Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún November
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 3
Orin 48
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. “Ìhìn Rere Lórí Ìsokọ́ra Alátagbà Internet.” Sọ̀rọ̀ lórí iṣẹ́ ìsìn pápá fún oṣù July, ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ àdúgbò.
15 min: “Ilẹ̀kùn Ńlá sí Ìgbòkègbodò Ṣí Sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà, àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fún gbogbo àwọn tí ó bá lè nàgà fún nínípìn-ín tí ó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀. Fi àwọn ìmọ̀ràn díẹ̀ tí a pèsè nínú Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1988, ojú ìwé 22 kún un.
20 min: “Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìròyìn Ìjọba.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó wà ní ìpínrọ̀ 6. Nínú ọ̀kan lára wọn, fi bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan hàn.
Orin 144 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 10
Orin 51
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ fún ìjọ nípa ìpínlẹ̀ tí ó ṣì kù láti mú Ìròyìn Ìjọba No. 35 dé. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti nípìn-ín kíkún nínú ọ̀sẹ̀ tí ó kẹ́yìn nínú ìgbétáásì àkànṣe yìí.
15 min: Àìní àdúgbò.
20 min: “Ẹ Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Alábàáṣègbéyàwó Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí.” Ìjíròrò láàárín alàgbà méjì tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa títúbọ̀ dojúlùmọ̀ àwọn alábàáṣègbéyàwó aláìgbàgbọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Wọ́n tún ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tí a pèsè nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1989, ojú ìwé 17 àti 18, ìpínrọ̀ 6 sí 9. Fi àwọn ìrírí kún un láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, October 1, 1995, ojú ìwé 10 àti 11, ìpínrọ̀ 11 àti 12.
Orin 148 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 17
Orin 53
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìnáwó. Ṣe ìfilọ̀ àwọn ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀. Sọ àwọn ìrírí àdúgbò díẹ̀ tí a ní nígbà ìgbétáásì Ìròyìn Ìjọba No. 35.
20 min: Lo Àǹfààní Aláìlẹ́gbẹ́ Yìí! Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, November 15, 1996, ojú ìwé 21 sí 23.
15 min: “Kí Ni Èmi Yóò Sọ?” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ ní ojú ìwé 8 nínú ìwé Reasoning, ṣàlàyé bí a ṣe pète ìwé náà láti ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí lọ́nà gbígbéṣẹ́ lórí onírúurú àkòrí Bíbélì. Fi àwọn àṣefihàn kan tàbí méjì tí a múra sílẹ̀ dáadáa ṣàkàwé.
Orin 151 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní November 24
Orin 56
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: Ìwà Tí Ó Dára Ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. A mọrírì ẹ̀mí aájò àlejò àwọn ìdílé tí wọ́n ṣí ilé wọn sílẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ. Èyí lè ní ìmúrasílẹ̀ àti àìrọgbọ púpọ̀ nínú. Nígbà tí a bá pésẹ̀ síbẹ̀, ó yẹ kí a hùwà lọ́nà tí ó dára kí a sì fi ọ̀wọ̀ àti ìgbatẹnirò hàn, èyí tí yóò ní àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú: (1) Kí a fara balẹ̀ nu ẹsẹ̀ wa kí a tó wọlé, kí a má baà dọ̀tí ilẹ̀ tàbí kápẹ́ẹ̀tì. (2) Kí àwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn, ní rírí i dájú pé wọ́n hùwà dáadáa kí wọ́n má sì kọjá àgbègbè tí a yàn nínú ilé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. (3) Nígbà tí ó jẹ́ pé àwùjọ náà lè kéré tí ipò náà sì lè má fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ bí àṣà, ìpàdé ìjọ ni èyí jẹ́, ó sì yẹ kí a wọṣọ bí a ti máa ń ṣe nígbà tí a bá ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. (4) A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ lẹ́yìn ìpàdé ṣe ṣókí kí agboolé náà bá lè ni àkókò àdálò fún ara wọn. (5) Nígbà tí ó jẹ́ pé agboolé náà, níbi tí a ti ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lè yàn lẹ́kọ̀ọ̀kan láti pèsè ìpápánu díẹ̀ lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́, gbogbo àwùjọ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ retí ìyẹn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì pọn dandan.
22 min: Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn, Ní Kíkọ́ Wọn. Alàgbà darí ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ akéde mẹ́ta tàbí mẹ́rin, ní dídáhùn àwọn ìbéèrè tí a gbé karí ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 88 sí 92: (1) Èé ṣe tí ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò fi ṣe kókó fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó gbéṣẹ́? Báwo ni ẹnì kan ṣe lè kojú ìpèníjà iṣẹ́ ìpadàbẹ̀wò? (2) Èé ṣe tí a fi ń tẹnu mọ́ bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gidigidi? Báwo ni a ṣe lè di ọ̀jáfáfá nínú dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́? (3) Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti darí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ètò àjọ náà? Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí? Àwùjọ náà tún ṣàlàyé bí àwọn àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ti June 1996 àti March àti April 1997 ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ ní àwọn àgbègbè yí.
Orin 160 àti àdúrà ìparí.