ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w11 10/1 ojú ìwé 7
  • 4 Ọlọ́run Kò Ṣe Ohun Tó Tọ́—Ṣé Òótọ́ Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 4 Ọlọ́run Kò Ṣe Ohun Tó Tọ́—Ṣé Òótọ́ Ni?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tó Yẹ Ká Ṣe Táwọn Èèyàn Bá Rẹ́ Wa Jẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
w11 10/1 ojú ìwé 7

4 Ọlọ́run Kò Ṣe Ohun Tó Tọ́​—Ṣé Òótọ́ Ni?

Ohun táwọn èèyàn ń sọ: “Ọlọ́run ló ni gbogbo ayé yìí, gbogbo ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ kò ṣẹ̀yìn rẹ̀. Nítorí náà, Ọlọ́run ló fà á bí ayé yìí ṣe kún fún ojúsàájú, àìṣẹ̀tọ́ àti ìpọ́njú.”

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: Ọlọ́run kọ́ ló fa àìṣẹ̀tọ́ tó wà láyé. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàpèjúwe Jèhófà, ó sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—Diutarónómì 32:4.

Ọlọ́run jẹ́ ọ̀làwọ́ sí gbogbo èèyàn, títí kan àwọn tí kò yẹ kó hùwà ọ̀làwọ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, “ó . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Ó máa ń ṣe ohun tó tọ́ fún gbogbo èèyàn lọ́gbọọgba láìka ìran àti ẹ̀yà tí wọ́n ti wá sí. Ìwé Ìṣe 10:34, 35 fi hàn pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”

Kí wá ló ń fa àìṣẹ̀tọ́? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ṣe nǹkan lọ́nà tí kò tọ́, wọ́n kì í tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́. (Diutarónómì 32:5) Bákan náà, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run fàyè gba ọ̀tá rẹ̀, ìyẹn Èṣù láti ṣàkóso ayé yìí.a (1 Jòhánù 5:19) Àmọ́, Ọlọ́run kò ní pẹ́ fòpin sí ìṣàkóso Èṣù yìí. Ó ti ṣètò ọ̀nà tó máa gbà “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”—1 Jòhánù 3:8.

Bí mímọ òtítọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Ìròyìn rẹpẹtẹ nípa ìwà ìbàjẹ́, ìpọ́njú àti àìṣẹ̀tọ́ tí à ń gbọ́ lè máa bà ọ́ nínú jẹ́. Mímọ̀ tó o mọ ohun tó ń fa ìṣòro náà máa jẹ́ kó o lóye ìdí tí ipò àwọn nǹkan fi burú tó bẹ́ẹ̀ àti ìdí tí ìsapá àwọn èèyàn láti sọ ayé di ibi rere fi máa ń já sí asán. (Sáàmù 146:3) Kàkà tí wàá fi máa lo àkókò àti okun rẹ dà nù sórí ìyípadà tí kò ní tọ́jọ́, gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Ọlọ́run, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá ní ìrètí tó dájú pé ọjọ́ ọ̀la máa dára.—Ìṣípayá 21:3, 4.

Mímọ̀ tá a mọ ibi tí àìṣẹ̀tọ́ ti wá lè ràn wá lọ́wọ́ pàápàá nígbà tí ìṣòro bá dé bá wa. Nígbà tí wọ́n bá ṣàìdáa sí wa, a lè kédàárò bí Hábákúkù ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe kédàárò, ó ní: “Òfin kú tipiri, ìdájọ́ òdodo kò sì jáde lọ rárá.” (Hábákúkù 1:4) Ọlọ́run kò bá Hábákúkù wí nítorí ohun tó sọ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run mú un dá a lójú pé òun ti dá àkókò kan tóun máa yanjú ọ̀ràn náà, ó sì ran Hábákúkù lọ́wọ́ láti ní ayọ̀ lákòókò wàhálà náà. (Hábákúkù 2:2-4; 3:17, 18) Bákan náà, tó o bá gba ìlérí Ọlọ́run gbọ́ pé yóò mú gbogbo àìṣẹ̀tọ́ kúrò, wàá ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ayé tí ó kún fún àìṣẹ̀tọ́ yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti mọ bí Èṣù ṣe di ẹni tó wà, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

Ṣé Ọlọ́run ló fa àìṣẹ̀tọ́ àti ìjìyà tó wà nínú ayé?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]

© Sven Torfinn/​Panos Pictures

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́