ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/95 ojú ìwé 8
  • Fi Ìwé Ìròyìn Lọni ní Gbogbo Ìgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìwé Ìròyìn Lọni ní Gbogbo Ìgbà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò Pẹ̀lú Ète
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 10/95 ojú ìwé 8

Fi Ìwé Ìròyìn Lọni ní Gbogbo Ìgbà

1 A ní ìdí rere fún mímọrírì Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Àwọn ìwé ìròyìn wo ni ó tún ní irú ìfanimọ́ra kárí ayé bẹ́ẹ̀? Ní oṣù yìí, a óò gbé àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí jáde lákànṣe nínú ìgbòkègbodò ìwàásù wa, ẹ sì wo irú ìsọfúnni alágbára tí ó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde ti October! Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń fi púpọ̀ jù lára àwọn ìwé ìròyìn wa síta nínú iṣẹ́ ilé dé ilé; bí ó ti wù kí ó rí, a óò fẹ́ láti gbara dì láti tún fi wọ́n lọni ní gbogbo ìgbà tí ó bá yẹ wẹ́kú.

2 Nígbà tí o bá ń fi “Ilé-Ìṣọ́nà” ti October 1 lọni, o lè ru ìfẹ́ sókè nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ayé kan Láìsí Ogun—Nígbà Wo?” nípa sísọ pé:

◼ “Ọ̀pọ̀ ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ó fi dà bíi pé ọwọ́ ènìyàn kò lè tẹ ayé kan láìsí ogun, láìka gbogbo ìsapá ènìyàn sí. Kí ni èrò rẹ nípa àwọn gbólóhùn wọ̀nyí, tí ó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti October 1, ní ojú ìwé 5? [Ka gbólóhùn àkọ́kọ́ nínú àwọn ìpínrọ̀ méjì àkọ́kọ́, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Ìsìn—Ohun Ìdènà Ńláǹlà,” kí o sì jẹ́ kí ó fèsì.] Dájúdájú, èyí kò túmọ̀ sí pé ogun yóò máa bá a lọ títí. Kíyè sí ìlérí Ọlọrun níhìn-ín ní Isaiah 9:6, 7.” O lè ka ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí láti inú Bibeli rẹ tàbí gẹ́gẹ́ bí a ti fà á yọ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà. Ṣàlàyé ní ṣókí pé, Ilé-Ìṣọ́nà ń ṣe alágbàwí Ìjọba Jehofa gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún ayé alálàáfíà, kí o sì fún ẹni náà níṣìírí láti san àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà fún ọdún kan, ní iye tí a ń fi síta.

3 Nígbà tí o bá ń fi “Jí!” October 22 lọni, o lè sọ pé:

◼ “Kí ni èrò rẹ nípa ìbéèrè tí ó wà níwájú ìwé ìròyìn yìí: ‘Èé Ṣe Tí Ìwàláàyè Fi Kúrú Tó Bẹ́ẹ̀?’ [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí pe àfiyèsí sórí ohun tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn mìíràn ní láti sọ nípa dídarúgbó, ó sì tún darí àfiyèsí sórí ohun tí Ẹlẹ́dàá wa ti ṣèlérí nípa ìfojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun.” Fi àsansílẹ̀-owó fún Jí! lọ̀ ọ́. Bí kò bá gba ìfilọni náà, fi Jí! àti Ilé-Ìṣọ́nà lọ̀ ọ́, fún ọrẹ ₦30.

4 Nígbà tí o bá bá àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn pàdé, èé ṣe tí o kò gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan nínú “Ilé-Ìṣọ́nà” ti October 15 jáde lákànṣe? Ìgbékalẹ̀ yìí lè sún ẹnì kan láti fetí sílẹ̀:

◼ “Èmi yóò fẹ́ láti mọ ojú ìwòye rẹ lórí ìbéèrè yìí: Ó ha ṣeé ṣe láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun kí a sì tún bẹ̀rù rẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan náà bí?” Jẹ́ kí ó fèsì, kí o sì ka àkọlé ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Èé Ṣe Tí A Ní Láti Bẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́ náà Nísinsìnyí?” kà. (Oniwasu 12:13) Lo ọ̀kan nínú àwọn àpèjúwe tí ó wà ní ojú ìwé 199 nínú ìwé Reasoning, kí o sì fi àsansílẹ̀-owó lọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n, bí òun kò bá gba àsansílẹ̀-owó náà, fi ìwé ìròyìn méjì lọ̀ ọ́.

5 Nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ láti ilé dé ilé, má ṣe gbójú fo àwọn ìsọ̀ kéékèèké àti àwọn ilé ìtajà dá. Àwọn tí ń ṣèbẹ̀wò sí ìsọ̀ àti àwọn ilé ìtajà déédéé ṣàlàyé ìgbòkègbodò yìí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń gbádùn mọ́ni tí ó sì ń méso jáde. O lè gbìyànjú ìgbékalẹ̀ rírọrùn bí èyí, nígbà tí o bá ń fi “Jí!” October 8 lọni:

◼ “A mọ̀ pé àwọn oníṣòwò nífẹ̀ẹ́ láti mọ àwọn ọ̀ràn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká wọn. Ó dá mi lójú pé ìwọ yóò gbádùn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí.” Ní ṣókí, ṣàjọpín kókó kan nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Tó?” pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, fi ìwé ìròyìn méjì lọ̀ ọ́, bí kò bá gba àsansílẹ̀-owó.

6 Bí ọwọ́ ẹni tí o tọ̀ lọ bá há gádígádí ní ti gidi, o lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà hàn án, kí o sì sọ pé:

◼ “Mo mọ̀ pé o kò retí àlejò kankan lónìí, nítorí náà, n óò gé ọ̀rọ̀ mi kúrú. N óò fẹ́ láti fún ọ láǹfààní láti ka ohun kan tí ó ṣe pàtàkì.” Fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o ti yàn hàn án, kí o sì fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọ̀ ọ́.

7 Pa àkọsílẹ̀ ilé dé ilé mọ́ dáradára, kí o sì padà bẹ gbogbo àwọn tí wọ́n gbá ìwé wò. Bí wọ́n bá fi ojúlówó ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, fi àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn kan tàbí méjèèjì lọ̀ wọ́n. Ẹ jẹ́ kí a múra sílẹ̀, kí a sì wà lójúfò láti fi àwọn ìwé ìròyìn wa lọni, ní gbogbo ìgbà tí ó bá yẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́