Ilẹ̀kùn Ńlá sí Ìgbòkègbodò Ṣí Sílẹ̀
1 Gẹ́gẹ́ bí onítara oníwàásù ìhìn rere, Pọ́ọ̀lù fi ìháragàgà ṣàwárí àwọn ìpínlẹ̀ tí àìní pọ̀ sí jù, èyí tí ìlú Éfésù jẹ́ ọ̀kan nínú rẹ̀. Òun ṣàṣeyọrí tó bẹ́ẹ̀ nínú wíwàásù níbẹ̀ tí ó fi kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀ fún mi.” (1 Kọ́r. 16:9) Pọ́ọ̀lù ń bá a nìṣó láti sìn ní ìpínlẹ̀ yẹn, ó sì ran ọ̀pọ̀ àwọn ará Éfésù lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́.—Ìṣe 19:1-20, 26.
2 Lónìí, a ti ṣí ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò sílẹ̀ fún wa. A ń ké sí wa láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìjọ tí kò ṣeé ṣe fún láti ṣe gbogbo ìpínlẹ̀ wọn kúnnákúnná lọ́dọọdún. Nípa báyìí, ìsapá wa lè kúnjú àìní tí ó wà ní àwọn àgbègbè kan.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 8:13-15.
3 Ìwọ Ha Lè Sìn Níbi Tí Àìní Pọ̀ sí Jù Bí? Ìwọ ha ti ronú tàdúràtàdúrà ní ti ṣíṣeéṣe náà pé kí o sìn níbòmíràn bí? Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ran ìjọ kan lọ́wọ́ ní ìlú tí o wà gan-an. Èé ṣe tí o kò fi bá alábòójútó àyíká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà kí o sì gbọ́ ohun tí yóò dábàá? Tàbí ó lè jẹ́ pé nínú ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ, ọ̀pọ̀ odi tàbí ọ̀pọ̀ àwọn tí ń sọ èdè àjèjì wà tí kò tí ì sí ẹni tí ó lè bójú tó wọn. Láti kúnjú àìní yìí, ìwọ ha lè lo ara rẹ tokunratokunra láti kọ́ èdè wọn bí? Síwájú sí i, bóyá ìjọ tàbí àwùjọ tí ń sọ èdè míràn wà nítòsí tí wọ́n ti ‘ń bẹ Ọ̀gá fún àwọn òṣìṣẹ́ Ìjọba púpọ̀ sí i.’ (Mát. 9:37, 38) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ha lè ṣèrànwọ́ bí?
4 Ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé Kristẹni ti ṣí lọ sí àwọn ilẹ̀ míràn láti nípìn-ín ní kíkún sí i nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Tọkọtaya kan tí ó ṣe èyí sọ pé: “A fẹ́ sin Jèhófà níbi tí a ti lè ṣe dáadáa jù lọ.” Bí o bá ní ìfẹ́ ọkàn yí tí o sì rí i pé ó ṣeé ṣe láti ṣí lọ sí ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè yí tàbí bí o bá tóótun láti sìn ní ilẹ̀ míràn, kọ́kọ́ jíròrò ìwéwèé rẹ pẹ̀lú àwọn alàgbà ìjọ rẹ.
5 Bí o bá fẹ́ láti béèrè lọ́wọ́ Society nípa ibi tí àìní gbé wà, fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ ní lẹ́tà tí ó ṣàlàyé ìfẹ́ ọkàn rẹ ní pàtó. Wọn yóò fi àlàyé wọn kún un, wọn yóò sì fi í ránṣẹ́ sí Society. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ilẹ̀kùn ńlá sí ìgbòkègbodò bá ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—1 Kọ́r. 15:58.