ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/95 ojú ìwé 3-6
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ti 1996
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 10/95 ojú ìwé 3-6

Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995

1 Ìdí mélòó ni a ní fún jíjẹ́ onídùnnú? Bóyá díẹ̀ nínú wa ti gbìyànjú láti to gbogbo wọn lẹ́sẹẹsẹ. A ní ìdí púpọ̀ jaburata láti dunnú, láìka gbígbé tí a ń gbé nínú ayé onírúkèrúdò àti aláìdánilójú sí. Gẹ́gẹ́ bí a ti fi lọ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1995, “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ afúnniníṣìírí fún àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè 1995.

2 A ń yin Jehofa nítorí pé ó kọ́ wa ní òtítọ́. (Isa. 54:13; Joh. 8:32) Tẹ̀ lé èyí, a ń fi ìdùnnú ṣàjọpín òtítọ́ náà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ń wá ààbò àti ayọ̀ kiri. (Esek. 9:4; Ìṣe. 20:35) Ẹgbẹ́ ará Kristian wa náà ń mú wa dunnú. Ìdílé tẹ̀mí onífẹ̀ẹ́ ń mú ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ wá. Ìwọ̀nyí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ nínú àwọn ìdí fún ìdùnnú wa, tí ó sì ń sún wa láti yin Jehofa. Àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé àti àṣefihàn tí a óò ṣe ní àpéjọpọ̀ náà yóò pe àfiyèsí wa sí àwọn àfikún ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìdùnnú ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn onídààmú wọ̀nyí.

3 Àpéjọpọ̀ Ọlọ́jọ́ Mẹ́ta: Ìwọ́ ha ti ṣètò pẹ̀lú agbanisíṣẹ́ rẹ láti gba ìsinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́, kí ó ba lè ṣeé ṣe fún ọ láti wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ náà? Àwọn òbí àwọn ọmọ tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, tí wọn yóò lọ sí ọ̀kan nínú àpéjọpọ̀ náà nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ ṣì ń lọ lọ́wọ́, ní láti fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún àwọn olùkọ́ pé àwọn ọmọ wọn kì yóò wá sí ilé ẹ̀kọ́ ní ọjọ́ Friday, nítorí apá pàtàkì ìjọsìn wọn yìí. Àpéjọpọ̀ wo ni ó sún mọ́ ọ jù lọ? Nísinsìnyí, akọ̀wé ìjọ yín yóò ti fi kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó kan ìjọ yín tó yín létí. Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè Ọta 6, a óò túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití.

4 Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní 9:20 òwúrọ̀ Friday, yóò sì parí ní nǹkan bíi 3:30 ìrọ̀lẹ́ Sunday. Ní Saturday àti Sunday, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní 9:00 òwúrọ̀.

5 Ìwọ Yóò Ha Wà Níbẹ̀ Bí?: A rọ̀ wá láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ náà. Èé ṣe? Jehofa fẹ́ kí a wà níbẹ̀. Lónìí, ìgbàgbọ́ àti ìlera wa tẹ̀mí wà lábẹ́ ìkọlù líle koko. Ní àkókò kan, nígbà tí àwọn Kristian ní Judea ń fojú winá ìkìmọ́lẹ̀ gíga, Paulu gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.” (Heb. 3:12, 13; 10:25) Àwọn ará Filippi ń gbé “ní àárín ìran oníwà wíwọ́ ati onímàgòmágó.” Síbẹ̀, wọ́n “ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ ninu ayé.” (Filip. 2:15) Èé ṣe tí àwọn Kristian ọ̀rúndún kìíní wọ̀nyí fi yàtọ̀? Nítorí wọ́n ń fi ìgbọràn tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́, tí ó pàṣẹ fún wọn láti pàdé pọ̀ ‘lati ru ara wọn lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà.’—Heb. 10:24.

6 Ayé yóò sún wa láti gbégbèésẹ̀ tí ó yàtọ̀ sí èyí, ní sísọ ìfẹ́ ọkàn wa láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa, kí á sì yin Jehofa di akúrẹtẹ̀. Ní ọdún yìí, a ké sí wa láti juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀mí Jehofa, kí á sì gbádùn ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ náà. A ha ti pinnu láti wà níbẹ̀ pẹ̀lú ìdílé wa lódindi bí? A ní láti fún ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ wa lókun déédéé. Jehofa ti pèsè àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí.

7 Mú Ìṣúra Lọ Sí Ilé: Báwo ni o ṣe lè jàǹfààní púpọ̀ jù lọ láti inú àpéjọpọ̀ náà? Ní ṣókí, ó jẹ́ nípa “pípa ọkàn pọ̀.” Èyí kò rọrùn rárá, nínú àwùjọ oníwàǹwára àti onípàképàké ti òde òní. Ó lè ṣòro fún àwọn ọ̀dọ́ abarapá láti pọkàn pọ̀, ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ìpèníjà tí gbogbo wa máa ń dojú kọ nígbà tí a bá pésẹ̀ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè. Bí a bá wéwèé ṣáájú, yóò rọrùn fún wa láti pọkàn pọ̀. Béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ náà?’ Ronú jinlẹ̀ lórí rẹ̀! ‘Èé ṣe tí mo fi ń lọ, kí ni n óò sì máa ṣe láàárín ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà? Ṣé eré ìnàjú ni n óò fi gbogbo ìrọ̀lẹ́ ṣe, tàbí mo ha ti ṣètò àkókò tí ó pọ̀ tó láti sinmi, kí n sì ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì àpéjọpọ̀ náà?’

8 Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà August 1, 1984, tí ó sọ pé, “O Ha Nṣe Aṣaro Ni Tabi O Wulẹ Nlálàá Ọsan Gangan?” fúnni ní àwọn àbá mélòó kan lórí bí a ṣe lè jàǹfààní púpọ̀ jù lọ láti inú ìpàdé, ó sì parí ọ̀rọ̀ báyìí: “Boya ikora-ẹni-nijanu ti iye-inu ni o jẹ koko pataki julọ.” Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ kan bá bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀, a sábà máa ń tẹ́tí sílẹ̀, ṣùgbọ́n bóyá, bí ó ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, a jẹ́ kí ọkàn wa “ṣako lọ.” Báwo ni a ṣe lè yẹra fún èyí?

9 Àwọn àbá tí a fúnni ní ìgbà tí ó ti kọjá yẹ fún àtúnsọ, nítorí pé wọ́n gbéṣẹ́. Bí ó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti sùn dáradára ní alaalẹ́. Èyí kì í fi ìgbà gbogbo rọrùn, nítorí ó lè ní rírin ìrìn àjò nínú, bí o bá sì wọ̀ sí ilé kan nítòsí àpéjọpọ̀ náà, o lè má tètè sùn tàbí sinmi bí o ti máa ń ṣe ní ilé. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwéwèé tí ó dára ń mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti sinmi bí ara ṣe ń fẹ́.

10 Ẹ̀rí fi hàn pé ṣíṣe àkọsílẹ̀ ní ìwọ̀nba ń ranni lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀. Bí o bá gbìyànjú láti kọ ìsọfúnni púpọ̀ jù sílẹ̀, o lè pàdánù àwọn kókó pàtàkì kan pátápátá. Gẹ́gẹ́ bí àbá, ṣàkọsílẹ̀ kan pẹ̀lú ète sísọ àkópọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan tàbí aláìsàn kan tí ó wà ní ilé ìwòsàn. Bí o kò tilẹ̀ ní ẹnì kan pàtó lọ́kàn, ìwọ yóò ní ète fún ṣíṣe àkọsílẹ̀, lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, o lè rí àwọn àkókò tí ó yẹ láti sọ àwọn kókó pàtàkì ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́. Nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ àti ṣíṣàjọpín ohun tí o gbọ́, ìwọ kì yóò tètè gbàgbé àwọn ìsọfúnni náà. Sísọ ohun kan jáde túbọ̀ ń mú kí á rántí rẹ̀.

11 Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn Ń Bu Ọlá fún Jehofa Nípa Ìṣe Oníwà-bí-Ọlọrun: Ní èṣí, a rí àwọn ọ̀rọ̀ oníṣìírí, dáradára gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn onílé àti àwọn ẹlòmíràn. Onílé kan sọ pé: “Ó máa ń dùn mọ́ mi nínú nígbà gbogbo láti gba àwọn Ẹlẹ́rìí sílé, nítorí pé wọ́n ní sùúrù, wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n sì máa ń bójú tó àwọn ọmọ wọn dáradára.” Onílé mìíràn sọ pé, ó dà bíi pé àwọn Ẹlẹ́rìí túbọ̀ jẹ́ aláyọ̀, wọ́n sì wà létòlétò ju àwọn àwùjọ mìíràn lọ.

12 Ìròyìn mìíràn sọ pé, àpéjọpọ̀ kan tí a ṣe ṣáájú tiwa, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, yọrí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbàjẹ́, títí kan olè jíjà. Ṣùgbọ́n, ní ti àpéjọpọ̀ wa, ìròyìn náà ń báa lọ pe: “A kò ní láti dààmú nípa ìyẹn ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”

13 A dàníyàn pé kí gbogbo ìròyìn tí a rí gbà rí bákan náà, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, kò rí bẹ́ẹ̀. Alága àpéjọpọ̀ kan ṣàkíyèsí pé: “Lẹ́yìn ìpàdé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ langba kóra wọn jọ sínú gbàgede [ilé ìtura] ní ọ̀gànjọ́ òru, wọ́n ń rẹ́rìn ín kèékèé, wọ́n sì ń pariwo gèè. Èyí dí àwọn àlejò mìíràn lọ́wọ́ . . . , ó sì dà bíi pé inú bí wọn. Àwọn ọ̀dọ́ kan ń sá káàkiri ọ̀dẹ̀dẹ̀, wọ́n ń ti ilẹ̀kùn gbàà-gbàà bí wọ́n ti ń ṣe ìbẹ̀wò sí iyàrá ara wọn, tí wọ́n sì ń pariwo sọ̀rọ̀ nínú àwọn iyàrá.”

14 Ìṣòro mìíràn tí ń báa lọ láìdabọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ará tí ń ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀yìn òde ilẹ̀ àpéjọpọ̀ nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Ní àpéjọpọ̀ kan ní ọdún tí ó kọjá, a rí ìwé kékeré kan, tí akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan kọ, nínú àpótí ọrẹ. Ó kà báyìí pé: “N kò tí ì gbọ̀n rìrì, kí ẹnu sì yà mí tó báyìí rí, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe, ní rírí ariwo, ìgbòkègbodò, àti ọ̀rọ̀ sísọ . . . tí ń lọ lọ́wọ́ nígbà tí a ń sọ àsọyé . . . Èmi kò tí ì di Ẹlẹ́rìí, mo wulẹ̀ jẹ́ ẹnì tí ń kẹ́kọ̀ọ́, tí ó sì ń kọ́ ìbẹ̀rù àti ọ̀wọ̀ fún Ọlọrun.” Dájúdájú, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò fẹ́ kí àwọn ènìyàn lérò pé a kò ní ìmọrírì fún àwọn ìpèsè Jehofa.

15 Ó yẹ kí á máa bi ara wa léèrè nígbà gbogbo pe: ‘Ta ni mo ń ṣojú fún, kí sì ni ìdí tí mo fi wà ní àpéjọpọ̀ yìí?’ Ìsọ̀rọ̀ wa, ìwà wa, àti ìmọrírì wa fún àwọn ìpèsè tẹ̀mí, ń fi ipò tẹ̀mí, àti ìfọkànsìn wa fún Ọlọrun hàn. (Jak. 3:13; 1 Pet. 2:2, 3, 12) A sábà máa ń kíyè sí i pé àwọn ará tí ó ti fara da ìkálọ́wọ́kò àti ìfòfindè fún ọ̀pọ̀ ọdún, máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáradára ju àwọn yòókù lọ, wọ́n sì máa ń fi ọ̀wọ̀ hàn ní àwọn àpéjọpọ̀, ní wíwà lórí ìjókòó wọn, ní fífara fún àwọn àsọyé àti àwọn àṣefihàn náà pátápátá.

16 Ìwọṣọ àti Ìmúra Rẹ Ń Sọ Púpọ̀ Nípa Rẹ: A rán wa létí ní 1 Samueli 16:7 pé, “ènìyàn a máa wo ojú, Oluwa a máa wo ọkàn.” Nípa báyìí, àwọn ènìyàn sábà máa ń fi ìrísí wa pinnu irú ẹni ti a jẹ́. Ìwọṣọ àti ìmúra wa ń wá sábẹ́ àyẹ̀wò kínníkínní, pàápàá nígbà tí a bá ń lọ sí àpéjọpọ̀ kan fún ìjọsìn àti ìtọ́ni nípa ìgbésí ayé Kristian. Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́ kan tí ń lọ ilé ẹ̀kọ́ tàbí bí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ bá mú ọ sún mọ́ àwọn ènìyàn tí ń tẹ̀ lé àwọn àṣà ayé pẹ́kípẹ́kí, ó lè jẹ́ ìpènijà láti rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n Kristian fún ìwọṣọ níwọ̀ntúnwọ̀nsì.

17 Ìlànà ìwọṣọ àti ìmúra yàtọ̀ síra jákèjádò ilẹ̀ ayé. A retí pé kí àwọn Kristian wọ aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ó wà létòlétò. Ta ni ó yẹ kí ó pinnu èyí? Àwọn òbí gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn ọ̀dọ́ langba kò wọṣọ bí àwọn ọ̀dọ́ ayé. A ti pèsè ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu yíyè kooro nínú ọ̀ràn tí ń béèrè fún ìṣọ́ra yìí. A rọ̀ ọ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Kinni Aṣọ-Wíwọ̀ Túmọ̀sí fún Iwọ?” nínú Ji! August 8, 1987. Kí ni a kíyè sí nínú àwọn àpéjọpọ̀ wa mélòó kan ní ọdún tí ó kọjá?

18 A rí àkíyèsí yìí gbà, lẹ́yìn ọ̀kan nínú Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun”: “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ti ṣe dáradára sí i nínú ìwọṣọ, ìmúra, àti ìṣe wọn ní àpéjọpọ̀ ní ọdún yìí. . . . Síbẹ̀, àwọn ipò àti àṣà kan ṣì wà tí ó yẹ láti ṣiṣẹ́ lé lórí.” A ròyìn lẹ́yìn àpéjọpọ̀ mìíràn pé, a kíyè sí ìwọṣọ lọ́nà àṣerégèé lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìròyìn náà mẹ́nu kàn án pé, ìwọṣọ àwọn kan bí àwọn ẹlòmíràn nínú. Àwọn ará ìta kan tí ó pésẹ̀ pẹ̀lú kíyè sí ìwọṣọ lọ́nà àṣerégèé náà. Aṣọ àwọn kan ṣí ara wọn sílẹ̀, ó sì tún fún mọ́ wọn lára.

19 Púpọ̀ jù lọ nínú àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wọ aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ń fi ọ̀wọ̀ hàn, nígbà tí wọ́n wà ní ilẹ̀ àpéjọpọ̀. Bí àwọn alàgbà bá kíyè sí i pé àwọn kan ní ìtẹ̀sí láti wọṣọ lọ́nà àṣerégèé ní àkókò ìgbòkègbodò fàájì, yóò bójú mu láti fún wọn ní ìmọ̀ràn onínúure ṣùgbọ́n tí ó ṣe ṣàkó, ṣáájú àpéjọpọ̀ náà pé, irú ìwọṣọ bẹ́ẹ̀ kò bójú mu, pàápàá jù lọ, gẹ́gẹ́ bí àyànṣojú tí ń lọ sí àpéjọpọ̀ Kristian. Jọ̀wọ́, ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìtọ́sọ́nà lórí ìṣarasíhùwà àti ìwọṣọ tí a là lẹ́sẹẹsẹ lókè yìí, pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ tí yóò lọ sí àpéjọpọ̀ náà.

20 Kámẹ́rà àti Àwọn Ohun Tí Ń Gba Ohùn Tàbí Àwòrán Sílẹ̀: Ó yẹ láti ránni létí nípa àwọn kámẹ́rà, àti àwọn ohun èlò tí a fi ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀. Bí o bá wéwèé láti lo kámẹ́rà, ẹ̀rọ fídíò, tàbí ohun èlò èyíkéyìí tí a fi ń gba ohùn sílẹ̀, jọ̀wọ́ rántí láti gba ti àwọn tí wọ́n wà nítòsí rẹ rò. Rírìn kiri ní àkókò tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, tàbí gbígba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ láti orí ìjókòó rẹ pàápàá, lè pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà. A kò gbọdọ̀ so ohun èlò èyíkéyìí tí a fi ń gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀ mọ́ iná tàbí mọ́ ẹ̀rọ tí a fi ń bá gbogbo àwùjọ sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò gbọdọ̀ fi ohun èlò dí àwọn ọ̀nà àbákọjá tí ó wà láàárín ìjókòó tàbí ọ̀nà àrìnlọrìnbọ̀. Yálà o pinnu láti ya fọ́tò tabi gba apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sílẹ̀ lórí ẹ̀rọ fídíò tàbí lórí ẹ̀rọ tí ń gba ohùn sílẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ti ara ẹni. Àwọn àwòrán àti ohùn tí a gbà sílẹ̀ lè mú wa rántí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá tí a fẹ́ràn, nígbà tí a bá wò wọ́n tàbí gbọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn náà. A ní láti lo gbogbo irú ohun èlò bẹ́ẹ̀ tìṣọ́ratìṣọ́ra, ní ọ̀nà tí kò ní pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà tàbí dí ọ lọ́wọ́ láti jàǹfààní kíkún láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lẹ́yìn tí o bá padà sílé, àkókò yóò ha wà fún ọ láti tún gbọ́ àwọn ohùn tí o gbà sílẹ̀ bí? O lè rí i pé ṣíṣe àkọsílẹ̀ nìkan ti tó.

21 Àyè Ìjókòó: Ìwọ ha kíyè sí i pé a ṣe dáradára sí i ní ti ọ̀ràn gbígba àyè sílẹ̀, ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọrun” ti 1994? Ìtẹ̀síwájú díẹ̀ ti wà, ṣùgbọ́n, a ṣì ní láti fiyè sí ìránnilétí yìí: O LÈ GBA ÀYÈ SÍLẸ̀ FÚN KÌKÌ MẸ́ḾBÀ ÌDÍLÉ RẸ ÀTI ẸNIKẸNI TÍ Ó BÁ Ọ WÁ NÍNÚ ỌKỌ̀ AYỌ́KẸ́LẸ́ RẸ.

22 Àwọn Àpótí Ọrẹ: Ó ṣeé ṣe kí o kíyè sí i ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè tí a ṣe ní èṣí pé, Society pèsè àwọn àpótí ọrẹ tuntun fún Ilẹ̀ Àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Ìdáhùnpadà sí àwọn ìfilọ̀ tí ń rọ̀ wá láti ṣètìlẹ́yìn fún Society, nípa ṣíṣe ìtọrẹ ní àwọn àpéjọpọ̀, dára gan-an ni, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo yín fún fífi owó ṣètìlẹ́yìn fún ètò àjọ Jehofa.

23 Tíkẹ́ẹ̀tì Oúnjẹ: A rọ̀ wá láti ra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ ṣáájú àpéjọpọ̀ náà. Kí ni ète èyí? Títa tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ ṣáájú àkókò ń pèsè owó fún àpéjọpọ̀ náà fún ríra àwọn oúnjẹ tí ó ṣe kókó sílẹ̀. A ní láti ra ìrẹsì, iṣu, gaàrí, màlúù, adìyẹ, ẹ̀wà, ẹ̀fọ́, àti àwọn oúnjẹ mìíràn sílẹ̀, láti ba lè ní wọn lọ́wọ́ fún ọ̀wọ́ àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè náà. Bí ó ti sábà máa ń jẹ́, owó oúnjẹ máa ń ga sókè gan-an bí àkókò ọlidé ti ń sún mọ́lé ní December. Alábòójútó Ìpèsè Oúnjẹ fún àwọn àpéjọpọ̀ ní láti ra oúnjẹ ní àràpọ̀ ní October àti November. Ó nílò owó láti ṣe èyí. Society ń ní ìṣòro fífi owó tí ó pọ̀ tó sílẹ̀ láti fi ṣe èyí, nítorí ọ̀pọ̀ àpéjọpọ̀ tí a ń ṣe nísinsìnyí ní orílẹ̀-èdè yìí. Ìdí nìyẹn tí a fi fún ọ níṣìírí láti ra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ sílẹ̀ lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Àpéjọpọ̀. A óò wá lo owó náà láti fi ra oúnjẹ sílẹ̀. Ìwọ yóò jàǹfààní ní ríra oúnjẹ tí kò wọ́n, ní kafitéríà àti àwọn ilé ìpápánu ní àwọn àpéjọpọ̀, níwọ̀n bí a ti lè ra oúnjẹ nígbà tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́nwó.

24 Nítorí náà, a rọ àwọn alábòójútó olùṣalága àti àwọn akọ̀wé ìjọ kọ̀ọ̀kan láti ṣètò fún ríra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ sílẹ̀. Olùṣekòkáárí àpéjọpọ̀ nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan lè báni ṣe èyí. Àwọn akéde lè fi owó sílẹ̀ fún àwọn tíkẹ́ẹ̀tì, gbàrà tí a bá ti jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ní October. A gbọ́dọ̀ pa àkọsílẹ̀ mọ́. Nígbà tí a bá ra àwọn tíkẹ́ẹ̀tì náà lọ́dọ̀ Ìgbìmọ̀ Àpéjọpọ̀, a óò fi wọ́n fún àwọn akéde tí ó sanwó fún wọn. Àwọn akéde ní láti pa wọ́n mọ́ bí owó, kí wọ́n sì tọ́jú wọn dáradára. Àwọn akéde lè lo àwọn tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ náà ní kafitéríà àti àwọn ilé ìpápánu, gbàrà tí wọ́n bá ti dé sí àpéjọpọ̀. A rọ gbogbo akéde láti ra tíkẹ́ẹ̀tì oúnjẹ sílẹ̀, ó kéré tán, fún ọjọ́ méjì àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú un rọrùn láti ra oúnjẹ ní àràpọ̀ ṣáájú kí àwọn àpéjọpọ̀ tó bẹ̀rẹ̀.

25 Ṣíṣe Ìtọrẹ Oúnjẹ: A rọ̀ wá láti fi àwọn oúnjẹ tọrẹ fún àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè. Èyí lè ní oríṣiríṣi oúnjẹ tí a ń jẹ nínú, bí iṣu, ìrẹsì, gaàrí, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ẹ̀wà, ata, tòmátì, èso, ẹ̀fọ́, màlúù, adìyẹ, àti oúnjẹ mìíràn tí o lè fẹ́ láti fi tọrẹ. Ọ̀nà dídára nìyí láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà. Gbogbo oúnjẹ wọ̀nyí ni Ẹ̀ka Ìpèsè Oúnjẹ ń lò. Fífi tí o fi irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ tọrẹ yóò ran àpéjọpọ̀ náà lọ́wọ́ láti kájú ìnáwó rẹ̀ àti láti pèsè oúnjẹ ọ̀fẹ́ fún àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.

26 A ní láti ṣètò nínú ìjọ fún fífi irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀ tọrẹ àti gbígbé wọn lọ sí Ilẹ̀ Àpéjọpọ̀, gbàrà tí a bá ti jíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí. Àmọ́ ṣáá o, a ní láti gbé àwọn oúnjẹ tí ó lè bàjẹ́ lọ lákòókò tí ó yẹ, kí wọ́n má baà bàjẹ́ ṣáájú àpéjọpọ̀ àkọ́kọ́. Bí Ìgbìmọ̀ Àpéjọpọ̀ kò bá tí ì fún yín ní ìtọ́ni pàtó lórí ìgbà tí ó yẹ kí ẹ gbé àwọn oúnjẹ náà wá, ẹ lè kàn sí wọn. Àwọn akéde lè gbé oúnjẹ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé wá, nígbà tí wọ́n bá ń bọ̀ wá sí àpéjọpọ̀ náà, lọ ní tààràtà sí ilé ìkóúnjẹsí. Nígbà tí àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì lọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún fún àjọ̀dún ní àgọ́ àjọ tàbí tẹ́ḿpìlì, Deuteronomi 16:16 sọ pé, a pa á láṣẹ fún wọn pé: “Kí wọn kí ó má sì ṣe ṣánwọ́ wá iwájú OLUWA.” Wọ́n kò ní láti ronú kìkì nípa ara wọn àti ìdílé wọn, ṣùgbọ́n nípa ọrẹ tí wọn yóò fi fún ètò àjọ Jehofa pẹ̀lú. Bákan náà lónìí, a ní láti wéwèé ìtìlẹ́yìn ohun ti ara tí a óò ṣe fún ètò àjọ Jehofa.

27 Ní àfikún sí ìpèsè jíjẹun ní kafitéríà àti ilé ìpápánu, bí àwọn akéde bá fẹ́ láti jẹ oúnjẹ tí wọ́n gbé wá láti ilé lábẹ́ ibi ìjókòógbọ́rọ̀, ní àkókò ìjẹun, a yọ̀ọ̀da fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí àwọn kan bá fẹ́ láti ra oúnjẹ láti kafitéríà tàbí láti ilé ìpápánu, kí wọ́n sì gbé oúnjẹ náà sínú abọ́ ti ara wọn láti jẹ ní ibi ìjókòógbọ́rọ̀, a lè yọ̀ọ̀da fún ìyẹn. Ó ṣe pàtàkì pé, olúkúlùkù gbọ́dọ̀ palẹ̀ mọ́ lẹ́yìn oúnjẹ. Ìṣètò àpéjọpọ̀ yóò pèsè apẹ̀rẹ̀ ìdọ̀tí tí ó pọ̀ tó fún àwọn akéde láti da pàǹtí àti àwọn ohun mìíràn sí, a óò sì pèsè àwọn ohun èlò ìmọ́tótó tí ó pọ̀ tó. Bí ó bá pọn dandan fún ọ láti gbé àwọn kúlà kékeré wa, a gbà ọ́ láyè ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọn yóò bá wọlé sábẹ́ ìjókòó rẹ. Ṣùgbọ́n, a kò gbọdọ̀ gbé àwọn kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀gbẹ̀ǹgbẹ̀, irú èyí tí a ń gbé lọ sí àjò ìgbafẹ́, tàbí mú ohun mímu ọlọ́tí wá sí ibi tí a ti ń jókòó gbọ́ ọ̀rọ̀. A gbọ́dọ̀ yẹra fún jíjẹ oúnjẹ tàbí ìpápánu nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bá ń lọ lọ́wọ́. Èyí kì i fọ̀wọ̀ hàn fún oúnjẹ tẹ̀mí tí a pèsè.

28 Ní November 3, 1995, àkọ́kọ́ nínú àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” yóò bẹ̀rẹ̀. O ha ti parí àwọn ìmúrasílẹ̀ rẹ, o ha sì ti ṣe tán láti gbádùn ọjọ́ mẹ́ta ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ aláyọ̀ àti àwọn ohun rere nípa tẹ̀mí bí? Àdúrà àtọkànwá wa ni pé, kí Jehofa bù kún àwọn ìsapá rẹ láti lọ sí àpéjọpọ̀ tí ń bọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ, bí a ti ń fiyè sí bí a ṣe lè jẹ́ onídùnnú-ayọ̀ olùyin Jehofa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ìránnilétí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè

Ìbatisí: Àwọn tí yóò ṣe ìbatisí ní láti wà lórí ìjókòó wọn ní apá tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ṣáájú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ Saturday. A ti kíyè sí i pé àwọn kan ń wọ àwọn aṣọ kan tí kò buyì kúnni, tí ó sì ń tàbùkù sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Gbogbo ẹni tí ó wéwèé láti ṣe ìbatisí ní láti mú aṣọ ìwẹ̀ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì àti aṣọ ìnura wá. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ìbatisí, tí asọ̀rọ̀ sì ti gbàdúrà, alága ìjókòó yóò pèsè ìtọ́ni ráńpẹ́ fún àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìbatisí, lẹ́yìn náà, yóò sì pe orin. Lẹ́yìn ìlà tí ó kẹ́yìn, àwọn olùṣàbójútó èrò yóò darí àwọn tí ó fẹ́ ṣe ìbatisí lọ sí odò ìrìbọmi. Níwọ̀n bí ìbatisí ní ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ ẹnì kan ti jẹ́ ọ̀ràn tímọ́tímọ́ kan, tí ó sì jẹ́ ti ara ẹni, láàárín ẹni náà àti Jehofa, kò sí àyè fún ohun tí a pè ní ìbatisí alájùmọ̀ṣe, nínú èyí tí àwọn ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó fẹ́ ṣe ìbatisí ti wà mọ ara wọn tàbí di ọwọ́ ara wọn mú nígbà tí a ń batisí wọn.

Ilé Gbígbé: A tún ń béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbogbòò ní ti ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ pèsè. Bí a bá ré ìṣètò Society kọjá, tí a sì gba ilé ibùwọ̀ tí àpéjọpọ̀ ti gbà tẹ́lẹ̀, a ń jin iṣẹ́ àṣekára àwọn arákùnrin wa, tí wọ́n dúnàádúrà fún iye owó tí ó bọ́gbọ́n mu, lẹ́sẹ̀. BÍ O BÁ NÍ ÌṢÒRO LÓRÍ ILÉ IBÙWỌ̀, jọ̀wọ́, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti mú un wá sí àfiyèsí alábòójútó Ẹ̀ka Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà, kí ó baà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀ràn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àwọn akọ̀wé ìjọ ní láti rí i dájú pé àwọn fọ́ọ̀mù Special Needs Room Request ni a tètè fi ṣọwọ́ sí àdírẹ́sì àpéjọpọ̀ tí ó yẹ. Bí o bá ní láti fagi lé wíwọ̀ sí ilé ibùwọ̀ kan tí a ṣètò nípasẹ̀ ètò fún àwọn àìnì àkànṣe, o ní láti fi tó onílé náà àti Ẹ̀ka Ilé Gbígbé àpéjọpọ̀ náà létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, kí a baà lè yan iyàrá náà fún ẹlòmíràn.

Káàdì Àyà: Jọ̀wọ́, fi káàdì àyà ti 1995 sí àyà ní àpéjọpọ̀ náà àti nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò lọ sí àti láti ilẹ̀ àpéjọpọ̀ náà. Èyí sábà máa ń mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fúnni ní ìjẹ́rìí rere nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò. O ní láti gba káàdì àyà àti ike rẹ̀ nípasẹ̀ ìjọ rẹ, níwọ̀n bí wọn kì yóò ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àpéjọpọ̀ náà. Rántí láti mú káàdì Advance Medical Directive/Release rẹ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ dání. Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli àti àwọn aṣáájú ọ̀nà ní láti mú káàdì ìdánimọ̀ wọn lọ́wọ́.

Iṣẹ́ Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni: Ìwọ ha lè ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ ní àpéjọpọ̀ náà láti ṣètìlẹ́yìn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ bí? Ṣíṣiṣẹ́ sin àwọn ará wa, bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ fún kìkì wákàtí díẹ̀, lè ṣèrànwọ́, kí ó sì mú ìwọ̀n ìtẹ́lọ́rùn dáradára wá. Bí o bá lè ṣètìlẹ́yìn, jọ̀wọ́, fara hàn ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni ní àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ọmọ ọdún 16 pẹ̀lú lè ṣe ìtìlẹ́yìn dáradára nípa ṣíṣiṣẹ́ lábẹ́ ìdarí òbí kan tàbí àgbàlagbà kan tí ó ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́.

Ìkìlọ̀: Nípa wíwà lójúfò sí àwọn ìṣòro tí ó lè yọjú, a lè yọ ara wa kúrò nínú ìṣòro tí kò pọn dandan. Àwọn olè àti ènìyànkénìyàn sábà máa ń dọdẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n jìnnà sí ilé. Rí i dájú pé o ti ọkọ̀ rẹ pa nígbà gbogbo, má sì ṣe fi ohunkóhun tí ojú lè tó sílẹ̀ láti dán ẹnì kan wò láti jalè. Àwọn olè àti àwọn jáwójáwó máa ń fojú sun àwọn ìkórajọpọ̀ ńlá. Kì yóò jẹ́ ìwà ọlọgbọ́n láti fi ohunkóhun tí ó ṣe iyebíye sílẹ̀ lórí ìjókòó rẹ. O kò lè ní ìdánilójú pé gbogbo ẹni tí ó wà ní àyíká rẹ ni ó jẹ́ Kristian. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi dán ẹnikẹ́ni wò? A ti rí ìròyìn gbà nípa ìgbìdánwò àwọn ará ìta kan láti tan àwọn ọmọdé lọ. JẸ́ KÍ ÀWỌN ỌMỌ RẸ WÀ LỌ́DỌ̀ RẸ NÍGBÀ GBOGBO.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́