Ìwọ Ha Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Alákòókò Kíkún Bí?
1 Ìwọ ha lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí ìbéèrè yí bí? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà olùṣèyàsímímọ́ ni ó lè forúkọ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, kò ha bọ́gbọ́n mu láti retí pé kí gbogbo wa wo ara wa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀ alákòókò kíkún bí? Dájúdájú, ó yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀.
2 Kò gbọ́dọ̀ sí irú ohun tí a ń pè ní Kristẹni aláàbọ̀ àkókò. Jésù sọ nípa Bàbá rẹ̀ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòh. 8:29) Pọ́ọ̀lù, ẹni tí ó nímọ̀lára bẹ́ẹ̀, rọ̀ wá láti “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Nítorí náà, ní gbogbo ọ̀nà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ ka ara wa sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà alákòókò kíkún. Ríronú tí a bá ń ronú lọ́nà yí yóò nípa lórí wa fún rere nínú gbogbo ìgbòkègbodò tí a bá ń lépa.
3 Gbé Ẹ̀rí náà Yẹ̀ Wò: Ìrísí, ọ̀rọ̀, àti ìwà wa lè fi han àwọn ẹlòmíràn pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní tòótọ́. A máa ń wà lójúfò nípa àìní náà fún ìrísí oníwọ̀ntúnwọ̀nsì, ọ̀rọ̀ tí ó gbámúṣé, àti ìwà tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu nígbàkigbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí tí a bá pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Ṣùgbọ́n, yálà a ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, a ń ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, tàbí a ń kópa nínú eré ìnàjú, ohun gbogbo tí a bá ń ṣe gbọ́dọ̀ fúnni ní ẹ̀rí pé a ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n òdodo Jèhófà.
4 Jésù sọ pé: “Ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá. . . . Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.” (Mát. 5:14-16) Èyí gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe àti nígbà gbogbo. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ láé pé a ń lọ́ tìkọ̀ láti jẹ́rìí nítorí ibi tí a wà tàbí ohun tí a ń ṣe, ó yẹ kí a béèrè lọ́wọ́ ara wa pé, ‘Èmi ha ń sin Jèhófà ní àkókò kíkún tàbí ní ààbọ̀ àkókò bí?’ Ǹjẹ́ kí a má ṣe jẹ́ kí àǹfààní láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kọjá wa láé.
5 Rántí pé a ń bọlá fún Jèhófà a sì ń mú inú rẹ̀ dùn nígbà tí a bá lè fi “Bẹ́ẹ̀ ni!” tí ó dún lọ réré dáhùn ìbéèrè náà, “Ìwọ Ha Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Alákòókò Kíkún Bí?”