Ipa Táwọn Akọ̀wé Ayé Ọjọ́un Kó Nínú Ṣíṣàdàkọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
WỌ́N ti kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù parí nígbà tó fi máa di ìparí ọ̀rúndún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Láwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, àwọn Júù tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé, pàápàá jù lọ àwọn Sóférímù àtàwọn Másórétì tó dé lẹ́yìn wọn, wá ń fara balẹ̀ ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù lọ́nà tí kò fi ní yingin. Àmọ́, ìgbà ayé Mósè àti Jóṣúà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ni wọ́n ti kọ àwọn ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú àkókò àwọn Sóférímù. Inú ohun tó lè bà jẹ́ ni wọ́n kọ àwọn ìwé náà sí láyé ìgbà náà; nítorí náà, ńṣe làwọn akọ̀wé ní láti máa dà wọ́n kọ sínú àwọn nǹkan mìíràn láìmọye ìgbà. Kí la mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe iṣẹ́ akọ̀wé nígbà láéláé? Ǹjẹ́ àwọn ọ̀jáfáfá adàwékọ wà ní Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un?
Àwọn kan lára àwọn ìwé inú Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ nígbà láéláé ṣì wà báyìí. Àwọn tó pẹ́ jù lára wọn ni àwọn èyí tí wọ́n rí lára àwọn ìwé tí wọ́n ń pè ní Àkájọ Ìwé Òkun Òkú. Àárín ọ̀rúndún kẹta sí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe àdàkọ àwọn kan lára àwọn àkájọ ìwé náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Alan R. Millard tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn èdè àti ìwalẹ̀pìtàn Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn sọ pé: “Ní báyìí, kò sí èyíkéyìí mọ́ lára àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ.” Ó wá fi kún un pé: “Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká [ilẹ̀ Ísírẹ́lì] lè jẹ́ ká mọ bí àwọn akọ̀wé ayé ọjọ́un ṣe ń ṣiṣẹ́ wọn, èyí sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ìtàn tó jẹ mọ́ ọn.”
Bí Iṣẹ́ Akọ̀wé Ṣe Rí Nígbà Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Bẹ̀rẹ̀
Ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn, wọ́n ń kọ àwọn ìwé tó dá lórí ìtàn, ìsìn, òfin, ẹ̀kọ́ ìwé, ewì, orin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní Mesopotámíà. Ilé ẹ̀kọ́ àwọn akọ̀wé wà káàkiri, ara àwọn ohun tí wọ́n sì ń kọ́ wọn níbẹ̀ ni bí wọ́n á ṣe máa ṣe àdàkọ àwọn ìwé tó ti wà tẹ́lẹ̀ lọ́nà tó péye. Nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé ayé òde òní fi àwọn ìwé tí wọ́n kọ ní Bábílónì ayé ọjọ́un wé àwọn ẹ̀dà rẹ̀ táwọn akọ̀wé dà kọ láìmọye ìgbà fún ẹgbẹ̀rún kan ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n rí i pé ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ kéré jọjọ.
Mesopotámíà nìkan kọ́ ni wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ akọ̀wé nígbà yẹn lọ́hùn-ún o. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Oxford Encyclopedia of Archaeology in the Near East sọ pé: “Tí akọ̀wé kan tó jẹ́ ará Bábílónì ní ìdajì ẹgbẹ̀rún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni bá lọ sáwọn ibòmíì tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé ní Mesopotámíà, Síríà, Kénáánì, àní títí kan Íjíbítì, ó ṣeé ṣe kó rí i pé bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé níbẹ̀ ò yàtọ̀ sí torílẹ̀-èdè òun.”a
Nígbà ayé Mósè, ojú ẹni pàtàkì láwùjọ ni wọ́n fi ń wo àwọn akọ̀wé ní Íjíbítì. Àwọn akọ̀wé ọ̀hún máa ń da onírúurú ìwé kọ. Àwòrán irú àwọn akọ̀wé bẹ́ẹ̀ tó wà lẹ́nu iṣẹ́ wà lára àwọn sàréè kan ní Íjíbítì. Ó sì ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún táwọn àwòrán náà ti wà níbẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ nípa àwọn akọ̀wé ayé ọjọ́un pé: “Nígbà tó fi máa di ẹgbẹ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n ti ṣe àdàkọ àti àkójọ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé tó fi bí ọ̀làjú àwọn ará Mesopotámíà àtàwọn ará Íjíbítì ṣe tó nígbà yẹn hàn, wọ́n sì fi òfin àti ìlànà táwọn tó ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé á máa tẹ̀ lé lélẹ̀.”
Ara “àwọn òfin àti ìlànà” yìí ni pé káwọn akọ̀wé máa ya ibì kan sọ́tọ̀ níparí ohun tí wọ́n bá kọ̀wé sí. Ibẹ̀ ni orúkọ àwọn akọ̀wé àtorúkọ ẹni tó ni wàláà tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sí máa ń wà, ìgbà tí wọ́n kọ ọ́, ibi tí wọ́n ti da ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ kọ, iye ìlà tí ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ pín sí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn akọ̀wé sábà máa ń fi kún un pé: “A yẹ̀ ẹ́ wò láti rí i pé ó bá ọ̀rọ̀ tó wà nínú ibi tá a ti dà á kọ mu.” Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ táwọn akọ̀wé ayé ìgbà yẹn máa ń kọ yìí fi hàn pé ṣíṣe àdàkọ tó péye jẹ wọ́n lógún.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Millard tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Èèyàn lè rí i pé àwọn akọ̀wé yìí ní ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Lára ẹ̀ ni pé kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò ìwé tí wọ́n dà kọ kí wọ́n sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ sí i. Àwọn ìlànà tí wọ́n máa ń tẹ̀ lé yìí kì í jẹ́ kí àṣìṣe wà nínú iṣẹ́ náà tí wọ́n bá parí rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ìlànà yìí, ìyẹn kíka iye ọ̀rọ̀ àti ìlà tó wà níbẹ̀, làwọn Másórétì náà ń tẹ̀ lé ní Sànmánì Ojú Dúdú.” Èyí fi hàn pé, nígbà ayé Mósè àti Jóṣúà, ó jẹ́ àṣà àwọn akọ̀wé tó wà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn láti máa fi ìṣọ́ra ṣe àdàkọ àwọn ìwé tó ti wà tẹ́lẹ̀ kó má bàa sí àṣìṣe nínú rẹ̀.
Ǹjẹ́ àwọn ọ̀jáfáfá adàwékọ wà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà? Kí lohun tí ọ̀rọ̀ Bíbélì fi hàn nípa èyí?
Àwọn Akọ̀wé ní Ísírẹ́lì Ayé Ọjọ́un
Ilé Fáráò ni wọ́n ti tọ́ Mósè dàgbà. (Ẹ́kísódù 2:10; Ìṣe 7:21, 22) Bí àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa orílẹ̀-èdè Íjíbítì ayé ọjọ́un ṣe sọ, ó ní láti jẹ́ pé ara ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ ọ ni bó ṣe lè kọ̀wé ní ọ̀nà ìgbàkọ̀wé àwọn ará Íjíbítì àti bó ṣe lè kà á. Bákan náà, ó ní láti jẹ́ pé wọ́n kọ́ ọ ní iṣẹ́ akọ̀wé díẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n James K. Hoffmeier sọ nínú ìwé rẹ̀ tó sọ nípa ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní Íjíbítì, pé: “Ẹ̀rí wà tó fi yẹ kéèyàn gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Mósè ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ìrìn àjò, àti pé ó ṣe àwọn iṣẹ́ míì táwọn akọ̀wé máa ń ṣe.”b
Bíbélì tún mẹ́nu kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì míì láyé ọjọ́un tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ akọ̀wé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Cambridge History of the Bible ṣe sọ, Mósè “yan àwọn tó mọ̀wéé kọ . . . pé kí wọ́n máa ṣàkọsílẹ̀ ìpinnu tí wọ́n bá ṣe àti bí nǹkan á ṣe máa lọ létòlétò láwùjọ.” Àwọn tó sọ èyí gbé àlàyé wọn ka Diutarónómì 1:15, níbi tí Mósè ti sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Nítorí náà, mo mú àwọn olórí ẹ̀yà yín . . . mo sì fi wọ́n ṣe olórí yín, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti olórí àràádọ́ta àti olórí ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá àti àwọn onípò àṣẹ nínú àwọn ẹ̀yà yín.” Àwọn wo ni àwọn olórí wọ̀nyí?
Ó tó ìgbà mélòó kan tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a pè ní “olórí” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí fara hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ nípa ìgbà ayé Mósè àti Jóṣúà. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí “akọ̀wé tó ń ṣàkọsílẹ̀,” “ẹni tó ń ‘kọ̀wé’ tàbí tó ń ‘ṣàkọsílẹ̀,’” àti “akọ̀wé adájọ́.” Bí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ṣe fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà fi hàn pé ọ̀pọ̀ akọ̀wé ló wà ní Ísírẹ́lì, ó sì fi hàn pé wọ́n ní ọ̀pọ̀ ojúṣe nínú ètò orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà yẹn.
Àpẹẹrẹ míì ni àwọn àlùfáà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé: “Nítorí ipa [táwọn àlùfáà] ń kó nínú ìjọsìn àtàwọn ètò mìíràn lórílẹ̀-èdè náà, ó di dandan kí wọ́n mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà.” Bí àpẹẹrẹ, Mósè pàṣẹ fáwọn ọmọ Léfì pé: “Ní òpin ọdún méje-méje, . . . ìwọ yóò ka òfin yìí ní iwájú gbogbo Ísírẹ́lì.” Bí àwọn àlùfáà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó ìwé Òfin tí Mósè kọ nìyẹn. Àwọn ni wọ́n ń fún àwọn tó bá fẹ́ ṣàdàkọ rẹ̀ láṣẹ láti ṣe é, àwọn nì wọ́n sì máa ń rí sí i pé àdàkọ náà ò yingin.—Diutarónómì 17:18, 19; 31:10, 11.
Ìwọ wo bí wọ́n ṣe ṣe àdàkọ àkọ́kọ́ nínú Òfin Mósè. Ní oṣù tí Mósè lò gbẹ̀yìn kó tó kú, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní ọjọ́ náà tí ẹ̀yin yóò bá sọdá Jọ́dánì sórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, kí o gbé àwọn òkúta ńláńlá nà ró fún ara rẹ, kí o sì fi ẹfun kùn wọ́n. Kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn.” (Diutarónómì 27:1-4) Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò àti Áì, wọ́n pé jọ lórí Òkè Ébálì, èyí tó wà ní àárín gbùngbùn Ilẹ̀ Ìlérí. Níbẹ̀, Jóṣúà kọ “ẹ̀dà òfin Mósè” sára àwọn òkúta pẹpẹ tí wọ́n mọ. (Jóṣúà 8:30-32) Kíyẹn tó lè ṣeé ṣe, àwọn tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà ní láti wà. Èyí fi hàn pé nígbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìmọ̀ tó tó láti máa ṣàdàkọ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tí kò yingin.
Ìwé Mímọ́ Ò Yingin
Lẹ́yìn ìgbà ayé Mósè àti Jóṣúà, àwọn míì tún fi èdè Hébérù kọ àwọn àkájọ ìwé mìíràn tó jẹ́ ti Bíbélì, àwọn akọ̀wé sì fọwọ́ ṣe àdàkọ wọn. Bí àwọn ohun tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí ṣe ń bu tí ọ̀rinrin sì ń bà wọ́n jẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ń di dandan pé kí wọ́n máa tún wọn dà kọ. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni wọ́n fi ṣe irú àdàkọ yìí.
Àwọn tó ń ṣàdàkọ Bíbélì fara balẹ̀ ṣe é kínní-kínní, síbẹ̀, àwọn àṣìṣe kan ṣèèṣì wọnú iṣẹ́ wọn. Àmọ́ ṣé àṣìṣe tí wọ́n ṣe wá yí ohun tó wà nínú Bíbélì padà? Rárá o. Nígbà táwọn ọ̀mọ̀wé fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì tó ti wà tipẹ́, wọ́n rí i pé àwọn àṣìṣe náà jẹ́ àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí kò yí ohun tí Bíbélì sọ padà.
Àwa Kristẹni gbà pé ojú tí Jésù Kristi fi wo àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ò yí padà. Àwọn ọ̀rọ̀ kan tó sọ fi hàn pé ó ka àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ tó wà nígbà ayé rẹ̀ sí èyí tó ṣeé gbára lé. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni, “Ṣé ẹ kò kà á nínú ìwé Mósè?” àti “Mósè fún yín ní Òfin, àbí kò fún yín?” (Máàkù 12:26; Jòhánù 7:19) Láfikún, Jésù fi hàn pé gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló péye nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.”—Lúùkù 24:44.
Nítorí náà, ó dá wa lójú pé wọ́n ṣe àdàkọ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó pé pérépéré láti ayé ìgbà láéláé wá. Ńṣe ló rí bí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí wòlíì Aísáyà láti sọ, pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jóṣúà tó gbé ayé ní ìdajì ẹgbẹ̀rún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, mẹ́nu kan ìlú àwọn ará Kénáánì kan tí wọ́n ń pè ní Kiriati-séférì, èyí tó túmọ̀ sí “Ìlú Ìwé” tàbí “Ìlú Àwọn Akọ̀wé.”—Jóṣúà 15:15, 16.
b A lè rí àwọn ohun tó jẹ mọ́ òfin, tí Mósè ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, nínú Ẹ́kísódù 24:4, 7; 34:27, 28; àti Diutarónómì 31:24-26. Bákan náà, Diutarónómì 31:22 sọ pé ó ṣàkọsílẹ̀ orin kan, àkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn nínú aginjù wà nínú Númérì 33:2.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Akọ̀wé ará Íjíbítì kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ìgbà ayé Mósè ni wọ́n ti kọ àwọn tó pẹ́ jù lọ lára àwọn ìwé inú Bíbélì