ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 4 ojú ìwé 4-7
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ ÒTÍTỌ́
  • Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ABỌ̀RÌṢÀ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í TÀN KÁLẸ̀
  • “ÒTÍTỌ́ YÓÒ SÌ DÁ YÍN SÍLẸ̀ LÓMÌNIRA”
  • Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àjíǹde Ti Lágbára Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìrètí Tí Ó Sàn Jù fún Ọkàn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ibo Làwọn Òkú Wà?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Ìgbàgbọ́ Àwọn Ènìyàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 4 ojú ìwé 4-7
Òkú tó wà nínú sàréè

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌYÈ ÀTI IKÚ?

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìyè àti Ikú

Tá a bá kà nípa bí lọ́run ṣe ṣẹ̀dá ayé nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, a máa rí i níbẹ̀ pé Ọlọ́run sọ fún Ádámù tó jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́ pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Gbólóhùn yẹn ṣe kedere, torí ó jẹ́ kí Ádámù mọ̀ pé tó bá pa òfin Ọlọ́run mọ́, kò ní kú, kàkà bẹ́ẹ̀ ó máa wà títí láé nínú ọgbà Édẹ́nì.

Ádámù àti Éfà tó ti darúgbó

Àmọ́, ó dunni pé dípò tí Ádámù ì bá fi yàn láti pa òfin Ọlọ́run mọ́ kó sì wà láàyè títí láé, ńṣe ló yàn láti rú òfin náà. Nígbà tí Éfà ìyàwó rẹ̀ fún un lára èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, ó gbà á, ó sì jẹ ẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) A ṣì ń jìyà ìwà àìgbọ́ràn yẹn títí dòní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà lọ́nà yìí: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Ádámù ni “ènìyàn kan” tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ. Àmọ́, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, kí sì nìdí tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fi yọrí sí ikú?

Ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù dá ni pé ó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ó sì rú òfin rẹ̀. (1 Jòhánù 3:4) Ọlọ́run sì ti sọ fún un tẹ́lẹ̀ pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà. Ká ní Ádámù àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ gbọ́ràn sí Ọlọ́run ni, wọn ò ní di ẹlẹ́ṣẹ̀, wọn ò sì ní kú rárá. Ọlọ́run kò dá èèyàn pé kó máa kú, kódà ńṣe ló fẹ́ ká wà láàyè títí láé.

Bí Bíbélì ṣe sọ, ikú ti tàn dé “ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn,” kò sì sẹ́ni tó lè jiyàn ẹ̀. Àmọ́, ṣé apá kan lára wa ṣì máa ń wà láàyè tí èèyàn bá kú? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Wọ́n gbà pé apá kan lára wa tí wọ́n ń pè ní ọkàn, kì í kú. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ohun tí à ń sọ ni pé Ọlọ́run parọ́ fún Ádámù. Kí nìdí? Tí apá kan lára wa bá lọ ń gbé ní ibòmíì lẹ́yìn téèyàn kú, á jẹ́ pé ikú kì í ṣe ìyà ẹ̀ṣẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe sọ nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Àmọ́ ká sòótọ́, Sátánì ló parọ́ fún Éfà nígbà tó sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:4.

Ìyẹn wá lè mú ká béèrè pé, Tó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ́ èké ni pé ọkàn èèyàn kì í kú, kí ló wá ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú?

BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ ÒTÍTỌ́

Ìtàn nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “alààyè ọkàn” ni ne’phesh, ó sì tún lè túmọ̀ sí “ẹ̀dá tó ń mí.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:7.

Bíbélì tipa báyìí mú kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò dá ọkàn tí kì í kú mọ́ wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni “alààyè ọkàn.” Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó o ti lè rí ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọkàn kì í kú.

Ní báyìí tá a ti rí i pé Bíbélì kò sọ pé èèyàn ní ọkàn táwọn kan sọ pé kì í kú, kí wá nídìí tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fi ń kọ́ni nírú ẹ̀kọ́ yìí? Láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, a máa ní láti ṣàgbéyẹ̀wò ìtàn ilẹ̀ Íjíbítì àtijọ́.

Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN ABỌ̀RÌṢÀ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í TÀN KÁLẸ̀

Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan tó ń jẹ́ Herodotus, tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ pé àwọn ará Íjíbítì “ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn pé ọkàn èèyàn kì í kú.” Àwọn ará Bábílónì ìgbàanì náà gbà pé ọkàn èèyàn kì í kú. Nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá fi máa ṣẹ́gun àwọn ará Ilà Oòrùn ayé lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Gíríìsì ti bẹ̀rẹ̀ sí tan ẹ̀kọ́ yìí kálẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi tàn jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwùjọ méjì tó ń ṣe ẹ̀sìn Júù, ìyẹn àwọn Essene àtàwọn Farisí, ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn pé tẹ́nì kan bá kú ọkàn rẹ̀ máa jáde lára rẹ̀, á sì lọ sí ibòmíì. Ìwé náà The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì làwọn Júù ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ọkàn èèyàn kì í kú, ní pàtàkì látinú ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí Plato.” Bákàn náà, Josephus tó jẹ́ òpìtàn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní kò sọ pé inú Ìwé Mímọ́ ni ẹ̀kọ́ yìí ti wá, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó sọ ni pé ó jẹ́ “ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì,” èyí tó gbà pé ó jẹ́ ìtàn àtẹnudẹ́nu lásán.

Bí àṣà àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ṣe túbọ̀ ń tàn kálẹ̀, àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni náà tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà yìí. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Jona Lendering, sọ pé: “Ohun tí Plato fi kọ́ni ni pé ìgbà kan wà tí ọkàn èèyàn wà nínú ìgbádùn, àmọ́ nígbà tó yá ó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, èrò yìí ló mú kó rọrùn fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì láti da ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni pọ̀ mọ́ ti Plato.” Torí náà, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wá fara mọ́ ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà tó sọ pé ọkàn èèyàn kì í kú, ó sì wá di ọ̀kan pàtàkì lára ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

“ÒTÍTỌ́ YÓÒ SÌ DÁ YÍN SÍLẸ̀ LÓMÌNIRA”

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Èmi ń tẹnu mọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tanni jẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1, Bíbélì Mímọ́ Ní Èdè Yorùbá Òde Òní.) Òótọ́ pọ́ńbélé mà lọ̀rọ̀ yìí o! “Ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù” gbáà ni pé ọkàn èèyàn kì í kú. Kò sí ní ibì kankan nínú Bíbélì, ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí láyé ìgbàanì ló ti wá.

Ó dùn mọ́ wa pé, Jésù ní: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Tá a bá ní ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì lọ́nà tó péye, a máa di òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀kọ́ tó ń tàbùkù sí Ọlọ́run àtàwọn àṣà tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn nínú ayé ń gbé lárugẹ. Láfikún sí i, òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti tú wa sílẹ̀ nínú àjàgà àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti ìgbàgbọ́ òdì nípa ipò tí àwọn òkú wà.—Wo àpótí náà “Ibo Làwọn Òkú Wà?”

Ẹlẹ́dàá wa kò dá àwa èèyàn pé ká kàn lo àádọ́rin [70] sí ọgọ́rin [80] ọdún láyé, ká wá papòdà lọ sí ilẹ̀ àwọn ẹ̀mí àìrí, ká sì wà níbẹ̀ títí gbére. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé kí àwa èèyàn tá a jẹ́ ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ká sì máa ṣègbọràn sí i. Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, kò sì sí oun tó lè yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà. (Málákì 3:6) Ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ìyè àti ikú, ka orí 6 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì wa www.jw.org/yo, tàbí kó o lo ìlujá yìí.

Kò sí ibì kankan nínú Bíbélì tó o ti lè rí ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé ọkàn kì í kú

Ṣé Èèyàn Lè Wà Láàyè Títí Láé?

Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn olùṣèwádìí ṣàwárí ewéko kan tó ń hù lábẹ́ omi. Wọ́n gbà pé ewéko náà ti lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé òun ni ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ nínú gbogbo ẹ̀dá aláàyè tó wà láyé. Ewéko náà wà lára àwọn ewéko kan tí wọ́n ń pè ní Posidonia oceanica, ìyẹn irú àwọn ewéko kan tó máa ń hù nísàlẹ̀ òkun. Ewéko yìí ló bo apá tó pọ̀ jù lọ lábẹ́ òkun Mẹditaréníà tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Sípéènì àti Cyprus.

Tí ewéko bá lè pẹ́ tó báyìí láyé, àwa èèyàn wá ńkọ́? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe ń darúgbó gbà pé ó ṣeé ṣe kí ẹ̀mí àwa èèyàn túbọ̀ máa gùn sí i. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣe ìwé kan tó dá lórí kókó yìí tó sọ̀rọ̀ nípa “onírúurú nǹkan táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣàwárí rẹ̀” kí ẹ̀mí àwọn èèyàn lè túbọ̀ máa gùn. Àmọ́, a ò tíì rí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwárí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe máa mú kí ẹ̀mí àwa èèyàn túbọ̀ gùn sí i.

Ohun kan tó dájú ni pé kì í ṣe àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló máa mú kí àwa èèyàn ní ìyè tí kò lópin. Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá nìkan ló lè ṣé e, ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Jésù Kristi gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ká sòótọ́, tá a bá sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀ fẹ́, wọ́n máa fi ìyè àìnípẹ̀kun san wá lẹ́san.

Ewéko òkun

Àwọn olùṣèwádìí gbà pé irú àwọn ewéko abẹ́ òkun yìí ti lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láyé

IBO LÀWỌN ÒKÚ WÀ?

Jésù jí Lásárù dìde

Ní kúkúrú, ohun tí Bíbélì sọ ni pé àwọn òkú wà nínú sàréè, wọ́n ń retí ọjọ́ àjíǹde. (Jòhánù 5:28, 29) Wọn ò jìyà, wọn ò sì jẹ ìrora kankan, torí pé “wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, ó sọ pé ńṣe ni ikú dà bí ìgbà téèyàn sùn wọra. (Jòhánù 11:11-14) Fún ìdí yìí, kò yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn tó sùn nínú oorun ikú tàbí ká máa rúbọ sí wọn ká lè fi tù wọ́n lójú. Wọn ò lè ràn wá lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè pa wá lára, torí pé “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [Sàréè].” (Oníwàásù 9:10) Àmọ́, Ọlọ́run máa lo àjíǹde láti mú ikú kúrò pátápátá, kò sì ní sí mọ́ títí láé.—1 Kọ́ríńtì 15:26, 55; Ìṣípayá 21:4.

Ìdí Tó O Fi Lè Gba Ohun Tí Bíbélì Sọ Gbọ́

Gbogbo ohun tí Bíbélì sọ pátá ló yẹ ká gbà gbọ́. Kí nìdí? Ronú lórí àwọn ohun tá a fẹ́ jíròrò yìí:

  • Ohun ìkọ̀wé àti yíǹkì

    Ẹni Tó Ṣe É: Ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló wà nínú Bíbélì, àwọn ogójì [40] èèyàn ló sì kọ ọ́. Ó gbà wọ́n ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ọdún kí wọ́n tó parí rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Kristẹni. Síbẹ̀, gbogbo ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bára mu látòkè-délẹ̀, ó sì ṣe kedere. Èyí fi hàn pé Ọlọ́run Olódùmarè ló ṣe Bíbélì. Ńṣe ló fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn èèyàn tó lò láti kọ Bíbélì.

  • Ọwọ̀n

    Òótọ́ Làwọn Ìtàn Inú Rẹ̀: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lóòótọ́ ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀. Ìwé kan tó ń jẹ́ A Lawyer Examines the Bible sọ pé: “Nínú ìtàn àròsọ, wọn kì í sọ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé àti àkókò tó wáyé, . . . àmọ́ tí Bíbélì bá sọ ìtàn kan, ó máa ń sọ àkókò tó ṣẹlẹ̀ àti ibi tó ti ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí tó sì péye.”

  • Átọ́ọ̀mù

    Ó Bá Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mu: Bíbélì kì í ṣe ìwé sáyẹ́ǹsì, ṣùgbọ́n tó bá sọ ohun tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, ó máa ń ṣe déédéé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sì máa kọjá káwọn èèyàn tó rí i pé òótọ́ ni Bíbélì sọ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Léfítíkù orí 13 àti 14 sọ òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìmọ́tótó àti bí wọ́n á ṣe fi ẹni tó bá ní àrùn tó lè ranni sọ́tọ̀. Àwọn èèyàn ò sì tíì mọ̀ nípa kòkòrò àrùn tó lè ran àwọn míì rárá nígbà yẹn. Bíbélì tún sọ pé roboto ni ayé àti pé kò sí ohun tó gbé e dúró, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sì kọjá káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọ̀ pé bó ṣe rí nìyẹn lóòótọ́.—Jóòbù 26:7; Aísáyà 40:22.

Àpẹẹrẹ díẹ̀ léyìí jẹ́ lára àwọn ẹ̀rí tó ti ohun tí Bíbélì sọ lẹ́yìn pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́