ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/95 ojú ìwé 8
  • Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò Pẹ̀lú Ète

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò Pẹ̀lú Ète
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìmúrasílẹ̀—Ọ̀nà Kan Ṣoṣo Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 10/95 ojú ìwé 8

Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò Pẹ̀lú Ète

1 Nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, ó yẹ kí o gbìyànjú láti lo ẹsẹ ìwé mímọ́ kan tí yóò fi kún ìmọ̀ tí ẹni náà ní nípa kókó ẹ̀kọ́ Bibeli tí o jíròrò pẹ̀lú rẹ̀ ṣáájú.

2 Ọ̀kan lára àwọn góńgó tí a fi ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí ó gba ìwé ìròyìn ni láti fìdí ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn múlẹ̀. Ìgbékalẹ̀ rírọrùn kan bí irú èyí lè gbéṣẹ́:

◼ “Mo lérò pé o gbádùn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí mo fi sílẹ̀ fún ọ, tí ó ṣàlàyé nípa ìdí tí a fi ní láti bẹ̀rù Ọlọrun. Lónìí, mo mú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan nínú ìwé ìròyìn Jí!, tí ó béèrè pé, ‘Èé Ṣe Tí Ìwàláàyè Fi Kúrú Tó Bẹ́ẹ̀?’ wá fún ọ. Ìbéèrè yẹn dára, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” O lè máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ ní sísọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jesu, tí a mọ̀ bí ẹni mowó, tí ó wà nínú Johannu 3:16, ṣe ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun. Jọ̀wọ́ gba ìwé ìròyìn yìí, kí o sì jẹ́ kí ìrètí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ síni, fún ọ níṣìírí.” Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé fún un pé ìwọ yóò padà láti mú ẹ̀dà tí ó tẹ̀ lé e wá àti, bí ó bá sì ṣeé ṣe, láti jíròrò síwájú sí i nípa ohun tí Ọlọrun ti ṣèlérí fún aráyé onígbọràn. Rántí pé, gbogbo ìgbà tí o bá mú àwọn ìwé ìròyìn náà lọ, o lè ròyìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpadàbẹ̀wò kan.

3 Bí ó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ayé kan Láìsí Ogun—Nígbà Wo?” ni o fi síta, o lè sọ pé:

◼ “Báwo ni ìgbésí ayé lórí ilẹ̀ ayé yìí yóò ṣe rí, bí kò bá sí ogun mọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jẹ́ kí n fi ohun tí Ọlọrun ti ṣèlérí láti ṣe hàn ọ́.” Ka Orin Dafidi 37:10, 11, kí o sì ṣàpèjúwe bí nǹkan yóò ṣe rí nígbà tí ìfẹ́ Ọlọrun bá di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. Rán ẹni náà létí ohun tí Jesu kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Matteu 6:9, 10. Ràn án lọ́wọ́ láti ronú lórí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jesu náà. Bí ó bá fi ojúlówó ìfẹ́ hàn, o lè fi àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! lọ̀ ọ́, kí o sì ṣètò láti padà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.

4 Bí o bá padà lọ fún ìjíròrò síwájú sí i lórí àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó wà níwájú ìwé ìròyìn náà, “Èé Ṣe Tí Ìwàláàyè Fi Kúrú Tó Bẹ́ẹ̀?” o lè bẹ̀rẹ̀ lọ́nà yìí:

◼ “Nígbà tí mo wá kẹ́yìn, a sọ̀rọ̀ nípa bí ìwàláàyè ènìyàn ti gùn tó. Gẹ́gẹ́ bí o ti kíyè sí i nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú Jí! náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nawọ́ ìrètí bín-ńtín jáde fún ríràn wá lọ́wọ́ láti wà láàyè ré kọjá 70 tàbí 80 ọdún. Ṣùgbọ́n, kí ni èrò rẹ nípa àwọn ìlérí Bibeli? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bibeli fi hàn pé Ọlọrun ní ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ìyẹn lọ lọ́kàn fún ènìyàn.” Lẹ́yìn náà, ka Johannu 17:3, kí o sì ṣàlàyé bí gbígba ìmọ̀ sọ́kàn ṣe lè sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ̀ ọ́ tàbí kí o ṣètò fún ìjíròrò Bibeli síwájú sí i, níbi tí o dé yìí.

5 Bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli jẹ́ góńgó pàtàkì kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bóyá o ti ṣe ìpadàbẹ̀wò mélòó kan sọ́dọ̀ ẹnì kan tí ó gba àwọn ìwé ìròyìn. Èé ṣe tí o kò gbìyànjú ọ̀nà ìgbàyọsíni yìí, nígbà tí o bá tún padà lọ?:

◼ “Oríṣiríṣi èrò ni àwọn ènìyàn ní nípa ìsìn àti ìníyelórí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé òde òní. Ọ̀pọ̀ ìgbàgbọ́ tí ó ta kora ni ó wà nípa ìdí tí Ọlọrun fi fàyè gba ìwà ibi tàbí ìdí tí a fi ń darúgbó, tí a sì ń kú. Àwọn kan yóò fẹ́ láti mọ bí a ṣe lè gbàdúrà kí Ọlọrun sì gbọ́ wa.” Ṣí ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde Bibeli wa sí kókó ẹ̀kọ́ kan tí o rò pé onílé náà yóò nífẹ̀ẹ́ sí, kí o sì fi bí a ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ hàn án, ní ṣókí.

6 Jehofa jẹ́ Ọlọrun ète. Ẹ jẹ́ kí a fara wé e ní October, nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò pẹ̀lú ète.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́