Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọrun
Cuba: Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìjọba Cuba yọ̀ọ̀da fún aṣojú Society láti ṣèbẹ̀wò sí Cuba gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìpínlẹ̀ ńlá. Ó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn alábòójútó àyíká àti àgbègbè. Nísinsìnyí, àwọn ará lè pé jọ tó 150 nínú àwùjọ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n mọrírì pé àwọn ń gbádùn òmìnira tí ó túbọ̀ pọ̀ sí i nísinsìnyí àti pé a tún lè lo Ilé Beteli lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí ibùdó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Cuba.