ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 12/1 ojú ìwé 14-15
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Yá Owó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Yá Owó?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ṢÉ Ó PỌN DANDAN KÉÈYÀN YÁWÓ?
  • ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TO LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́
  • Yíyá Àwọn Ọ̀rẹ́ Lówó àti Yíyáwó Lọ́wọ́ Wọn
    Jí!—1999
  • Yíyá Awọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ wa Lówó
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ó Ha Yẹ Kí N Yáwó Lọ́wọ́ Arákùnrin Mi Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Owó
    Jí!—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 12/1 ojú ìwé 14-15
A man borrowing money from someone

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Yá Owó?

Òwe àwọn ẹ̀yà Swahili kan sọ pé:​—“Béèyàn bá ń yáwó, ńṣe ló máa ń dà bí ẹni ń gbéyàwó, àmọ́ béèyàn bá fẹ́ san án pa dà, ńṣe ló máa ń dà bí ẹni ń ṣọ̀fọ̀.”

TÀWỌN ará Ìlà Oòrùn Áfíríkà mọ òwe yìí bí ẹni mowó, ó sì dájú pé gbogbo èèyàn kárí ayé ló gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Àmọ́ ṣé bí ọ̀rọ̀ owó yíyá ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn? Nígbà míì, nǹkan lè há gan-an fún wa, àmọ́ ṣé ó pọn dandan ká yáwó? Ewu wo ló wà nínú kéèyàn máa yáwó?

Òwe Yorùbá kan sọ ewu ńlá tó wà níbẹ̀, ó ní: “Owó ló ń bojú ọ̀rẹ́ jẹ́.” Òótọ́ sì ni ọ̀rọ̀ yẹn, torí pé àìmọye ọ̀rẹ́ ló ti tú ká nítorí ọ̀rọ̀ owó. Èèyàn lè yáwó kó sì ṣètò bó ṣe fẹ́ dá owó náà pa dà, àmọ́ nǹkan lè yíwọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ayáwó ò bá rí owó san pa dà fún ẹni tó yá a lowó ní àkókò tó dá, ẹni tó lowó lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú. Ọ̀rọ̀ náà lè le débi tí wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í yan ara wọn lódì, tó bá jẹ́ ẹbí ni wọ́n pàápàá, àárín wọn lè máà fi bẹ́ẹ̀ wọ̀ mọ́. Bá a ṣe wá mọ̀ pé yíyáwó lè fa irú ìṣòro báyìí, ó yẹ ká rò ó dáadáa ká tó yáwó, kódà bí nǹkan ò bá dójú ẹ̀ tán, kò yẹ ká kù gìrì lọ yáwó. Torí pé wàhálà tó máa dá sílẹ̀ lè le ju ìṣòrò owó náà lọ.

Ìyẹn nìkan kọ́, ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé yíyáwó tún lè bá àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́? Ọ̀nà kan tí ìyẹn fi lè rí bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Bíbélì sọ pé ẹni tó bá yá nǹkan, tí kì í sì í san án pa dà jẹ́ ẹni burúkú. (Sáàmù 37:21) Ó tún sọ pé “ayá-nǹkan ni ìránṣẹ́ awínni.” (Òwe 22:7) Ìyẹn ni pé bí ẹni tó yáwó ò bá tíì dá owó olówó pa dà, kò sí àrà tí olówó ò lè fi dá. Abájọ tí òwe ilẹ̀ Áfíríkà kan fi sọ pé: “Bí èèyàn bá yá ẹsẹ̀ ẹnì kan rìn, ó di dandan kó lọ sí ibikíbi tí ẹni tó ni ẹsẹ̀ bá darí rẹ̀ lọ.” Ohun tí ìyẹn ń sọ fún wa ni pé a kì í fi gbèsè sọ́rùn ṣọ̀ṣọ́, béèyàn bá jẹ gbèsè, àtiṣe bó ṣe wuni á di ìṣòro.

Torí náà, ńṣe ló yẹ kéèyàn máa wá bó ṣe máa tètè san gbèsè ọrùn rẹ̀. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, agbára wa lè máà ká wàhálà tí gbèsè náà á dá sílẹ̀. Ẹni bá jẹ gbèsè rẹpẹtẹ máa ń ní ìdààmú ọkàn, kì í sábà rí oorun sùn lálẹ́, á máa ṣiṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ tàbí kó tiẹ̀ máa kanra mọ́ ìyàwó rẹ̀, tí ò bá ṣọ́ra, ọ̀rọ̀ gbèsè náà lè fa ìpínyà tàbí kí ẹni to lowó tiẹ̀ wọ́ ọ lọ sí ilé ẹjọ́ tí ò bá rí owó san. Ṣẹ́ ẹ wá rí i pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú ìwé Róòmù 13:8 pé: “Ẹ má ṣe máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan, àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”

ṢÉ Ó PỌN DANDAN KÉÈYÀN YÁWÓ?

Gbogbo ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé ó yẹ ká rò ó jinlẹ̀ ká tó lọ yáwó. Ńṣe ló yẹ ká bi ara wa pé: Kí nìdí tí mo fi fẹ́ yáwó gan-⁠an? Ṣé mo fẹ́ fi owó yìí gbọ́ bùkátà ìdílé mi ni àbí mo kàn fẹ́ yá owó yìí láti ra ohun kan tó máa jẹ́ káwọn èèyàn gba tèmi? Lọ́pọ̀ ìgbà, bó o bá ro ọ̀rọ̀ náà jinlẹ̀ dáadáa, wàá rí i pé ó sàn kó o ṣe bó o ti mọ ju kó o yáwó lọ.

Àmọ́ ṣá o, bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, tó ò sì rí ibi yẹ ọ̀rọ̀ náà sí àfi kó o yáwó, má fìyẹn kẹ́wọ́ láti fọgbọ́n gbowó lọ́wọ́ àwọn èèyàn, hùwà ọmọlúwàbí nítorí ọjọ́ míì. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Lákọ̀ọ́kọ́, má ṣe máa rò pé àwọn tó lówó díẹ̀ lọ́wọ́ gbọ́dọ̀ máa fowó ta ẹ́ lọ́rẹ, kó o wá máa fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gbówó lọ́wọ́ wọn, rántí pé ìwọ kọ́ lo ṣiṣẹ́ owó sí wọn lápò. Bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá yá ẹ lówó, tó o sì jẹ owó náà mọ́lẹ̀, tó o wá rò pé kò sí nǹkan kan tó máa ṣẹlẹ̀, ńṣe lo fojú olóore rẹ gúngi, ìwà àìdáa sì nìyẹn. Má gbàgbé pé ìlànà Bíbélì kọ́ wa pé ká má ṣe ìlara àwọn tó lówó lọ́wọ́.​—Òwe 28:22.

O tún yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti mú àdéhùn rẹ ṣẹ, kó o sì dá owó náà pa dà lákòókò. Ohun tó tiẹ̀ ti dáa jù ni pé kí ìwọ àti ẹni tó o yáwó lọ́wọ́ rẹ̀ jọ ṣèwé. Ìwé yẹn ló máa jẹ́rìí sí àdéhùn yín kí àríyànjiyàn má bàa wáyé. (Jeremáyà 32:​9, 10) Bó bá ṣeé ṣe, ìwọ fúnra ẹ ni kó o dá owó tó o yá pa dà fún ẹni tó lowó, kó o lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ṣe tán, bá a bá dúpẹ́ oore àná, àá rí mí ì gbà. Jésù pàápàá mọyì kéèyàn mú àdéhùn ṣẹ torí ó sọ nínú Ìwàásù tó ṣe lórí Òkè pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Bákan náà, máa rántí Ìlànà Pàtàkì tó sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”​—Mátíù 7:12.

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ TO LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

Bíbélì sọ ìlànà kan tó lè jẹ́ kó o yẹra fún yíyá owó. Ìlànà yẹn sọ pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.” (1 Tímótì 6:6) Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé, ẹni bá ní ìtẹ́lọ́rùn kò ní kó sí wàhálà tí àwọn tó máa ń yáwó máa ń kó sí. Ṣùgbọ́n gbogbo wa la mọ̀ pé kò rọrùn láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínu ayé yìí torí pé ohun táwa èèyàn ń fẹ́ pọ̀ lọ jàra, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó máa ń ṣe wá bíi pé ojú ẹsẹ̀ ni ká ní wọn. Ibi tí “fífọkànsin Ọlọ́run” ti kan ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ nìyí. Lọ́nà wo?

Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ tọkọtaya kan ní Éṣíà yẹ̀ wò kí ọ̀rọ̀ náà lè yé wa dáadáa. Ó pẹ́ tí tọkọtaya yìí ti máa ń gbèrò láti nílé ara tiwọn, wọ́n sì ti ń tu owó jọ sí báńkì. Ṣùgbọ́n owó wọn ò pé, ni wọ́n bá yáwó kún un ní báńkì, kódà wọ́n tún yáwó lọ́wọ́ àwọn ẹbí wọn mí ì. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i rọ́ gbèsè san lóṣooṣù, ọrùn wọ̀ wọ́n. Wọ́n gba iṣẹ́ kún iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, èyí mú wọn jìnnà sílé tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ò fi ráyè fún àwọn ọmọ wọn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, baálé ilé náà sọ pé: “Ńṣe ló dà bíi pé a gbé àpáta rù tí ọrùn sì ń wọ̀ wá. Wàhálà, ìrora àti àìrí oorun sùn fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wa.”

“Ààbò ni àwọn ìlànà Bíbélì lórí nǹkan ìní jẹ́ fún wa”

Tọkọtaya yìí ronú lórí ohun tó wà nínú ìwé 1 Tímótì 6:​6, wọ́n sì pinnu pé káwọn ta ilé náà ni àwọn fi lé rí ojútùú sí ìṣòro àwọn. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ọdún méjì kọjá kí wọ́n tó bọ́ nínú gbèsè tí wọ́n tọrùn bọ̀. Wọ́n sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n ní: “Ààbò ni àwọn ìlànà Bíbélì lórí nǹkan ìní jẹ́ fún wa.”

Ṣàṣà lẹni tí kò gbà pé òótọ́ ni òwe àwọn ara Swahili tá a fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa, síbẹ̀ ìyẹn ò sọ pé kí wọ́n jáwọ́ nínú yíyáwó. Gbogbo ìlànà Bíbélì tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí ìbéèrè náà, Ǹjẹ́ ó yẹ kí n yá owó?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́