ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/95 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 2
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 30
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 10/95 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October

ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan lákòókò àpéjọpọ̀. Àwọn ìjọ lè ṣàtúnṣe tí ó yẹ láti yọ̀ọ̀da fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn,” àti fún àtúnyẹ̀wò àwọn kókó inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún 30 ìṣẹ́jú ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. A ní láti yan àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọpọ̀ àgbègbè náà fún àwọn arákùnrin títóótun méjì tàbí mẹ́ta, tí yóò lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn kókó pàtàkì jù lọ, ṣáájú àkókò. Àtúnyẹ̀wò tí a múra sílẹ̀ dáradára yìí, yóò ran ìjọ lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì tí wọn yóò lè fi sílò, tí wọn yóò sí lè lò nínú pápá. Àwọn àlàyé láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àti àwọn ìrírí tí a sọ ní láti ṣe ṣókí, kí ó sì sọ ojú abẹ níkòó.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 2

Orin 149

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Pe àkànṣe àfiyèsí sórí ìfilọ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Jí! November 8, bí ó bá bá ìpínlẹ̀ yín mu.

10 min: “Jíjẹ́ Ẹni Tí Jehofa Ń Yẹ̀ Wò—Èé Ṣe Tí Ó Fi Ṣàǹfààní?” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ń gbéni ró, láti ẹnu alàgbà kan.

15 min: “Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ ìfisílò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí àti àwọn tí a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ.

15 min: “Fi Ìwé Ìròyìn Lọni ní Gbogbo Ìgbà.” Jíròrò àwọn kókó inú rẹ̀, lẹ́yìn náà, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí a lè lò ní fífi àwọn ìtẹ̀jáde tí ó dé kẹ́yìn lọni. Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta.

Orin 153 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 9

Orin 131

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn’ ti 1995.” Kí a kárí ìpínrọ̀ 1 sí 15 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

15 min: “A Ha Ń Wà Lójúfò—Ní Yíyẹra fún Ìpínyà Ọkàn Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà ti May 1, 1992, ojú ìwé 20 sí 22, kún un, bí àkókò bá ti yọ̀ọ̀da tó.

Orin 128 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 16

Orin 120

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Pe àfiyèsí sórí ìwé pélébé náà, Good News for All Nations, tí ó pèsè ìgbékalẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà ní èdè 59 tí ó yàtọ̀ síra. Fún àwùjọ níṣìírí láti lo ìwé pélébé yìí nígbà tí wọ́n bá bá àwọn tí ń sọ èdè mìíràn pàdé ní ìpínlẹ̀ wọn.

20 min: “Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ‘Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn’ ti 1995.” Kí a kárí ìpínrọ̀ 16 sí 28 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò “Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè.”

15 min: “Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò Pẹ̀lú Ète.” Jíròrò àwọn ète tí a ní fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò. Ṣètò kí àwọn akéde tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn oríṣi ìgbékalẹ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Jẹ́ kí akéde kan ṣàlàyé bí ọrẹ tí a ń gbà lórí àwọn ìwé wa kò ṣe kájú iye owó rẹ̀.

Orin 130 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 23

Orin 100

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọrun.

15 min: “A Nílò Ìjọ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.

20 min: Darí Ìfẹ́ Sínú Ètò Àjọ. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn darí ìjíròrò pẹ̀lú akéde méjì tàbí mẹ́ta, ní lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, Awọn Ẹlẹrii Jehofah—Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé. Ṣàlàyé ìdí tí ó fi ṣàǹfààní láti jẹ́ kí àwọn olùfìfẹ́hàn mọ bí a ti ń darí ètò àjọ náà, bí a ti ń ṣètò onírúurú ìgbòkègbodò, àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ apá kan rẹ̀. Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó tí ó wà ní ojú ìwé 14 sí 15 lórí “Awọn Ipade fun Ìrunilọ́kànsókè si Ifẹ ati Awọn Iṣẹ Rere.” Àwọn akéde náà ṣàṣefihàn kúkúrú lórí bí a ṣe lè fi àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ yìí kún ìjíròrò wa nígbà ìpadàbẹ̀wò tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, láti ran olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ láti mọrírì ìdí fún lílọ sí ìpàdé.

Orin 126 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 30

Orin 159

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Pẹ̀lú àwọn ọlidé ayé tí ń bọ̀ ní December àti January, fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti gbé fíforúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà yẹ̀ wò.

15 min: O Ha Ti Gbìyànjú Ìtọ́ka Rí Bí? Ọ̀rọ̀ àsọyé. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn akéde kan láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tuntun ní ọ̀nà yìí: Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú olùfìfẹ́hàn kan fún ìgbà díẹ̀, wọ́n béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bí ó bá mọ ẹnì kan lára àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí, tàbí ojúlùmọ̀ rẹ̀ tí ó lè nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fúnni ní orúkọ àwọn bíi mélòó kan. Béèrè pé bóyá o lè dárúkọ rẹ̀ nígbà tí o bá ń ké sí wọn. Nígbà tí o bá ń ṣe ìkésíni náà, o lè sọ pé: “Ẹni báyìí-báyìí ti gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli gan-an débi pé, ó ronú pé ìwọ pẹ̀lú yóò fẹ́ láti jàǹfààní láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ọ̀fẹ́ tí a máa ń ṣe.” Èyí lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ìpadàbẹ̀wò tí ó dára, tí ó lè yọrí sí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ń méso jáde. Fi ìrírí kan tàbí méjì láti ọ̀dọ̀ àwọn akéde tí ó ti rí àwọn olùfìfẹ́hàn tàbí bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun ní ọ̀nà yìí kún un.

20 min: Fífi Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Lọni ní November. Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀ka Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki. Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí: Orí kí ni a gbé ìtumọ̀ yìí kà? Àwọn wo ní ó túmọ̀ rẹ̀? Ṣé lóòótọ́ ni ó jẹ́ ìtumọ̀ tí ó ta yọ lọ́lá? Èé ṣe tí a fi lo orúkọ náà, Jehofa? Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé ìdí tí ó fi yẹ kí a kún fún ọpẹ́ fún níní ìtumọ̀ yìí. Jẹ́ kí akéde kan tí ó dáńgájíá ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kúkúrú. Rán gbogbo àwùjọ létí láti gba àwọn ẹ̀dà tí wọn yóò lò nínú iṣẹ́ ìsìn ní ọ̀sẹ̀ yìí.

Orin 138 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́