Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Alábàáṣègbéyàwó Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí
1 Ìdùnnú ńlá ló jẹ́ nígbà tí tọkọtaya bá so pọ̀ ṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́. Ṣùgbọ́n, nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, ọ̀kan ṣoṣo nínú àwọn alábàáṣègbéyàwó náà ni ó tí ì tẹ́wọ́ gba ọ̀nà òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn alábàáṣègbéyàwó tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí kí a sì fún wọn níṣìírí láti jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú wa?—1 Tím. 2:1-4.
2 Mọ Èrò Wọn: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alábàáṣègbéyàwó kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè ṣàtakò, lọ́pọ̀ ìgbà, ìṣòro náà sábà máa ń jẹ́ nítorí ìwà ìdágunlá tàbí àṣìlóye. Ẹnì kan lè nímọ̀lára pé a pa òun tì tàbí kí ó máa jowú nítorí ọkàn ìfẹ́ tẹ̀mí tí alábàáṣègbéyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ní. Ọkọ kan rántí pé: “Ní dídánìkanwà ní ilé, mo ní ìmọ̀lára pé a kọ̀ mi tì.” Òmíràn sọ pé: “Mo nímọ̀lára bí ẹnipe aya mi ati awọn ọmọ mi ńfi mi silẹ.” Àwọn ọkùnrin kan lè ronú pé ṣe ni ìsìn kan fẹ́ gba ìdílé àwọn mọ́ wọn lọ́wọ́. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1990, ojú ìwé 20 sí 23.) Ìdí nìyẹn tí ó fi dára jù lọ pé kí a jẹ́ kí ọkọ wà pẹ̀lú aya rẹ̀ nínú ìṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé láti ìbẹ̀rẹ̀ bí ó bá ṣeé ṣe.
3 Ẹ Jùmọ̀ Ṣiṣẹ́ Pọ̀: Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan ṣiṣẹ́ pọ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tọkọtaya láti wá sínú òtítọ́. Lẹ́yìn tí arábìnrin náà bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú aya, arákùnrin náà yóò ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ọkọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ṣeé ṣe fún arákùnrin náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọkọ.
4 Jẹ́ Ẹni Tí Ó Yá Mọ́ni Kí O Sì Lẹ́mìí Aájò Àlejò: Àwọn ìdílé nínú ìjọ lè ṣèrànwọ́ nípa fífi ìfẹ́ ọkàn hàn nínú àwọn ìdílé tí kò tí ì ṣọ̀kan síbẹ̀ nínú ìjọsìn tòótọ́. Ìbẹ̀wò ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ díẹ̀ lè ran alábàáṣègbéyàwó tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ láti rí i pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àwọn Kristẹni ọlọ́yàyà àti olùbìkítà tí wọ́n ní ire dídára jù lọ gbogbo ènìyàn lọ́kàn.
5 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn alàgbà lè ṣàyẹ̀wò àwọn ìsapá tí a ti ṣe lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn alábàáṣègbéyàwó tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí kí wọ́n sì pinnu ohun tí a tún lè ṣe ní ríretí pé a óò jèrè wọn fún Jèhófà.—1 Pét. 3:1, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW.