ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w17 June ojú ìwé 32
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
w17 June ojú ìwé 32
Jésù lé àwọn oníṣòwò tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì síta

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé lóòótọ́ la lè pe àwọn oníṣòwò tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ní “ọlọ́ṣà”?

ÌWÉ Ìhìn Rere Mátíù sọ pé, “Jésù sì wọ inú tẹ́ńpìlì, ó sì lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà. Ó sì wí fún wọn pé: ‘A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, “Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà,” ṣùgbọ́n ẹ ń sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.’”​—Mát. 21:12, 13.

Ìwé ìtàn àwọn Júù kan fi hàn pé lóòótọ́ làwọn tó ń ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì máa ń bu owó gegere sórí àwọn ọjà wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìtàn àwọn Júù kan sọ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, wọ́n ń ta ẹyẹlé méjì ní owó dínárì wúrà kan. Ìyẹn sì jẹ́ owó tí lébìrà kan máa gbà fún iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. Òfin Mósè sọ pé àwọn tálákà lè fi ẹyẹlé tàbí àdàbà rúbọ, síbẹ̀ owó gegere tí apá mẹ̀kúnnù ò lè ká ni wọ́n ń ta àwọn ẹyẹ náà. (Léf. 1:14; 5:7; 12:6-8) Inú bí Rábì kan tó ń jẹ́ Simeon ben Gamaliel sí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, torí náà ó mú kí iye ìrúbọ tó yẹ káwọn èèyàn náà máa rú dín kù. Èyí wá mú kí iye tí wọ́n ń ta ẹyẹlé méjì já wálẹ̀ gan-an.

Àwọn nǹkan yìí jẹ́ ká rí i pé bí Jésù ṣe pe àwọn oníṣòwò inú tẹ́ńpìlì ní “ọlọ́ṣà” bá a mu lóòótọ́ torí pé olójúkòkòrò ni wọ́n, wọ́n sì máa ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́