẹun, àmọ́ lọ́jọ́ tí a kò bá rí iṣẹ́ ṣe, kò sí oúnjẹ lọ́jọ́ yẹn nìyẹn. Tó bá ti ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni mo máa ń kúrò nílé nítorí pé ara mi ò ní gbà á nígbà táwọn ọmọ bá ń kígbe pé ebi ń pa àwọn.”
Victor àti Carmen máa ń tún bàtà ṣe. Àwọn àtàwọn ọmọ wọn márààrún ń gbé ní ìlú kan tó wà ní àdádó ní orílẹ̀-èdè Bolivia. Wọ́n gba yàrá kan nínú ilé àwókù kan tí páànù òrùlé rẹ̀ ń jò, ilé náà kò sì ní iná mànàmáná. Àwọn ọmọ tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ pọ̀ débi pé Victor ní láti ṣe àga ìkọ̀wé fún ọmọbìnrin rẹ̀, kí ọmọ náà bàa lè lọ sílé ìwé. Tọkọtaya yìí ní láti rin ìrìn kìlómítà mẹ́wàá kí wọ́n tó lè gé igi tí wọ́n máa fi se oúnjẹ àti omi tí wọ́n máa mu. Carmen sọ pé: “A kò ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Nítorí náà, odò la máa ń lọ tí a bá fẹ́ yàgbẹ́, omi odò yìí náà la fi ń wẹ̀, inú rẹ̀ la sì ń da ìdọ̀tí sí. Àwọn ọmọ wa sábà máa ń ṣàìsàn.”
Francisco àti Ilídia ń gbé ní ìgbèríko kan ní orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì. Ọmọ márùn-ún ni wọ́n bí, àmọ́ ibà pa ọ̀kan lára wọn nítorí pé ilé ìwòsàn kan kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀. Tọkọtaya yìí gbin ìrẹsì àti ọ̀dùnkún tí wọ́n lè jẹ fún oṣù mẹ́ta sórí ilẹ̀ kékeré tí wọ́n ní. Francisco sọ pé: “Nígbà míì, irè oko wa máa ń bà jẹ́ nítorí pé òjò kò rọ̀, ìgbà míì sì wà tí àwọn olè máa ń jí wọn, nítorí náà, mo máa ń gé ọparun fún àwọn tó ń kọ́lé kí n lè rí owó díẹ̀. A tún máa ń lọ gé igi ìdáná nínú igbó, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn wákàtí méjì sílé wa. Èmi àti ìyàwó mi máa ń ru ìdì igi kọ̀ọ̀kan, a ó fi ọ̀kan dáná fún ọ̀sẹ̀ kan, a ó sì ta ìkejì.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé àìdáa àti àìṣẹ̀tọ́ pọ̀ nínú ayé yìí, tí ẹnì kan nínú méje ti ń gbé ìgbésí ayé bíi ti Mbarushimana, Victor, àti Francisco, nígbà tó sì jẹ́ pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn wà tí wọ́n ń jayé bí ọba. Àwọn kan ti sapá láti ṣe nǹkan sí ọ̀ràn yìí. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí sọ àwọn ìsapá tí wọ́n ti ṣe àti àwọn ohun tí wọ́n ń retí pé ó máa jẹ́ àbájáde wọn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]
Carmen àti méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀ ń pọn omi nínú odò