Kí Ni Èmi Yóò Sọ?
Nígbà tí a bá bá àwọn ènìyàn pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n dáhùn padà lọ́nà rere, a máa ń fẹ́ láti pa dà lọ láti jẹ́rìí fún wọn síwájú sí i. Ṣùgbọ́n, ohun tí a óò sọ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò tí ó tẹ̀ lé e lè máà dá wa lójú. O lè gbìyànjú ìyọsíni yìí: Gbé ìbéèrè kan tí ń fani lọ́kàn mọ́ra dìde, lẹ́yìn náà kí o sì ṣí ìwé Reasoning láti fi ìdáhùn tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu hàn. Yóò ṣèrànwọ́ bí o bá ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìbéèrè nínú èyí tí o ti lè yan ọ̀kan tí o ronú pé àwọn ènìyàn yóò dáhùn pa dà sí lọ́nà tí ó dára jù lọ nígbà ìkésíni pàtó kan. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó wà nísàlẹ̀, tí a kó jọ láti inú ìwé Reasoning, fi nọ́ńbà ojú ìwé tí a ti lè rí ìdáhùn kọ̀ọ̀kan hàn:
◼ Èé ṣe tí a fi ń darúgbó tí a sì ń kú? (98)
◼ Àwọn ìdí yíyè kooro ha wà fún níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run bí? (145)
◼ Ọlọ́run ha bìkítà ní ti gidi nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwa ènìyàn bí? (147)
◼ Ènìyàn ha ní láti lọ sí ọ̀run kí ó tó lè ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ ní tòótọ́ bí? (163)
◼ Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì láti mọ orúkọ Ọlọ́run, kí a sì máa lò ó? (196)
◼ Kí ni ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe? (227)
◼ Kí ni ète ìgbésí ayé ènìyàn? (243)
◼ Èé ṣe tí ìsìn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi wà? (322)
◼ Báwo ni ẹnì kan ṣe lè mọ ìsìn tí ó tọ̀nà? (328)
◼ Báwo ni Sátánì ti jẹ́ ẹ̀dá alágbára tó nínú ayé òde òní? (364)
◼ Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? (393)
◼ Èé ṣe tí ìwà ibi púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi wà? (427)
Ìwọ lè fi irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ sínú Bíbélì tàbí ìwé Reasoning rẹ fún ìtọ́kasí kíákíá. Níní ohun kan pàtó lọ́kàn láti sọ nígbà ìpadàbẹ̀wò yóò fún ọ níṣìírí láti jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú pípadàṣiṣẹ́ lórí gbogbo ọkàn ìfẹ́ tí o bá rí.