ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/96 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Apá Keje: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Mọyì Ipò Orí Tí Jèhófà Ṣètò Nínú Ìjọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 4/96 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ọ̀nà wo ni ó tọ́ láti gbà lo ọ̀rọ̀ náà “arákùnrin” àti “arábìnrin”?

Nígbà tí a bá lò ó ní olówuuru, gbólóhùn náà, “arákùnrin” àti “arábìnrin” tọ́ka sí àwọn ẹnì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ní òbí kan náà. Ipò ìbátan lọ́nà ti ẹ̀dá yìí sábà máa ń dá ìsomọ́ra ọlọ́yàyà kan sílẹ̀, ìsúnmọ́ra tí àwọn ẹni wọ̀nyí sì ń gbádùn ni ìdè ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àyíká, àti ti èrò ìmọ̀lára ń mú lókun sí i.

Jesu kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti pe Jehofa ní “Baba wa,” nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Lílo gbólóhùn ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn pé, gẹ́gẹ́ bíi Kristian, gbogbo wá jẹ́ ara agbo ìdílé sísún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí kan, níbi tí a ti ń gbádùn ipò ìbátan tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ kan. Jesu tẹnu mọ́ èyí síwájú sí i nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, “arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.”—Matt. 6:9; 23:8.

Nítorí ìdè tẹ̀mí sísún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí tí a ní láàárín agbo ilé Ọlọrun, a ń pe ara wa ní “Arákùnrin” àti “Arábìnrin,” pàápàá ní àwọn ìpàdé ìjọ. Nígbà àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀mí wọ̀nyí, ẹni tí ń darí ìpàdé mọ àwọn tí ó ti ṣe ìrìbọmi nípa lílo gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “arákùnrin” tàbí “arábìnrin” tí orúkọ ìdílé ẹni tí a ń lo gbólóhùn náà fún yóò sì tẹ̀ lé e.

Bí ẹni tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi bá fẹ́ láti kópa nínú àwọn ìpàdé ńkọ́? Nígbà tí ẹnì kan bá ti ń dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyan Jehofa fún àkókò pípẹ́, tí ó sì ń sún mọ́ àtiṣe ìyàsímímọ́, ní kíka ara rẹ̀ sí ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, kò burú láti pé “Arákùnrin” tàbí “Arábìnrin” ṣáájú orúkọ ìdílé rẹ̀. Èyí yóò jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì, bí ẹni náà bá ti di akéde tí kò tí ì ṣèrìbọmi.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sí àwọn ìpàdé wa kò tí ì gbé ìgbésẹ̀ tí yóò fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí ara agbo ilé Ọlọrun. A kì yóò pe àwọn ẹni wọ̀nyí ní “Arákùnrin” tàbí “Arábìnrin,” níwọ̀n bí ipò ìbátan tẹ̀mí ti ìdílé Ọlọrun kò ti ṣiṣẹ́ nínú ọ̀ràn tiwọn. Nítorí náà, nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, a óò pè wọ́n lọ́nà àṣà gbogbogbòò, ní lílo àpèmórúkọ tí ó bá a mu bí “Ọ̀gbẹ́ni” mọ́ orúkọ ìdílé wọn.

Lílo àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà, “arákùnrin” àti “arábìnrin” ní àwọn ìpàdé ìjọ wa ń fi ìdè tí ó túbọ̀ sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, tí ó sì túbọ̀ ṣe iyebíye ju èyíkéyìí tí lílo orúkọ àbísọ lè fi hàn lọ. Ó ń rán wa létí ipò ìbátan oníbùkún tí a ń gbádùn gẹ́gẹ́ bí ìdílé tẹ̀mí lábẹ̀ Baba kan, Jehofa Ọlọrun. A tún ń rán wa létí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìfẹ́ni tí a ní fún ara wa lẹ́nì kíní-kejì.—Efe. 2:19; 1 Pet. 3:8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́