Ìgbà Wo Ni Wọ́n Kọ Bíbélì?
Ìwé kan tí kó lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì. Èèyàn tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́ta ló gbà pé ìwé mímọ́ ni. Òun ni ìwé tó tà jù lọ láyé, nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000,000] ni wọ́n ti tẹ̀ jáde (yálà ní odindi tàbí ní apá kan) ní èdè tó lé ní egbèjìlá [2,400].
ÒÓTỌ́ ni pé Bíbélì ni ìwé tí àwọn èèyàn tí ì kà jù lọ, àmọ́ ọ̀pọ̀ èrò làwọn èèyàn ní nípa ìgbà tí wọ́n kọ ọ́, ní pàtàkì nípa ìgbà tí wọ́n kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí wọ́n sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé. Ó ṣeé ṣe kó o ti kà nípa irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé míì tàbí kó o ti wo ètò orí tẹlifíṣọ̀n níbi táwọn ọ̀mọ̀wé ti ṣàlàyé èrò náà. Díẹ̀ rèé lára ohun tí àwọn èèyàn kan tí wọ́n jọ gbé ayé lásìkò kan náà sọ nípa ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì.
▪ “Ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ sí ìkẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ìwé Bíbélì tàbí kó jẹ́ láàárín àkókò tí wòlíì Aísáyà àti Jeremáyà gbé láyé.”
▪ “Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì sẹ́yìn tí àwọn tó ń ṣèwádìí Bíbélì ti máa ń sọ pé ìgbà àwọn ará Páṣíà àti ìgbà àwọn ará Gíríìsì ni wọ́n kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n sì ṣàtúnṣe èyí tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ (ìyẹn ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún sí ìkejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni).”
▪ “Gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó wà lónìí ti wà láti ìgbà àwọn ará Gíríìsì (ìyẹn ìparí ọgọ́rùn-ún kejì sí ìkíní [ṣáájú Sànmánì Kristẹni]).”
Ojú wo ló yẹ kí Kristẹni kan tó gbà gbọ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí” fi wo èrò tó ta ko ara wọn yìí? (2 Tímótì 3:16) Láti rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí àwọn alárìíwísí sọ àti ohun tí Bíbélì sọ.
Àkókò Táwọn Nǹkan Inú Bíbélì Ṣẹlẹ̀
Ọ̀pọ̀ ìtàn ló wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nípa àkókò tí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé ara wọn. Èyí fi hàn pé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] sẹ́yìn, ìyẹn nígbà tí Mósè àti Jóṣúà gbé láyé ni wọ́n kọ àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ.a Sámúẹ́lì, Dáfídì, Sólómọ́nì àtàwọn míì náà kọ àwọn ìwé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkànlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó di ọgọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án sí ìkarùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n kọ àwọn ìwé ìtàn, ewì àtàwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀.
Àwọn ẹ̀dà tàbí àwọn àjákù ìwé àfọwọ́kọ àwọn ìwé Bíbélì yìí wà lára àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú tí wọ́n rí, ìwé Ẹ́sítérì nìkan ni kò sí níbẹ̀. Èròjà kan tí wọ́n ń pè ní carbon 14 tí wọ́n fi ń mọ àkókò tí wọ́n kọ ìwé kan àti ìwádìí nípa ìwé àfọwọ́kọ fi hàn pé èyí tó pẹ́ jù lọ lára àwọn àkájọ ìwé yìí jẹ́ láti nǹkan bí ọdún 200 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 100 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Ohun Tí Àwọn Alárìíwísí Sọ
Ìdí pàtàkì tó mú káwọn èèyàn máa ṣiyèméjì nípa àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ jẹ́ nítorí sísọ tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ Bíbélì. Lórí kókó yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Walter C. Kaiser, Jr. sọ ohun táwọn èèyàn sọ nínú ìwé rẹ̀, The Old Testament Documents, ó ní: “[Bíbélì] kò ṣeé fọkàn tán nítorí sísọ tó sọ nípa iṣẹ́ ìyanu àti Ọlọ́run, tó tún sọ pé Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ òun.” Àwọn ọ̀mọ̀wé tí kò gbà pé Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé, ó yẹ kí wọ́n ṣèwádìí Bíbélì dáadáa bí àwọn ìwé yòókù.
Láwọn àkókò kan, wọ́n lo àbá ọgbọ́n orí ọ̀gbẹ́ni Darwin láti ṣàlàyé bí ìtẹ̀síwájú ṣe bá ẹ̀sìn, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ látorí ìbọgibọ̀pẹ̀ dórí jíjọ́sìn ọ̀pọ̀ ọlọ́run, nígbà tó sì yá, èrò pé ọlọ́run kan ló yẹ láti jọ́sìn tún bẹ̀rẹ̀. Nítorí pé àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ ṣàlàyé pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló yẹ ká jọ́sìn, àwọn kan sọ pé, kì í ṣe ìgbà tí wọ́n sọ pé wọ́n kọ àwọn ìwé Bíbélì yẹn ni wọ́n kọ wọ́n, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ wọ́n.
Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ti gbà ṣe àríwísí Bíbélì láti ìgbà yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé atúmọ̀ èdè tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí tó ṣàlàyé nípa Májẹ̀mú Láéláé ní àwọn àpilẹ̀kọ kan tó sọ nípa àríwísí táwọn èèyàn ṣe sí Bíbélì. Àwọn àríwísí náà jẹ́ nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ Bíbélì, ìtàn inú rẹ̀, àlàyé inú rẹ̀, ìtàn nípa ìwé márùn-ún àkọ́kọ́, orísun ìsọfúnni rẹ̀ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn èèyàn inú Bíbélì.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, èrò àwọn ọ̀mọ̀wé kò ṣọ̀kan lórí ìgbà tí wọ́n kọ àwọn ìwé Bíbélì, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ló fara mọ́ èrò tí Ọ̀jọ̀gbọ́n R. E. Friedman gbé kalẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn làwọn òǹkọ̀wé ayé ìgbàanì ti kọ ewì, ìtàn àti òfin. Àwọn nǹkan tí wọ́n kọ yìí làwọn tó ń ṣèwé jáde máa ń lò. Òun ni wọ́n lò láti fi ṣe Bíbélì.”
Ìwé tí wọ́n pè ní Faith, Tradition, and History ṣàlàyé ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìgbàgbọ́, àṣà àti ìtàn, ó sì tún sọ nípa àwọn àríwísí míì táwọn èèyàn ṣe sí Bíbélì. Àmọ́, ìwé yìí ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ṣọ̀kan pé àwọn kò fara mọ́ Ìwé Mímọ́, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì gbà pé èrò òun nípa Ìwé Mímọ́ tọ̀nà, gbogbo wọn ló máa ń ṣàríwísí èrò ara wọn.”
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àkókò Táwọn Nǹkan Inú Bíbélì Ṣẹlẹ̀
Orí àwọn nǹkan tó lè bà jẹ́ ni wọ́n kọ àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ sí. Nítorí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu láti rò pé èèyàn ṣì lè rí àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ gangan nígbà ayé Mósè, Jóṣúà, Sámúẹ́lì àti Dáfídì tàbí àdàkọ rẹ̀. Àmọ́, ó ṣeé ṣe láti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tí kò ṣe tààràtà tó fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti gba àwọn déètì tí Bíbélì sọ, èyí tí ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé àtàwọn awalẹ̀pìtàn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún náà tẹ́wọ́ gbà. Kí làwọn ẹ̀rí yẹn jẹ́ ká mọ̀? Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára wọn.
▪ Ǹjẹ́ wọ́n ti ń kọ ìwé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, ìyẹn ìgbà tí Bíbélì sọ pé Mósè àti Jóṣúà gbé láyé? Wọ́n kọ àwọn ìwé tó dá lórí ìtàn, ìsìn, òfin, ewì, orin àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ láyé ìgbàanì ní Mesopotámíà àti Íjíbítì. Ọ̀rọ̀ nípa Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ńkọ́? Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Dictionary of the Old Testament: Pentateuch, tó ń ṣàlàyé ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì dáhùn, ó ní: “Kò sí ìdí láti jiyàn pé wọ́n ti ń kọ àwọn ìwé ní ilẹ̀ Kénáánì láti nǹkan bí ọdún 1550 sí 1200 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.” Ó tún sọ pé: “Pẹ̀lú bí àwọn èèyàn ayé ìgbàanì ṣe máa ń kọ̀wé, kó sí ìdí láti sọ pé Mósè kọ́ ló kọ ìwé tó kọ, kò sì yẹ kí èèyàn sọ pé àwọn òǹkọ̀wé yòókù kọ́ ló kọ ìwé tí wọ́n kọ.”—Ẹ́kísódù 17:14; 24:4; 34:27, 28; Númérì 33:2; Diutarónómì 31:24.
▪ Ǹjẹ́ àwọn tó kọ Bíbélì lo àwọn ìwé míì láyé ìgbàanì láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn? Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn kan tọ́ka sí ‘àwọn ìwé,’ tó ṣeé ṣe kó sọ nípa ìtàn ìlú, ìtàn ìgbésí ayé, ìtàn nípa iṣẹ́, ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìtàn ìdílé.—Númérì 21:14; Jóṣúà 10:13; 2 Sámúẹ́lì 1:18; 1 Àwọn Ọba 11:41; 2 Kíróníkà 32:32.
▪ Kí nìdí tó fi jẹ́ pé, wọn kò rí àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ láyé ìgbàanì àyàfi Àkájọ Ìwé Òkun Òkú? Ìwé Biblical Archaeology Review tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ní gbogbo ilẹ̀ Palẹ́sínì, wọn kò rí àkọsílẹ̀ tí wọ́n kọ sórí òrépèté àti awọ, àyàfi àwọn tí wọ́n rí níbi tó gbẹ́ táútáú, irú bí àgbègbè Òkun Òkú. Àwọn ohun ìkọ̀wé yìí máa ń jẹrà láwọn àgbègbè olómi. Àmọ́, pé wọn kò tíì ṣàwárí èyíkéyìí nínú wọn kò túmọ̀ sí pé wọn kò sí.” Kódà, wọ́n ti rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún amọ̀ tí wọ́n lù ní òǹtẹ̀ èyí tí wọ́n máa ń fi di àwọn ohun tí wọ́n ti kọ̀wé sórí rẹ̀. Iná tàbí omi ti ba àwọn òrépèté àtàwọn awọ tí wọ́n kọ̀wé sí jẹ́, àmọ́ àwọn amọ̀ tí wọ́n lù ní òǹtẹ̀ tí wọ́n fi di àwọn ohun tí wọ́n kọ̀wé sórí rẹ̀ yìí ṣì wà. Àwọn amọ̀ yìí ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án sí ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
▪ Kí ni wọ́n ṣe tí àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n ṣàdàkọ wọn kò fi bà jẹ́? Ìwé The Bible as It Was tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣàdàkọ àwọn ìtàn, sáàmù, òfin àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ara Bíbélì tá a ní lónìí ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àní ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì pàápàá. . . . Pé wọ́n ṣàdàkọ àwọn ìwé yìí ní ọ̀pọ̀ ìgbà lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n lò wọ́n, wọ́n sì kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn lójoojúmọ́. . . . Kò sẹ́ni tí á máa da ara rẹ̀ láàmú láti máa ṣàdàkọ ìwé kan ní ọ̀pọ̀ ìgbà láìsí ìdí tó fi ń kọ ọ́.”—Diutarónómì 17:18; Òwe 25:1.
Èyí túmọ̀ sí pé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ọdún ni wọ́n fi ń ṣàdàkọ àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ léraléra títí di ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Ìwé kan tó sọ nípa Bíbélì, ìyẹn On the Reliability of the Old Testament sọ pé, láti kọ ìwé yìí lọ́nà tó péye gba pé kí wọ́n “ṣàtúnṣe gírámà àti sípẹ́lì ọ̀rọ̀, èyí sì jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń ṣe káàkiri ní ayé ìgbàanì ní Ìtòsí Ìlà Oòrùn ayé.”b Ẹ̀rí yìí fi hàn pé àríwísí táwọn èèyàn ń ṣe sí ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ Bíbélì kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Ìgbà Wo ni Wọ́n Kọ Bíbélì?
Nítorí pé wọn kò rí àwọn ìwé tí wọ́n kọ lákòókò Mósè, Jóṣúà, Sámúẹ́lì àtàwọn ìwé táwọn èèyàn míì kọ, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn kò kọ àwọn ìwé Bíbélì ní àkókò tí wọ́n sọ pé wọ́n kọ wọ́n? Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé ló gbà pé, bí wọn kò ṣe rí àwọn ìwé yìí kì í ṣe ẹ̀rí pé wọn kò kọ wọ́n. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, mélòó lára àwọn ohun ìkọ̀wé tó lè bà jẹ́ tí wọ́n ń lò láyé ìgbà yẹn ló lè wà títí dòní? Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀gbẹ́ni K. A. Kitchen tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ohun ìṣẹ̀ǹbáyé Íjíbítì fojú bù ú pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òrépèté ilẹ̀ Íjíbítì tí wọ́n kọ̀wé sórí wọn ṣáájú ìgbà ìṣàkóso Gíríìsì àti Róòmù ló ti bà jẹ́.
Àwọn tó bọ̀wọ̀ fún Bíbélì lè ṣe kàyéfì pé, ‘Ojú wo ni Jésù fi wo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?’ Kò tíì sí awuyewuye lórí ìgbà tí wọ́n kọ ọ́ nígbà yẹn. Bíi ti àwọn Júù yòókù, kò sí àní-àní pé Jésù fara mọ́ ìtàn tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Ǹjẹ́ Jésù kọminú sí àwọn tó kọ àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ?
Jésù tọ́ka sí ìwé tí Mósè kọ. Bí àpẹẹrẹ, ó mẹ́nu kan, “ìwé Mósè.” (Máàkù 12:26; Jòhánù 5:46) Ó tọ́ka sí àwọn ohun tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì (Mátíù 19:4, 5; 24:37-39); Ẹ́kísódù (Lúùkù 20:37); Léfítíkù (Mátíù 8:4); Númérì (Mátíù 12:5); àti ohun tó wà nínú ìwé Diutarónómì (Mátíù 18:16). Ó sọ pé: “Gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.” (Lúùkù 24:44) Tí Jésù bá fara mọ́ ìwé tí Mósè àtàwọn míì kọ, kò sí àní-àní pé ó gbà pé ìtàn tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù péye nìyẹn.
Tóò, ìgbà wo gan-an ni wọ́n kọ Bíbélì? Ǹjẹ́ àkókò táwọn nǹkan inú Bíbélì ṣẹlẹ̀ ṣeé gbára lé? A ti ṣàgbéyẹ̀wò àríwísí tí ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé ṣe àti ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ, a sì ti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tí kò ṣe tààràtà lórí ọ̀ràn yìí àti ohun tó jẹ́ èrò Jésù. Pẹ̀lú àwọn nǹkan tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, ṣé ìdáhùn rẹ á fi hàn pé ó fara mọ́ ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ pé, “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ”?—Jòhánù 17:17.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí àwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe tẹ̀ lé ara wọn, ka ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 447 sí 467. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
b Ka àpilẹ̀kọ náà, “Ipa Táwọn Akọ̀wé Ayé Ọjọ́un Kó Nínú Ṣíṣàdàkọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2007, ojú ìwé 18 sí 20.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20-23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
(Àtẹ ìsọfúnni nípa àwọn ọdún tí wọ́n fojú bù pé wọ́n kọ àwọn ìwé Bíbélì parí)
2000 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
1800
[Àwòrán]
Àwọn òǹkọ̀wé ilẹ̀ Íjíbítì ti ń kọ̀wé ṣáájú kí Mósè tó gbé ayé
[Credit Line]
© DeA Picture Library/Art Resource, NY
1600
[Àwòrán]
Mósè parí kíkọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì ní ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àmọ́ orí ohun ìkọ̀wé tó lè bà jẹ́ ló kọ ọ́ sí
Jẹ́nẹ́sísì 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
Jóṣúà
1400
1200
Sámúẹ́lì
1000 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán]
Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún amọ̀ tí wọ́n fi òǹtẹ̀ lù ló wà títí dòní
Wọ́n kọ ọ́ láti ọdún 900 sí 500 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
Jónà
800
Aísáyà
600
Jeremáyà
Dáníẹ́lì
[Àwòrán]
Òrépèté tí wọ́n kọ nǹkan sórí rẹ̀, tí wọ́n fi okùn àti amọ̀ tí wọ́n lù ní òǹtẹ̀ dì
Wọ́n kọ ọ́ láti ọdún 449 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
[Credit Line]
Ibi Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé sí tó wà ní Brooklyn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Ogún tí ọ̀gbẹ́ni Theodora Wilbour jẹ látinú ohun ìní bàbá rẹ̀ tó ń jẹ́, Charles Edwin Wilbour
400
200
[Àwòrán]
Wọ́n yí Àkájọ Òkun Òkú mọ́ aṣọ, wọ́n sì fi pa mọ́ sínú ìṣà. Ìwọ̀nyí ni ìwé Bíbélì tó tíì pẹ́ jù lọ tí wọ́n rí
Wọ́n kọ ọ́ láti ọdún 200 sí 100 ṣáájú Sànmánì Kristẹni
[Credit Line]
Shrine of the Book, Photo © The Israel Museum, Jerusalem