ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/97 ojú ìwé 8
  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àkànṣe Ìgbòkègbodò Tá A Ó Ṣe Láàárín February 19 sí March 18!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • ‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Jẹ́ “Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà” ní April!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 10/97 ojú ìwé 8

Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò

1 October àti November yóò jẹ́ oṣù tí ọwọ́ gbogbo wa yóò dí. Ní ọjọ́ mọ́kànlá àkọ́kọ́ ní October, a óò fi àsansílẹ̀ owó fún yálà Jí! tàbí Ilé Ìṣọ́ tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì lọni. Lẹ́yìn náà, láti Sunday, October 12, títí di Sunday, November 16, a óò dara pọ̀ nínú ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 35 kárí ayé. Àǹfààní ni yóò jẹ́ fún wa láti mú ìhìn iṣẹ́ pàtàkì kan lọ sọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn tí ó wà ní àdúgbò wa. Ó jẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè náà, “Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?” Nígbà ìgbétásì àkànṣe yìí, a óò pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 ní àárín ọ̀sẹ̀. Ní àfikún sí fífúnni ní Ìròyìn Ìjọba ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀, a óò fi àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni. Níbi tí a kò bá ti gba àsansílẹ̀ owó, ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà ni a lè fi lọni.

2 Àwọn Wo Ni Ó Lè Nípìn-Ín Nínú Rẹ̀? Bí ó ti máa ń rí, àwọn alàgbà ni yóò mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ náà. Gbogbo ènìyàn ni ó ń gbádùn pípín Ìròyìn Ìjọba kiri, láìsí àní àní, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn akéde yóò forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nínú oṣù kan tàbí méjèèjì tí a óò fi ṣe ìgbétásì náà. Àwọn akéde yòó kù yóò fẹ́ láti lò ju àkókò tí wọ́n ti máa ń lò tẹ́lẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

3 Ìwọ ha ní akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó ti tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nínú ìwé Ìmọ̀, tí yóò sì tóótun láìpẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá bí? Bóyá ó lè di akéde tí kò tí ì ṣe batisí láìpẹ́ jọjọ kí ó lè kópa nínú ìgbétásì Ìròyìn Ìjọba. Ìgbékalẹ̀ rírọrùn ni gbogbo ohun tí a nílò láti nasẹ̀ ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Fún àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè sọ pé: “Ìhìn iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi ń pín in kiri jákèjádò ayé ní oṣù yí ní 169 èdè. Èmi yóò fẹ́ kí o ní ẹ̀dà tìrẹ.” Àní àwọn ọmọ kéékèèké pàápàá lè nípìn-ín tí ó nítumọ̀ nínú iṣẹ́ tí ń runi lọ́kàn sókè yí.

4 Kí àwọn olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ fún gbogbo mẹ́ńbà àwùjọ wọn níṣìírí láti nípìn-ín nínú ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 35. Àwọn akéde kan lè wà pẹ̀lú tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n lè di aláápọn lẹ́ẹ̀kan sí i nínú iṣẹ́ ìsìn bí wọ́n bá gba ìṣírí tí wọ́n nílò. Ṣáájú ìgbétásì yí, kí àwọn alàgbà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí lọ́kọ̀ọ̀kan láti rí ohun tí wọ́n lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá àwọn akéde onírìírí ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí.

5 Ìgbà Wo Ni A Lè Pàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn? Gbogbo ìgbòkègbodò yí yóò béèrè fún àwọn ìṣètò fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ tí ó rọrùn tí ó sì gbéṣẹ́. Níbikíbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, ìpàdé iṣẹ́ ìsìn ni kí a ṣètò fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láàárín ọ̀sẹ̀, ní òpin ọ̀sẹ̀, àti ní ìrọ̀lẹ́. Kí a ṣe é ní àwọn àkókò tí yóò ṣeé ṣe fún àwọn akéde àti àwọn aṣáájú ọ̀nà láti lo àǹfààní sáà ìjẹ́rìí náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. A tún lè ṣètò láti pàdé ní ọwọ́ ọ̀sán pátápátá fún àǹfààní àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ láṣegbà, àti àwọn mìíràn. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ tó wà fún ìjẹ́rìí ilé dé ilé àti ní ibi iṣẹ́ ajé, kí gbogbo àwọn ará lè nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ náà. Níbi tí àwọn akéde púpọ̀ bá ti wà ní àgbègbè kan, wọ́n gbọ́dọ̀ lo òye nípa iye àwọn tí yóò ṣiṣẹ́ ní apá kan pàtó nínú ìpínlẹ̀ náà.

6 Àwọn Kò-Sí-Nílé Ńkọ́? A fẹ́ fúnra wa bá àwọn onílé púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó sọ̀rọ̀ kí a lè ṣàlàyé ìdí tí ó fi yẹ kí wọ́n ka Ìròyìn Ìjọba No. 35. Nítorí náà bí ẹnikẹ́ni kò bá sí nílé nígbà tí o ṣe ìkésíni, kọ àdírẹ́sì ibẹ̀ sílẹ̀ kí o tún pa dà ṣe ìkésíni ní àkókò míràn. Bí àwọn ìsapá rẹ láti kàn sí onílé wọ̀nyí kò bá tí ì yọrí sí rere títí di ọ̀sẹ̀ tí ó kẹ́yìn fún ìgbétásì náà, o lè fi ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba náà sílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà níbi tí àwọn tí ń kọjá lọ kò ti lè rí i. Ní àwọn àgbègbè tí àwọn ènìyàn ń gbé, wà lójúfò láti fi Ìròyìn Ìjọba lọ àwọn tí ó lè máa rìn lọ lójú pópó. Nígbà tí ẹ bá ń ṣiṣẹ́ ní àwọn àgbègbè ìgbèríko àti níbi tí ìpínlẹ̀ púpọ̀ wà ju ohun tí ẹ lè kárí nígbà ìgbétásì náà, a lè fi ẹ̀dà kan Ìròyìn Ìjọba sílẹ̀ fún àwọn kò-sí-nílé nígbà ìkésíni àkọ́kọ́.

7 Kí Ni Ète Ìlépa Wa? Kí àwọn ìjọ sakun láti lo gbogbo ìpèsè Ìròyìn Ìjọba láti kárí ìpínlẹ̀ wọn kí ìgbétásì náà tó parí ní November 16. Bí ìpínlẹ̀ tí a yàn fún ìjọ rẹ bá tóbi gan-an, bí dídáṣiṣẹ́ dípò bíbá ẹlòmíràn ṣiṣẹ́ kò bá sì léwu, o lè rí i pé ó gbéṣẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni yíyẹ púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Mát. 10:11) Ó lè ṣàǹfààní láti kó ìwé àṣàrò kúkúrú mélòó kan dání, kí o sì fi Bíbélì sínú àpò aṣọ rẹ tàbí sínú àpamọ́wọ́, dípò gbígbé àpò. Rí i dájú pé o pa àkọsílẹ̀ pípéye mọ́ nípa ibi tí wọ́n ti fi ìfẹ́ hàn.

8 O Ha Ti Ṣe Tán Láti Bẹ̀rẹ̀ Bí? Ó yẹ kí àwọn alàgbà ronú ṣáájú nípa iye àfikún ìwé ìròyìn tí ìjọ yóò nílò, kí wọ́n sì kọ̀wé béèrè fún iye náà. Ẹ kò ní láti kọ̀wé béèrè fún Ìròyìn Ìjọba No. 35, níwọ̀n bí a ti ń kó wọn ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, aṣáájú ọ̀nà déédéé, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yóò gba 60 ẹ̀dà láti pín kiri nígbà tí a óò pín 20 ẹ̀dà fún akéde ìjọ kọ̀ọ̀kan. A ti pín iṣẹ́ wa fún wa. Ìwọ ha ń hára gàgà láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò dídùnmọ́ni jọjọ yìí bí? Láìsí àní àní ìwọ ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a pín ìhìn iṣẹ́ tí a gbé ka Bíbélì tí ó wà nínú Ìròyìn Ìjọba No. 35 yìí kiri lọ́nà tí ó gbòòrò jù lọ bí ó bá ti ṣeé ṣe tó!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́