ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 4 ojú ìwé 16
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí àníyàn rẹ?
  • Ṣé àníyàn máa dópin?
  • Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Kó Gbogbo Àníyàn Rẹ lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Àníyàn
    Jí!—2016
  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkùnrin Tó Ń Ṣàníyàn Lọ́wọ́?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 4 ojú ìwé 16
Ìdílé kan nínú Párádísè

Nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn máa “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ṣé Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí àníyàn rẹ?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́

  • Kò dá mi lójú

Ohun tí Bíbélì sọ

“Kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:7) Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Tá a bá ń gbàdúrà, a lè ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tó máa mú kí àníyàn wa fúyẹ́.—Fílípì 4:6, 7.

  • Láfikún sí i, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè mú ká fara da ìdààmú ọkàn.—Mátíù 11:28-30.

Ṣé àníyàn máa dópin?

Èrò àwọn kan ni pé. . . kò sí báwa èèyàn kò ṣe ní ṣàníyàn tàbí dààmú, àwọn míì sì gbà pé ó di ayé àtúnwá ká tó lè bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣe àníyàn. Kí lèrò rẹ?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run máa mú ohun tó ń fa àníyàn kúrò. “Ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

Kí làwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ?

  • Tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, àwọn èèyàn á máa gbé ayé ní àlàáfíà, láìsí ìyọlẹ́nu kankan.—Aísáyà 32:18.

  • Kò ní sídìí fún wọn láti máa ṣàníyàn tàbí dààmú.—Aísáyà 65:17.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é

Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́