ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 5 ojú ìwé 3
  • Ṣé Àwọn Áńgẹ́lì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àwọn Áńgẹ́lì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Fara Wé Àwọn Áńgẹ́lì Olóòótọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 5 ojú ìwé 3
Tọkọtaya kan ń fi Bíbélì tu obìnrin kan nínú

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ?

Ṣé Àwọn Áńgẹ́lì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?

Lọ́sàn-án ọjọ́ Sunday kan, Kenneth àti Filomena, tí wọ́n ń gbé ní ìlú Curaçao lọ sọ́dọ̀ tọkọtaya kan tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kenneth sọ pé: “Nígbà tá a débẹ̀, ilẹ̀kùn wà ní títìpa, a ò sì bá mọ́tò wọn níta. Àmọ́, ọkàn mi ṣáà ní kí n pe fóònù ìyàwó.”

Obìnrin náà dáhùn, ó sì sọ pé ọkọ òun ti lọ síbi iṣẹ́. Àmọ́, nígbà tó mọ̀ pé Kenneth àti Filomena wà níwájú ilé àwọn, ó wá ṣílẹ̀kùn, ó sì ní kí wọ́n wọlé.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ti rí i pé obìnrin náà ti sunkún. Bí Kenneth ṣe ń gbàdúrà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, ńṣe lobìnrin náà tún bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Kenneth àti Filomena wá fẹ̀sọ̀ béèrè ohun tó ń pa á lẹ́kún.

Obìnrin náà ṣàlàyé pé òun ti pinnu láti pa ara òun àti pé lẹ́tà ìdágbére lòun ń kọ lọ́wọ́ sí ọkọ òun tí ìpè Kenneth fi wọlé tí òun sì dáwọ́ dúró. Ó ṣàlàyé fún wọn pé òun ní ìdààmú ọkàn, torí náà wọ́n fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tù ú nínú. Ọ̀rọ̀ ìtùnú yẹn ni kò jẹ́ kó pa ara rẹ̀.

Kenneth sọ pé: “A dúpẹ́ pé Jèhófà lò wá láti ṣèrànwọ́ fún obìnrin tó ní ìdààmú ọkàn yìí. A ò lè sọ bóyá áńgẹ́lì ni Jèhófà lò tàbí ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀, tó fi sún wa láti pe fóònù obìnrin náà!”a

Ṣé ó tọ̀nà bí Kenneth àti Filomena ṣe ronú pé Ọlọ́run ló dá sì ọ̀rọ̀ náà, bóyá nípasẹ̀ áńgẹ́lì tàbí ẹ̀mí mímọ́ Rẹ̀? Ṣé bí Kenneth ṣe pe obìnrin náà kàn bọ́ sásìkò ni?

A ò lè sọ. Àmọ́ ohun tó dájú ni pé Ọlọ́run máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti mú káwọn èèyàn sún mọ́ ọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí òṣìṣẹ́ ọba kan tó jẹ́ ọmọ ìlú Etiópíà ń wá ìtọ́sọ́nà nípa bó ṣe máa sún mọ́ Ọlọ́run, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti darí Fílípì ajíhìnrere sọ́dọ̀ rẹ̀.​—Ìṣe 8:​26-31.

Ọ̀pọ̀ ìsìn ló gbà pé àwọn ẹ̀dá kan wà tó lágbára ju àwa èèyàn lọ, wọ́n sì gbà pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run làwọn kan lára wọn tàbí pé wọ́n máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà àti pé wọ́n máa ń ran àwọn lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn míì kò gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà rárá.

Ṣé àwọn áńgẹ́lì wà lóòótọ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ibo ni wọ́n ti wá? Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì? Ṣé wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀rí mélòó kan yẹ̀wò.

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́